Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ọlọ́run Fẹ́ràn Àwọn Ọmọ Rẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Ọlọ́run Fẹ́ràn Àwọn Ọmọ Rẹ̀

Èmi fẹ́ láti ṣe àbápín àwọn ọ̀nà mẹ́tà pàtò tí Bàbá Ọ̀run ti nfi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn fún wa, àwọn ọmọ Rẹ̀.

Ẹ̀yin arákùnrin àti aràbìnrin, mo yọ̀ pẹ̀lú yín nínú ìhiǹrere jésù Krístì. Mo mu ìfẹ́ wá pẹ̀lú mi láti ọ̀dọ̀ àwọn olùfaradà ọmọ ìjọ ní Philippines, ní ìtìlẹhìn wọn, mo sì wípè, Màbúhày!

Ní òwúrọ̀ Àjínde yí, mo jẹ́ ẹ̀rí nípa Krístì alààyè, pé O jí dìde kúrò nínú òkú àti pé ìfẹ́ Rẹ̀ fún wá àti fún Baba wa ní Ọ̀run jẹ́ mímọ́ àti ayérayé. Ní òní, mo ní ìfẹ́ láti dojúkọ ìfẹ́ni ti Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì fún ènìyàn gbogbo, èyí tí a fihàn nípasẹ̀ Ètùtù Ọmọ Rẹ, Jésù Krístì. “Nítorí Ọlọ̀run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ̀, tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ níkanṣoṣo fúnni” (Jóhánù 3:16).

Nígbàtí ángẹ́lì kan bèèrè lọ́wọ́ wòlíì Néfi nípasẹ̀ ìmọ̀ rẹ̀ nípa Ọlọ́run, Néfì fèsì jẹ́jẹ́, “Mo mọ̀ wípé ó fẹ́ràn àwọn ọmọ rẹ̀” (wo 1 Néfì 11:16–17).

Ẹsẹ kan látinú Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Ẹ̀rí Míràn ti Jésù Krístì ṣe àpèjúwe alágbára nípa ìfẹ́ pípé ti Olùgbàlà: “Aràyè, nítorí àìṣedéédé wọn, yíò sì ṣe ìdájọ́ fún un bí ohun asán; … wọ́n nà á, … wọn si lùú, … wọ́n tutọ́ sórí rẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀, nítorí ti oore rẹ̀ àti ìpamọ́ra rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn” (1 Nephi 19:9). Ìfẹ́ káríayé Olùgbàla ni okun ìwuni lẹ́hìn gbogbo ohun tí Ó ṣe. A mọ̀ pé irú ìfẹ́ kannáà tí Baba ní Ọ̀run ní fún wa ni, nítorí Olùgbàlà fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ kọ́ni pé Òun àti Baba “jẹ́ ọ̀kan” (wo John 10:30; 17:20–23).

Nígbànáà, báwo, ni a ó ṣe sán padà kí a sì fi ìmoore hàn fún ìfẹ́ káríayé Wọn? Olùgbàlà kọ́ wá pẹ̀lú ìfipè jẹ́jẹ́, ìrọ̀gbàká-gbogbo: “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́” (John 14:15).

Ààrẹ Dallin H. Oaks kọ́ni pé, “Ìfẹ́ pípé àti káríayé Ọlọ́run ni a fihàn nínú gbogbo àwọn ìbùkún ti èto ìhìnrere Rẹ̀, pẹ̀lú òtítọ́ pé àwọn àṣàyàn ìbùkún Rẹ̀ ní a fipamọ́ fún àwọn ẹnití ó gbọ́ran sí àwọn àṣẹ Rẹ̀.”1

Èmi fẹ́ láti ṣe àbápín àwọn ọ̀nà mẹ́tà pàtò tí Bàbá Ọ̀run ti nfi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn fún wa, àwa ọmọ Rẹ̀.

