Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 92


Ìpín 92

Ìfihàn tí a fi fúnWòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 15 Oṣù Keta 1833. Ìfihàn náà kọ́ Frederick G. Williams, ẹnití a ṣẹṣẹ̀ yàn sí ipò olùdámọ̀ràn sí Joseph Smith, lóri àwọn ojúṣe rẹ̀ nínú Ilé Iṣẹ́ Ìṣọ̀kan (wo àwọn àkọlé sí àwọn ìpín 78 àti 82).

1–2, Olúwa fi òfin kan fúnni tí ó ní í ṣe sí ìgbaniwọlé sí ètò ìṣọkan náà.

1 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí, èmi fi fún ètò ìṣọ̀kan náà, tí a ṣe ètò ní ìbámu sí òfin tí a fi fúnni ṣíwájú, ìfihàn àti òfin kan nípa ìránṣẹ́ mi Frederick G. Williams, pé ẹ̀yin yíò gbà á sínú ètò náà. Ohun tí èmi wí fún ẹnìkan mo wí fún gbogbo ènìyàn.

2 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, èmi wí fún ọ ìránṣẹ́ mi Frederick G. Williams, ìwọ yíò jẹ́ alákíkanjú ọmọ ẹgbẹ́ nínú ètò yìí; àti níwọ̀nbí ìwọ bá jẹ́ olõtọ́ ní pípa gbogbo àwọn òfin ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ìwọ yíò dí ẹni ìbùkún títí láéláé. Àmín.