Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ọlọ́run Láarín Wa
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Ọlọ́run Láarín Wa

Ọlọ́run wà ní àárín wa—ó sì wà nínú ayé wa fúnrarẹ̀ àti ní ìtọ́sọ́nà aápọn àwọn ọmọ Rẹ̀.

Ní gbogbo ìgbà, Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀, àwọn wòlíì.1 Ní òwúrọ̀ yí a ti ní ànfàní láti gbọ́ tí wòlíì Ọlọ́run bá gbogbo ayé sọ̀rọ̀. A nifẹ rẹ, Ààrẹ Nelson, mo sì gba gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ṣe àṣàrò kí wọ́n sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Ṣíwájú kí ntó dé ọjọ́-ìbí kejìlá, wọ́n ti fi ipá mú ẹbí wa ní ẹ̀ẹ̀mẹ́jì láti sá kúrò ní ilé wa tí a sì bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansi ní àárín ìrúkèrúdò, ẹ̀rù, àti àìní-ìrètí tí ogun àti ẹ̀yà òṣèlú mú wá. Ó jẹ́ ìgbà ìtara kan fún mi, ṣùgbọ́n ó gbọ́dọ̀ ti jẹ́ ìbẹ̀rù fún àwọn àyànfẹ́ òbí mi.

Ìyá àti bàbá mi pín díẹ̀ nípa àjàgà yí pẹ̀lú àwa ọmọ mẹ́rẹ̀rin. Wọ́n gba ìnira wọ́n sì jìyà dáadáa bí wọn ṣe lè ṣe. Ẹ̀rù náà ti gbọ́dọ̀ jẹ́ ìnilára, mímú àwọn wákàtí wọn lọ àti rírẹ ìrètí wọn sílẹ̀.

Ìgbà ṣíṣòfo yí lẹ́hìn Ogun Àgbáyé Kejì fi àmì sílẹ̀ lórí ayé. Ó fi àmì rẹ̀ sí orí mi.

Nígbànáà, nínú àìléwu àwọn wákàtí adáwà mi, mo máa nronú pé, “Ṣé ìrètí kankan kù sí ayé?”

Àwọn ángẹ́lì láarín Wa

Bí mo ṣe jíròrò àwọn ìbèèrè wọ̀nyí, mo ronú nípa àwọn ọ̀dọ́ òjíṣẹ́ ìhìnrere Amẹ́ríkà tí wọ́n sìn ní àárín wa ní àwọn ọdún wọnnì. Wọ́n fi ìtura àti ààbò ilé wọn sílẹ̀ ní ìlàjì ayé jìnnà kúrò wọ́n sì rin ìrìnàjò lọ sí Germany—ilẹ̀ àwọn ọ̀tá àìpẹ́—láti fúnni ní ìrètí ti ọ̀run sí àwọn ènìyàn wa. Wọn kò wá láti dánilẹ́bi, kọ́ ẹ̀kọ́, tàbí dójútì. Wọ́n fi tìfẹ́tìfẹ́ fúnni ní ìgbé ayé ọ̀dọ́ wọn láìsí èrò ìjèrè ti ayé, wọ́n nfẹ́ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ àti àláfíà tí wọ́n ti ní ìrírí nìkan.

Fún mi, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọ̀nyí àti àwọn obìnrin wà ní pípé. Ó dá mi lójú pé wọ́n ní àlébù, ṣùgbọ́n kìí ṣe sí mi. Èmi ó máa ronu nípa wọn bíi jíjẹ́ títóbí ju ayé lọ—àwọn ángẹ́lì ìmọ́lẹ̀ àti ògo, àwọn oníṣẹ́ ìránṣẹ́ àánú, ìwàrere, àti òtítọ́.

