Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 18


Ìpín 18

Ìfihàn sí Wòlíì Joseph Smith, Oliver Cowdery, àti David Whitmer, tí a fi fúnni ní Fayette, New York, Oṣú Kẹfà 1829. Gẹ́gẹ́bí Wòlíì ti sọ, ìfihàn yìí sọọ́ di mímọ̀ “ìpè ti àwọn àpóstélì méjìlá ní àwọn ọjọ́ tí ó gbẹ̀hìn wọ̀nyí, àti bákannáà àwọn òfin tí ó ní í ṣe sí mímú Ìjọ dàgbà.”

1–5 Àwọn ìwé mímọ́ fi ọ̀nà tí a lè fi gbé ìjọ kalẹ̀ hàn, 6–8, Ayé nbàjẹ́ síi nínú àìṣedéédé; 9–16, Àwọn ọkàn ṣe iyebíye púpọ̀; 17–25, Láti jẹ èrè ìgbàlà, àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ gba orúkọ Krísti sí orí wọn; 26–36, Pípè àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn Méjìlá ni a fi hàn; 37–39, Oliver Cowdery àti David Whitmer yíò ṣe àwárí àwọn Méjìlá; 40–47, Láti jẹ èrè ìgbàlà, àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà, kí a sì rì wọ́n bọmi, kí wọ́n ó sì pa àwọn òfin mọ́.

1 Nísisìyí, kíyèsíi, nítorí ohun eyítí ìwọ, ìransẹ́ mi Oliver Cowdery, ti ní ìfẹ́ lati mọ̀ nípasẹ̀ mi, mo fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún ọ.

2 Kíyèsíi, mo ti fi hàn fún ọ, nípa Ẹ̀mí mi nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpẹrẹ, pé awọn ohun tí ìwọ ti kọ jẹ́ òtítọ́; nítorínáà ìwọ mọ̀ pé wọ́n jẹ́ òtítọ́.

3 Àti pé bí ìwọ bá mọ̀ pé wọ́n jẹ́ òtítọ́, kíyèsíi, èmi fi òfin kan fún ọ, pé kí ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ohun tí a ti kọ.

4 Nítorí nínú wọn ni a kọ ohun gbogbo sí nípa ìpìlẹ̀ ìjọ mi, ìhìnrere mi, àti àpáta mi.

5 Nítorínáà, bí ìwọ yíò bá kọ́ ìjọ mi lé orí ìpìlẹ̀ ìhìnrere mi àti àpáta mi, àwọn ẹnu ọ̀nà ọ̀run àpãdì kì yíò lè borí rẹ.

6 Kíyèsíi, ayé nbàjẹ́ nínú àìṣedéédé; ó sì di gbígbọdọ̀ ṣe pé kí a rú àwọn ọmọ ènìyàn sókè sí ironúpìwàdà, àti àwọn Kèfèrí àti bákannáà ìdílé Isráelì.

7 Nítorínáà, bí a ṣe ti rì ọ́ bọmi láti ọwọ́ ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, gẹgẹbí èyíinì tí mo pàṣẹ fún un, òun ti ṣe ohun tí mo pa láṣẹ fún un.

8 Àti nísisìyí, kí ẹnu máṣe yà ọ pé mo ti pè é fún ètò tèmi, ètò èyítí ó jẹ́ mímọ̀ nínú mi; nítorí èyí, bí òun yíò bá jẹ́ aláìṣèmẹ́lẹ́ ní pípa àwọn òfin mi mọ́ òun yíò di alábùkún fún sí ìyè ayérayé; àti pé orúkọ rẹ̀ ni Joseph.

9 Àti nísisìyí, Oliver Cowdery, èmi bá ọ sọ̀rọ̀, àti bákannáà sí David Whitmer, nípa ọ̀na àṣẹ; nítorí, kíyèsíi, mo pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbigbogbo láti ronúpìwàdà, àti pé mo wí fún yín, àní bíi sí Paul Àposteli mi, nítorí a pè yín àní pẹ̀lú ìpè kannáà pẹ̀lú èyítí a pè òun.

10 Rántí, àwọn ọkàn ṣe iyebíye púpọ̀ níwájú Ọlọ́run;

11 Nítorí, kíyèsíi, Olúwa Olùràpadà yín jìyà ikú nínú ẹran ara; nítorínáà òun jìyà fún ìrora gbogbo ènìyàn, kí gbogbo ènìyàn lè ronúpìwàdà kí wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

12 Àti pé òun ti tún jí dìde kúrò nínú òkú, kí òun lè mú gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ní orí ìpinnu ironúpìwàdà.

