Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Yàrá ní Ilé Èrò
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Yàrá ní Ilé Èrò

Ní Àkokò Ọdún Àjínde yí, Jésù Krístì npè wá láti dà, bíi Tirẹ̀, ará Samáríà rere kan, láti ṣe ilé èrò Rẹ̀ (Ìjọ Rẹ̀) ní ibi ààbò kan fún gbogbo ènìyàn.

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kọjá lọ ní ogún ọdún sẹ́hìn, àwọn ìgbà kan wà tí mo nṣe àfẹ́rí bàbá mi. Ọdún àjínde nṣe ìlérí pé èmi ó tún rí i lẹ́ẹ̀kansíi.

Nígbàtí mo wà ní ilé ìwé ìkẹ́kọ̃-gboyè ní England, bàbá mi wá láti ṣe àbẹ̀wò. Ọkàn bàbá rẹ̀ mọ̀ pé mo ṣe àfẹ́rí ilé.

Bàbá mi fẹ́ràn ìdáwọ́lé àyàfi nínú ounjẹ. Àní ní France gan, tí a dámọ̀ fún àsè rẹ̀, òun yío sọ pé, “Jẹ́kí a jẹ oúnjẹ Chinese.” Pátríákì kan nínú Ìjọ tí ó sìn fún ìgbà pípẹ́, bàbá mi jẹ́ ti ẹ̀mí ó sí jẹ́ alãnú. Ní òru ọjọ́ kan, bí àwọn ọkọ̀ ìsẹ̀lẹ̀ òjijì pẹ̀lú àwọn fèrè aláriwo ti sáré la Paris kọjá, ó sọ pé, “Gerrit, àwọn igbe wọnnì jẹ́ àwọn ọgbẹ́ ti ilú nlá kan.”

Ní ìrìn ajò náà, mo ní ìmọ̀lára àwọn igbe àti àwọn ọgbẹ́ miràn. Ọdọ́mọbìnrin kan nta kírímù dídì láti inú ọmọlanke kékeré kan. Àwọn kónù wéfà rẹ̀ jẹ́ dẽdé ìwọ̀n fún ẹ̀kún kan ti kírímù dídì. Fún àwọn ìdí kan, ọkùnrin títóbi kan dojúkọ ọ̀dọ́mọbìnrin náà. Ó npariwo ó sì ntì i, ó da orí ọmọlanke rẹ̀ kodò, ní dída àwọn kónù kírímù dídì rẹ̀ nù. Kò sí ohun tí mo le ṣe bí ó ti rún àwọn kónù náà pẹ̀lú bàtà rẹ̀. Mo ṣì le rí ọ̀dọ́mọbìnrin náà ní orí eékún rẹ̀ ní òpópónà, tí ó ngbìyànjú láti ṣe ìpamọ́ àwọn èérún kónù fífọ́ rẹ̀, tí àwọn omijé ìrora nṣàn wálẹ̀ ní ojú rẹ̀. Àwòrán rẹ̀ ndọdẹ mi, ìránnilétí àìlãnú, àìṣetọ́jú, èdèàìyédè tí a nfi ìgbàgbogbo fà sí ara wa.

Ní ọ̀sán miràn, ní ẹ̀bá Paris, bàbá mi àti èmi ṣe àbẹ̀wò sí kàtídírà nlá ní Chartres. Malcolm Miller,1 akọ́ṣẹmọṣẹ́ àgbáyé lórí kàtídírà náà, tọ́ka sí ìdì mẹ́ta àwọn fèrèsé oní gíláàsì alábàwọ́n ti Chartres náà Ó ni wọ́n sọ ìtàn kan

Fèrèsé àkọ́kọ́ fi Ádámù àti Éfà hàn tí wọ́n njáde nínú Ọgbà Édẹ́nì.

Èkejì sọ nípa òwe ará Samaríà rere

Ìkẹta ṣe àpéjúwe Bíbọ̀ Ẹẹ̀kejì ti Olúwa.