Nígbàtí ayé nrì sínú ìlara, ìkorò, ìríra, àti ẹ̀rù, àpẹrẹ àti àwọn ìkọ́ni ti àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn wọ̀nyí kún inú mi pẹ̀lú ìrètí. Ọ̀rọ̀ ìhìnrere tí wọ́n fúnni kọjá àwọn òṣèlú, ìtàn-àkọọ́lẹ̀, àríyànjiyàn, ìbànújẹ́, àti àwọn ètò àwòṣe araẹni. Ó fúnni ní àwọn ìdáhùn ti ọ̀run sí àwọn ìbèèrè pàtàkì tí a ní ní àwọn ìgbà ìṣòro wọ̀nyí.

Ọ̀rọ̀ náà ni pé Ọlọ́run wà láàyè Ó sì ntọ́jú wa, àní ní àwọn wákàtí ti ìpọ́njú, ìrújú, àti ìrúkèrúdò. Pé dájúdájú Ó farahàn ní ìgbà wa láti mú ìhìnrere àti Ìjọ Rẹ̀ padàbọ̀sípò. Pé Ó nsọ̀rọ̀ sí àwọn wòlíì lẹ́ẹ̀kansi; Ọlọ́run wà ní àárín wa—ó sì wà nínú ayé wa fúnrarẹ̀ àti ní ìtọ́sọ́nà aápọn àwọn ọmọ Rẹ̀.

Ó yanilẹ́nu ohun tí a lè kọ́ nígbàtí a bá wo ètò Bàbá Ọ̀run ti ìgbàlà àti ìgbéga tínítíní díẹ̀ si, ètò ìdùnnú, fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Nígbàtí a bá ní ìmọ̀lára àìnípá, ìjákulẹ̀, àti ìgbàgbé, a kọ́ pé a lè ní ìdánilójú pé Ọlọ́run kò gbàgbé wa; lotitọ, pé Òun fi ohun àìlèrò kan fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀: láti di “ajogún Ọlọ́run, àti ìdàpọ̀-ajogún pẹ̀lú Krístì.”2

Kíni èyí túmọ̀ sí?

Pé a ó gbé títíláé, gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀,3 àti kí a ní agbára láti “jogún àwọn ìtẹ́-ọba, ìjọba, agbára-ọba, àti agbára.”4

Ó nírẹ̀lẹ̀ gidi láti mọ̀ pé ọjọ́ ọ̀la tí ó ju ti ẹ̀dá lọ àti títóbi ṣeéṣe—kìí ṣe nítorí ẹni tí a jẹ́ ṣùgbọ́n nítorí ẹni tí Ọlọ́run jẹ́.

Ní mímọ èyí, báwo ni a ṣe lè ṣọ̀fọ̀, ráhùn, tàbí dúró nínú ìkorò? Báwo ni a ṣe lè pa ojú wa mọ́ sílẹ̀ nígbàtí Ọba àwọn ọba npè wá láti fò lọ sínú ọjọ́ ọ̀la àìlerò ti ìdùnnú ọ̀run?5

Ìgbàlà laarin Wa

Nítorí ifẹ́ pípé Ọlọ́run fún wa àti ìrúbọ ayérayé ti Jésù Krístì, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa—nlá àti kékeré bákannáà—lè di nínú kúrò kí a má sì ṣe rántí wọn mọ́.6 A lè dúró níwájú Rẹ̀ ní mímọ́, yíyẹ, àti yíyàsímímọ́.

Ọkàn mi kún-àkúnwọ́sílẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́ fún Bàbá mi Ọ̀run. Mo damọ̀ pé Òun kò pa àwọn ọmọ Rẹ̀ run láti ṣubú nínú ayé ikú láìsí ìrètí fún ọjọ́ ọ̀la dídán àti ayérayé. Óun ti pèsè àwọn àṣẹ tí ó fi ọ̀na padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ hàn. Àti pé ní gbùngbun gbogbo rẹ̀ ni Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì7 àti ohun tí Ó ṣe fún wa.

