Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 71


Ìpín 71

Ìfihàn ti a fifún Wòlíì Joseph Smith àti Sidney Rigdon, ni Hiram, Ohio, 1 Oṣù Kejìlá 1831. Wòlíì náà ti tẹ̀síwájú láti túmọ̀ Bíbélì pẹ̀lú Sidney Rigdon bíi akọ̀wé rẹ̀ títí tí a fi gba ìfihàn yìí, ní àkókò èyí tí wọ́n pa á tì sí ẹ̀gbẹ́ kan fún igbà díẹ̀ ná kí ó le fún wọn ní ààyè lati mú ìtọ́sọ́nà tí a fún wọn níhĩnyí ṣẹ. Àwọn arákùnrin níláti jade lọ láti wàásù pẹ̀lú ètò láti mú ìmọ̀lára àìṣọ̀rẹ́ kúrò èyí tí ó ti ngbèrú tako Ǐjọ ní àyọrísí ti àtẹ̀jáde ti àwọn ìwé kíkọ láti ọwọ́ Ezra Booth, ẹni tí ó ti yapa.

1–4, Joseph Smith àti Sidney Rigdon ni a rán jade láti kéde ìhìnrere; 5–11, Àwọn ọ̀tá àwọn Èniyàn Mímọ́ ni wọn yíò dààmú.

1 Ẹ kíyèsíi, báyìí ni Olúwa wí fún yín ẹ̀yin ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, àti Sidney Rigdon, pé àkókò náà ti dé lõtọ́ tí ó jẹ́ dandan àti tí ó tọ́ ní ojú mi pé kí ẹ̀yin ó ya ẹnu yín ní kíkéde ìhìnrere mi, àwọn ohun ti ìjọba náà, ní sísọ àsọyé àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìbẹ̀ láti inú àwọn ìwé mímọ́, gẹ́gẹ́bí apákan ti Ẹ̀mí àti agbára èyi tí a ó fi fún yín, àní bí èmi ṣe fẹ́.

2 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ kéde sí gbogbo ayé ní àwọn agbègbè yíkáàkiri, àti nínú ìjọ bákannáà, fún àyè àkókò kan, àní títí tí a ó fi sọọ́ di mímọ̀ fún yín.

3 Lõtọ́ èyi jẹ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún ìgbà kan, èyí tí èmi fi fún yín.

4 Nítorínáà, ẹ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà ajarà mi. Ẹ ké pe gbogbo àwọn olùgbé orí ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì jẹ́rìí, kí ẹ sì tún ọ̀nà ṣe fún àwọn òfin àti àwọn ìfihàn tí wọn yíò dé.

5 Nísisìyí, ẹ kíyèsíi èyí jẹ́ ọgbọ́n; ẹni tí ó bá kàá, ẹ jẹ́kí òun ní òye kí ó sì gbà bákannáà.

6 Nítorí sí ẹni tí ó bá gbà á ní a ó fi fún ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ síi, àní agbára.

7 Nísisìyí, ẹ dààmú àwọn ọ̀tá yín; ẹ pè wọ́n láti pàdé yín ní gbangba àti ní ìkọ̀kọ̀; àti níwọ̀nbí ẹ̀yin bá jẹ́ olõtọ́ ìtìjú wọn ni a ó fi hàn.

8 Nísisìyí, ẹ jẹ́ kí wọn ó mú àwọn èrèdí wọn tí ó ní agbára jáde wá ní ìdojúkọ Olúwa.

9 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí fún yín—kò sí ohun ijà kan tí wọ́n ṣe láti dojúkọ yín tí yíò ṣe rere;

10 Àti pé bí ẹnìkan bá gbé ohùn rẹ̀ sókè takò yín a ó dà á láàmú ní àkókò tí ó tọ́ lójú mi.

11 Nísisìyí, ẹ pa àwọn òfin mi mọ́; wọ́n jẹ́ òtítọ́ àti òdodo. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.