Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 61


Ìpín 61

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní etí bèbè Odò Missouri, Mcllwaine’s Bend, 12 Oṣù Kẹjọ 1831. Ní ìrinàjò wọn padà sí Kirtland, Wòlíì náà àti àwọn alàgbà mẹ́wã ti rin ìrìnàjò sí ìsàlẹ̀ Odò Missouri nínú àwọn ọkọ̀ ọlọ́pọ́n. Ní ọjọ́ kẹta nínú ìrìnàjò wọn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewu ni wọ́n ní ìrírí rẹ̀. Alàgbà William W. Phelps, nínú ìran ọ̀sán-gangan, rí apanirun náà tí ó nkáàkiri nínú agbára ní ojú omi.

1–12, Olúwa ti pàṣẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìparun ní ojú àwọn omi; 13–22, A fi àwọn omi náà bú nípasẹ̀ John, apanirun náà sì nkáàkiri ojú wọn; 23–29, Àwọn díẹ̀ ní agbára láti pàṣẹ fún àwọn omi náà; 30–35, Àwọn alàgbà yíò rìn ìrìnàjò ní méjì méjì wọ́n yíò sì wàásù ìhìnrere; 36–39, Wọ́n yío múrasílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn.

1 Ẹ kíyèsíi, kí ẹ sì fetísílẹ̀ sí ohùn ẹni náà tí ó ni gbogbo agbára, ẹni tí ó jẹ́ láti àìlópin dé àìlópin, àní Álfà àti Òmégà, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin.

2 Kíyèsíi, lõtọ́ báyìí ni Olúwa wí fún yín, Áà ẹ̀yin alàgbà ìjọ mi, ẹ̀yin tí ẹ péjọ pọ̀ sí ibí yìí, ẹ̀nití a ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì nísisìyí, nítorí èmi, Olúwa, ndárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jì, mo sì kún fún àánú sí àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn;

3 Ṣùgbọ́n lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé kò nílò kí gbogbo ọ̀wọ́ àwọn alàgbà mi yìí máa yára lọ ní orí àwọn omi, nígbàtí àwọn olùgbé ní ẹ̀gbẹ́ kan tàbí èkejì nṣègbé nínú àìgbàgbọ́.

4 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi faradà á pé kí ẹ̀yin lè jẹ́rìí; kíyèsíi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewu ni ó wà ní ojú àwọn omi náà, àti ní pàtàkì jù lẹ́hìnwá;

5 Nítorí èmi, Olúwa, ti pàṣẹ nínú ìbínú mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìparun sí orí àwọn òmi; bẹ́ẹ̀ni, àti ní pàtàkì ní orí àwọn omi wọ̀nyí.

6 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, gbogbo ẹran ara wà ní ọwọ́ mi, ẹnití ó bá sì jẹ́ olõtọ́ láàrin yín kì yíò parun nípasẹ̀ àwọn omi náà.

7 Nísisìyí, ó jẹ́ dandan pé kí ìránṣẹ́ mi Sidney Gilbert àti ìránṣẹ́ mi William W. Phelps ó yára ní orí iṣẹ́ tí a rán wọn àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn.

8 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi kò lè faradà á pé kí ẹ pínyà títí tí a ó fi báa yín wí fún gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀yin ó lè jẹ́ ọ̀kan, kí ẹ má baà ṣègbé nínú ìwà búburú;

9 Ṣùgbọ́n nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí, ó jẹ́ dandan fúnmi pé kí ẹ̀yin ó pínyà. Nítorínáà ẹ jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi Sidney Gilbert àti William W. Phelps mú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn ti tẹ́lẹ̀, kí wọ́n ó sì yára rin ìrìnàjò wọn kí wọ́n ó lè ṣe àṣeparí ìṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, àti nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, wọn yíò borí;

10 Àti níwọ̀nbí wọ́n bá ṣe olõtọ́ a ó pa wọ́n mọ́, àti pé, èmi, Olúwa, yíò wà pẹ́lu wọn.

11 Ẹ sì jẹ́kí àwọn yìókù mú èyíinì tí wọ́n nílò fún aṣọ wíwọ̀.

12 Ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Sidney Gilbert mú èyíinì tí wọn kò nílò pẹ̀lú rẹ̀, gẹ́gẹ́bí ẹ̀yin yíò ṣe fi ọwọ́ síi.