Àkọ́kọ́, Ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run àti Ẹbí Fi Ìfẹ́ Rẹ̀ Hàn

Iyì àwọn ìbáṣepọ̀ wa jùlọ wà pẹ̀lú Bàbá àti Ọmọ àti pẹ̀lú àwọn ẹbí wa nítorí ìsopọ̀ wa sí wọn jẹ́ ayèrayè. Ètò nlá ti ìdùnnú ni ìfihàn ìyanu ti ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa. Pẹ̀lú ìdojúkọ ojú wa lórí ètò Ọlọ́run, a fi tìfẹ́-tìfẹ́ yàn láti gbẹ́ ilẹ̀ àti àwọn òkúta jáde ní àárín wa tí ó faramọ́ àwọn ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkàn nínù wa kí a sì rọ́pò wọn pẹ̀lú àwọn ìpìlẹ̀ tí ó ngbé àwọn ìbáṣepọ̀ ayérayé ga. Ní ọgbọ́n kan, èyí ni a lè pè ní “ìhúlẹ̀ ti ẹ̀mí.” Ní ṣiṣe ìhúlẹ̀ ti ẹ̀mí wa, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wá Ọlọ́run kí a sì ké pè É (wo Jeremiah 29:12–13).

Wíwá A àti kíké pè É yíò mú ìlànà wá yíò sì pèsè ààyè láti gbéga àti láti fún àwọn ìbáṣepọ̀ ayérayé wa lókun. Ó nmú ìwò ti ẹ̀mí wa gbòòrò ó sì nràn wá lọ́wọ́ lati dojúkọ yíyí ohun tí a lè darí padà sànjú lórí àwọn ẹ̀rù tí ó kọjá ìdarí wa. Ṣiṣe àṣàrò ìgbé ayé àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, yíò fún wá lágbára láti wo àwọn àníyàn míràn pẹ̀lú ìrò ayérayé.

Àwọn ìdààmú nígbàmíràn lè dènà wá kúrò ní níní ìrírí ìfẹ́ ti Ọlọ́run nínú àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí wa àti àwọn ṣíṣe. Ìyá kan, tí ó ní ìmọ̀lára pé àwọn ohun ìgbàlódé ngbá agbára lórí àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí rẹ̀ wá àbájáde kan. Níbi tábìlì oúnjẹ-alẹ́ àti àwọn àkokò ẹbí míràn, ó pè jáde lásán pé, “àwọn fóònù lórí dẹ́ẹ̀kì; ẹ jẹ́ kí a ní àkokò ìfojúkojú.” Ó wípé èyí ni ìṣe titun fún ẹbí wọn àti pè ó fún àwọn ìbáṣepọ̀ wọn ní okun gẹ́gẹ́bí ẹbí nígbàtí wọ́n ní àkokò ìfojúkojú ní òtítọ́. Nísisìyí wọ́n ngbádùn ìjíròrò Wá, Tẹ̀lẹ́ Mi papọ̀ bí ẹbí dáadáa.

Èkejì, Ó Nfi Ìfẹ́ Rẹ̀ Hàn sí Àwọn Ọmọ Rẹ̀ nípa Pípe àwọn Wòlíì

Ayé wa lọ́wọ́lọ́wọ́ dúró nínú “ogun àwọn ọ̀rọ̀ àti ìrùkèrùdò ti àwọn èrò” (Joseph Smith—History 1:10). Paul rán wa létí pé “onírurú ohùn … ni ó wà ní ayé” (1 Kọ́ríntì 14:10). Èwo nínú àwọn ohùn náà ní ó gòkè ṣákáṣáká tí ó sì ní ìtumọ̀ ju ìjà? Ohùn àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn Ọlọ́run ni.

Mo rántí dájúdájú, lẹ́hìn ṣíṣe iṣẹ́-abẹ ní 2018, lórí pípadà lọ síbí iṣẹ́, mo wà ní gárájì ọkọ̀ ní olú-ilé iṣẹ́ Ìjọ. Lọ́gán, mo gbọ́ ohùn Ààrẹ Russell M. Nelson tí ó npe, “Taniela, Taniela.” Mo sáré síwájú rẹ̀, ó sì bèèrè àláfíà mi.

Mo wípé, “Mò nbọ́sípò dáadáa, Ààrẹ Nelson.”

O fún mi ní ìmọ̀ràn àti ìgbámọ́ra. Mo ní ìmọ̀lára iṣẹ́ ìránṣẹ́ araẹni ti wòlíì kan lódodo “ọ̀kan.”

