Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 136


Ìpín 136

Ọ̀rọ̀ náà àti ìfẹ́ inú Olúwa, tí a fifúnni nípasẹ̀ Àrẹ Brigham Young ní Winter Quarters, ní ibùdó ti Ísráẹ́lì, Orílẹ̀-èdè Omaha, ní ìwọ̀ oòrùn bèbè odò Missouri, nítòsí Council Bluffs, Iowa.

1–16, Bí ikọ̀ ti Ísráẹ́lì yíò ṣe jẹ́ títò fún ìrìnàjò sí ìhà ìwọ̀ oòrùn ni a ṣe àlàyé; 17–27, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ni a pàṣẹ fún láti gbé nípa àwọn àkàìníye òsùnwọ̀n ìhìnrere; 28–33, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ yíò kọrin, jó, gbàdúrà, àti kọ́ ọgbọ́n; 34–42, Àwọn wòlíì ni a pa kí wọ́n ó lè di ẹni ìdálọ́lá àti kí àwọn ẹni búburú le ní ìdálẹ́bi.

1 Ọ̀rọ̀ àti Ìfẹ́ Inú Olúwa nípa Àgọ́ Ísráẹ́lì nínú àwọn ìrìnàjò wọn sí Ìwọ̀ oòrùn:

2 Kí gbogbo àwọn ènìyàn ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, àti àwọn tí wọ́n nrìnrìnàjò pẹ̀lú wọn, ó jẹ́ síṣètò sí àwọn ọ̀wọ́, pẹ̀lú májẹ̀mú kan àti ìlérí láti pa gbogbo àwọn òfin àti àwọn ìlànà Olúwa Ọlọ́run wa mọ́.

3 Kí àwọn ọ̀wọ́ náà kí ó jẹ́ síṣètò pẹ̀lú àwọn balógun ti àwọn ọgọ́rũn, àwọn balógun ti àwọn àádọ́ta, àti àwọn balógun ti àwọn mẹ́wã, pẹ̀lú ààrẹ kan àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ méjì bí olórí wọn, lábẹ́ ìdarí àwọn Àpóstélì Méjìlá.

4 Èyí ni yíò sì jẹ́ májẹ̀mú wa—pé àwa yíò rìn nínú gbogbo àwọn ìlànà Olúwa.

5 Kí ọ̀kọ̀kan ọ̀wọ́ ó pèsè fún ara wọn pẹ̀lú gbogbo àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn kẹ̀kẹ́ ìkẹ́rù, àwọn ohun ìpèsè, aṣọ, àti àwọn ohun míràn tí a kò lè ṣe aláìní fún ìrìnàjò náà, tí wọ́n lè rí.

6 Nígbàtí àwọn ọ̀wọ́ bá ti jẹ́ ṣíṣètò, ẹ jẹ́kí wọ́n kọjá lọ pẹ̀lú agbára wọn, láti gbáradì fún àwọn wọnnì tí wọn yío dúró.

7 Kí ọ̀kọ̀kan ọ̀wọ́, pẹ̀lú àwọn balógun àti àwọn ààrẹ wọn, ṣe ìpinnu iye àwọn tí wọn yíò lè lọ ní àkókò ìrúwé tí ó nbọ̀; nígbànáà ẹ yan iye àwọn abarapá àti àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ènìyàn tí wọ́n pọ̀ tó, láti mú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn èso, àti àwọn ohun èlò iṣẹ́ àgbẹ̀, láti lọ bí ará ìṣaájú láti gbáradì fún gbígbìn àwọn irè oko ti igbà ìrúwé.

8 Kí ọ̀wọ́ kọ̀kan kí ó kó ìpín tí ó dọ́gba, ní ìbámu sí ìpín ohun ìní wọn, nínú ìtọ́jú àwọn tálákà, àwọn opó, àwọn aláìníbaba, àti àwọn ẹbí ti àwọn wọnnì tí wọ́n ti lọ sínú iṣẹ́ ológun, kí àwọn igbe opó àti àwọn aláìníbaba kí ó má ṣe gòkè wá sí etí Olúwa lòdì sí àwọn ènìyàn yìí.

9 Kí ọ̀wọ́ kọ̀kan kí ó pèsè àwọn ilé, àti àwọn oko fún gbígbin ohun ọ̀gbìn oníhóró, fún àwọn wọnnì tí wọn yíò kù sẹ́hìn ní àkókò yìí; èyí sì ni ìfẹ́ inú Olúwa nípa àwọn ènìyàn rẹ̀.

