Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Kìí ṣe bí Ayé Tií Funni
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Kìí ṣe bí Ayé Tií Funni

Àwọn ohun èlò tí a nílò láti dá ọjọ́ dídán sílẹ̀ àti ìdàgbà ọ̀rọ̀-ajé ìwàrere òtítọ́ ní àwùjọ ni a pèsè lọ́pọ̀lọpọ̀ fún nínú ìhìnrere Jésù Krístì.

Ṣaájú Ọdún Ajínde àkọ́kọ́, bí Jésù ti parí ìlànà ti oúnjẹ Olúwa titun tí ó ti pín fún àwọn Méjìlá, Ó bẹ̀rẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìdágbére ti ọlánlá Rẹ̀ ó sì tẹ̀síwájú sí ọ̀nà Getsémánì, ìwà ọ̀dàlẹ̀, àti kíkàn mọ́ àgbélèbú. Ṣùgbọ́n, ní fífura sí àníyàn àti bóyá ìbẹ̀rù tààrà díẹ̀ lára èyí tí àwọn ọkùnrin wọnnì le ti fihàn, Jésù sọ èyí fún wọn (àti fún àwa):

“Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú: ẹ̀yin gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ẹ gbàgbọ́ bákannáà nínú mi. .…

“Èmi kì yíò fi yín sílẹ̀ ní aláìní olùtùnú: èmi ó tọ̀ yín wá. …

“Àlàáfíà ni mo fi fún yín, àlàáfíà mi ni mo fi fún yín: kìí ṣe bí ayé ti í funni, ni èmi fi fún yín. Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó wárìrì.”1

Àwọn àkokò ìpènija nwá ninú ayé kíkú yi, sí àwọn olódodo pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ti Krístì tí ó ntún ìdánilójú ṣe ni pé Òun, ọ̀dọ́ àgùtàn fún pípa, yío lọ bíi “àgùtàn kan níwàjú olùrẹ́rùn [rẹ̀],”2 bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀ Òun ó dìde, bí onísáàmù ti sọ, láti jẹ́ “ààbò àti agbára [wa], lọ́wọ́lọ́wọ́ ìrànlọ́wọ́ ní [ìgbà] ìpọ́njú.“3

Dídá àwọn wákàtí ìṣòrò tí ó wà níwájú fún Krístì mọ̀ bí Ó ti rìn síwájú àgbélèbú àti fún àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ bí wọ́n yíò ti mu ìhìnrere Rẹ̀ lọ sí ayé ní àkokò pàtàkì náà, ẹ lọ pẹ̀lú mi báyí sí ọ̀rọ̀ ìbámu fún àwọn ọmọ Ìjọ Olùgbàlà ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Ọrọ̀ yí wà nínú ònkà yíyanilẹ́nu ti àwọn ẹsẹ inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì tí a fi jìn sí irú ìjàkadì kan tàbí òmíràn, láti orí ìwà tí ó nbíni nínú títí ayérayé ti Lámánì àti Lẹ́múẹlì dé orí àwọn ìjà ìkẹhìn tí ó wé mọ́ ọgọgọ́rũn àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn jagunjagun. Ọ̀kan lára àwọn èrèdí tí ó farahàn jùlọ fún àtẹnumọ́ yí lórí ogun jíjà ni pé níwọ̀n bí Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti jẹ́ kíkọ fún ìpéjọpọ̀ ọjọ́ ìkẹhìn, àwọn olùkọ̀wé wọ̀nyí (nípàtàkì tí wọ́n jẹ́ ológun fúnra wọn) kìlọ̀ fún wa bíi ti wòlíì pé rògbòdìyàn àti ìjàkadì yío jẹ́ àmì ìhùwàsí ti àwọn ìbáṣepọ̀ ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn.

Nítòótọ́, àwọn èrò orí mi nípa ìjà ti ọjọ́ ìkẹhìn kìí ṣe ojúlówó gan. Ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sẹ́hìn, Olùgbàlà kìlọ̀ pé ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn “àwọn ogun, àti àwọn ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun yio wà,”4 lẹ́hìnnáà ó wípé “àlàfíà ni [yíó] di mímú kúrò ní orí ilẹ̀ ayé.”5 Dájúdájú Olùgbàlà Ọmọ Aládé Àlàáfíà, ẹnití ó kọ́ni pẹ̀lú àtẹnumọ́ pé ìjà jẹ́ ti èṣù,6 gbọdọ̀ sunkún ní ẹ̀gbẹ́ kannáà pẹ̀lú Baba Rẹ̀ ti Ọrun lóri àwọn wọnnì nínú ẹbí ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n wà “láìsí ìfẹ́ràn” tí wọn kò sì le ronú bí wọ́n ti le gbé papọ̀ nínú ìfẹ́.7

