Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Isà Òkú Kò Ní Ìṣẹ́gun
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Isà Òkú Kò Ní Ìṣẹ́gun

Mo jẹ́ri pé nípasẹ̀ Ètùtù ìràpadà àti Àjínde ológo ti Jésù Krístì, àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn lè rí ìwòsàn, ìbànújẹ́ lè di àlàáfíà, àti pé àìní-ìrètí lè di ìrètí.

Ní ọjọ́ àjínde ológo yi, àwọn ọmọ wa fi ayọ̀ kọrin, “Ní àkókò ìgbà òjò dídán bíi góòlù kan, Jésù Krístì jí ó sì lọ kúrò ní ibojì níbití ó ti sùn; ìdè ikú ni ó já.”1

A dúpẹ́ fún ìmọ̀ wa nípa Àjínde Jésù Krístì. Àti pé síbẹ̀síbẹ̀, ní àkókò kan nínú àwọn ìgbésí ayé wa, àwa ìbá ti ní ìbànújẹ́ ọkàn lẹ́hìn pípàdánù ẹnìkan tí à nífẹ gidigidi. Nípasẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn àgbáyé lọ́wọ́lọ́wọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ti pàdánù àwọn àyànfẹ́—bóyá àwọn mọ̀lẹ́bí tàbí àwọn ọ̀rẹ́2 A gbàdúrà fún àwọn tí nbanújẹ́ irú ìsọnu náà.

Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ́ pé:

“Láìbìkítà ọjọ́-orí, a ṣọ̀fọ̀ fún àwọn tí a nífẹ tí a sì pàdánù. Ìbànújẹ́ jẹ́ ọkàn nínú àwọn ìjìnlẹ̀ ìfihàn ifẹ pípé. …

“Pẹ̀lúpẹ̀lù, a kò lè mọ rírì ní kíkún àwọn ìdàpọ̀ ayọ̀ lẹ́hìnnáà láìsí àwọn ìpínyà olómijé báyi. Ọ̀nà kan tí ó lè mú ìbànújẹ́ kúrò nínú ikú ní láti mú ìfẹ́ kúrò nínú ìgbésí ayé. ”3

Àwòrán
Àwọn ọmọẹ̀hìn obìnrin ṣọ̀fọ̀ Jésù.

A lè ronú báwo ni àwọn ọ̀rẹ́ Jésù, tí ó ti tẹ̀lé E àti ṣe iranṣẹ fun Un,4 fi nímọ̀lára lórí jíjẹ́ri kíkàn mọ́ àgbélébu Rẹ̀ àti ikú Rẹ̀ àti àwọn àmì tí ó yí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nnì ká.5 A mọ̀ pé wọ́n “ṣọ̀fọ̀ wọn sọkún.”6 Ní ọjọ́ kíkàn-mọ́-àgbélébu, láìmọ ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ Ìsinmi, wọ́n gbọ́dọ̀ ti jẹ́ kí ìbẹ̀rù àti ìpọ́njú bo wọn mọ́lẹ̀, ni ìyàlẹ́nu bí wọ́n yíò ṣe lọ láìsí Olúwa wọn. Bí o tì wù kí ó rí, wọ́n tẹ̀síwájú láti ṣe ìránṣẹ́ fún Un paapaa nínú ikú.

Jósẹ́fù ti Arimatéà bẹ Pílátù láti fún òun ní ara Jésù. Ó gbé òkú náà kalẹ̀, ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà dì í, ó tẹ́ ẹ sí ibojì titun tirẹ̀, ó yí òkúta ńlá kan sí ẹnu ọ̀nà ibojì náà.7

Nikodémù mú òjíá àti álóè wá. Ó ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ láti gbé òkú náà ó sì fi aṣọ-ọ̀gbọ̀ bò o pẹ̀lú àwọn tùràrí.8