Ètùtù àìlópin Olùgbàlà yí ọ̀nà tí a lè fi wo àwọn àìrékọjá àti àìlera wa pátápátá padà. Dípò gbígbé lórí wọn kí a ní ìmọ̀lárá àìlení-ìràpadà tàbí àìnírètí, a lè kọ́ ẹ̀kọ́ látinú wọn kí a sì ní ìmọ̀lára pẹ̀lú ìrètí.8 Ẹ̀bùn ìwẹ̀nùmọ́ ti ìrònúpìwàdà fi ààyè gbà wá láti fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sílẹ̀ sẹ́hìn kí a sì jáde bí ẹ̀dá titun.

Nítoríti Jésù Krístì, àwọn àṣìṣe wa kò ní láti fi wá hàn. Wọ́n lè tún wa ṣe.

Bíiti òṣùwọn ìgbáradì olórin, a lè rí àwọn àṣìṣe-ìgbésẹ̀ wa, àbàwọ́n, àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bí ànfàní fún ìfura-araẹni nlá jùlọ, jíjinlẹ si àti ìfẹ́ òtítọ́ si fún àwọn ẹlòmíràn, àti títúnṣe nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà.

Bí a bá ronúpìwàdà, àṣìṣe kò mú wa kùnà. Wọ́n jẹ́ ara ìlọsíwájú wa.

Gbogbo wa jẹ́ ọmọ-ọwọ́ ni àfiwé sí jíjẹ́ ti ògo àti ọlánlá tí a yàn wá làti dà. Kò sí ìṣíwájú ayé ikú látinú fífà sí rírìn sí sísaré láìsí ìṣubú lemọ́lemọ́, àwọn òkè, àti ìfarapa. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe nkọ́ ẹ̀kọ́.

Bí a bá nfi taratara tẹramọ́ gbígbáradì, tẹramọ́ títitaraka nígbàgbogbo láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kí a sì fi àwọn ìlàkàkà wá sí ríronúpìwàdà, fífaradà, àti lílo ohun tí a kọ́, ìlà lórí ìla, a ó kó ìmọ́lẹ̀ jọ sínú ọkàn wa.10 Bíótilẹ̀jẹ́pé a ko lè ní òye kíkún ti agbára wa ní kíkún nísisìyí, “A mọ̀ pé, nígbàtí [Olùgbàlà] yíò dé,” a ó rí ìwò Rẹ̀ nínú wa, àti pé “a ó ri I bí Ó ti wà.”11

Ìlérí ológo kan ni èyí!

Bẹ́ẹ̀ni, ayé wà nínú wàhálà. Bẹ́ẹ̀ni, a ní àwọn àìlera. Ṣùgbọ́n a kò nílò láti di orí wá mú nínú àìní-ìrètí, nítorí a lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, a lè gbẹ́kẹ̀lé Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, a sì lè tẹ́wọ́gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí láti tọ́wasọ́nà ní ìpa-ọ̀nà síwájú ayé tí ó kún fún ayọ̀ àti ìdùnnú tọ̀run.12

Jésù wa láarín Wa

Mo nfi ìgbàkugbà ronú, ohun tí Jésù ìbá kọ́ni àti tí yíò ṣe bí Ó bá wa ní àárín wa ní òní?

Lẹ́hìn Àjinde, Jésù Krístì mú ìlérí Rẹ̀ ṣẹ láti bẹ àwọn “àgùtan Rẹ̀ míràn wò.”13

Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Ẹ̀rí Míràn ti Jésù Krístì sọ̀rọ̀ nípa irú ìfarahàn bẹ́ẹ̀ sí àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀ Amẹ́ríkà. A ní àkọsílẹ̀ iyebíye bi ojúlówó ẹ̀ri iṣẹ́ Olùgbàlà kan.

Àwọn ènìyàn Iwé ti Mọ́mọ́nì gbé ní ẹ̀gbẹ́ kejì ayé—ìtàn-àkọọ́lẹ̀ wọn, àṣà, àti òṣèlú ojú-ọjọ́ yàtọ̀ ní iyára sí àwọn ènìyàn tí Jésù kọ́ ní ìgbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé ikú Rẹ̀. Síbẹ̀ Ó kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú àwọn ohun kannáà tí Ó kọ́ni ní Ilẹ̀ Mímọ́.

