Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ohun ti A Nkọ́ tí A Kò Sì Ní Gbàgbé Laé
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Ohun ti A Nkọ́ tí A Kò Sì Ní Gbàgbé Laé

Bí ẹ bá wo ìgbé ayé yín pẹ̀lú àdúrà, mo gbàgbọ́ pé ẹ ó rí àwọn ọ̀nà pùpọ̀ nínú èyí tí Olúwa ntọ́ yín la àkókò ìṣoro yi kọjá.

Ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n, mo ti fojúsọ́nà sí ìpàdé ti orí afẹ́fẹ́ yí pẹ̀lú yín. Ìgbà ìkẹhìn tí a ṣe abala oyè àlùfáà ti ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ni Oṣù Kẹrin 2019. Ohun púpọ̀ ti ṣẹlẹ̀ láàrin ọdún, méjì tó kọjá! Awọn kan nínú yín ti pàdánù àwọn olólùfẹ́. Àwọn míràn ti pàdánù iṣẹ́; ọ̀nà àtijẹ tàbí ìlera. Síbẹ̀ àwọn míràn ti pàdánù èrò orí ti àlàáfíà tàbí ìrètí fún ọjọ́ iwájú. Ọkàn mi lọ sí ọ̀dọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan yín tí ó ti jìyà àwọn àdánù wọ̀nyí tàbí òmíràn. Mo máa ngbàdúrà nígbà gbogbo pé Olúwa yío tùyín nínú. Bí ẹ ti ntẹ̀síwájú láti jẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ayé yín, mo mọ̀ pé Ó ní ìgbẹkẹ̀lé nípa ọjọ́ ọ̀la yín bí Òun ti máa nwà láeláé.

Láàrin àwọn àdánù tí a ti ní ìrírí, àwọn nkan díẹ̀ wà bákannáà tí a ti . Àwọn kan ti rí ìgbàgbọ́ tí ó jinlẹ̀ síi nínú Bàbá wa Ọrun àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Púpọ̀ ti rí ìkíyèsí titun nípa ìgbé ayé—àní ìkíyèsí ti ayérayé. Ẹyin kan le ti ri àwọn ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán síi pẹ̀lú àwọn olùfẹ́ yín àti pẹ̀lú Olúwa. Mo sì ní ìrètí pé ẹ ti rí àlẹ́kún agbára láti gbọ́ Tirẹ̀ àti láti gba ìfihàn ti ara ẹni. Àwọn àdánwò líle máa nfi ìgbà gbogbo pèsè àwọn ànfàní láti dàgbà tí kò ní wá ní èyíkeyi ọ̀nà míràn.

Ẹ ronú padà lóri àwọn ọdún méjì tó kọjá. Báwo ni ẹ ti dàgbà? Kíni ẹ ti kọ́? Ẹ lè ti kọ́kọ́ fẹ́ pé kí ẹ padà sí 2019 kí ẹ sì dúró síbẹ̀! Ṣùgbọ́n bí ẹ bá wo ayé yín pẹ̀lú àdúrà, mo gbàgbọ́ pé ẹ ó rí àwọn ọ̀nà púpọ̀ nínú èyí tí Olúwa ti ntọ́ yín la àkókò ìṣoro yi kọjá, tí ó nràn yín lọ́wọ́ láti di ọkùnrin olùfọkànsìn síi, ẹnití ó ní ìyípadà ọkàn síi—ènìyàn Ọlọ́run ní tòótọ́.

Mo mọ̀ pé Olúwa ní àwọn ètò nlá àti yíyanilẹ́nu fún wa—bí ẹnìkọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀. Pẹ̀lú àánú àti sùúrù, Ó wípé:

“Ẹyín jẹ́ ọmọ kékeré, ẹ̀yin kò sì tíì ní òye síbẹ̀ bí àwọn ìbùkún ti tóbi tó tí Bàbá … ti múrasílẹ̀ fún yín;

“Ẹyin kò sì lè gba ohun gbogbo mọ́ra nísisìyí; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ tújúká, nítorí èmí ó darí yin lọ.”1

Ẹyin arákùnrin mi, mo jẹ́ri pé Ó ti wà, Ó , ndarí wa lọ, nítòótọ́ bí a ti nlépa láti gbọ́ Tirẹ̀. Ó fẹ́ kí a dàgbà kí a sì kọ́ ẹ̀kọ́, àní—bóyá ní pàtàkì la—ìpọ́njú já.

Ìpọ́njú jẹ́ olùkọ́ni nlá. Kínni ti kọ́ nínú ọdún méjì tó kọjá tí ẹ fẹ́ máa rántí nígbà gbogbo? Àwọn ìdáhun yín yio jẹ́ àrà àìláfiwé síi yín, ṣùgbọ́n njẹ́ mo le dábáà àwọn ẹ̀kọ́ mẹ́rin kan tí mo ní ìrètí pé gbogbo wa ti kọ́ tí a kò sì níi gbàgbé láe.