Ààrẹ Nelson ti rin ìrìnàjò sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè ayé. Nínú mi, òun kò kan ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ẹgbẹgbẹ̀rún lásán, ṣùgbọ́n ó nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ẹgbẹgbẹ̀rún ti “àwọn kan.” Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Ó npín ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀.

Láìpẹ́, àwọn ọ̀rọ̀ Ààrẹ Nelson ti jẹ̀ orísun okun àti ìmísí sí àwọn ènìyàn Philippines. Gẹ́gẹ́bí gbogbo orílẹ̀-èdè ní ayé, ní 2020 àwọn Philippens ní ó ní ìpalára nípasẹ̀ àjàkálẹ̀-àrun COVID-19, bákannáà bi ti bíbú-gbàmù fòlkáníkì, ìṣẹ̀lẹ̀, àwọn ìjì líle, àti àgbàrá ìparun.

Ṣùgbọ́n bíiti òpó ìmọ́lẹ̀ kan tí ó ntàn nínú ìkukù òkùnkùn ẹ̀rù, àdánìkanwa, àti àìnírètí ni àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì ti nwá. Ó pẹ̀lú ìpè fún àwẹ̀ àgbáyé àti àdúrà àti àmọ̀ràn láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú àjàkàlẹ̀ àrùn. Ó pè wá láti ṣe àwọn ilé wa ní ilé-mímọ́ araẹni ti ìgbàgbọ́. Ó pe àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn níbi-gbogbo láti bọ̀wọ̀ fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run àti láti jẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ayé wa.2

Bákannáà wíwọnilọ́kàn ni ẹ̀rí fídíò Ààrẹ Nelson àìpẹ́ nípa agbára ìmoore àti àdúrà ìparí rẹ̀, èyí tí ó tàn káàkiri àwọn Philippine.3 Ní agbègbè ti Leyte, fídíò nṣere ní ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ìgbágbọ́, àti pé bákannáà ó jẹ́ ara ilé ti àlùfáà. Àwọn Philippine, lẹgbẹ pẹ̀lú gbogbo ayé, di alábùkúnfún gidi láti ní ìmọ́lára ìfẹ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ti wòlíì tí a yàn.

Ẹ̀kẹ́ta, Ìbáwí Lè Jẹ́ Ìfihàn Ìfẹ́ Ọlọ́run kan fún àwọn Ọmọ Rẹ̀

Nígbàmíràn Ọlọ́run nfi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn nípa bíbá wa wí. Ó jẹ́ ọ̀nà kan láti rán wa létí pé Ó nifẹ wa Ó sì mọ̀ ẹni tí a jẹ́. Ìlérí ìbùkún àláfíà Rẹ̀ ṣí sílẹ̀ sí gbogbo àwọn ẹni tí wọ́n rìn ní ipá ọ̀nà májẹ̀mú pẹ̀lú ìgboyà tí wọ́n sì nfẹ́ láti gba àtúnṣe.

Nígbàtí a bá dá ìbáwí náà mọ̀ tí a sì jẹ́ olùgbà tọkàntọkàn, ó di ti iṣẹ́-ábẹ ẹ̀mí kan. Tani ó fẹ́ràn iṣẹ́-abẹ, bẹ́ẹ̀ náà? Ṣùgbọ́n sí àwọn ẹni tí ó nílò rẹ̀ tí wọ́n sì fi tọkàntọkàn gbà á. Ó lè jẹ́ ìgbàlà-ẹ̀mí. Olúwa nbá ẹni tí Ó nifẹ wí. Ìwé mímọ́ wí fún wa bẹ́ẹ̀ (wo Hébérù 12:5–11; Hẹ́lámánì 12:3; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 1:27; 95:1). Ìbáwí náà, tàbí iṣẹ́-abẹ ti ẹ̀mí, yíò mú ìyípadà tí a nílò wá nínú ayé wa. Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, a ó dàmọ̀, pé ó nṣe àtúnṣe ó sì nwẹ ohun-èlò inú wa mọ́.