Kínidí tí Ó níláti ṣe bẹ́ẹ̀?

Olùgbàlà nkọ́ni ní àwọn òtítọ́ àìlásìkò nígbàgbogbo. Wọ́n wúlò sí àwọn ènìyàn ọjọ́ orí gbogbo àti ipòkípò.

Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ni ó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ ìrètí àti wíwà pẹ̀lú—ẹ̀rí kan pé Ọlọ́run Bàbá wa Ọ̀run kò pa àwọn ọmọ Rẹ̀ tì.

Pé Olúwa wà láarín Wa!

Igba ọdún sẹ́hìn, Olùgbàlà padà wá sí Ilẹ̀-ayé lẹ́ẹ̀kansi. Lápapọ̀ pẹ̀lú Bàbá Ọ̀run, Ó farahàn sí Joseph Smith ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ó sì mú ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere àti Ìjọ Jésù Krístì wọlé wá Láti ọjọ́ náà síwájú, àwọn ọ̀run ṣí, àwọn ìránṣẹ́ ọ̀run sọ̀kalẹ̀ láti gbọ̀ngan ògo ayérayé. A da ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀ jáde wá láti ìtẹ́-ọba sẹ̀lẹ́stíà.

Olúwa Jésù Krístì sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kansi sí ayé.

Kíni Ó sọ?

Sí ìbùkún wa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ni a kọsílẹ̀ nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú—ó wà fún ẹnikẹ́ni ní àgbáyé tí wọ́n bá fẹ́ kàá àti láti ṣe àṣàrò wọn. Bí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe jẹ́ oníyelórí tó ní òní!

Ko níláti yà wá lẹ́nu láti ri pé Olùgbàlà nkọ́ni ní kókó ọ̀rọ̀ ìhìnrere Rẹ lẹ́ẹ̀kansi: “Ìwọ ó fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, pẹ̀lú gbogbo okun, àyà, àti agbára, àti ní orúkọ Jésù Krístì ni ìwọ ó máa sìn In.”14 Ó nmísí wa láti wá Ọlọ́run15 kí a sì gbé nípasẹ̀ àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ bí a ti fihàn sí àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀, àwọn wòlíì.16

Ó nkọ́ wa láti ní ìfẹ́ arawa17 kí a sì ní “ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ní kíkún sí gbogbo ènìyàn.”18

Ó pè wá láti jẹ́ ọwọ́ Rẹ̀, láti lọ nípa ṣíṣe rere.19 “Ẹ jẹ́ kí a ní ìfẹ́ nínú ọ̀rọ̀ … ṣùgbọ́n ìṣe àti ní òtítọ́.”20

Ó pè wá níjà láti kọ́ gbọ́ àṣẹ nlà Rẹ̀: láti nifẹ, láti pín, láti pe gbogbo ènìyàn sí ìhìnrere Eẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀.21

Ó pàṣẹ fún wa láti kọ́ àwọn tẹ́mpìlì mímọ́ kí a sì wọlé ki a sìn níbẹ̀.22

Ó kọ́ wa láti di àwọn ọmọẹ̀hìn—kí ọkàn wa máṣe tiraka fún agbára araẹni, ọ̀rọ̀, ìfọwọ́sí, tàbí ipò. Ó kọ́ wa láti “gbé ohun ayé yí sẹgbẹ, kí a wá ohun dídára.”23

Ó rọ̀ wá láti wá ayọ̀, òye, àláfíà, ìdùnnú,24 àti ìlérí ayé-àìlópin àti ìyè ayérayé.25

Ẹ jẹ́ kí a gbé ìgbésẹ̀ kan síwájú si. Ẹ gbà wípé Jésù wá sí wọ́ọ̀dù, ẹ̀ka, tàbí ilé yín ní òní. Báwo ni ìyẹn ó ti rí?

Òun ó rí inú ọ̀kàn yín tààrà. Ìwò ìta yíò sọ pàtàkì rẹ nù. Òun yíò mọ yín bí ẹ ti jẹ́. Òun yíò mọ ìfẹ́ ọkàn yín.