10 Kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó lo gbogbo agbára àti ohun ìní rẹ̀ láti ṣí àwọn ènìyàn wọ̀nyí nípò padà lọ sí ibi náà tí Olúwa yíò fi èèkàn Síónì kan sí.

11 Bí ẹ̀yin bá sì ṣe èyí pẹ̀lú ọkàn mímọ́, nínú gbogbo ìwà ìṣotítọ́, a ó bùkún yín; a ó bùkún yín nínú àwọn ẹran ọ̀sìn yín, àti nínú àwọn agbo ẹran yín, àti nínú àwọn oko yín, àti nínú àwọn ilé yín, àti nínú àwọn ẹbí yín.

12 Kí àwọn ìránṣẹ́ mi Ezra T. Benson àti Erastus Snow ṣe ètò ọ̀wọ́ kan.

13 Àti kí àwọn ìránṣẹ́ mi Orson Pratt àti Wilford Woodruff ṣe ètò ọ̀wọ́ kan.

14 Bákannáà, kí àwọn ìránṣẹ́ mi Amasa Lyman àti George A. Smith ṣe ètò ọ̀wọ́ kan.

15 Kí wọ́n ó sì yan àwọn ààrẹ, àti àwọn balógun ti àwọn ọgọ́rùn, àti ti àwọn àádọta, àti ti àwọn mẹ́wàá.

16 Àti kí àwọn ìránṣẹ́ mi tí a ti yàn ó lọ kí wọn ó sì kọ́ni ní èyí, ìfẹ́ inú mi, sí àwọn ẹni mímọ́, pé kí wọ́n lè múra láti lọ sí ilẹ̀ àlãfíà.

17 Ẹ lọ ní ọ̀nà yín kí ẹ sì ṣe bí mo ṣe wí fún yín, ẹ má sì ṣe bẹ̀rù àwọn ọ̀tá yín; nítorí wọn kì yíò ní agbára láti dá iṣẹ́ mi dúró.

18 Síónì ni a ó ràpadà ní àkókò tí ó tọ́ ni ojú mi.

19 Àti bí ẹnikẹ́ni bá lépa láti gbé ara rẹ̀ ga, tí kò sì wá ìmọ̀ràn ti èmi, òun kì yíò ní agbára, àìgbọ́n rẹ̀ ni á ó sì sọ di mímọ̀.

20 Ẹ wá kiri; kí ẹ sì pa gbogbo àwọn ìlérí yín mọ́ ọ̀kan sí ẹlòmíràn; ẹ má sì ṣe ṣe ojúkòkòrò sí èyíinì tí ṣe ti arákùnrin yín.

21 Ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú ibi láti pe orúkọ Olúwa lásán, nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, àní Ọlọ́run àwọn bàbá yín, Ọlọ́run Ábráhámù àti ti Ísákì àti ti Jákọ́bù.

22 Èmi ni ẹni náà tí ó mú àwọn ọmọ Ísráẹ́lì jade kúrò ní ilẹ̀ Égiptì; apá mi sì nà jade ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn, láti gba ènìyàn mi Ísráẹ́lì là.

23 Ẹ dẹ́kun iyàn jíjà ẹnikan pẹ̀lú ẹlòmíràn; ẹ dẹ́kun sísọ ọ̀rọ̀ ibi ẹnikan nípa ẹlòmíràn.

24 Ẹ dẹ́kùn ìmutípara; ẹ sì jẹ́kí àwọn ọ̀rọ̀ yín kí ó jẹ́ sí ìgbéga ẹnikan sí ẹnìkejì.

25 Bí ìwọ bá yá ohun kan lọ́wọ́ aládũgbò rẹ, ìwọ yíò dá èyíinì tí ìwọ̀ ti yá padà; bí ìwọ kò bá sì lè sán án padà nígbànáà lọ ni ojúkannáà kí o sì sọ fún aládũgbò rẹ, bíbẹ́ẹ̀kọ́ òun yío dá ọ lẹ́bi.

26 Bí ìwọ bá rí èyíinì tí aládũgbò rẹ sọnù, ìwọ yíò ṣe ìwádìí pẹ̀lú aápọn títí tí ìwọ yíò fi jọ̀wọ́ rẹ̀ lé òun lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kansíi.

27 Ìwọ yíò jẹ́ aláápọn ní ṣíṣe ìpamọ́ ohun tí o ní, kí ìwọ ó lè jẹ́ ọlọ́gbọ́n ìríjú; nítorí ó jẹ́ ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ sì jẹ́ ìríjú rẹ̀.

