Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 33


Ìpín 33

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Ezra Thayre àti Northrop Sweet, ní Fayette, New York, Oṣù Kẹwã 1830. Ní ṣíṣe àfimọ̀ ìfihàn yìí, Ìtàn ti Joseph Smith fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé “Olúwa … ṣetán nígbà-gbogbo láti kọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ tí ó ṣe aápọn lati wá kiri nínú ìgbàgbọ́.”

1–4, Àwọn alágbàṣe ni a pè láti kéde ìhìnrere ní wákàtí kọkànlá ọjọ́; 5–6 A ti gbé ìjọ náà kalẹ̀, àti pe àwọn àyànfẹ́ ni a ó kójọ; 7–10 Ẹ ronúpìwàdà, nítorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀; 11–15 A kọ́ ìjọ náà lé orí àpáta ìhìnrere; 16–18, Ẹ múrasílẹ̀ fún bíbọ̀ Ọkọ Ìyàwó.

1 Kíyèsíi, mo wí fún yín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ mi Ezra àti Northrop, ẹ̀ la etí yín kí ẹ sì fetísílẹ̀ sí ohùn Olúwa Ọlọ́run yín, ẹnití ọ̀rọ̀ rẹ̀ yè tí ó sì ní agbára, ó mú ju ìdà olójú méjì lọ, láti pín sí ọ̀tọọ̀tọ̀ oríkèé àti mùndùnmúndùn, ẹ̀mí àti ọkàn, Òun sì ni olùmọ̀ àwọn èrò àti àwọn ète ọkàn.

2 Nítorí lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín pé a pè yín láti gbé ohùn yín sókè gẹ́gẹ́bí ìró ohùn fèrè, láti kéde ìhìnrere mi sí ìran oniwà wíwọ́ àti alàrékérekè.

3 Nítorí kíyèsíi, oko náà ti funfun tán nísisìyí fún ìkórè, ó sì ti di wákàtí kọkànlá, àti ìgbà ìkẹhìn tí èmi yíò pè àwọn alágbàṣe sínú ọ̀gbà ajarà mi.

4 Àti pé ọgbà ajarà mi náà ti díbàjẹ́ tán láì ku kékeré kan, kò sì sí ẹnití ó nṣe rere bíkòṣe àwọm díẹ̀; wọ́n sì ti ṣìnà lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà nítorí àwọn iṣẹ́ àlùfáà àrékérèkè, gbogbo wọ́n ni wọ́n ní àwọn àyà dídíbàjẹ́.

5 Àti pé lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, pé ìjọ yìí ni mo ti dá sílẹ̀ tí mo sì pè é jade láti inú agìnjú.

6 Àní bẹ́ẹ̀ni èmi yíò sì kó àwọn àyànfẹ́ mi jọ láti igun mẹ́rẹ̀rin ayé, àní iye àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nínú mi, tí wọ́n sì fetísílẹ̀ sí ohùn mi.

7 Bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, pé oko náà ti funfun tán nísisìyí fún ikórè; nítorínáà, ẹ fi awọn dòjé yín, kí ẹ sì kórè pẹ̀lú gbogbo agbára, iyè, àti okun yín.

8 Ẹ la ẹnu yín a ó sì kún wọn, àní ẹ̀yin yíò sì dàbí Néfì ti ìgbàanì, ẹnítí ó rìn ìrìn-ajò láti Jerusalẹ́mù ní inú aginjù.

9 Bẹ́ẹ̀ni, ẹ la ẹnu yín ẹ má sì ṣe dásí, ẹ̀yin yíò sì kó àwọn ìtí sí ẹ̀hìn yín, nítorí ẹ wòó, èmi wà pẹ́lú yín.

10 Bẹ́ẹ̀ni, ẹ la ẹnu yín a ó sì kún wọn, wipe: Ẹ ronúpìwàdà, ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì tún ọ̀nà Olúwa ṣe, kí ẹ ṣe àwọn ojú-ọ̀nà rẹ̀ ní títọ́; nítorítí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.

11 Bẹ́ẹ̀ni, ẹ ronúpìwàdà kí á sì rì yín bọmi, olukúlùkù yín, fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ yín; bẹ́ẹ̀ni, kí á rì yín bọmi àní nípa omi, àti lẹ́hìn náà ni ìrìbọmi ti iná àti ti Ẹ̀mí Mímọ́ yíò wá.

12 Ẹ kíyèsíi, lõtọ́, lõtọ́ ni mo wí fún yín, èyí ni ìhìnrere mi; àti kí ẹ sì rantí pé wọn yíò ní ìgbàgbọ́ nínú mi tàbí a kì yío gbà wọ́n là bí ó ti wù kí ó rí.

13 Àti pé ní orí àpáta yìí ni èmi yíò kọ́ ìjọ mi lé; bẹ́ẹ̀ni, ní orí àpáta yìí ni a fi ẹsẹ̀ yín lé, bí ẹ̀yin bá sì tẹ̀síwájú, àwọn ẹnu-ọ̀nà ọ̀run àpãdì kì yíò lè borí yín.

14 Àti pé ẹ̀yin yíò máa rantí àwọn ìlana òfin àti àwọn májẹmú ìjọ láti máa pa wọ́n mọ́.

15 Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ ni ẹ̀yin yíò fi ìdí wọn múlẹ̀ nínú ìjọ mi, nípa gbígbé ọwọ́ lé wọn ní orí, èmi yíò sì fún wọn ní ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́.

16 Àti pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti àwọn ìwé mímọ́ yókù ni a fi fún yín nípa mi fún ẹ̀kọ́ yín; àti pé agbára Ẹ̀mí mi ni ó nsọ ohun gbogbo di ààyè.

17 Nítorínáà, ẹ jẹ́ olõtọ́, ẹ máa gbàdúrà nígbà-gbogbo, kí ẹ tún fìtílà yín ṣe kí ó sì máa jó, àti òróró pẹ̀lú yín, kí ẹ lè múrasílẹ̀ fún bíbọ̀ Ọkọ Ìyàwó—

18 Nítorí ẹ kíyèsíi, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé èmi nbọ̀ kánkán. Àní Bẹ́ẹ̀ni. Amin.