Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Fi ìbùkún fún ní Orúkọ Rẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Fi ìbùkún fún ní Orúkọ Rẹ̀

Èrèdí fún gbígba oyèàlùfáà wa ni láti fi ààyè gbà wá láti bùkún àwọn ènìyàn fún Olúwa, à nṣe bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Rẹ̀.

Ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ̀yin ẹlẹgbẹ́ ìránṣẹ́ nínú oyèàlùfáà Ọlọ́run, ó jẹ́ ọlá fún mi láti sọ̀rọ̀ sí i yín lalẹyi. Ẹ ní ọ̀wọ̀ mi tó jinlẹ̀ àti ìmoore. Nígbàtí mo bá sọ̀rọ̀ pẹ̀lú yín tí mo sì gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ títóbi yín, ó jẹ́ ìgbàgbọ́ mi pé àlékún agbára oyèàlùfáà wà nínú, pẹ̀lú àwọn iyejú olókun àti àwọn olùdìmú oyèàlùfáà olotitọ pupọ̀ si láé.

Ní àwọn àkokò díẹ̀ pẹ̀lú yín lalẹ́yi, èmi yíò sọ̀rọ̀ sí àwọn wọnnì lára yín tí wọ́n fẹ́ láti ṣe dídára si nínú iṣẹ́-ìsìn araẹni oyèàlùfáà. Ẹ mọ̀ nípa àṣẹ pé ẹ níláti gbé ìpè yín ga láti sìn.1 Ṣùgbọ́n ó lè yà yín lẹ́nu ohun tí gbígbé ìpè yín ga túmọ̀ sí fún yín.

Èmi ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn díákónì titun jùlọ nítorí wọ́n lè lọ ní ìmọ̀lára àìní-ìdánilójú nípa ohun tí gbígbé iṣẹ́-ìsìn oyèàlùfáà wọn ga túmọ̀ sí. Àwọn alàgbà titun jùlọ bákannáà lè fẹ́ fetísílẹ̀. Bíṣọ́ọ̀pù kan ní àwọn ọ̀sẹ̀ kínní iṣẹ́-ìsìn rẹ̀ lè nífẹ́síi bákannáà.

Ó jẹ́ ìkọ́ni fún mi láti wo ẹ̀hìn ní àwọn ọjọ́ mi bí díakónì. Èmi ìbá ti fẹ́ kí ẹnìkan wí ohun tí èmi ó daba nísisìyí fún mi. Ó lè ti ṣèrànwọ́ nínú gbogbo àwọn ìyànsíṣẹ́ tí ó ti wá sọ́dọ̀ mi látì ìgbà náà—àní àwọn tí mo gbà ní ọjọ́ òní.

A yà mí sọ́tọ̀ sí díákónì ní ẹ̀ka kékeré kan gidi tí mo ti jẹ́ díákónì nìkanṣoṣo tí arákùnrin mi Ted sì jẹ́ olùkọ́ni kanṣoṣo. A jẹ́ ẹbí kanṣoṣo ní ẹ̀ka náà. Gbogbo ẹ̀ka npàdé nílé wa. Olórí oyèàlùfáà fún arákùnrin mi àti èmi ni olùyípada-ọkàn titun kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba oyèàlùfáà ararẹ̀. Mo gbàgbọ́ pé ojúṣe oyèàlùfáà mi kanṣoṣo ni láti gbé oúnjẹ́ Olúwa kiri nínú yàrá ijẹun ara mi.

Nígbàtí ẹbí mi kó wá sí Utah, mo rí arami nínú wọ́ọ̀dù títóbi pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn díákónì. Ní ìpàdé oúnjẹ́ Olúwa mi àkọ́kọ́ níbẹ̀, mo ṣàkíyèsí pé àwọn díákónì nrìn pẹ̀lú àìtàsé bí wọ́n ti ngbé oúnjẹ́ Olúwa kiri bíiti ẹgbẹ́ kan tí a ti dalẹkọ.

Ẹ̀rù bà mí gidi ní Ọjọ́-ìsinmi tó tẹ̀le mo tètè lọ sí ilé wọ́ọ̀dù láti dáwà fúnra mi níbití ẹnìkẹ́ni kò ti lè rí mi. Mo rántí pé Wọ́ọ̀dù Yalecrest ní Ìlú Salt Lake. Mo lọ sẹ́hìn èrè mo sì gbàdúrà taratara fún ìrànlọ́wọ́ láti mọ bí èmi kò ṣe ní kùnà ní gbígbé oúnjẹ Olúwa kiri. A dáhùn àdúrà náà.