Ẹkọ́ 1: Ibùgbé Ni Ààrin Gbùngbùn Ìgbàgbọ́ àti Ìjọ́sìn

Nígbà púpọ̀ tí Olúwa bá nkìlọ̀ fúnwa nípa àwọn ìparun ọjọ́ ìkẹhìn, Ó fúnni ní ìmọ̀ràn báyìí: “Ẹ máa dúró ní àwọn ibi mímọ́, kí ẹ má sì ṣe yẹsẹ̀.”2 “Àwọn ibi mímọ́” wọ̀nyí dájúdájú ní àwọn tẹ́mpìlì Olúwa àti àwọn ilé ìpàdé. Ṣùgbọ́n bí agbára wa láti péjọ nínú àwọn ibi wọ̀nyí ti ní ìdènà ní àwọn ìpele yíyàtọ síra, a ti kọ́ ẹ̀kọ́ pé ọ̀kàn nínú àwọn ibi mímọ́ jùlọ ni ilé—bẹ́ẹ̀ni, àní ilé yín .

Ẹyin arákùnrin, ẹ ní oyè àlùfáà ti Ọlọ́run. “Àwọn ẹ̀tọ́ ti oyè alùfáà ní ìsopọ̀ àìlepínníyà pẹ̀lú àwọn agbára ti ọ̀run.”3 Ẹyin àti àwọn ẹbí yín ti gba àwọn ìlànà oyè àlùfáà. Ó jẹ́ pé “nínú àwọn ìlànà [ti oyè àlùfáà] ni agbára jíjẹ́ ti ọ̀run nfarahàn.”4 Agbára náà wà fún yín àti ẹbí yín nínú ilé tiyín bí ẹ ti npa àwọn májẹ̀mú tí ẹ ti dá mọ́.5

Bíi ọdún marunlelọgọsan sẹ́hìn, ní ọjọ́ náà gan, Ọjọ́ Kẹta Oṣù Kẹrin, 1836, Elijah mú àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà tí ó fàyè gba àwọn ẹbí láti ṣe èdidì papọ̀ títíláé padàbọ̀sípò. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ ìmọ̀lára dídára láti ṣe ìpínfúnni oúnjẹ Olúwa nínú ilé yín. Báwo ni ó ṣe kan àwọn ẹbí yín láti rí yín—bàbá wọn, bàbá àgbà, ọkọ, ọmọkùnrin, tàbí arákùnrin—tí ò nṣe ìpínfúnni ìlànà mímọ́ yi? Kíni ẹ ó ṣe lati mú ìmọ̀lára mímọ́ náà dúró nínú ẹbí yín?

Ẹ lè ní ìmọ̀lára pé ó ṣì ku ohun tí ẹ nílò láti ṣe síi láti mú kí ilé yín jẹ́ ibi mímọ́ ti ìgbàgbọ́. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́ ṣe é. Bí o bá ti gbéyawó, dámọ̀ràn pẹ̀lú ìyàwó rẹ bíi alábáṣepọ̀ dídọ́gba nínú iṣẹ́ pàtàkì yí. Àwọn ìlépa díẹ̀ wà tí ó ṣe pàtàkì ju èyí lọ. Láàrin ìsisìyí àti ìgbà tí Olúwa yío padà wá, gbogbo wa nílò àwọn ilé wa láti jẹ́ àwọn ibi àlàáfíà àti ààbò.6

Àwọn ìhùwàsí àti àwọn ìgbésẹ̀ tó npe Ẹ̀mí yío ṣe àfikún ìwà mímọ́ ti ilé yín. Dídájú bákannáà ni òtítọ́ pé ìwà mímọ́ yío parẹ́ bí ohunkóhun bá wà nínú ìwà tàbí àyíká yín tí ó nmú Ẹmí Mímọ́ binú.”7

Njẹ́ ẹ ti ròó rí ìdí tí Olúwa fi nfẹ́ kí a mú àwọn ilé wa ẹ́ ààrin gbùgbun ikẹkọ ìhìnrere àti ìgbé ayé ìhìnrere? Kìí ṣe láti múwa gbaradì fún, àti kí ó rànwá lọ́wọ́ kọjá nínú, àjàkálẹ̀ àrùn kan lásán. Àwọn ìdènà lọ́wọ́lọ́wọ́ yi lórí ìpéjọpọ̀ yío dópin níkẹhìn. Ṣùgbọ́n, ìfarajìn yín láti mú ilé yín jẹ́ kókó ibi mímọ́ ti ìgbàgbọ́ kò gbọdọ̀ dópin láé . Bí ìgbàgbọ́ àti ìwà mímọ́ ti ndínkù nínú ayé tó nṣubú yi, ìnílò yín fún àwọn ibi mímọ́ nlékún. Mo rọ̀ yín láti tẹ̀síwájú láti máa mú ilé yín jẹ́ ibi mímọ́ nítõtọ́ “àti pé kí ẹ máṣe yẹsẹ̀8 kúrò nínú kókó àfojúsùn náà.

