Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, èmi yíò gbé àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, àwọn Àádọ́rin Agbègbè, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò Ìjọ fún ìbò ìmúdúró yín.

Ẹ jọ́wọ́ e fi ìbò yín hàn bí ẹ ti nṣe níbikíbi tí ẹ lè wà. Bí a bá rí àwọn wọ̀nni tí wọń tako eyikeyi nínú àwọn àbá, a bèèrè pé kí ẹ kàn sí ààrẹ èèkan yín.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró Russell Marion Nelson bí wòlíì, aríran, àti olùfihàn àti Ààrẹ Ìjọ Jésù Kristì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn; Dallin Harris Oaks bí Olùdámọ̀ràn Kínní; àti Henry Bennion Eyring bí Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkinní.

Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.

Àwọn wọnnì tó bá tàkòó, tí ẹnikẹ́ni bá wà, lè fihàn.

A dalaba pé kí a ṣe imúdúró Dallin H. Oaks bí Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá àti M. Russell Ballard bí Aṣojú Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá.

Àwọn to bá faramọ, jọ̀wọ́ ṣàpẹrẹ.

Alátakò kankan tó bá wa lè fihàn.

A dalaba kí a ṣe imúdúró àwọn wọ̀nyí bí ọmọ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá: M. Russell Ballard, Jeffrey R. Holland, Dieter F. Uchtdorf, David A. Bednar, Quentin L. Cook, D. Todd Christofferson, Neil L. Andersen, Ronald A. Rasband, Gary E. Stevenson, Dale G. Renlund, Gerrit W. Gong, àti Ulisses Soares.

Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Alátakò kankan lè ṣe àmì bẹ́ẹ̀.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn olùdámọ̀ràn nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bí àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Ìlòdì, tí ẹnìkankan bá wá, nípa irú àmì kannáà.

Bí ọ̀ràn ìwífúnni, àwọn Alàgbà Robert C. Gay àti Terence M. Vinson ni a ó dásílẹ̀ kúrò nínu iṣẹ́-ìsìn bí ọmọ Àjọ Ààrẹ Àádọ́rin bẹ̀rẹ̀ láti Ọjọ́ Ìkínní Oṣù Kẹjọ, 2021.

Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arákùnrin wọ̀nyí fún iṣẹ́ ìfọkànsì wọn lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìnawọ́ sókè.

Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ní a ti dásílẹ̀: Alàgbà Sean Douglas, Michael A. Dunn, Clark G. Gilbert, Alfred Kyungu, Carlos G. Revillo Jr., àti Vaiangina Sikahema.

Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arákùnrin wọ̀nyí fún iṣẹ́ ìsin wọn tó tayọ, jọ̀wọ́ fihàn.

A ti dá Àjọ Ààrẹ Gbogbogbò Alakọbẹrẹ sílẹ̀: Joy D. Jones bí Ààrẹ, Lisa L. Harkness bí Olùdámọ̀ràn Ìkínní, àti Cristina B. Franco bí Olùdámọ̀ràn Ìkejì.

Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arábìnrin wọ̀nyí fún iṣẹ́ ìsin olùfọkànsìn, jọ̀wọ́ fihàn.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn Alàgbà Paul V. Johnson àti S. Mark Palmer bí ọmọ Àjọ Ààrẹ Àádọ́rin bẹ̀rẹ̀ láti Ọjọ́ Ìkínní Oṣù Kẹjọ, 2021.

Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.

Àwọn alátakò, nípa irú àmì kannáà.

A dalaba kí a ṣe ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbo Àádọ́rin wọ̀nyí: Sean Douglas, Michael A. Dunn, Clark G. Gilbert, Patricio M. Giuffra, Alfred Kyungu, Alvin F. Meredith lll, Carlos G. Revillo Jr., àti Vaiangina Sikahema.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Àwọn alátakò, nípa irú àmì kannáà.

A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn Àádọ́rin Agbègbè titun bí a ti kéde ní Ìjọ ṣíwájú ní ọ̀sẹ̀ yí.

Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Àwọn alátakò, nípa irú àmì kannáà.

A dalaba kí a ṣe ìmúdúró àwọn Àjọ Ààrẹ Gbogbogbò Alakọbẹrẹ Camille N. Johnson bí Ààrẹ, Susan Elizabeth Porter bí Olùdámọ̀ràn Kínní, àti Amy Eileen Wright bí Olùdámọ̀ràn Kejì.

Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.

Alátakò kankan lè ṣe àmì bẹ́ẹ̀.

A dalaba pé kí a ṣè ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò bí a ṣe gbé wọn kalẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.

Àwọn alátakò, bí ọ̀kankan bá wà.

Lẹ́ẹ̀kansi, a pe àwọn wọnnì tí wọ́n lè tako èyíkéyi nínú àbá wọ̀nyí láti rí àwọn ààrẹ èèkan.

A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìtẹ̀síwájú ìgbàgbọ́ yín àti àdúrà ní ìtìlẹhìn àwọn olórí Ìjọ.

Àwọn Ìyípadà sí Àwọn Àádọ́rin Agbègbè

Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a ṣe ìmúdúró fún nínú abala àwọn olórí kan tí a ṣe bí ara ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò.

Daniel P. Amato, Rodney A. Ames, Marcelo Andrezzo, Samuel Annan-Simons, Patrick Appianti-Sarpong, Eduardo M. Argana, Steven C. Barlow, Erik Bernskov, Mark E. Bonham, K. Bruce Boucher, Jonathan G. Cannon, Juan P. Casco, Gregorio E. Casillas, Fernando R. Castro, Ranulfo Cervantes, Thomas K. Checketts, Ross A. Chiles, Benjamin Cinco, David C. Clark, Félix Conde, Jorge A. Contreras, Corbin E. Coombs, Moroni Costa, Leandro J. Curaba, B. Corey Cuvelier, Ernesto A. Deyro Jr., J. Kimo Esplin, Tomás Familia, Michael D. Groll, John Gutty, Oleksiy H. Hakalenko, Tommy D. Haws, Levi W. Heath, Brian J. Holmes, Hal C. Hunsaker, Yuichi Imai, Bruce H. Ixcot, Paul H. Jean Baptiste, Dong Hwan Jeong, Frederick M. Kamya, Gaëtan Kelounou, David S. Kinard, Julio E. Lee, R. Darío Lorenzana, Odair José Castro de Lira, Enrique M. Loo, Hernán D. Lucero, Bartolome Madriaga, Douglas P. Maxfield, Héctor Méndez, Steven C. Merrell, Quinn S. Millington, Siegfried A. Naumann, Ricardo J. Nieves, Lorenzo E. Norambuena, Enefiok Ntem, Charles O. Oide, Juan L. Orquera, Roberto C. Pacheco, Damon Page, Franck A. Poznanski, T. Michael Price, Alexandre Ret, Frédéric T. Riemer, Russell A. Robinson, Leonardo S. Rojas, Douglas A. Rozsa, Lee M. Shumway, Robert H. Simpson, Vance K. Smith, Martiniano S. Soquila Jr., Victor H. Suazo, Raul Tapia, Carlos Torres, Bruno E. Vásquez, M. Travis Wolsey, àti Richard G. Youngblood.