Màríà Magdalénè àti àwọn obìnrin míran tẹ̀lé Jósẹ́fù àti Níkódémù, wọ́n wo ibi tí wọ́n gbé òkú Jésù si, wọ́n sì pèsè àwọn tùràrí dídùn àti àwọn òróró ìkunra láti yàn án.9 Gẹ́gẹ́bí àwọn òfin tí ó le ní ọjọ́ wọ̀nnì, wọ́n dúró láti múrasílẹ̀ ṣíwájú àti fi òróró yan ara náà nítorí Ọjọ́ Sátidé ni Ọjọ́ ìsimi.10 Lẹ́hìnnáà, ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní ọjọ́ Ìsimi, wọn lọ sí ibojì. Lẹ́hìn tí wọ́n ríi pé ara Olùgbàlà kò sí níbẹ̀, wọ́n lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn tí wọ́n jẹ́ Àwọn Àpóstélì Jésù. Àwọn Àpóstélì wá pẹ̀lú wọn sí ibojì wọ́n sì ríi pé ó ṣófo. Gbogbo wọn ṣùgbọ́n Màríà Magdalene lọ kúrò níkẹhìn, ní ìyàlẹ́nu kíni ó ti ṣẹlẹ̀ sí ara Olùgbàlà.11

Màríà Magdalene dúró sí ibojì ní òun nìkan. Ní ọjọ́ méjì péré ṣáájú, ó ti rí ikú àjálù ti ọ̀rẹ́ àti Ọ̀gá rẹ̀. Báyi ibojì rẹ̀ ṣófo, òun kò sì mọ ibití ó wà. Ó ti pọ̀ púpọ̀ ju fún láti gbàmọ́ra, ó sì sọkún. Ní àkókò yẹn, Olùgbàlà tí ó jínde wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì bèèrè ìdí tí ó fi nsọkún àti pé tani ó nwá. Ní ìrònú pé olùṣọ́gbà ni ó nba sọ̀rọ̀, ó bèèrè pé, tí ó bá mú ara Olúwa rẹ̀, kí ó sọ fún ibití ó wà kí òun lè gbáá.12

Àwòrán
Mary Magdalene

Mo ròó pé Olúwa lè ti fàyè gba Mary Magdalene láti ṣọ̀fọ̀ àti láti fi ìrora rẹ̀ hàn.13 Lẹ́hìnnáà Ó pé ní orúkọ rẹ̀, ó sì yípadà si I ó dá A mọ̀. Ó rí Krístì tí ó jínde ó sì jẹ́ ẹlẹ́ri kan nípa Àjínde ológo Rẹ̀.14

Bíi ìwọ, ní díẹ̀ nínú ọ̀na mo lè ní ìbámu sí ìbànújẹ́ ti Màríà Magdalene àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ní ìmọ̀lára bí wọ́n ṣe banújẹ́ lórí ikú Olúwa wọn. Nígbàtí mo di ọmọ ọdún mẹ́san, arákùnrin mi àgbàlagbà pàdánù nígbà ìwárìrì ilẹ̀ tí ó parun. Nítorí gbogbo rẹ̀ ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, ó gbà mi ní àkókò láti lóye òtítọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Mo ní ìròbìnújẹ́ ọkàn ti ìbànújẹ́ àti ìkorò, èmi yíò sì bèèrè lọ́wọ́ ara mi, “Kíni ó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin mi? Ibo ló wà? Níbo ni ó lọ̀? Njẹ́ èmi ó tún ri i mọ?

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ èmi kò tíì mọ̀ nípa ètò ìgbàlà Ọlọ́run, àti pé mo ní ìfẹ́ láti mọ ibití a ti wá, kíni ìdí ìgbésí ayé wa, àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa lẹ́hìn tí a bá kú. Ṣé gbogbo wa kò ní àwọn ìlọ́ra wọ̀nnì nígbà tí a bá pàdánù ẹnìkan tí a fẹ́ràn tàbí nígbà tí a bá kọjá àwọn ìṣòro ninu igbesi aye wa?

Ní ọdún díẹ̀ lẹ́hìnnà, mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú arákunrín mi ní ọ̀nà kan pàtó. Èmi yíò fojú-inú wo bi ó ti nkan ilẹ̀kùn wa. Èmi yíò ṣí ilẹ̀kùn, òun yíò dúró níbẹ̀, yíò sọ fún mi pé, “Èmi kò kú. Mo wà láàyè. Èmi kò lè wa sí ọ̀dọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n nísisìyí èmi yíò dúró pẹ̀lú rẹ àti pé èmi kò ní lọ mọ́.” Èrò yẹn, fẹ́rẹ́ jẹ́ àlá, ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi láti farada ìrora àti ìbànújẹ́ tí mo mọ̀lára lórí pípàdánù rẹ̀. Ìrònú pé òun yíò wà pẹ̀lú mi wá sí mi lọ́kàn léraléra. Nígbà míràn èmi yíò tilẹ̀ tẹjú sí ẹnu-ọ̀nà, nírètí pé òun yíò kànkùn àti pé èmi yíò rí i lẹ́ẹ̀kansi.