Ẹkọ́ 2: A Nílò Ara Wa

Ọlọ́run fẹ́ kí á ṣiṣẹ́ papọ̀ kí a sì ran ara wa lọ́wọ́. Ìdí nìyí tí Ó fi rán wa wá sí ilẹ̀ ayé nínú àwọn ẹbí tí Ó sì ṣètò wa sínú àwọn wọ́ọ̀dù àti àwọn èèkàn. Ìdí nìyí tí Ó fi sọ fúnwa láti sìn kí a sì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ara wa. Ìdí nìyí tí Ó fi sọ fúnwa láti gbé nínú ayé ṣùgbọ́n kí a máṣe jẹ́ ti ayé.9 A le ṣe àṣeyọrísí ohun púpọ̀ síi lápapọ̀ ju bí a ti le dá nìkan ṣe lọ.10 Ètò ìdùnnú ti Ọlọ́run yío di mímú rẹ̀wẹ̀sì bí àwọn ọmọ Rẹ̀ bá dúró nínú ìyàsọ́tọ̀, ọ̀kàn kúrò lọ́dọ̀ òmíràn.

Àjàkálẹ̀ àrùn ti àìpẹ́ yí ti jẹ́ àìláfiwé fún ìdí pé ó ti kan gbogbo ènìyàn ní àgbáyé ní àkókò kannáà tí ó ṣe kókó. Nígbàtí àwọn kan ti jìyà ju àwọn miràn lọ, gbogbo wa ti ní ìpèníjà ní àwọn ọ̀nà kan, Nítorí èyí, àdánwò wa tí ó wọ́pọ̀ ni agbára láti ṣèrànwọ́ láti mú ìrẹ́pọ̀ wá fún àwọn ọmọ Ọlọ́run ju bí ó ti wà rí láé. Nítorínáà, mo bèèrè, njẹ́ àdánwò tí a pín yí fà yín súnmọ́ àwọn aládugbò yín bí—sí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin ní odìkejì òpópónà ati kaàkiri àgbáyé?

Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn òfin nlá méjì le tọ́ wa sọ́ná: ìkínní, láti fẹ́ Ọlọ́run àti, ekejì, láti fẹ́ aladugbò wa.11 A nfi ìfẹ́ wa hàn nípa sísìn.

Bí ẹ bá mọ nípa ẹnìkan tí ó nìkan wà, nawọ́ jáde síi— àní bí ìwọ bá ní ìmọ̀lára dídáwà bákannáà! Ẹ kò nílò láti ní èrèdí tàbí ọ̀rọ̀ tàbí ọrọ̀-ajé láti ṣe. Ìwọ kàn ṣe hẹ́lòó kí o sì fi ìfẹ́ hàn. Ìmọ̀ ẹ̀rọ lè ràn yín lọ́wọ́. Àjàkálẹ̀ àrùn tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, ikọ̀ọ̀kan ọmọ iyebíye ti Ọlọ́run nílò láti mọ̀ pé òun, lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin, kò dá nìkan wà.

Ẹ̀kọ́ 3: Iyejú Oyè-Àlùfáà Yín Wà Fún Ju Ìpàdé kan Lásán Lọ

Ní ìgbà àjàkálẹ̀ àrùn, àwọn ìpàdé Ọjọ́ Ìsinmi ti Ìyejú ní a fagilé fún ìgbà kan. Àwọn ìyejú kan ti le pàdé nisisìyí lórí afẹ́fẹ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ tí Olúwa ti fi fún àwọn iyejú oyè-àlùfáà kò fi ìgbà kankan wá fún híhámọ́ sí ìpàdé kan. Àwọn ìpàdé jẹ́ apákan kékeré nìkan nínú ohun tí iyejú kan wà fún àti ohun tí ó le ṣe.

