Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 70


Ìpín 70

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Hiram, Ohio, 12 Oṣù Kọkànlá 1831. Ìtan ti Wòlíì sọ pé àwọn ìpàdé àpéjọpọ̀ pàtàkì mẹ́rin ni a ti ṣe láti ọjọ́ kínní sí ọjọ́ kejìlá Oṣù Kọkànlá, àwọn ọjọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú. Nínú èyí tí ó kẹ́hìn àwọn ìpéjọ̀pọ̀ wọ̀nyí, jíjẹ́ pàtàkì púpọ̀ ti àwọn ìfihàn tí a ó tẹ̀ ní ẹ̀hìnwá bíi Book of Commandments (Ìwé àwọn Òfin) àti nígbànáà Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ní a gbéyẹ̀wò. Ìfihàn yíì ni a fifúnni lẹ́hìn tí ìpàdé àpéjọpọ̀ náà ti dìbò pé àwọn ìfihàn náà “níye ní orí sí Ìjọ bíi àwọn ọrọ̀ ti gbogbo Ilẹ̀ Ayé.” Ìtàn ti Joseph Smith tọ́ka sí àwọn ìfihàn náà bíi “ìpìlẹ̀ Ìjọ̀ ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn wọ̀nyí, àti ànfààní kan sí aráyé, tí ó nfihàn pé àwọn kọ́kọ́rọ́ ti àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Olùgbàlà wa ni a tún fi lé ọwọ́ ènìyàn lẹ́ẹ̀kansíi.”

1–5, A yan àwọn ìríjú láti kéde àwọn ìfihàn náà; 6–13, Àwọn tí wọ́n ṣe lãlã nínú àwọn ohun ti ẹ̀mí yẹ fún ọ̀yà wọn; 14–18, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ níláti dọ́gba nínú àwọn ohun ti ara.

1 Ẹ kíyèsíi, ẹ sì fetísílẹ̀, Áà ẹ̀yin olùgbé Síónì, àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ijọ mi tí ẹ wà ní ọ̀nà jíjìn, ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí mo fi fún ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, àti bákannáà sí ìránṣẹ́ mi Martin Harris, àti bákannáà sí ìránṣẹ́ mi Oliver Cowdery, àti bákannáà sí ìránṣẹ́ mi John Whitmer, àti bákannáà sí ìránṣẹ́ mi Sidney Rigdon, àti bákannáà sí ìránṣẹ́ mi Willam W. Phelps, nípa ọ̀nà òfin sí wọn.

2 Nítorí èmi fi òfin kan fún wọn; nísisìyí ẹ fetísílẹ̀ kí ẹ sì gbọ́, nítorí báyìí ni Olúwa wí fún wọn—

3 Èmi, Olúwa, ti yàn wọ́n, mo sì ti ṣe yíyàn wọn láti jẹ́ ìríjú ní orí àwọn ìfihàn àti àwọn àṣẹ náà tí èmi ti fi fún wọn, àti tí èmi yíò fi fún wọn lẹ́hìnwá;

4 Àti pé ìṣirò iṣẹ́ ìríjú yìí ni èmi yíò béèrè lọ́wọ́ wọn ní ọjọ́ ìdájọ́.

5 Nítorínáà, èmi ti yàn fún wọn, èyí sì ni iṣẹ́ wọn nínú ìjọ Ọlọ́run, láti ṣe àmójútó wọn àti àwọn àníyàn wọn, bẹ́ẹ̀ni, àwọn ànfàní ibẹ̀.

6 Nítorínáà, òfin kan ni èmi fi fún wọn, pé wọn kì yíò fi àwọn ohun wọ̀nyí fún ìjọ, tàbí fún aráyé;

7 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀nbí wọ́n bá gbà ju ohun tí ó wúlò fún àwọn àìní ati ohun ti wọ́n fẹ́ lọ, ó nílati jẹ́ fífi fún ile ìṣúra mi;

8 Àti pé àwọn ànfàní náà ni a ó yà sí mímọ́ fún àwọn olùgbé Síónì, àti sí àwọn ìràn wọn, níwọ̀nbí wọ́n bá di àjogún gẹ́gẹ́bí àwọn òfin ti ìjọba náà.

9 Kíyèsíi, èyí ni ohun tí Olúwa nbéèrè lọ́wọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú iṣẹ́ ìríjú rẹ̀, àní bí èmi, Olúwa, ti yàn tàbí tí yíò yàn lẹhìnwá sí ẹnikẹ́ni.

10 Sì kíyèsíi, a kò yọ ẹnikẹ́ni kúrò nínú òfin yìí àwọn ẹnití wọ́n jẹ́ ara ti ìjọ Ọlọ́run alààyè;

11 Bẹ́ẹ̀ni, kìí ṣe bíṣọ́pù, kìí ṣe aṣojú tí ó nṣe ìpamọ́ ìlé ìsúra ti Olúwa, kìí ṣe ẹni tí a yàn sí iṣẹ́ ìríjú ní orí àwọn ohun ti ara.

12 Ẹni náà tí a yàn láti ṣe ìpínfúnni àwọn ohun ti ẹ̀mí, òun kan náà yẹ fún owó iṣẹ́ rẹ̀, àní bíi àwọn wọnnì tí a yàn sí iṣẹ́ ìríjú láti ṣe ìpínfúnni àwọn ohun ti ara;

13 Bẹ́ẹ̀ni, àní ní púpọ̀ síi, èyí tí púpọ̀ rẹ̀ jẹ́ ní ìlọ́po fún wọn nípasẹ̀ àwọn ìfarahàn ti Ẹ̀mí.

14 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nínú àwọn ohun ti ara, ẹ̀yin níláti dọ́gba, àti èyí kì íṣe pẹ̀lú ìlọ́ra, bíbẹ́ẹ̀kọ́ àwọn ìfarahàn ti Ẹ̀mí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ó dá dúró.

15 Nísisìyí, òfin yìí ni èmi fi fún àwọn ìránṣẹ́ mi fún ànfààní wọn níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá dúró, fún ìfarahàn àwọn ìbùkún mí ní orí wọn, àti fún èrè aápọn wọn àti fún ààbò wọn;

16 Fún oúnjẹ àti fún aṣọ; fún ogún ìní kan; fún àwọn ilé àti fún àwọn ilẹ̀, ní èyíkéyìí ipò tí èmi, Olúwa, lè fi wọ́n sí, àti níbikíbi tí èmi, Olúwa, yíò rán wọn lọ.

17 Nítorí wọ́n ti jẹ́ olõtọ́ nínú àwọn ohun púpọ̀, wọ́n sì ti ṣe dáradára níwọ̀nbí wọn kò ti dá ẹ̀ṣẹ̀.

18 Ẹ kíyèsíi, èmi, Olúwa, jẹ́ alàánú èmi yíò sì bùkún wọn, wọn yíò sì wọ inú ayọ̀ àwọn nkan wọ̀nyí. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.