Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 137


Ìpín 137

Ìran tí a fifún Wòlíì Joseph Smith, nínú tẹ́mpìlì ní Kirtland, Ohio, 21 Oṣù Kínní 1836. Àkókò náà jẹ́ ti àmójútó àwọn ìlànà ní ìmúrasílẹ̀ fún yíya tẹ́mpìlì sí mímọ́.

1–6, Wòlíì náà rí arákùnrin rẹ̀ Alvin nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà; 7–9, Ẹ̀kọ́ ìgbàlà fún àwọn òkú ni a fihàn 10, Gbogbo àwọn ọmọdé ni a gbàlà nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà.

1 Àwọn ọ̀run ni a ṣí sílẹ̀ sí wa, mo sì rí ìjọba sẹ̀lẹ́stíà ti Ọlọ́run, àti ògo ibẹ̀, bóyá nínú ara tàbí lóde èmi kò lè sọ.

2 Mo rí ẹwà tí ó tayọ ti ẹnu ọ̀nà nípasẹ̀ èyítí àwọn ajogún ti ìjọba náà yíò wọlé, èyítí ó dà bí ọ̀wọ́ iná tí ó nyípo;

3 Bákannáà ìtẹ́ Ọlọ́run tí ó ntàn mọ̀nàmọ̀nà, ní orí èyítí Bàbá àti Ọmọ jókòó sí.

4 Mo rí àwọn òpópó ọ̀nà tí ó lẹ́wà ti ìjọba náà, èyítí ó ní ìfarahàn jíjẹ́ títẹ́ pẹ̀lú wúrà.

5 Mo rí Bàbá Ádámù àti Ábráhámù; àti bàbá mi àti ìyá mi; arákùnrin mi Alvin, tí ó ti sùn ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́hìn;

6 Mo sì ní ìyàlẹ́nu bí ó ṣe jẹ́ pé òun ti ní ogún nínú ìjọba náà, ní rírí pé òun ti lọ kúrò ní ayé yìí sáájú kí Olúwa tó nawọ́ rẹ̀ láti kó Ísráẹ́lì jọ lẹ́ẹ̀kejì, tí kò sì tíì ṣe ìrìbọmi fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀.

7 Báyìí ni ohùn Olúwa kọ sími, wípé: Gbogbo àwọn tí wọ́n ti kú láì ní ìmọ̀ ìhìnrere yìí, àwọn ẹnití ìbá gbà á bí a bá gbà wọ́n láàyè láti dúró, ni wọn yíò jẹ́ ajogún ìjọba sẹ̀lẹ́stíà Ọlọ́run;

8 Bákannáà gbogbo àwọn tí yíò kú láti ìgbà yí lọ láì ní ìmọ̀ rẹ̀, àwọn ẹnití ìbá gbàá pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn, ni yíò jẹ́ ajogún ìjọba náà;

9 Nítorí èmi, Olúwa, yíò ṣe ìdájọ́ gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ wọn, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú ọkàn wọn.

10 Bákannáà mo sì ríi pé gbogbo àwọn ọmọdé tí wọ́n kú ṣaájú kí wọ́n ó tó dé àwọn ọdún ìjíhìn ni a gbàlà nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà ti ọ̀run.