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, a nrí rògbòdìyàn, ìbínú, àti àìní-ọ̀làjú púpọ̀ ní àyíká wa. Pẹ̀lú oríire, ìran ti ìsisìyí kò tíì ní Ogun Àgbáyé Kẹta kan láti jà, tàbí bẹ́ẹ̀ ni a kò ní ìrírí ìjákulẹ̀ ọrọ̀-ajé àgbáyé bí ọ̀kan tí ó ṣẹlẹ̀ ní 1929 tí ó darí sí Ìbànújẹ́ Nlá. Ṣùgbọ́n a nkojú ohun kan tí ó dàbí irú Ogun Àgbáyé Kẹta kan, kìí ṣe ìjà kan láti tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀ ṣùgbọ́n gbígba àwọn ọmọ Ọlọ́run sí ètò ṣíṣe àmójútó síi nípa ara wa, àti láti ṣe ìrànwọ́ wo àwọn ọgbẹ́ ti a rí ní ayé rògbòdìyàn sàn. Ìbànújẹ́ Nlá tí a dojúkọ nísisìyí ní díẹ̀ íṣe pẹ̀lú àdánù ìta ti ìkópamọ́ wa àti púpọ̀ ṣíṣe pẹ̀lú àdánù inú ti ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni wa, pẹ̀lú ìdínkù ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ gbogbo ní àyíka wa. Ṣùgbọ́n àwọn ohun èlò tí a nílò láti dá ọjọ́ dídán sílẹ̀ àti ìdàgbà ọ̀rọ̀-ajé ìwàrere òtítọ́ ní àwùjọ ni a pèsè lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ìhìnrere Jésù Krístì. A kò ní le gba—ayé náà kò ní le gba—ìkùnà wa láti fi àwọn ìmọ̀ràn ìhìnrere wọ̀nyí àti àwọn ìdáààbò májẹ̀mú sí lílò araẹni àti gbogbogbò ní kíkún.

Nítorínáà, nínú ayé tí “ìjì ngbé, tí kò ní ìtùnú,” bí Jehofah ti wí pé yíò jẹ́, báwo ni a ṣe lè rí ohun tí Ó pè ní “májẹ̀mú … àláfíà”? A nri nípa yíyípadà sí I ẹnití ó wípé Òun yíò ní ìyọ́nú sí wa “pẹ̀lú inúrere àìlópin” yíò sì fún àwọn ọmọ wa ní àláfíà.8 Nítorínáà, pẹ̀lú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bíbanilẹ́rù àti àwọn ìwé mímọ́ tí ndààmú ẹni ní kíkéde pé àlàáfíà yío di mímú kúrò lórí ilẹ̀ ayé gbogbo, àwọn wòlíì, pẹ̀lú olùfẹ́ ọ̀wọ́n tiwa Russell M. Nelson, ti kọ́ni pé èyí kò túmọ̀ sí pé yío di mímú kúrò lọ́dọ̀ wa bí ẹnìkọ̀ọ̀kan!9 Nítorínáà, ní Ọdún Ajínde yi ẹ jẹ́kí a gbìyànjú láti ṣe ìṣe àlàáfíà ní ọ̀nà araẹni kan, ní lílo ore ọ̀fẹ́ àti òróró ìwòsàn ti Ètùtù Olúwa Jésù Krístì sí arawa àti àwọn ẹbí àti àwọn wọnnì ní àyíká wa. Lóríre, àní pẹ̀lú ìyanu, ohun ìtura yí ni a mú wá fún wa “láìsí owó àti láìsí ìdíyelé.”10

A nílò irú ìrànlọ́wọ́ àti ìrètí bẹ́ẹ̀ dáadáa nítori nínú ìpéjọpọ̀ gbogbo ayé yi lóni ni púpọ̀ àwọn tí ntiraka pẹ̀lú eyikeyi oye ìpèníjà—ti àfojúrí tàbí ti ẹ̀dùn-ọkàn, ti àwùjọ tàbí ti ọ̀rọ̀ ìsúná, tàbí dọ́sìnnì kan irú àwọn wàhálà míràn. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwọ̀nyí ni a lágbára tó láti ṣe amójútó wọn nínú àti nípa arawa, nítorí ìrànlọ́wọ́ àti àlàáfíà tí a nílò kìí ṣe irú èyí “tí ayé nfúnni.”11 Rárá, nítorí àwọn wàhàlà ṣíṣòro nítoótọ́ a nílò ohun tí àwọn ìwé mímọ́ pè ní “àwọn agbára ọ̀run,” àti láti dé ibi àwọn agbára wọ̀nyí a gbọdọ̀ gbé nípa ohun tí àwọn ìwé mímọ́ kannáà pè ní “àwọn ìpilẹ̀ ẹ̀kọ́ ti òdodo.”13 Nísisìyí, lílóye ìsopọ̀ náà ní àárín ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àti agbára ni ẹ̀kọ́ kan náà tí ẹbí ẹ̀dá ènìyàn dábíi pé wọn kò tíi le kọ́ rárá, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run ọ̀run àti ayé wí!14

