Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Wọn Kò Le Borí, A Kò Le Ṣubú
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Wọn Kò Le Borí, A Kò Le Ṣubú

Bí a bá kọ́ ìpìlẹ̀ wa lé orí Jésù Krístì, a kò le ṣubú!

Wòlíì wa ọ̀wọ́n, Ààrẹ Russell M. Nelson, sọ nínú ìpàdé àpapọ gbogbogbò wa tó kẹ́hìn pé: “Ní àwọn ìgbà èwu wọ̀nyí nípa èyí tí Àpóstélì Páùlù sọtẹ́lẹ̀, Sátánì kò tilẹ̀ gbìyànjú láti fi àwọn àtakò rẹ̀ pamọ́ lórí ẹ̀tò Ọlọ́run. Ibi híhàn-gboro wà káàkiri. Nítorínáà, ọ̀nà kanṣoṣo láti wà láìléwu níti ẹ̀mí ni láti pinnu láti jẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ayé wa, láti kọ́ láti gbọ́ ohun Rẹ̀, àti láti lo agbára wa láti ṣèrànwọ́ kó Ísráẹ́lì jọ.”1

Bí a ti ngbèrò ìfipè ti wòlíì náà láti kọ́ láti gbọ́ ohùn Ọlọ́run, njẹ́ ọkàn wa ti pinnu tàbí ó sé le? Ẹ jẹ́kí a rántí ìmọ̀ràn tí a fúnni nínú Jacob 6:6: “Bẹ́ẹ̀ni, ní òní, tí ẹ̀yin yíò bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn yín le; nítorí kíni ẹ̀yin yíò ṣe kú? Ẹ jẹ́ kí a pinnu láti jẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ìgbé ayé wa.

Báwo ni a ṣ lè jẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ìgbé ayé wa tí kìí sì íṣe èṣù? Nínú Ẹkọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:34 a kà pé, “Nítorínáà, ẹ máṣe bẹ̀rù, ẹ̀yin agbo kékeré; ẹ ṣe rere; jẹ́ kí ayé àti ọ̀run jùmọ̀ takò yín, nítorí bí ẹ̀yin bá jẹ́ kíkọ́ lé orí àpáta mi, wọn kì yíò lè borí.” Ó jẹ́ ìlérí pàtàkì kan. Bíótilẹ̀jẹ́pé ayé àti ọ̀run jùmọ̀ takò wá, wọn kì yíò lè borí bí a bá yàn láti jẹ́ kí Ọlọ́run borí nípa síṣe àgbékalẹ̀ ìgbé ayé wa lé orí àpáta Rẹ̀.

Ní bíbá àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ sọ̀rọ̀, Jésù Krístì kọ́ni nípa ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan àti aṣiwèrè ènìyàn kan, tí a kọsílẹ̀ nínú Matte orí keje ti Májẹ̀mú Titun. Púpọ̀ nínú yín ti gbọ́ orin Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ “Ọlọ́gbọ́n Ènìyàn àti Aṣiwèrè Ènìyàn.”2 Bí ẹ bá ti fi ara balẹ̀ láti ṣe àfiwé àwọn ẹsẹ mẹ́rin inú orin náà, p ó ríi pé àwọn ẹsẹ ìkínní àti ìkejì fi ara jọ àwọn ẹsẹ ìkẹta àti ìkẹrin gidigidi. Méjèèjì àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn àti aṣiwèrè ènìyàn nkọ́ ilé kan. Wọ́n fẹ́ pèsè ìbùgbé tí ó ní ààbò tí ó sì tunilára fún ẹbí wọn. Wọ́n ní ìfẹ́ inú-láti gbé papọ̀ nínú ìdúnnú títí láé bíi ẹbí kan, gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀yin àti èmi. Ipò tí ó wà ní àyíká wọn jẹ́ bákannáà—”Àwọn òjò wá sílẹ̀, àti pé àgbàrá wá sókè.” A nkọ ọ́ ní ìgbà mẹ́fà nígbàtí a bá kọ orin náà. Ìyàtọ̀ kan ṣoṣo ni pé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kọ́ ilé rẹ̀ lé orí àpáta ilé náà sì dúró títí, nígbàti ó jẹ́ pé aṣiwèrè ènìyàn kọ́ ilé rẹ̀ lé orí iyanrìn ilé rẹ̀ sì wó dànù. Nítorínáà, ibi tí ìpìlẹ wa bá wà ṣe pàtàkì púpọ̀, èyí sì ní àyọrísí ìpinnu lórí àbájáde ní ìgbẹ̀hìn àti ní ayérayé.