28 Bí ìwọ bá nyọ̀, yin Olúwa logo pẹ̀lú orin kíkọ, pẹ̀lú orin, pẹ̀lú ijó jíjó, àti pẹ̀lú àdúrà ti ìyìn àti ìdúpẹ́.

29 Bí ìwọ bá kún fún ìbànújẹ́, ké pe Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀, pé kí ọkàn rẹ kí ó lè kún fún ayọ̀.

30 Máṣe bẹ̀rù àwọn ọ̀tá rẹ, nítorí wọ́n wà ní ọwọ́ mi èmi yíò sì ṣe ohun tí mo fẹ́ pẹ̀lú wọn.

31 Àwọn ènìyàn mi ni a gbọ́dọ̀ dán wò nínú ohun gbogbo, kí a lè múra wọn sílẹ̀ láti gba ògo náà tí mo ní fún wọn, àní ògo ti Síónì; ẹnití kò bá sì lè farada ìbáwí kò yẹ fún ìjọba mi.

32 Kí ẹni náà tí ó jẹ́ òpè ó kọ́ ọgbọ́n nípa rírẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ àti ní kíké pe Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, kí ojú rẹ̀ kí ó lè là kí òun ó lè ríran, àti kí etí rẹ̀ ó lè ṣí kí òun ó lè gbọ́;

33 Nítorí Ẹ̀mí mi ni a rán jáde sínú ayé láti fi òye yé àwọn onírẹ̀lẹ̀ àti oníròbìnújẹ́, àti sí ìdálẹ́bi àwọn aláìwàbí Ọlọ́run.

34 Àwọn arákùnrin rẹ ti kọ̀ ìwọ àti ẹ̀rí rẹ sílẹ̀, àní orílẹ̀-èdè náà tí ó ti lé ọ jade;

35 Àti nísisìyí ni ọjọ́ ìdàmú wọn dé, àní àwọn ọjọ́ ìbànújẹ́, bí òbìnrin tí a mú sínú ìrọbí; ìbànújẹ́ wọn yíò sì jẹ́ púpọ̀ jọjọ bíkòṣe pé wọ́n ronúpìwàdà kánkán, bẹ́ẹ̀ni, ní kánkán gan an.

36 Nítorí wọ́n pa àwọn wòlíì, àti àwọn tí a rán sí wọn; wọ́n sì ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, èyítí ó nkígbe láti inú ilẹ̀ takò wọ́n.

37 Nítorínáà, ẹ máṣe jẹ́kí ẹnu yà yín nítorí àwọn ohun wọ̀nyí, nítorí ẹ̀yin kò tíì di mímọ́ síbẹ̀; ẹ̀yin kò tíì lè farada ògo mi síbẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin yíò ríi bí ẹ bá jẹ́ olõtọ́ ní pípa gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ mi mọ́ èyítí mo ti fifún yín, láti àwọn ọjọ́ Ádámù sí Ábráhámù, láti Ábráhámù sí Mósè, láti Mósè sí Jesù àti àwọn àpóstélì rẹ̀, àti láti Jésù àti àwọn àpóstélì rẹ̀ sí Joseph Smith, ẹnití èmi pè nípasẹ̀ àwọn ángẹ́lì mi, àwọn ìránṣẹ́ mi tí wọ́n njíṣẹ́ ìránṣẹ́, àti nípa ohùn tèmi jade láti inú àwọn ọ̀run, láti mú iṣẹ́ mi jade wá;

38 Ìpìlẹ̀ èyítí òun fi lélẹ̀, òun sì jẹ́ olõtọ́; èmi sì mú un sí ọ̀dọ̀ ara mi.

39 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ẹnu ti yà nítorí ikú rẹ̀; ṣùgbọ́n ó jẹ́ dandan kí òun ṣe èdídí ẹ̀rí rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, pé kí òun ó lè gba èrè àti kí àwọn ènìyàn búburú ó lè gba ìdálẹ́bi.

40 Èmi kò ha ti gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín, nínú èyí nìkan tí èmi fi ẹ̀rí orúkọ mi sílẹ̀?

41 Nísisìyí, nítorínáà, ẹ fetísílẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn ìjọ mi; àti ẹ̀yin alàgbà ẹ jùmọ̀ tẹ́tí sílẹ̀; ẹ̀yin ti gba ìjọba mi.

42 Ẹ jẹ́ aláápọn nínú pípa gbogbo àwọn òfin mi mọ́, bíbẹ́ẹ̀kọ́ àwọn ìdájọ́ yío wá sí orí yín, ìgbàgbọ́ yín yíó sì kùnà fún yín, àti kí àwọn ọ̀tá yín borí yín. Nítorínáà kò sí mọ́ ní àkókò yí. Àmín àti Àmín.