Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 16


Ìpín 16

Ìfihàn tí a fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Peter Whitmer Kékeré, ní Fayette, New York, Oṣu Kẹfà 1829. (wo àkọlé sí ìpín 14). Peter Whitmer Kekere di ọ̀kan nínú Àwọn Ẹlérìí Mẹ́jọ fún ìwé Ti Mọ́mọ́nì lẹ́hìn náà.

1–2, Apá Olúwa wà kárí gbogbo ilẹ̀ ayé; 3–6, Láti wàásù ìhìnrere àti láti gba àwọn ọkàn là ni ohun tí ó níye ní orí jùlọ.

1 Fetísílẹ̀, ìránṣẹ́ mi Peter, kí o sì tẹ́tísí àwọn ọ̀rọ̀ ti Jésu Krísti, Olúwa rẹ àti Olùràpadà rẹ.

2 Nítorí kíyèsíi, èmi sọ̀rọ̀ sí ọ pẹ̀lú ohùn mímú àti pẹ̀lú agbára, nítorí apá mi wà ní orí gbogbo ilẹ̀ ayé.

3 Àti pé èmi yíò sọ àwọn nkan fún ọ tí èniyàn kankan kò mọ̀ bíkòṣe èmi àti ìwọ nìkan—

4 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ìwọ ti fẹ́ mọ̀ lati ọ̀dọ̀ mi èyíinì tí yíó ní iye ní orí jùlọ sí ọ.

5 Kíyèsíi, ìbùkún ni fún ọ nítorí ohun yìí, àti fún sísọ àwọn ọ̀rọ̀ mi èyí tí mo ti fi fún ọ gẹ́gẹ́bí àwọn òfin mi.

6 Àti nísisìyí, kíyèsíi, mo wí fún ọ, pé ohun tí yíó níye ní orí fún ọ jùlọ ni lati kéde ironúpìwàdà sí àwọn ènìyàn yìí, kí ìwọ baà lè mú àwọn ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí ìwọ baà lè sinmi pẹ̀lú wọn nínú ìjọba Bàbá mi. Amin.