Ní ìwọ̀n ogójì ọdún lẹ́hìnnáà, lákokò Àjínde, mò nronú nípa Àjínde Jésù Krístì mo sì bẹ̀rẹ̀ síí ronú nípa arákùnrin mi. Ní àkókò yẹn, ohunkan tẹ̀ mí lọ́kàn. Mo rántí lérò pé òun nbọ̀ láti wá bá mi.

Lọ́jọ́ náà mo damọ̀ pé Ẹ̀mí ti fún mi ní ìtùnú ní àkókò ìṣòro kan. Mo ti gba ẹ̀rí pé ẹ̀mí arákùnrin mi kò kú; ó wà láàyè. Ó sì nní ìlọsíwájú nínú ìgbé ayérayé rẹ̀. Nísisìyí mo mọ̀ pé “arákùnrin [mi] yíò dìde lẹ́ẹ̀kansi”16 ní àkókò títóbi náà, nítorí Àjínde Jésù Krístì, gbogbo wa ni a o jínde. Ní àfikún, Ó ti jẹ́ kí ó ṣe é ṣe fún gbogbo wa láti tún wà papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbi àti láti ní ayọ̀ ayérayé níwájú Ọlọ́run tí a bá yàn láti ṣe àti láti pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ pẹ̀lu Rẹ̀ mọ́.

Ààrẹ Nelson ti kọ́ni:

“Ikú jẹ́ ipa pàtàkì fún wíwa ní ayérayé wa. Kò sí ẹnìkan tí ó mọ ìgbà tí yíò dé, ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì sí ètò ayọ̀ nlá Ọlọ́run. Ìdúpẹ́ sí Ètùtù Olúwa, ìṣẹ̀lẹ̀ àjínde jẹ́ òtítọ́ àti pé ìyè ayérayé ni ìṣeéṣe kan sí gbogbo ẹlẹ́ran-ara. …

“… Fún ìbànújẹ́ àwọn olólùfẹ́ tí a fi sílẹ̀… oró ikú ni ó rọlẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ ìdúróṣinṣin nínú Krístì, dídán ìmọ́lẹ̀ pípé, ìfẹ́ Ọlọ́run àti ti gbogbo ènìyàn, àti ìfẹ́ jíjinlẹ̀ láti sìn wọ́n. Ìgbàgbọ́ náà, ireti náá, ìfẹ́ náà yíò mú wa yẹ láti wá síwájú Ọlọ́run mímọ́ àti, pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ ayérayé àti àwọn ẹbí wa, ni ijóko pẹ̀lú Rẹ̀ láéláé.”16

Àwòrán
Ọgbà ibojì

Mo jẹri pé “bí Krístì kò bá ti jínde kúrò nínú òkú, tàbí kí ó ti já ìdè ikú, kí ìsà-òkú má lè ní ìṣẹ́gun, àti kí ikú má lè ní oró, kì bá ti sí àjĩnde.

“Ṣùgbọ́n àjĩnde wà, nítorínã ìsà-òkú kò ní ìṣẹ́gun, oró ikú sì jẹ́ gbígbémì nínú Krístì.

“Òun ni ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ayé; bẹ́ẹ̀ni, ìmọ́lẹ̀ tí ó wà láìnípẹ̀kun, tí a kò lè sọ di òkùnkùn; bẹ́ẹ̀ni, àti pẹ̀lú iyé tí ó wà láìnípẹ̀kun, tí kò sì ní sí ikú mọ́.”19

Àwòrán
Olùjínde Olùgbàlà

Jésù Kristi Fúnrarẹ̀ kéde, “Èmi ni àjíǹde, àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, síbẹ̀ yíò yè.”20

Mo jẹ́ri pé nípasẹ̀ Ètùtù ìràpadà àti Àjínde ológo ti Jésù Krístì, àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn lè rí ìwòsàn, ìbànújẹ́ lè di àlàáfíà, àti pé àìní-ìrètí lè di ìrètí. Ó lè gbà wá mọ́ra ní apá àánú Rẹ̀, ìtùnú, ìfúnni-lágbára, ati wíwo ọkọọkan wa sàn. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.