Ní mímú papọ̀, àwọn fèrèsé oní gíláàsì alábàwọ́n náà ṣe àpèjúwe ìrìnàjò ayérayé wa. Wọ́n npè wá láti kí ẹni gbogbo káàbọ̀ pẹ̀lú yàrá nínú ilé èrò Rẹ̀2

Àwòrán
Fèrèsé ní Catheral Chartres

iStock.com/digitalimagination

Bíi Ádámù àti Éfà, a kúrò nínú Ọgbà Édẹ́nì sínu ayé àwọn ẹ̀gún àti òṣùṣu.3

Àwòrán
Fèrèsé ní Catheral Chartres

iStock.com/digitalimagination

Ní àwọn ojú ọ̀nà eléruku wa sí Jericho, a jẹ́ dídá lọ́nà, pípa lára, àti fífi sílẹ̀ nínú ìrora.4

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a níláti ran ara wa lọ́wọ́, ní ìgbà púpọ̀jù a máa nkọjá sí ẹ̀gbẹ́ kejì ọ̀nà, fún èyíkéyi ìdí.

Ṣùgbọ́n, pẹ̀lú àànú, Ará Samáríà Rere dúró ó sì ndi àwọn ọgbẹ́ wa pẹ̀lú wáìnì àti òróró. Àwọn àmì oúnjẹ Olúwa àti àwọn ìlànà míràn, wáìnì àti òróró tọ́wá sọ́nà ìwòsàn ti-ẹ̀mí nínú Jésù.5 Ará Samáríà Rere náà gbé wa lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Tirẹ̀ tàbí, nínú àwọn àkọsílẹ̀ díẹ̀ ti gíláàsì alábàwọ́n, ó gbé wa lé orí àwọn èjìká Rẹ̀. Ó nmú wa wá sí ilé-èrò, èyí tí ó lè rọ́pò Ìjọ Rẹ̀. Ní ilé-èrò, ará Samáríà rere wípé, “Tọ́jú rẹ̀; … nígbà tí mo bá padà dé, èmi ó san fún ọ.”6 Ará Samáríà Rere náà, àmì ti Olùgbàlà wa, ṣe ìlérí láti padà wá, ní àkókò yí nínú ọlánlá àti ògo.

Àwòrán
Fèrèsé ní Catheral Chartres

iStock.com/digitalimagination

Ní ákokò Ọdún Àjínde yí, Jésù Krístì npè wá láti dà, bíi Tirẹ̀, ará Samáríà rere kan, láti ṣe ilé èrò Rẹ̀ (Ìjọ Rẹ̀) ní ibi ààbò kan fún gbogbo ènìyàn kúrò nínú àwọn ìpalára àti àwọn ìjì ìgbé ayé.7 A nmúra fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Rẹ̀ tí Ó ṣèlérí bí a ti nṣe ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan sí èyí tí ó “kéré jùlọ nínú àwọn wọ̀nyí”8 bí a ó ti ṣe sí Òun. “Èyí ti ó kéré jùlọ nínú àwọn wọ̀nyí” ni ọ̀kọ̀ọ̀kan wa.

Bí a ti nwá pẹ̀lú Ará Samáríà Rere sí ilé èrò, a nkọ́ àwọn ohun márũn nípa Jésù Krístì àti àwa fúnra wa.

Lakọkọ, a wá sínú ilé-èrò bí a ti wà, pẹ̀lú àlébù àti àìlera tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní. Síbẹ́ gbogbo wá ní ohunkan láti dásí. Ìrìnàjò wa sí Ọlọ́run ni a máa nrí papọ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà. A jẹ́ ti bíi ìṣọ̀kan àdúgbò—bóyá ní dídojúkọ àwọn àjàkálẹ̀ àrùn, àwọn ìjì, àwọn ìjà iná, àwọn ọ̀gbẹlẹ̀ tàbí tí a rọra nbá àwọn àìní ojojúmọ́ pàdé. A ngba ìmísí bí a ṣe ndámọ̀ràn papọ̀, ní fífetísí ohùn ara wa, pẹ̀lú arábìnrin kọ̀ọ̀kan, àti sí Ẹ̀mí.