Ṣùgbọ́n mo mọ̀ nísisìyí pé ọ̀nà dídára jùlọ kan wà láti gbàdúrà àti láti ronú bí a ti ngbìyànjú láti dàgbà nínú iṣẹ́-ìsìn oyèàlùfáà wa. Ó ti wá nípasẹ̀ lílóye ìdí mi èrèdí tí a fi fún olúkúlùkù ní oyèàlùfáà. Èrèdí fún gbígba oyèàlùfáà wa ni láti fi ààyè gbà wá láti bùkún àwọn ènìyàn fún Olúwa, à nṣe bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Rẹ̀.2

Lẹ́hìn àwọn ọdún díẹ̀ tí mo jẹ́ díákónì nígbàtí mo kọ́ ohun tí ó túmọ̀ sí ní ṣíṣe. Fún àpẹrẹ, bí àlùfáà gíga kan, a yàn mí láti bẹ ípàdé oúnjẹ Olúwa gbùngbun ìtọ́jú wò. Wọ́n ní kí n gbé oúnjẹ Olúwa kiri. Dípò ríronú nípa àwọn ètò tàbí àìtàsé ọ̀nà tí mo fi gbé oúnjẹ Olúwa kiri, mo wo ojú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àgbàlàgba dípò bẹ́ẹ̀. Mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n nsọkún. Obìnrin àgbà kan di etí ẹ̀wù mi mú, ó wòkè, ó wí síta pé, “Áà, o ṣé, o ṣé.”

Olúwa ti bùkún iṣẹ́-ìsìn mi tí a fúnni ní orúkọ Rẹ̀. Ní ọjọ́ náà mo gbàdúrà fún irú iṣẹ́-ìyanu bẹ́ẹ̀ láti wá dípò gbígbàdúrà fún bí mo ṣe lè sa ipá mi dáradára. Mo gbàdúrà pé àwọn ènìyàn yíò ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Olúwa nípasẹ̀ iṣẹ́-ìsìn ìfẹ́ni. Mo ti kọ́ pé èyí ni kọ́kọ́rọ́ láti sìn àti láti bùkún àwọn ẹlòmíràn ní orúkọ Rẹ̀.

Mo gbọ́ ìrirí àìpẹ́ kan tí ó mú mi rántí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀. Nígbàtí a dá gbogbo ìpàdé ìjọ dúró nítorí àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19, arákùnrin òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ kan tẹ́wọ́gba ìyànsíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ ààrẹ iyejú àwọn alàgbà láti bùkún àti láti ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa sí arábìnrin kan tí ó nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí. Nígbàtí ó pe obìnrin náà láti gbà láti mú oúnjẹ́ Olúwa wá, ó fi ìlọ́ra tẹ́wọ́gbàá, ó korira láti mu u jáde nínú ilé ara rẹ̀ ní irú àkokò eléwu bẹ́ẹ̀ àti ní ìgbàgbọ́ pé ohun gbogbo yíò padà sípò kíakíá.

Nígbàtí ó dé ilé rẹ̀ ní òwúrọ̀ Ọjọ́-ìsinmi náà, ó ní ìbèèrè kan. Ṣe wọ́n lè rìn dé ilẹ̀kùn tó tẹ̀le kí wọ́n sì gba oúnjẹ Olúwa bákannáà pẹ̀lú aladugbo rẹ̀ ọmọ-ọdún mẹ́tadínlaadọrun? Pẹ̀lú àṣẹ ti bíṣọ́ọ̀pù, ó gbà.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀, àti pẹ̀lú ìjìnnà síra pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ àwùjọ àti àwọn òdiwọ̀n ààbò míràn, ẹgbẹ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Kékeré yí kórajọ ní ọjọọjọ́ Ìsinmi fún iṣẹ́-ìsìn oúnjẹ Olúwa. Ẹyọ búrẹ́dì jíjá díẹ̀ àti ago omi lásán—ṣùgbọ́n tita ọ̀pọ̀ omijé sílẹ̀ fún ìwàrere olùfẹ́ni Ọlọ́run.