Mo ní ìrètí mo sì gbàdúrà pé kí gbogbo wa lè rí kí a sì dúró lórí ìpìlẹ̀ tó dájú náà bí a ti nṣe àgbékalẹ̀ ìgbé ayé ọjọ́ iwájú wa. A rán wa létí nínú Helaman 5:12: “Àti nísisìyí, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ rántí, ẹ rántí pé lórí àpáta Olùràpadà wa, ẹnití íṣe Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, ni ẹ̀yin níláti kọ́ ìpìlẹ̀ nyín lé, pé nígbàtí èṣù bá sì fẹ́ ẹ̀fũfù líle rẹ̀ wá, bẹ̃ni, ọ̀pá rẹ̀ nínú ìjì, bẹ̃ni, nígbàtí gbogbo àwọn òkúta yìnyín nínú ìjì líle rẹ̀ bá rọ̀ lé yín kò lè ní agbára lórí yín láti fà yín sínú ọ̀gbun òṣì àti ègbé aláìlópin, nítorí àpáta èyítí a kọ́ yín lé lórí, èyítí íṣe ìpìlẹ̀ tí o dájú, ìpìlẹ̀ èyítí ènìyàn kò lè ṣubú lórí rẹ̀ bí nwọ́n bá kọ́ lé e lórí.”

Èyíinì jẹ́ ìlérí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Bí a bá kọ́ ìpìlẹ̀ wa lé orí Jésù Krístì, a kò le ṣubú! Bí a ti nfaradà pẹ̀lú òtítọ́ dé òpin, Ọlọ́run yío ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àgbékalẹ̀ ìgbé ayé wa le orí àpáta Rẹ̀, “àti pé àwọn ẹnu ọ̀nà ọ̀run apáàdì kì yío le borí wa [us]” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 10:69). Ó ṣeéṣe kí a má le yí gbogbo ohun tó nbọ̀ padà, ṣùgbọ́n a le yan bí a ó ṣe múra sílẹ̀ fún ohun tó nbọ̀.

Àwọn kan nínú wa le rò pé, “Ìhinrere dára, nítorínáà a nílò láti fi í sí inú ìgbé ayé wa, bóyá ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀.” Lílọ sí ilé ìjọsìn ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ kò tó láti kọ́ lé orí àpáta náà. Gbogbo ìgbé ayé wa pátápatá níláti kún fún ìhìnrere Jésù Krístì. Ìhìnrere kìí ṣe apákan ìgbé ayé wa, ṣùgbọ́n ìgbé ayé wa jẹ́ apákan ìhìnrere Jésù Krístì. Ronú nípa rẹ̀. Njẹ́ èyí kìí ṣe òtítọ́ bí? Ìgbé ayé ikú wa jẹ́ apákan odidi èrò ìgbàlà àti ìgbéga.

Ọlọ́run ni Bàbá wa Ọ̀run. Ó fẹ́ràn gbogbo wa. Ó mọ agbára wa dára jùlọ jìnnà ju bí a ti mọ ara wa lọ. Kìí ṣe pé ó mọ gbogbo ìgbé ayé wa nìkan. Ọlọ́run mọ gbogbo ti gbogbo ti gbogbo ọ̀rọ̀ ìgbé ayé wa.

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ tẹ̀lé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n ti wòlíì alààyè wa Ààrẹ Nelson. Bí a ti kọọ́ sílẹ̀ nínú Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹmú 21:5–6:

“Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ẹ̀yin yío gbà, bí ẹnipé láti ẹnu tèmi, pẹ̀lú gbogbo sùúrù àti ìgbàgbọ́.

“Nítorí nípa ṣíṣe àwọn ohun wọ̀nyí ìlẹ̀kùn ọ̀run àpáàdì kò ní borí yín; bẹ́ẹ̀ni, Olúwa Ọlọ́run yíò sì tú gbogbo agbára òkùnkùn ká kúrò ní iwájú yín, yío sì mú àwọn ọ̀run mi tìtì fún rere yín, àti nítorí ògo orúkọ rẹ̀.”

Nítorí ìdí èyí, wọn kò le borí, a kò sì le ṣubú!

Mo jẹ́ ẹ̀rí sí yín pé Krístì yío wá lẹ́ẹ̀kansíi ní ẹ̀ẹ̀kejì bí Ó ti ṣe ní àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n ní àkókò yí, yío jẹ́ pẹ̀lú ogo títóbi àti ọlánlá. Mo ní ìrètí mo sì gbàdúrà pé èmi ó ṣetán láti pàdé Rẹ̀, bóyá ní ẹ̀gbẹ́ ìhín ti ìbòjú tàbí ní ẹ̀gbẹ́ kejì. Bí a ti nṣe àjọyọ̀ nínú ọdún Àjínde ìyanu yi, mo ní ìrètí, nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì àti agbára Àjínde Rẹ̀ (wo Moronì 7:41), èmi ó le lọ sókè k nsì pàdé pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá mi k nsì sọ pé, “O ṣeun.” Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Ẹ Jẹ́ Kí Ọlọ́run Borí; Liahona, Nov. 2020, 94.

  2. “Ọlọgbọ́n Ọkùnrin náà àti Aṣiwere Ọkùnrin náà,” Ìwé Orin Àwọn Ọmọdé, 281.