Bí ọkan wa ti nyí padà tí a sì ngba àwòràn Rẹ̀ nínú ìwò ojú wa,9 a rí I àti ara wa nínú Ìjọ Rẹ̀. Nínú Rẹ̀, a nrí síṣe kedere, kìí ṣe iyapa Nínú Rẹ̀, a nrí ohun kan láti ṣe rere, ìdí láti jẹ́ rere, àti àlékún agbára láti di dídára síi. Nínú Rẹ̀, a nṣe àwárí ìgbágbọ́ tí nbáni gbé, àìmọ- tàra-ẹni-nìkan tí nṣe ìtúsílẹ̀, ìyípadà ní síṣe ìtọ́jú, àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run. Nínú ilé èrò Rẹ̀, a nrí a sì nmú ìbáṣepọ̀ ti ara ẹni wa pẹ̀lú Ọlọ́run, Bàbá wa, àti Jésù Krístì jinlẹ̀ síi.

Ó ngbẹ́kẹ̀lé wa láti ṣe ìrànwọ́ mú kí ilé èrò náà jẹ́ ibi tí Ó nílò rẹ̀ láti jẹ́. Bí a ti nfi àwọn tálẹ́ntì àti àwọn aápọn dídárajùlọ wa sílẹ̀, àwọn ẹ̀bùn ti ẹ̀mí Rẹ̀10

Ògbufọ̀ kan ní èdè Spanish sọ fúnmi pé, “Alàgbà Gong, èmi mọ̀ nípasẹ̀ Ẹmí ohun tí o fẹ́ sọ kí èmi le ṣe ìtúmọ̀,” arákùnrin onígbàgbọ́ yi sọ pé, “nípasẹ̀ ẹ̀bùn àwọn èdè.”

Àwọn ẹ̀bùn ìgbàgbọ́ àti ìdánilójú nwá, wọ́n sì nfarahàn pẹ̀lú ìyàtọ̀ ní àwọn ìpò tó yàtọ̀. Arábìnrin ọ̀wọ́n kan gba ìtùnú ti ẹ̀mí bí ọkọ rẹ̀ ti kọjá lọ láti ipasẹ̀ COVID-19. Ó sọ pé, “Mo mọ pé ọkọ mi ọ̀wọ́n àti èmi yíò wà papọ̀ lẹ́ẹ̀kansíi.” Nínú ipò COVID kan tí ó yàtọ̀, arábìnrin ọ̀wọ́n miràn sọ pé, “Mo ní ìmọ̀lára pé mo níláti bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa àti àwọn dókítà láti fún ọkọ mi ní àkókò kékeré díẹ̀ síi.”

Èkejì, Ó nrọ̀ wá láti ṣe ilé èrò Rẹ̀ ní ibi oore ọ̀fẹ́ àti ààyè, níbití olukúlùkù ti le kórajọ papọ̀, pẹ̀lú yàrá fún gbogbo ènìyàn. Bíi ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì, gbogbo ènìyàn dọ́gba, láìsí àwọn ẹgbẹ́ kílásì-kejì.

Gbogbo ènìyàn ni a kí káàbọ̀ láti wá sí àwọn ìpàdé ounjẹ Olúwa, àwọn ìpàdé Ọjọ́ Ìsinmi míràn, àti àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ìpẹ́jọpọ̀ àwùjọ.11 A nsin Olùgbàlà wa, a nronú à sì ngbèrò nípa ọmọnìkejì wa. A nrí a sì nṣe ìdámọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan. A nrẹ́rĩn músẹ́, a njókõ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n bá ndá jókõ, a nkọ́ àwọn orúkọ, pẹ̀lú àwọn olùyípadà ọkàn titún, arákùnrin àti arábìnrin tí npadà bọ̀, ọ̀dọ́mọbìnrin àti ọ̀dọ́mọkùnrin, olùfẹ́ ọmọ Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