Ọlọ́kàn tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ni Òun ó gbé ga.

Òun yíò wo aláìsàn sàn.

Òun yíò fi ìgbàgbọ́ sínú oníyèméjì àti ìgboyà láti gbàgbọ́.

Òun yíò kọ́ wa láti ṣí ọkàn wa sí Ọlọ́run àti láti nawọ́ sí áwọn ẹlòmíràn.

Òun yíò damọ̀ yíò si bú ọlá fún òtítọ́, ìrẹ̀lẹ̀, ìyege, òdodo, àánú, àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́.

Wíwo ojú Rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan a kò sì ní rí bákannáà mọ́ láéláé. A ó yí padà títí láéláé. Ìyípadà nípasẹ̀ dídámọ̀ ìjìnlẹ̀ pé, nítòọ́tọ́, Ọlọ́run wà ní àárín wa.

Kíni Kí A Ṣe?26

Mo wo ẹ̀hìn wò pẹ̀lú ìnúrere lórí ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí mo jẹ́ ní àwọn ọdún tí mò ndàgbà. Bí mo bá lè padà ní àkokò, èmi ó tù ú nínú n ó sì wí fún láti tẹrámọ́ ìwákiri. Èmi ó sì ní kí ó pe Jésù Krístì sínú ayé rẹ̀, nítorí Ọlọ́run wà láarín wa!

Síi yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, àti sí gbogbo ẹni tí ó nwákiri fún ìdáhùn, òtítọ́, àti ìdùnnú, mo fúnni ní irú àmọ̀ràn kannáà: Tẹramọ́ ìwákiri pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti sùúrù.27

Ẹ bèèrè, ẹ ó sì rí gbà. Ẹ kànkùn, a ó sì ṣíi sílẹ̀ fún yín.28 Ẹ gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.29

Nínú ìgbé ayé wa ojojúmọ́ ó jẹ́ iṣẹ́ tó ṣe kókó àti ànfàní ìbùkún láti bá Ọlọ́run pàdé.

Bí a ti gbé ìgbéraga sẹgbẹ tí a sì dé ìtẹ́-ọba Rẹ̀ pẹ̀lú ìròbìnújẹ́ ọkàn àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,30 Òun yíò súnmọ́ wa si.31

Bí a ti nwá láti tẹ̀lé Jésù Krístì kí a sì rìn ní ipa ọ̀nà ọmọlẹ́hìn, ìlà lórí ìlà, ọjọ́ náà yíò dé tí a ó ní ìrírí ẹ̀bùn àìlèrò ti gbígba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ náà.

Ẹ̀yin àyànfẹ́ ọ̀rẹ́ mi, Bàbá yín Ọ̀run ní ìfẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ pípé. Óun ti jẹrisi ìfẹ́ Rẹ̀ ní àìlópin ọ̀nà, ṣùgbọ́n parí gbogbo rẹ̀ nípa fífúnni ní Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Nìkanṣoṣo bí ìrúbọ àti bí ẹ̀bùn sí àwọn ọmọ Rẹ̀ láti mú ìpadà sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí ọ̀run jẹ́ òdodo.

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Bàbá wa Ọ̀run wà láàyè, pé Jésù Krístì ndarí Ìjọ Rẹ̀. Àti pé Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì Rẹ̀.

Mo nawọ́ ìfẹ́ mi àti ìbùkún sí yín ní àkokò aláyọ Ọdún-àjínde. Ẹ ṣí ọkàn yín sí Olùgbàlà àti Olùràpàdà wa, bí ó ti wù kí ipó yín, àdánwò, ìjìyà, tàbí àṣiṣe rí, ẹ lè mọ̀ pé Ó wà láàyè, pé Ó ní ìfẹ́ yín, àti pé nítorí Rẹ, ẹ kò ní dáwà láéláé.

Ọlọ́run wà láarín Wa.

Nípa Èyí ni mo jẹ ẹ̀rí ni orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.