Ní àkokò, arákùnrin òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ náà, ẹbí rẹ̀, àti arábìnrin tí ó nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ti padà sí ìjọ. Ṣùgbọ́n opó ọmọ-ọdún mẹ́tàdínlaadọ́run náà, aladugbo, nínú ọ̀pọ̀ ìkìlọ̀, níláti dúró sílé. Arákùnrin òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ náà—rántí pé ìyànsíṣẹ́ rẹ̀ sí aladugbo rẹ̀ àní tí kìí ṣe arábìnrin alàgbà yí fúnrarẹ̀—di òní yí ṣì nwá jẹ́jẹ́ sí ilé rẹ̀ lọjọọjọ Ìsinmi, àwọn ìwé mímọ́ àti ẹyọ búrẹ́dì kékeré kan ní ọwọ́, láti ṣe àbápín Ounjẹ Alẹ́ Olúwa.

Iṣẹ́-ìsìn oyèàlùfáà rẹ̀, bii tèmi ní ọjọ́ náà ní gbùngbun ìtọ́jú, ni a fúnni nínú ìfẹ́. Nítòótọ́, arákùnrin òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ bèèrè lọ́wọ́ bíṣọ́ọ̀pù rẹ̀ láìpẹ́ bí àwọn míràn bá wà ní wọ́ọ̀dù tí òun lè tọ́jú. Ìfẹ́ Rẹ̀ ni láti gbé iṣẹ́-ìsìn oyè-àlùfáà rẹ̀ ga bí ó ti dàgbà bí ó ti nsìn ní orúkọ Olúwa àti ní ọ̀nà kan tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ Òun nìkan ni ó mọ̀. Èmi kò mọ̀ bí arákùnrin òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ ti gbàdúrà, bí mo ti ṣe, fún àwọn tí ó mọ ìfẹ́ Olúwa, ṣùgbọ́n nítorí iṣẹ́-ìsìn rẹ̀ tí ó wà ní orúkọ Olúwa, àbájáde náà ti jẹ́ irúkannáà.

Àbájáde irú ìyanu kannáà nwá nígbàtí mo bá gbàdúrà fún un ṣíwájú kí ntó fún ẹnikan tí àìsàn nṣe tàbí ní àkokò àìní ní ìbùkún oyèàlùfáà. Ó ṣẹlẹ̀ nígbàkan ní ilé-ìwòsàn kan nígbàtí àwọn dókítà tí kò ní sùúrù rọ̀ mí —ju rírọ̀ mí lọ—pàṣẹ fún mi—láti ṣe kía kí nsì jáde kúrò lọ́nà kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ wọn, sànju kí wọ́n fún mi ní ànfàní láti fúnni ní ìbùkún oyèàlùfáà. Mo dúró, mo sì fúnni ní ìbùkún. Àti pé ọmọdébìnrin kékeré ọjọ́ náà, ẹnití àwọn dókítà ti rò pé yíò kú, yè. Mo dúpẹ́ ní àkokò yí pé ọjọ́ náà, èmi kò jẹ́ kí ìmọ̀lára tèmi dènà ṣùgbọ́n mo ní ìmọ̀lára pé Olúwa nfẹ́ kí ọmọdébìnrin náà ní ìbùkún. Àti pé mo mọ ohun tí ìbùkún náà jẹ́: Mo fun ní ìbùkún láti ní ìwòsàn. Ó sì wòsàn.

Ó ti ṣẹlẹ̀ nígbà púpọ̀ bí mo ti nfún ẹnìkan tí ó nsúnmọ́ ojú ikú ní ìbùkún, pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹbí tí wọ́n yí ibùsùn ká, ní ìrètí fún ìbùkún ìwòsàn kan. Àní bí mo bá ní àkokò díẹ̀ nìkan, mo gbàdúrà láti mọ ohun tí ìbùkún Olúwa ní ní ìṣura tí mo lè fúnni ní orúkọ Rẹ̀. Mo sì bèèrè láti mọ̀ bí Oùn ṣe fẹ́ láti bùkún ẹni náà kìí ṣe ohun tí èmi tàbí àwọn ènìyàn tó dúrò nítòsí fẹ́. Ìrírí mi ni pé àní nígbàtí ìbùkún kìí ṣe ohun tí àwọn míràn nfẹ́ fúnrawọn tàbí olólùfẹ́ wọn, Ẹ̀mí fọwọ́tọ́ àwọn ọkàn láti ní ìrírí ìtẹ́wọ́gbà àti ìtùnú sànju ìjákulẹ̀ lọ.