13 Àti nísisìyí, ẹ kíyèsíi, fún ire yín ni èmi fún yín ní òfin kan nípa àwọn ohun wọ̀nyí; àti pé èmi, Olúwa, yíò sọ àsọyé pẹ̀lú yín gẹ́gẹ́bí pẹ̀lú àwọn èniyàn ti ọjọ́ ìgbàanì.

14 Kíyèsíi, èmi, Olúwa, ní àtètèkọ́ṣe ti fi ìbùkún fún àwọn omi náà; ṣùgbọ́n ni àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn, nípa ọ̀rọ̀ ẹnu ìránṣẹ́ mi John, èmi fi àwọn omi náà bú.

15 Nítorínáà, àwọn ọjọ́ nbọ̀ tí kì yíò sí ẹran ara kankan tí yíò wà ní àìléwu ní orí àwọn omi náà.

16 A ó sì sọ ní àwọn ọjọ́ tí ó nbọ̀ pé kò sí ẹnikan tí ó lè gòkè lọ sí ilẹ̀ Síónì ní orí àwọn omi náà, ṣùgbọ́n ẹni náà tí ó ní ọkàn títọ́.

17 Àti, bí èmi, Olúwa, ní àtètèkọ́ṣe ti fi ilẹ̀ náà bú, àní bẹ́ẹ̀ni ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn èmi ti ṣúre fún un, ní àkókò rẹ̀, fún ìlò àwọn ẹni mímọ́ mi, pé kí wọ́n lè kópa nínú ọ̀rá ibẹ̀.

18 Àti nísisìyí mo fí òfin kan fún yín pé ohun tí èmi wí fún ẹnikan mo wí fún ẹni gbogbo, pé ẹ̀yin yíò ti kìlọ̀ ṣaájú fún àwọn arákùnrin yín nípa àwọn omi wọ̀nyí, pé kí wọn ó máṣe wá ní rírin ìrìnàjò gba orí wọn, bí bẹ́ẹ̀kọ́ kí ìgbàgbọ́ wọn má baà yẹ̀ kí wọ́n sì bọ́ sínú àwọn ìkẹkùn;

19 Èmi, Olúwa, ti pàṣẹ, apanirun náà sì nkáàkiri ní ojú wọn, èmi kò sì yí òfin náà padà.

20 Èmi, Olúwa, bínú síi yín ní àná, ṣùgbọ́n lónìí ìbínú mi ti yípadà kúrò.

21 Nísisìyí, ẹ jẹ́kí àwọn wọnnì nípa àwọn tí èmi ti sọ̀rọ̀, tí wọn yíò rin ìrìnàjò ní kánkán—lẹ́ẹ̀kansíi mo wí fún yín, kí wọ́n ó rin ìrìnàjò wọn ní kánkán.

22 Kò sì jẹ́ ohun kan fún mi, ní àìpẹ́, bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ pé wọ́n ṣe àṣeparí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, bóyá wọ́n lọ nípa omi tàbí nípa ilẹ̀; ẹ jẹ́ kí èyí ó rí bí a ṣe sọọ́ di mímọ̀ fún wọn gẹ́gẹ́bí àwọn ìdájọ́ wọn lẹ́hìnwá.

23 Àti nísisìyí, nípa ti àwọn ìránṣẹ́ mi, Sidney Rigdon, Joseph Smith Kékeré, àti Oliver Cowdery, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n ó tún wá sí orí àwọn omi náà mọ́, bíkòṣe ní orí ipa omi lílà, nígbàtí wọ́n bá nrìn ìrìnàjò lọ sí ìlé wọn; tàbí ní ọ̀nà míràn wọn kì yíò wá sí orí àwọn omi náà lati rin ìrìnàjò, bíkòṣe ní orí àwọn ipa omi lílà.