13 Àti pé báwo ni ayọ̀ rẹ̀ ti pọ̀ tó ní orí ọkàn tí ó ronúpìwàdà!

14 Nítorínáà, a pè yín láti kígbe ironúpìwàdà sí àwọn ènìyàn yìí.

15 Bí ó bá sì rí bẹ́ẹ̀ pé ẹ̀yin ṣe làálàá ní gbogbo ọjọ́ ayé yín ní kíkígbe ironúpìwàdà sí àwọn ènìyan yìí, tí ẹ̀yin sì mú, bí ó ṣe ọkàn kan péré wá sí ọ̀dọ̀ mi, báwo ni ayọ̀ yín yíò ṣe pọ̀ tó pẹ̀lú rẹ̀ ní ìjọba Bàbá mi!

16 Àti nísisìyí, bí ayọ̀ yín yíò bá pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan tí ẹ̀yin mú wá sí ọ̀dọ̀ mi sínú ìjọba Bàbá mi, báwo ni ayọ̀ yín yíò ṣe pọ̀ tó bí ẹ̀yin bá lè mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ mi!

17 Kíyèsíi, ẹ̀yin ní ìhìnrere mi níwájú yín, àti àpáta mi, àti ìgbàlà mi.

18 Ẹ béèrè ní ọwọ́ Bàbá ní orúkọ mi pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ní gbígbàgbọ́ pé ẹ̀yin yío rí gbà, ẹ̀yin yíò sì ní Ẹ̀mí Mímọ́, èyítí ó nfi ohun gbogbo hàn tí ó wúlò fún àwọn ọmọ ènìyàn.

19 Àti pé bí ẹ̀yin kò bá ní ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, ẹ̀yin kò lè ṣe ohunkóhun.

20 Ẹ máṣe ja ìjàdù pẹ̀lú ìjọ kankan, bíkòṣe pé ó bá jẹ́ ìjọ ti èṣù.

21 Ẹ gba orúkọ Jésu sí orí yín, kí ẹ sì sọ òtítọ́ pẹ̀lú ìronújinlẹ̀.

22 Àti pé iye àwọn tí wọ́n bá ronúpìwàdà tí a sì rìbọmi ní orúkọ mi, èyí tíí ṣe Jésu Krísti, àti ti wọ́n forítì í dé òpin, àwọn kannáà ni a ó gbàlà.

23 Kíyèsíi, Jésu Krísti ni orúkọ tí Bàbá fi fúnni, àti pé kò sí orúkọ míràn tí a fi fúnni nípa èyí tí ènìyàn lè rí ìgbàlà.

24 Nítorínáà, gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ gba orúkọ náà sí orí ara wọn èyítí Bàbá fi fúnni, nítorí nínú orúkọ yìí ni a ó pè wọ́n ní ọjọ́ ìkẹhìn;

25 Nítorínáà, bí wọn kò bá mọ orúkọ èyí tí a fi pè wọ́n, wọn kì yíò lè ní ààyè nínú ìjọba Bàbá mi.

26 Àti nísisìyí, kíyèsíi, àwọn kan wà tí a pè láti kéde ìhìnrere mi, sí àwọn Kèfèrí àti sí àwọn Júù.

27 Bẹ́ẹ̀ni, àní àwọn méjìlá; àti pé àwọn Méjìlá náà yíó jẹ́ ọmọ ẹ̀hìn mi, wọn yíò sì gba orúkọ mi sí orí wọn; àti pé àwọn Méjìlá náà ni àwọn tí yíò ní ìfẹ́ láti gba orúkọ mi sí orí wọn pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrò ọkàn.

28 Àti pé bí wọ́n bá ní ìfẹ́ láti gba orúkọ mi sí orí wọn pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrò ọkàn, a pè wọ́n láti lọ sí gbogbo ayé láti wàásù ìhìnrere mi sí gbogbo ẹ̀dá.

29 Àti pé àwọn ni àwọn náà tí a ti yàn láti ọwọ́ mi láti rìbọmi ní orúkọ mi, gẹ́gẹ́bí èyítí a ti kọ;

30 Àti pé ìwọ ní èyí tí a ti kọ níwájú rẹ; nítori èyí, o gbọ́dọ̀ ṣe e gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti kọ.

