Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
COVID-19 àti àwọn Tẹ́mpìlì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


COVID-19 àti àwọn Tẹ́mpìlì

Ẹ tẹramọ́ pípa àwọn májẹ̀mú yín àti ìbùkún mọ́ ṣíwájú jùlọ ní inú àti ọkàn yín. Ẹ dúró nínú òtítọ́ sí àwọn májẹ̀mú ti ẹ ti dá.

Ẹ̀yin olólùfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, nítòótọ́ a ti ní àpèjẹ ti ẹ̀mí. Bí mo ṣe dúpẹ́ fún àwọn àdúrà, ọ̀rọ̀, àti orin ti gbogbo ìpàdé àpapọ̀. Ọpẹ́ sí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín fún dídarapọ̀ pẹ̀lú wa, níbikíbi tí ẹ wà.

Ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tó kọjá, nítorí àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 àti ìfẹ́ wa láti jẹ́ ọmọ ìlú rere ní gbogbo ayé, a ṣe ìpinnu líle láti ti gbogbo àwọn tẹ́mpìlì fún ìgbà díẹ̀. Ní àwọn oṣù tó tẹ̀le, a ní ìmọ̀lára ìmísí láti ṣí àwọn tẹ́mpìlì padà díẹ̀díẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀nà ìṣọ́ra púpọ̀. Àwọn tẹ́mpìlì ni à nṣí nísisìyí tí a sì nṣe ní ipele mẹ́rin, ní fífaramọ́ àwọn ìlànà ìjọba ìbílẹ̀ àti àwọn ìṣe ààbò.

Fún àwọn tẹ́mpìlì ní ipele àkọ́kọ́, àwọn lọ́kọ-láyà tí wọ́n ti gba agbára tẹ́mpìlì tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ yege láti ṣe èdidì bí ọkọ àti aya.

Fún àwọn tẹ́mpìlì ní ipele ìkejì, gbogbo ìlànà fún àwọn alààyè nì à nṣe, pẹ̀lú agbára tẹ́mpìlì ti arawa, èdidì ọkọ àti aya, àti àwọn ọmọ sí òbí. A ti tún àwọn ìpèsè ti ipele ìkejì ṣe láìpẹ́ ó sì fi ààyè gba àwọn ọ̀dọ́, ọmọ ìjọ titun, àti àwọn míràn pẹ̀lú ìkaniyẹ ìlò-òpin nísisìyí láti kópa nínú arọ́pò ìrìbọmi fún àwọn babanla wọn.

Fún àwọn tẹ́mpìlì ní ipele ìkẹ́ta àwọn wọnnì pẹ̀lú ìpinnu-ìpàdé lè kópa kìí ṣe nínù àwọn ìlànà fún alààyè nìkan ṣùgbọ́n bákannáà ní gbogbo àwọn ìlànà arọ́pò fún òkú àwọn babanlá.

Ipele kẹrin ni ípadàbọ̀ sí kíkún, ìṣẹ́ ṣíṣe tẹ́mpìlì déédé .

A dúpẹ́ fún sùúrù yín àti iṣẹ́-ìsìn ìfọkànsìn ní àkokò yíyípadà àti ìpènijà yí. Mo gbàdúrà pé ìfẹ́ yín láti jọ́sìn àti láti sìn nínú tẹ́mpìlì tàn mọ́lẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ nísisìyí àti láéláé.

Ẹ lè máa ronú ìgbàtí ẹ̀yin yíò lè padà sí tẹ́mpìlì. Ìdáhùn: Tẹ́mpìlì yín yíò ṣí nígbàtí ìṣe àwọn ìjọba ìbílẹ̀ bá fi ààyè gbàá. Nígbàtí ìṣẹ̀lẹ̀ COVID-19 ni agbègbè yín bá tiwà nínú òpin ààbò, tẹ́mpìlì yín yíò ṣí padà. A gbà yín níyànjú láti ṣe gbogbo ohun tí ó lè ràn yín lọ́wọ́ láti mú oye COVID-19 wálẹ̀ ní agbègbè yín kí ànfàní tẹ́mpìlì yín lè pọ̀ si.

Nibayi, ẹ tẹramọ́ pípa àwọn májẹ̀mú yín àti ìbùkún mọ́ ṣíwájú ní inú àti ọkàn yín. Ẹ dúró nínú òtítọ́ sí àwọn májẹ̀mú ti ẹ ti dá.

À ngbéga nísisìyí fún ọjọ́ ọ̀la! Tẹ̀mpìlì mọ́kànlélógójì ni wọ́n wà lábẹ́ kíkọ́ tàbí àtúnṣe. Ní ọdún tó kọjá lásán, bíotilẹ̀jẹ́pé àjàkálẹ̀ àrùn wa, a ṣe ìfọ́lẹ̀ fún àwọn tẹ́mpìlì titun mọ́kànlélógún.

A fẹ́ mú ilé Olúwa wá sítòsí àwọn ọmọ ìjọ, kí wọ́n lè ní ànfàní mímọ́ ti lílọ sí tẹ́mpìlì léraléra bí ipò wa ṣe fi ààyè gbà.

Bí mo ti kéde ètò wa láti kọ́ ogun tẹ́mpìlì si, mo ronú mo sì yin àwọn olùlànà—lọ́wọ́lọ́wọ́ àti ìkọjá—àwọn tí ìyàsọ́tọ̀ ayé wọn ti ṣèrànwọ́ láti mú àkọọ́lẹ̀-ìtàn òní ṣeéṣe. A ó kọ́ tẹ́mpìlì titun kọ̀ọ̀kan sí ibí wọ̀nyí: Oslo, Norway; Brussels, Belgium; Vienna, Austria; Kumasi, Ghana; Beira, Mozambique; Cape Town, South Africa; Singapore, Republic of Singapore; Belo Horizonte, Brazil; Cali, Colombia; Querétaro, Mexico; Torreón, Mexico; Helena, Montana; Casper, Wyoming; Grand Junction, Colorado; Farmington, New Mexico; Burley, Idaho; Eugene, Oregon; Elko, Nevada; Yorba Linda, California; àti Smithfield, Utah.

Iṣẹ́ tẹ́mpìlì ni kókó ara Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀. Àwọn ìlànà tẹ́mpìlì kún inú ayé wa pẹ̀lú agbára àti okun tí kò sí ní ọ̀nà míràn. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àwọn ìbùkún wọnnì.

Bí a ṣe parí ìpàdé àpapọ̀ yí, a fi ìfẹ́ wa hàn fún yín lẹ́ẹ̀kansi. A gbàdúra pé Ọlọ́run yíò ṣe ìtọ́jú yíò sì da àwọn ìbùkún Rẹ̀ lé yín lórí. Lápapọ̀ a wà nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ Rẹ̀. Pẹ̀lú ìgboyà, ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ológo ti Olúwa! Fún èyí ni mo gbàdúrà ni orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.