Ní fífi ojú inú wo ara wa ní ipò wọn, a ṣe ìkíni káàbọ̀ àwọn ọ̀rẹ́, àwọn àlejò, àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kó wá, olukúlùkù àwọn tí ọwọ́ wọn dí tí a nfà ní àwọn ọ̀nà púpọ̀ jù. A nsọ̀fọ̀, a nṣe àjọyọ̀, a sì nwà níbẹ̀ fún ara wa. Nígbàtí a bá kùnà ohun tí ó yẹ kí a ṣe tí a sì kán wa lójú, tí a ṣe àìmọ̀, tí a dáni lẹ́jọ́, tàbí tí a fì sí ẹ̀gbẹ́ kan, a nwá ìdáríjì ara wa a sì nṣe dáradára síi

Ẹbí kan láti ilẹ̀ Áfríkà tí wọn ngbé ní United States nísisìyí, sọ pé, “Láti ọjọ́ kinní, àwọn ọmọ Ìjọ jẹ́ ọ̀rẹ́ àti ọlọ́yàyà. Gbogbo wọn mú wa ní ìmọ̀lára pé a wà nílé. Kò sí ẹnikankan tí ó fi ojú tẹ̀ wá mọ́lẹ̀.” Bàbá sọ pé, “Bíbélì Mímọ́ kọ́ni pé àwọn èso ìhìnrere nwá láti inú àwọn gbòngbò ìhìnrere.” “Àti àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere,” bàbá àti ìyá sọ pé, “a fẹ́ kí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wa ó dàgbà sókè bíi àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wọnnì.” Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, njẹ́ kí a le fi ọ̀yàyà kí gbogbo ènìyàn káàbọ̀ sí ilé èrò Rẹ̀.

Ìkẹta, nínú ilé èrò Rẹ̀ a nkọ́ pé jíjẹ́ pípé wà nínú Jésù Krístì, kìí ṣe nínú jìjẹ́ pípé ti ayé. Àìjẹ́-òtítọ́ àti àiṣeéṣe, nínú ayé ti “pípé-ojú-ẹsẹ̀” jíjẹ́ pípẹ sísẹ́ le mu wa ní ìmọ̀lára àìkún-ojú-òsùnwọ̀n, ìgbèkùn sí àwọn ọ̀rọ̀ ìdọ̀tí, àwọn ohun tí a fẹ́ràn, tàbí àwọn ìṣe ojú méjì. Ní ìlòdí sí, Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, mọ ohun gbogbo nípa wa tí a kìí fẹ́ kí ẹlòmíràn mọ̀, Ó sì fẹ́ràn wa síbẹ̀. Tirẹ̀ ni ìhìnrere ààyè ìkejì àti ìkẹ́ta, tí a mú ṣeéṣe nípa Ètùtù ìrúbọ Rẹ̀.12 Ó npe ọ̀kọ̀ọ̀kan wa láti jẹ́ ará Samáríà rere, dídínkù nínú dídánilẹ́jọ́ àti ṣíṣe ìforíjì síi fún ara wa àti fún ẹlòmíràn, a`ní bí a ṣe ntiraka si ní kíkún láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.

A nran ara wa lọ́wọ́ bí a ti nran ẹlòmíràn lọ́wọ́. Ẹbí kan tí mo mọ̀ gbé rí ní ẹ̀bá ọ̀nà tí ó máa ndí gan an. Àwọn arìnrìnàjò máa ndúró nígbà púpọ̀ láti bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kan ẹbí náà gbọ́ gbígbá aláriwo lára ìlẹ̀kùn wọn. Ní rírẹ̀ àti ṣíṣe àníyàn ẹnití ó le jẹ́ ní aago méjì òru, wọ́n ronú bóyá, ní ẹ̀ẹ̀kan yí, ẹnikẹ́ni miràn le ṣe ìrànwọ́. Bí kíkànkù lemọ́lemọ́ náà ti ntẹ̀síwájú, wọ́n gbọ́, “Iná—iná wà ní ẹ̀hìn ilé yín!” Àwọn ará Samáríà rere máa nran ara wọn lọ́wọ́.