24 Ẹ kíyèsíi, èmi, Olúwa, ti yan ọ̀nà kan fún rírin ìrìnàjò àwọn ẹni mímọ́ mi, ẹ sì kíyèsíi, èyí ni ọ̀nà náà—pe bí wọ́n bá ti kúrò ní orí ipa omi lílà náà wọn yíò rin ìrìnàjò ní orí ilẹ̀, níwọ̀nbí a bá ṣe pàṣẹ fún wọn láti rìn ìrìnàjò kí wọn ó sì gun òkè lọ sí ilẹ̀ Síónì;

25 Wọn yíò sì ṣe bíi ti àwọn ọmọ Isráẹlì, ní pípa àwọn àgọ́ wọn sí ẹ̀bá ọ̀nà.

26 Àti pé, ẹ kíyèsíi, òfin yìí ni ẹ̀yin yíò fi fún gbogbo àwọn arákùnrin yín.

27 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, sí ẹnití a fi agbára fún láti pàṣẹ fún àwọn omi, sí òun náà ni a fi fún nípasẹ̀ Ẹ̀mí láti mọ gbogbo ọ̀nà rẹ̀;

28 Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí òun ṣe bí Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè bá ṣe pàṣẹ fún un, ìbáàṣe ní orí ilẹ̀ tàbí ní orí àwọn omi, bí ó ṣe wà pẹ̀lú mi láti ṣe lẹ́hìnwá.

29 Àti pé ẹ̀yin ni a fún ní ipa ọ̀nà náà fún àwọn ẹni mímọ́, tàbí ọ̀nà fún àwọn ẹni mímọ́ tí wọ́n jẹ́ ara ọ̀wọ́ ti Olúwa, láti rin ìrìnàjò.

30 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, àwọn ìránṣẹ́ mi, Sidney Rigdon, Joseph Smith Kékeré, àti Oliver Cowdery, kì yíò la ẹnu wọn nínú ìpéjọpọ̀ àwọn ènìyàn búburú títí tí wọn yíò fi dé Cincinnati;

31 Níbẹ̀ ni wọn yíò sì ti gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run lòdì sí àwọn ènìyàn náà, bẹ́ẹ̀ni, sí ẹni náà tí ìbínú rẹ̀ ru sókè sí ìwà búbúrú wọn, àwọn ènìyàn tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ gbó tán fún ìparun.

32 Àti láti ibẹ̀ ẹ jẹ́ kí wọ́n ó rin ìrìnàjò lọ sí àwọn ìpéjọpọ̀ àwọn arákùnrin wọn, nítorí a fẹ́ iṣẹ́ wọn àní nísisìyí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ síi láàrin wọn ju láàrin ìpéjọpọ̀ àwọn ènìyàn búburú.

33 Àti nísisìyí, nípa àwọn ìyókù, ẹ jẹ́kí wọn ó rin ìrìnàjò kí wọ́n ó sì kéde ọ̀rọ̀ náà lààrin ìpéjọpọ̀ àwọn ènìyàn búburú, níwọ̀nbí a ti fi í fúnni;

34 Àti níwọ̀nbí wọ́n bá ṣe èyí wọn yíò fọ aṣọ wọn mọ́, wọn yíò sì wà láìní àbàwọ́n níwájú mi.

35 Ẹ sì jẹ́kí wọn ó rìn ìrìnàjò papọ̀, tàbí ní méjì méjì, bí ó bá ṣe dára sí wọn, kìkì pé ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Reyolds Cahoon, àti ìránṣẹ́ mi Samuel H. Smith, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi, ó má ṣe yapa títí tí wọn yíò fi padà sí ilé wọn, èyí sì jẹ́ nítorí èrò ọgbọ́n kan nínú mi.

36 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín, àti pé ohun tí èmi bá wí fún ẹnikan mo wí fún ẹni gbogbo, ẹ tújúká, ẹ̀yin ọmọ kékèké; nítorí èmi wà láàrin yín, èmi kò sì tíì kọ̀ yín sílẹ̀;

37 Àti níwọ̀nbí ẹ̀yin ti rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú mi, àwọn ìbùkún ti ìjọba náà jẹ́ ti yín.

38 Ẹ di àmùrè yín ati kí ẹ máa sọ́ra kí ẹ sì máa ronújinlẹ̀, ní fífi ojú sọ́nà fún bíbọ̀ Ọmọ Ènìyàn, nítorí òun yíò dé ní wákàtí tí ẹ̀yin kò lérò.

39 Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo kí ẹ̀yin ó má baà bọ́ sínú ìdánwò, kí ẹ̀yin baà lè dúró de ọjọ́ bíbọ̀ rẹ̀, ìbáàṣe ní yíyè tàbí ní kíkú. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.