A bá Joseph Smith, wòlíì Ìmúpadàbọ̀sípò, náà wí. Lẹ́hìn tí Joseph sọ àwọn ojú-ewé mẹ́rìndínlọ́gọ́fà àkọsílẹ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì nù, Olúwa bawí bákannáà Ó sì fi ìfẹ́ hàn nípa sísọ wípé: Ìwọ̀ kò níláti bẹ̀rù ènìyàn ju Ọlọ́run lọ. … Ó yẹ kí o jẹ́ olótítọ́. … Kíyèsi, ìwọ ni Joseph, a sì ti yàn ọ́. … Rántí pé, aláàánú ni Ọlọ́run, nítorínáà, ronúpìwàdà” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 3:6–10).

Ní 2016 nígbàtí mò nsìn ní míṣọ̀n kan ní Little Rock, Arkansas, mo ní kí arákùnrin Cava fi ìdí kan jíṣẹ́ fún arábìnrin mi àgbà, ẹni tí ó ngbé lórí erékùṣù ní Fiji. Ìfèsì rẹ̀ kìí ṣe ohun tí mo lèrò. “Ààrẹ Wakolo,” ó ráùn, “arábìnrin rẹ̀ ti kú wọ́n sì ti sín ní ọjọ́ mẹwa sẹ́hìn.” Mo ní ìkẹdùn-araẹni mo sì ní ìmọ̀lára ìbínú díẹ̀ pé ẹbí mi kò tilẹ̀ mira láti jẹ́ kí nmọ̀.

Ní ọjọ́ kejì, nígbàtí ìyàwó mi nkọ́ àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere, èrò yí wá sínú ẹ̀mì mi: “Taniela, gbogbo àwọn ìrírí wọ̀nyí wà fún rere àti ìdàgbàsókè ara rẹ. Ìwọ ti nkọ́ni o sì npín ẹ̀rí rẹ nípa Ètùtù Jésù Krístì; nísisìyí ò ngbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.” A rán mi létí pé “ìbùkún ni fún [àwọn] ẹni tí Ọlọ́run báwí; nítorínáà [kí a] maṣe … gan ìbáwí Olódùmarè” (Job 5:17). Ó jẹ́ iṣẹ́-abẹ ti ẹ̀mí fún mi, àbájáde rẹ̀ sì jẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ngbèrò ìrírí náà, a pè mí láti fúnni ní èrò ìparí mi sí ìjíròrò náà. Ní àárín àwọn ohun míràn, mo pín àwọn ẹ̀kọ́ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ni: èkíní, tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ìbáwí láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́, tí mò sì nifẹ rẹ̀ nítorí èmi nìkan ni ó gbọ́ ọ; èkejì, nítorí ti ìrúbọ àti ìràpadà ti Olùgbàlà, èmi kò ní tọ́ka sí àwọn ìpènijà bí àdánwò àti ìpọ́njú mi mọ́ ṣùgbọ́n bí àwọn ìrírí ikẹkọ mi; àti ìkẹ́ta, nítorí ìgbé-ayé pípé àti àìlẹ́ṣẹ̀ Rẹ̀, èmi kò ní tọ́ka sí àwọn àìṣedéédé àti àìnì-agbára bí àìlera mi mọ́ ṣùgbọ́n sànju bí àwọn ànfàní ìdàgbàsókè mi. Ìrírí yí ràn mí lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Ọlọ́run n bá wá wí nítorí Ó nifẹ wa.

Mo parí pé. Bàbá wa Ayérayé àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístí, fi ìfẹ́ Wọn hàn nípa mímu ṣeéṣe fún wa láti ní àwọn ìbáṣepọ̀ ayérayé pẹ̀lú Wọn àti ọmọ ẹbí wa, nípa pípe àwọn wòlíì òde-òní láti kọ́ni àti láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí wa, àti nípa bíbá wa wí láti ràn wá lọ́wọ́ ní kíkọ́ ẹ̀kọ́ àti dídàgbà. Ọlọ́run ni kí a dúpẹ́ fún, fún ẹ̀bùn àìláfiwé ti Ọmọ Rẹ̀ ní ọ̀run,”4 olùjínde Olúwa wa, àní Krístì alààyè. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.