Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 83


Ìpín 83

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Independence, Missouri, 30 Oṣù Kẹrin 1832. A gba ìfihàn yìí bí Wòlíì ṣe jókòó nínú ìgbìmọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀.

1–4, Àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé ní ẹ̀tọ́ lọ́dọ̀ àwọn ọkọ àti àwọn bàbá wọn fún àtilẹ́hìn wọn; 5–6, Àwọn opó àti àwọn ọmọ òrúkàn (aláìní òbí) ní ẹ̀tọ́ lọ́dọ̀ Ìjọ fún àtilẹ́hìn wọn.

1 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí, ní àfikún sí àwọn òfin ti ìjọ nípa àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àwọn tí wọ́n jẹ́ ti ìjọ, tí wọ́n ti pàdánù àwọn ọkọ tàbí àwọn bàbá wọn:

2 Àwọn obìnrin ní ẹ̀tọ́ lọ́dọ̀ àwọn ọkọ wọn fún ìtọ́jú, títí tí Olúwa yíò fi mú wọ́n kúrò; àti pé bí a kò bá rí wọn bíi arúfin wọn yíò ní àjùmọ̀kẹ́gbẹ́ nínú ìjọ.

3 Àti pé bí wọ́n kò bá jẹ́ olõtọ́ wọn kì yíò ní àjùmọ̀kẹ́gbẹ́ nínú ìjọ; síbẹ̀ wọ́n lè wà ní orí àwọn ogún ìní wọ́n gẹ́gẹ́bí àwọn òfin ilẹ̀ náà.

4 Gbogbo àwọn ọmọdé ni wọ́n ní ẹ̀tọ́ lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn fún ìtọ́jú títí tí wọn yíò fi dàgbà tó lati dá dúró.

5 Àti lẹ́hìn náà, wọ́n ní ẹ̀tọ́ lọ́dọ̀ ìjọ, tàbí ní ọ̀nà míràn níbi ilé ìṣura Olúwa, bí àwọn òbí wọn kò bá ní ọ̀nà lati lè fún wọn ní àwọn ogún ìní.

6 Ilé ìṣúra náà ni a ó sì pa mọ́ nípa àwọn ohun tí a yà sí mímọ́ fún ìjọ; àti àwọn opó àti àwọn ọmọ òrukàn (aláìní òbí) ni a ó máa pèsè fún, bíi ti àwọn tálákà bákannáà. Àmín.