Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 47


Ìpín 47

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 8 Oṣù Kejì 1831. John Whitmer, ẹnití ó ti sìn tẹ́lẹ̀rí bíi akọ̀wé sí Wòlíì, kọ́kọ́ lọ́ra nígbàtí wọ́n sọ fún un láti sìn bíi olùkọ̀tàn àti alákọsílẹ̀ Ìjọ, ní dídípò Oliver Cowdery. Ó kọ pé, “Èmi ìbá má ti ṣe é ṣùgbọ́n mo wòye pé ìfẹ́ ti Olúwa ni ṣíṣe, àti bí òun bá fẹ́ ẹ, èmi fẹ́ pé kí ó fi hàn nípasẹ̀ Jóseph Aríran náà.” Lẹ́hìn tí Joseph Smith gba ìfihàn yìí, John Whitmer fi ara mọ́ ọ ó sì sìn ní ipò iṣẹ́ tí a yàn án sí.

1–4 John Whitmer ni a yàn láti pa ìtàn ìjọ mọ́ àti láti kọ̀wé fún Wòlíì.

1 Kíyèsíi, ó tọ́ lójú mi pé kí ìránṣẹ́ mi John ó kọ̀wé kí òun sì pa ìtàn ìjọ mọ́ déédé, àti kí ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ, ìránṣẹ́ mi Joseph, ní ṣíṣe ìtumọ̀ gbogbo èyí tí a ó fi fún ọ, títí tí a ó fi pè é fún àwọn iṣẹ́ míràn síwájú.

2 Lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni èmi wí fún ọ pé bákannáà òun lè gbé ohùn rẹ̀ sókè nínú àwọn ìpàdé, nígbà-kúùgbà tí èyí bá tọ́.

3 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún ọ pé a ó yàn án fún un láti pa àwọn àkọsílẹ̀ ìjọ mọ́ àti ìwé ìtàn nígba gbogbo; nítorí Oliver Cowdery ni Èmí ti yàn sí ipò iṣẹ́ míràn.

4 Nítorínáà, a ó fi fún un, níwọ̀n ìgbàtí òun bá jẹ́ olõtọ́, nípa Olùtùnú náà, láti kọ àwọn nkan wọ̀nyí. Àní bẹ́ẹ̀ ni. Amin.