Irú ìmísí kannáà nwá nígbàtí àwọn babanlá bá gbàwẹ̀ tí wọ́n sì gbàdúrà fún ìtọ́nisọ́nà láti fúnni ní ìbùkún tí Olúwa nfẹ́ ẹnìkan. Lẹ́ẹ̀kansi, mo ti gbọ́ àwọn ìbùkún tí a fúnni tí ó yà mí lẹ́nu tí ó ya ẹni tí ó gba ìbùkún náà lẹ́nu. Ní kedere, ìbùkún nwá láti ọ̀dọ̀ Olúwa—àwọn ìkìlọ̀ àti ìlérí méjèèjì tí ó wà nínú rẹ̀ bákannáà pín nínú orúkọ Rẹ̀. Àdúrà babanla àti gbígbàwẹ̀ ní èrè láti ọwọ́ Olúwa.

Bíi bíṣọ́ọ̀pù, mo kẹkọ nígbàtí mò ndarí ìfọ̀rọ̀wanilẹ́nuwò yíyẹ láti gbàdúra fún Olúwa láti jẹ́ kí nní ọgbọ́n ohun tí Ó fẹ́ fún ẹnì náà, pípa ìmísíkímísi tí Òun yíò pèsè mọ́ ní ṣíṣí nípasẹ̀ ìdájọ́ ti arami. Ìyẹn le bí Olúwa, nínú ìfẹ́, bá lè fẹ́ láti bùkún ẹnìkan pẹ̀lú ìbáwí. Ó gba ìtiraka láti mọ ìyàtọ̀ ohun tí Olúwa nfẹ́ látinú ohun tí ẹ̀yin fẹ́ àti tí ẹ̀nìyàn míràn lè fẹ́.

Mo gbàgbọ́ pé a lè gbé iṣẹ́-ìsìn oyèàlùfáà wa ga ní ìgbà-ayé wa àti bóyá ìkọjá. Yíò dá lórí aápọn wa ní gbígbìyànjú láti mọ ìfẹ́ Olúwa àti àwọn ìtiraka wa láti gbọ́ ohùn Rẹ̀ kí a lè mọ ohun tí Ó fẹ́ fún ẹnì náà tí a nsìn fún Un dáradára. Títóbi náà yíò wá ní àwọn ìṣísẹ̀ kékeré. Ó lè wá díẹ̀díẹ̀, ṣùgbọ́n yìó wa. Olúwa ṣe àwọn ìlérí yí fún wa:

“Fún ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olotitọ sí gbígba àwọn oyè-àlùfáà méjì wọ̀nyí nínú èyí tí a ti sọ̀rọ̀, àti ìgbéga ìpè wọn, ni a yà sí mímọ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí sí títún ara wa ṣe.

“Wọ́n di àwọn ọmọkùnrin Mósè àti Áárónì àti irú-ọmọ Ábráhámù, àti ìjọ àti ìjọba, àti ẹnití Ọlọ́run yàn.

“Àti pé gbogbo ẹnití ó gba oyèàlùfáà yí bákannáà gbà mi, ni Olúwa wí.”3

Ó jẹ́ ẹ̀rí mi pé àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà ni a múpadàbọ̀sípò sí Wòlíì Joseph Smith. Àwọn ìránṣẹ́ Olúwa farahàn láti ọ̀run láti mú oyèàlùfáà padàbọ̀sípò fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ti ṣí àti tí ó wà níwájú wa. A o kó Ísráẹ́lì jọ. Àwọn ènìyàn Olúwa yíò múrasílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ ológo Ẹ̀ẹ̀kejì. Ìmúpadàbọ̀sípò yíò tẹ̀síwájú. Olúwa yíò fi púpọsì lára ìfẹ́ Rẹ̀ hàn fún wòlíì Rẹ̀ àti ìránṣẹ́ Rẹ̀.

Ẹ lè ní ìmọ̀lára kékeré ní àfiwé sí ohun nlá tí Olúwa yíò ṣe. Bí ẹ bá ṣeé, mo pè yín láti fi àdúrà bèèrè bí Olúwa ti rí yín. Ó mọ̀ yín ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, Ó fi oyèàlùfáà sórí yín, àti pé dídìde sókè yín àti gbígbéga ọ̀ràn oyeàlùfáà sí I nítorí Ó nifẹ yín Ó sì nígbẹ́kẹ̀lé nínú yín láti bùkún àwọn ènìyàn tí Ó fẹ́ràn ní orúkọ Rẹ̀.

Mo bùkún yín nísisìyí láti lè ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀ àti ìgbẹ́kẹ̀lé Rẹ̀, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.