Àti pé kínni àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọnnì? Ó dára, wọ́n ti jẹ́ títò sílẹ̀ lemọ́lemọ́ nínú ìwé mímọ́, a ti fiwọ́n kọ́ni lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kansíi nínú àwọn ìpàdé àpapọ̀ bíi èyí, àti pé ní àkókò iṣẹ́ ìríyjú wa, a fi wọ́n kọ́ Wòlíì Joseph Smith ní ìdáhùn sí ẹ̀dà igbe tirẹ̀ pé “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀mí sílẹ̀?”15 Nínú àhámọ́ tútù àti àìsí àmójútó ti Ẹ̀wọ̀n Liberty, a kọ́ ọ pé àwọn ìpilẹ̀ ẹ̀kọ́ ti òdodo ní irú àwọn ìwà bíi sùúrù, ìpamọ́ra, ìrẹ̀lẹ̀, àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn nínú.15 Ní mímúkúrò àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọnnì, ó dájú pé a ó dojúkọ ìríra àti ọ̀tẹ̀ nígbẹ̀hìn.

Nípa èyí, njẹ́ kí nsọ̀rọ̀ lotitọ nípa ìmúkúrò nínú àwọn ibìkan nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti òdodo ní ìgbà tiwa wọ̀nyí. Bí òfin, mó jẹ́ àìlèmú, ẹni ọlọ́yàyà kan, àwọn ohun dídára àti ẹlẹ́wà sì wà ní ayé wa. Dájúdájú a ní àwọn ìbùkún ti ara ju ìran eyikeyi nínú àkọọ́lẹ̀-ìtàn, ṣùgbọ́n nínú àṣà sẹ́ntúrì mọ́kànlélógún gbogbogbò àti léraléra si nínú Ìjọ, a ṣì nrí àwọn ìgbé ayé tí ó wà nínú ìdàmú, pẹ̀lú àdéhùn tí ó jáde nínú jíjá púpọ̀jù àwọn májẹ̀mú àti púpọ̀jù àwọn ìrora ọkàn. Ẹ ro èdè líle ti ìbádọ́gba ìrèkọjá ìbáralòpọ̀, méjèèjì èyí tí ó nwà nígbàgbogbo nínú fíìmù tàbí lórí amóhùnmáwòrán, tàbí àkọsílẹ̀ ránpẹ́ ìhalẹ̀ ìbaralòpọ̀ àti àwọn ipò àìdára míràn ti a ka púpọ̀ gan nípa rẹ̀ ní ibi-iṣẹ́. Nínú ọ̀ràn ìṣòdodo ti májẹ̀mú, ohun mímọ́ ni à nmú wọpọ̀ nígbàkugba àti pé ohun mímọ́ ni à nmú díbàjẹ́ nígbàkugbà. Sí ẹnikẹ́ni tí ó ngba àdánwò láti rìn tàbí sọ̀rọ̀ tàbí hùwà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí— “bí ayé tií fúnni,” kí a wí bẹ́ẹ̀—ẹ máṣe retí rẹ̀ kí ó darí sí ìrírí àláfià; mo ṣe ìlérí fún yín ní orúkọ Olúwa pé kò ní rí bẹ́ẹ̀. “Ìwà-ìkà kìí ṣe ìdùnnú,”17 ni wòlíì àtijọ́ kan sọ nígbàkan. Nígbàtí ijo bá parí, olùkọrin gbọ́dọ̀ gbá owó rẹ̀ nígbàgbogbo, àti pé nígbàkugbà jùlọ oye owó njẹ́ ẹkún àti àbámọ̀.18

Tàbí bóyá a rí àwọn ọ̀nà ìlòkulò míràn tàbí àìníyì. Bí a ṣe ní láti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣe bí ọmọẹ̀hìn Olúwa Jésù Krístì láti máṣe kópa ní èyíkéyí irú ìwà bẹ́ẹ̀. Kò sí ọ̀nà tí ó yẹ kí a fi jẹ̀bi ṣíṣe ìjọba àìṣòdodo tàbí irú èyíkéyi ìlòkulò tàbí ìwà ipá búburú—kìí ṣe àfojúrí tàbí ẹ̀dùn-ọkàn tàbí àlùfáà tàbí ti irú èyíkéyi míràn. Mo rántí bí iyè mi ṣe ṣí nípasẹ̀ ìtara Ààrẹ Gordon B. Hinckley nígbàtí ó sọ̀rọ̀ sí àwọn ọkùnrin Ìjọ nípa àwọn wọnnì tí ó pè ní “oníwà ipá nínú ilé arawọn ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn”:19