31 Àti nísisìyí èmi báa yín sọ̀rọ̀, ẹ̀yin Méjìlá—Ẹ kíyèsíi, oore ọ̀fẹ́ mi tó fún yin; ẹ gbọ́dọ̀ rìn ní títọ́ níwájú mi kí ẹ sì máṣe dẹ́ṣẹ̀.

32 Àti, kíyèsíi, ẹ̀yin ni awọn náà tí a yàn láti ọwọ́ mi lati yan àwọn àlùfáà àti àwọn olùkọ́ni; lati kéde ìhìnrere mi, gẹ́gẹ́bí agbára Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó wà nínú yin, àti gẹ́gẹ́bí àwọn ìpè àti àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run sí àwọn ènìyàn;

33 Àti pé èmi, Jésu Krísti, Olúwa yín àti Ọlọ́run yín, ti sọ ọ́.

34 Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kìí ṣe lati ọ̀dọ̀ awọn ènìyàn tàbí láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan; ṣùgbọ́n lati ọ̀dọ̀ mi; nítorínáà, ẹ̀yin yíò jẹ́rìí síi pé wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ mi, kìí sìí ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn.

35 Nítorí ohùn ti èmi ni èyítí ó sọ wọ́n jade fún yín; nítorí a fi wọ́n fúnni nípa Ẹ̀mí mi síi yín, àti nípa agbára mi ẹ̀yin le kà wọ́n, ẹ̀nìkan sí ẹlòmíràn; àti pé bíkòṣe nípa agbára mi ẹ̀yin kò lè ní wọn.

36 Nítorínáà, ẹ̀yin le jẹ́rìí pé ẹ ti gbọ́ ohùn mi, ẹ̀yin sì mọ àwọn ọ̀rọ̀ mi.

37 Àti nísisìyí, kíyèsíi, èmi fi fún ọ, Oliver Cowdery, àti bákannáà fún David Whitmer, pé ẹ̀yin yíò ṣe àwárí àwọn Méjìlá, tí wọn yíò ní ìfẹ́ inú èyí tí mo ti sọ nípa rẹ̀;

38 Àti nípa àwọn ìfẹ́ inú wọn àti àwọn iṣẹ́ wọn ni ẹ̀yin yíò mọ̀ wọ́n.

39 Àti pé nígbàtí ẹ̀yin bá ti rí wọn ẹ̀yin yíò fi àwọn nkan wọ̀nyí hàn sí wọn.

40 Ẹ̀yin yíò sì wólẹ̀, ẹ ó sí bu ọlá fún Bàbá ní orúkọ mi.

41 Àti pé ẹ̀yin gbọ́dọ̀ wàásù fún ayé, ní sísọ pé: Ẹ gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà kí a sì ṣe ìrìbọmi fún yín, ní orúkọ Jésu Krísti;

42 Nítorí gbogbo ènìyàn ni wọ́n gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà kí wọ́n sì rì wọ́n bọmi, kìí sìí ṣe ọkùnrin nìkan, ṣùgbọ́n àti àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé tí wọ́n ti dé awọn ọdún ìjíhìn.

43 Àti nísisìyí, lẹ́hìn tí ẹ bá ti gba èyí, ẹ̀yin gbọ́dọ̀ pa àwọn òfin mi mọ́ nínú ohun gbogbo.

44 Àti pé láti ọwọ́ yín èmi yíò ṣe iṣẹ́ yíyanilẹ́nu kan láàrin àwọn ọmọ ènìyàn, sí fífi dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ lójú ní ti awọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí wọ́n ó lè wá sí ironúpìwàdà, àti pé kí wọn ó lè wá sí ìjọba Bàbá mi.

45 Nítorínáà, àwọn ìbùkún tí èmi fi fún yín ju ohun gbogbo lọ.

46 Àti pé lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá ti gba èyí, bí ẹ̀yin kò bá pa àwọn òfin mi mọ́, a kì yíò gbà yín là nínú ìjọba Bàbá mi.

47 Kíyèsíi, èmi, Jésù Krístì, Olúwa yín àti Ọlọ́run yín, àti Olùràpadà yín, nípa agbára Ẹ̀mí mi ni mo sọ ọ́. Amin.