Ìkẹrin, ní ilé èrò Rẹ̀ a ndi ara àdúgbò ìhìnrere kan tí ó dá lórí Jésù Krístì, tí a ndarí nínú òtítọ́, àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì alààyè, àti ẹ̀rí míràn ti Jésù Krístì—Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ó nmú wa wá sí ilé èrò Rẹ̀ àti bákannáà sí ilé Rẹ̀—tẹ́mpìlì mímọ́. Ilé Olúwa jẹ́ ibi kan tí, bíi ti ọkùnrin tí wọ́n ṣá lọ́gbẹ́ ní ojú ọ̀nà sí Jericho, ará Samáríà rere ti le wẹ̀ wá nù kí ó sì wọ̀ wá ní aṣọ, kí ó múra wa sílẹ̀ láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kí ó sì mú wa wà ní ìrẹ́pọ̀ títí ayérayé nínú ẹbí Ọlọ́run. Àwọn tẹ́mpìlì Rẹ̀ ṣí sílẹ̀ sí gbogbo ẹnití ó ngbé ìgbé ayé ìhìnrere Rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn.

Yíyọ àyọ tẹ́mpìlì ní ìṣọkan ìhìnrere nínú láàrin onírúurú àwọn ìní, àwọn àṣà, àwọn èdè, àti àwọn ìran, Ní ibi ìpìlẹ̀ Tẹ́mpìlì ti Taylorsvill Utah, Max Harker ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún pín ogún ìní kan tí ìgbàgbọ́ ẹbí tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ìran kẹfà ṣaájú láti ipasẹ̀ baba nlá baba tó bí baba tó bí baba-àgbà Joseph Harker àti ìyàwó rẹ̀, Susannah Sneath. Nínú ìhìnrere ti Jésù Krístì tí a mú padàbọ̀sípọ̀, a lè di oríke ìsopọ̀ líle kan nínú àwọn ìran ẹbí wa.

Ní ìparí, ìkarũn, a yọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn ọmọ Rẹ̀ nínú gbogbo àwọn ìyàtọ àtilẹ̀wá àti àwọn ipò wa, ní gbogbo orílẹ̀ èdè, ìbátan, àti èdè, pẹ̀lú yàrá fún gbogbo ènìyàn nínú ilé èrò Rẹ̀.

Ó lé ní ogójì ọdún sẹ́hìn, àwọn ọmọ Ìjọ tí di lílékún ní lílọ káàkiri àwọn orílẹ̀ èdè míràn. Láti 1998, púpọ̀ síi àwọn ọmọ Ìjọ ti gbé ní òde ju inú United States àti Canada. Tí ó ba di 2025, a nwòye pé pùpọ̀ àwọn ọmọ Ìjọ lè máa gbé ní Latin Amẹ́ríkà bíiti United States àti Canada. Kíkójọ àwọn olõtọ́ àtẹ̀lé Baba Léhì nṣe ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Ǎwọn olõtọ́ Ènìyàn Mímọ́, pẹ̀lú àwọn olùlànà ipá ọ̀nà, dúró bíi ìfipamọ́ ti ìfọkànsìn àti iṣẹ́ ìsìn fún Ìjọ àgbáyé náà.

Bákannáà, púpọ̀jù àwọn àgbàlagbà nínú àwọn ọmọ Ìjọ ní kò ṣe ìgbéyàwó, ni wọ́n jẹ́ opó, tàbí ni wọ́n ti kọ ara wọn sílẹ̀. Èyí jẹ́ ìyípadà kan tí ó tóbi àti tí ó ṣe kókó. Nínú wọn ni púpọ̀ ju ìdajì àwọn arábìnrin Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ wa àti púpọ̀ju ìdajì àwọn àgbà arákùnrin olóyè àlùfáà. Àwòrán ìfijúwe yi ti wà bẹ́ẹ̀ nínú Ìjọ jákèjádò àgbáyé láti 1992 àti ní United States àti Canada láti 2019.