“Bí ìṣẹ̀lẹ̀ ìlòkulò ìyàwó ti jẹ́ búburú àti rírínilára pátápátá tó,” ni ó sọ. “Èyíkéyi ọkùnrin nínú Ìjọ yi tí ó lo ìyàwó rẹ̀ ní ìlòkulò, tí ó tẹ́mbẹ́lú rẹ̀, tí ó ṣáátá rẹ̀, tí ó lo ìjọba àìṣòdodo lé e lórí jẹ́ àìyẹ láti ní oyè àlùfáà. [Òun] jẹ́ àìyẹ láti ní ìwé ìkaniyẹ ti tẹ́mpìlì.”20 Búburú bákannáà, ni eyikeyi irú ìlòkulò ọmọ—tàbí èyíkéyí irú ìlòkulò míràn, ni ó sọ.20

Nínú àwọn àpẹrẹ púpọ̀, bíbẹ́ẹ̀kọ́ àwọn ọkùnrin olódodo, obìnrin, àní àti àwọn ọmọ lè lẹ́bi ti sísọ̀rọ̀ àìdára, àní ìparun, sí àwọn wọnnì ẹnití wọ́n lè ṣe èdidì pẹ̀lú nípasẹ̀ ìlànà mímọ́ kan nínú tẹ́mpìlì Olúwa. Gbogbo ènìyàn ní ẹ̀tọ́ láti ní ìfẹ́ni, nimọ̀lára àláfíà, àti láti rí ààbò ní ilé. Ẹ jọ̀wọ́, njẹ́ kí a gbìyànjú láti ṣe ìmúdúró àyíká náà níbẹ̀. Ilérí ti jíjẹ́ onílàjà ni pé ìwọ ó ní Ẹmí Mímọ́ bíi ojúgbà rẹ ní gbogbo ìgbà, àwọn ìbùkún yío sì ṣàn sí ọ̀dọ̀ rẹ “láìsí àwọn ọ̀nà dandan” títí láé.23 Kò sí ẹnìkẹ́ni tí ó nílò ahọ́n mímú tàbí àwọn ọ̀rọ̀ àìdára láti “kọ orin ìfẹ́ ìràpadà.”23

Njẹ́ kí nparí níbití mo ti bẹ̀rẹ̀. Ọla ni Ọdún Àjínde, àkókò kan fún òdodo ti àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere Jésù Krístì ati Ètùtù Rẹ̀ láti “kọjá lóri” ìjà àti rògbòdìyàn, lóri àìnírètí àti ìrékọjá, àti ní ìgbẹ̀hìn lóri ikú. Ó jẹ́ àkókò láti ṣe ìlérí ìṣòótọ́ pátápátá ní ọ̀rọ̀ àti ìṣe sí Ọdọ́ Àgùtàn Ọlọ́run, ẹnití “ó [ru] àwọn ìbànújẹ́ wa, tí ó sì gbé àwọn ìkorò wa lọ”24 nínú ìpinnu Rẹ̀ láti parí iṣẹ́ ìgbàlà ní ìtìlẹhìn wa.

Àní pẹ̀lú ìwà ọ̀dàlẹ̀ àti ìrora, àní pẹ̀lú ìṣekúṣe àti ìwà ìkà, nígbàtí ó nṣe àkópọ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ẹbí ẹ̀dá ènìyàn, Ọmọ Ọlọ́run Alààyè tún le bojú wolẹ̀ sí ipa ọ̀nà gígùn ti ayé iku, ó rí wa, ó sì sọ pé: “Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ pẹ̀lú yín, àlààfíà mi ni mo fi fún yín: kìí ṣe bí ayé tií funni, ni emi fifun yín. Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó wárìrì.”24 Kí ẹ ní Ọdún Àjínde alábùkúnfún, aláyọ̀, àti àlàáfíà. Àwọn ìṣeéṣe rẹ̀ tí a kò tíi sọ ni a ti san nípasẹ̀ Ọmọ Aládé Alàáfíà náà, ẹni tí mo fẹ́ràn pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi, ẹnití èyí iṣe Ìjọ rẹ̀, àti nípa ẹni tí mo jẹ́ ẹ̀ri àìlẹ́gbẹ́, àní Olúwa Jésù Krístì, àmín.