Ẹyin arákùnrin mi ti Oyè Àlùfáà Áárónì àti ẹ̀yin iyejú ti àwọn alàgbà, ẹ mú ìran ìfojúsùn yín gbòrò nípa ìdí tí a fi ní àwọn iyejú. Báwo ni Olúwa ti fẹ́ kí ẹ lo iyejú yín láti ṣe iṣẹ́ Rẹ̀ yọrí—nísisìyí? Ẹ wá ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀. Ẹ bèèrè! Ẹ fetísílẹ̀! Bí a bá ti pè yín láti dárí, dámọ̀ràn bí àjọ ààrẹ àti pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ iyejú. Èyíkéyí ipò iṣẹ́ ti oyè àlùfáà tàbí ìpè yín, ẹ jẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ìfarajìn yín bíi ọmọ ẹgbẹ́ ti iyejú yín àti nínú iṣẹ́ ìsìn yín. Pẹ̀lú ayọ̀ ẹ ní ìrírí ìwà òdodo tí ẹ ó mú wá sí ìmúṣẹ bí ẹ ti “nlọ́wọ́ nínú iṣẹ́ rere pẹ̀lú ìtara.”12 Àwọn iyejú wà ní ipò àrà ọ̀tọ̀ láti mú kíkójọ Ísráẹ́lì ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú yá kánkán.

Ẹ̀kọ́ 4: A Ngbọ́ Jésù Krístì Dáradára Síi Nígbàti A Bá Dúró Jẹ́ẹ

A ngbé nínú àkókò kan tí a ti sọtẹ́lẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn, nígbàtí “ohun gbogbo yío wà ní ìdárúdàpọ̀; ọkàn àwọn ọkùnrin yío sì já wọn kulẹ̀; nítorí èrù yío wá sí orí gbogbo ènìyàn.”13 Èyí jẹ́ òtítọ́ ṣaájú àjàkálẹ̀ àrùn, yío sì jẹ́ òtítọ́ lẹ́hìnwá. Ìdàrúdàpọ̀ nínú ayé yío tẹ̀síwájú láti máa pọ̀ síi. Ní ìlòdì sí, ohùn Olúwa kì í ṣe “ohùn ariwo ìrúkèrúdò nlá, ṣùgbọ́n … ó [jẹ́] ohùn jẹ́jẹ́ ti ìdákẹ́ rọ́rọ́ pípé, [bíi] ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ó sì [wọ] inú ọkàn lọ.”14 Kí ẹ le gbọ́ ohùn jẹ́jẹ́ yi, ẹ̀yin pẹ̀lú gbọdọ̀ dúró jẹ́!15

Fún ìgbà kan, àjàkálẹ̀ àrùn náà ti fagilé àwọn àwọn ìṣe ìdárayá tí ìbá kún ìgbé ayé wa. Láìpẹ́ ó ṣeéṣe kí a lè yàn láti kún àkókò náà lẹ́ẹ̀kansíi pẹ̀lú ariwo àti ìdàrúdàpọ̀ ti ayé. Tàbí a le lo àkókò wa láti gbọ́ ohùn ti Olúwa tí nsọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ní ti ìtọ́ni, ìtùnú, àti àlàáfíà Rẹ̀. Àkokò ìdákẹ́rọ́rọ́ jẹ́ àkokò mímọ́—àkokò tí yío ṣe okùnfà ìfihàn ti ara ẹni tí yío sì gbìn àlàáfíà.

Ẹ kó ara yín níjanu láti ní àkokò dídáwà àti pẹ̀lú àwọn olóùfẹ́ yín. Ẹ ṣí ọkàn yín sí Ọlọ́run nínú àdúrà. Ẹ mú àkókò láti ri ara yín sínú àwọn ìwé mímọ́ kí ẹ sì máa jọ́sìn ní tẹ́mpìlì.

Ẹyin arákùnrin mi ọ̀wọ́n, àwọn ohun púpọ̀ wà tí Olúwa fẹ́ kí a kọ́ láti inú àwọn ìrírí wa ní ìgbà àjàkálẹ̀ àrùn yi. Mo ti to mẹ́rin péré sílẹ̀. Mo pè yín láti ṣe títò sílẹ̀ tiyín, ẹ gbèrò rẹ̀ pẹ̀lú ìṣọ́ra, kí ẹ sì pín in pẹ̀lú àwọn wọnnì tí ẹ fẹ́ràn.

Ọjọ́ ọ̀la jẹ́ mímọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí wọ́n npa májẹ̀mú mọ́.”16 Olúwa yío máa pe àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ ní púpọ̀ síi tí wọ́n yẹ láti ní oyè àlùfáà láti bùkún, tù nínú, àti láti fún ẹ̀dá èniyàn lókun, àti láti ṣe ìrànwọ́ láti múra ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Rẹ̀. Ó yẹ kí olukúlùkù wa kún ojú òsùnwọ̀n sí ìlànà mímọ́ tí a ti gbà. A lè ṣeé! Mo jẹri bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú fífi ìfẹ́ mi hàn fún ọ̀kọ̀ọ̀kan yín, ẹ̀yin olólùfẹ́ arákùnrin mi, ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.