Ìdúró wa níwájú Oluwa àti Ìjọ Rẹ̀ kìí ṣe ọ̀rọ̀ ipò ìgbéyàwó ṣùgbọ́n ti dída olotítọ́ àti onígboyà ọmọlẹ́hìn ti Jésù Krístì.12 Àwọn àgbàlagbà fẹ́ láti jẹ́ rírí bíi àgbàlagbà àti láti le ṣe ojúṣe kí wọn ó sì lọ́wọ́ sí bíi àwọn àgbàlagbà. Àwọn ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì wá láti ibi gbogbo, ní olukúlùkù ẹ̀yà, ìwọ̀n, àwọ̀, ọjọ́ orí, olukúlùkù pẹ̀lú tálẹ́ntì, àwọn ìfẹ́ inú òdodo, àti àwọn agbára ìleṣe púpọ̀ láti bùkúnni àti láti sìn. À nwá láti tẹ̀lé Jésù Krístì lójojúmọ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ sí ìrònúpìwàdà14 àti ayọ̀ pípẹ́.

Ní àkókò ìgbé ayé yi, nígbà míràn a máa nduró dé Oluwa. A lè má tilẹ̀ tí dé ibi tí a ní ìrètí àti ìfẹ́ inú láti dé ní ọjọ́ iwájú. Olùfọkànsìn ọmọ Ìjọ kan sọ pé, “Dídúró dé Olúwa pẹ̀lú ìgbàgbọ́ fún àwọn ìbùkún rẹ̀ jẹ́ ipò mímọ́ kan. A kò gbọdọ̀ pàdé rẹ̀ pẹ̀lú ìkáànú, sísọ ara ẹni sílẹ̀, tàbí dá lẹ́jọ́ ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú bíbu ọlá mímọ́,”13 Ní àkókò díẹ̀ ná, a ngbé nísisìyí, kìí ṣe pé a ndúró fún ìgbé ayé láti bẹ̀rẹ̀.

Ìsáíàh nṣelérí pé, “Àwọn ẹnití ó dúró de Olúwa yíò tún agbára wọn ṣe; wọn yío fi ìyẹ́ gun òkè bí ìdì; wọn ó sáré, kì yíò rẹ̀ wọ́n; wọn ó rìn, àárẹ̀ kì yíò mú wọn.”14

Ará Samáríà rere ṣèlérí láti padà. Àwọn iṣẹ́-ìyanu nṣẹlẹ̀ bí a ti ntọ̀jú ara wa bí Òun ó ti ṣe. Nígbàtí a ba wá pẹ̀lú ìròbìnújẹ́ ọkàn àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,17 a lè rí ohùn nínú Jésù Krístì kí a sì wà nínú apá ìkámọ́ lílóye ààbò Rẹ̀.18 Àwọn ìlànà Mímọ́ fúnni ní májẹ̀mú wíwà pẹ̀lú àti “agbára ìwa-bí-ọlọ́run”20 láti wẹ èrò inú àti ìṣe ìta mọ́. Pẹ̀lú ìfẹ́ni-inúrere àti ìpamọ́ra Rẹ̀, Ìjọ Rẹ̀ ndì ilé-èrò wa.

Bí a ti npèsè yàrá nínú ilé èrò Rẹ̀, ní kíkí ẹni gbogbo káàbọ̀, ará Samáríà rere wa le wò wá sàn lórí àwọn ojú ọ̀nà eléruku ti ayé ikú wa. Wọ́n ṣe ìlérí “àlàáfíà ní ayé yi, àti ìyè ayérayé ní ayé tí nbọ̀”5—”pé níbití èmi wà ni ẹ̀yin yío wà bákannáà.”21 Mo fi pẹ̀lú ìmoore ṣe ẹlẹ́rìí mo sì jẹ́ri bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín