Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Mo Fẹ́ láti Rí Tẹ́mpìlì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Mo Fẹ́ láti Rí Tẹ́mpìlì

Inú tẹ́mpìlì nìkan ni a ti lè gba ìdánilójú àwọn ìsopọ̀ olùfẹ́ni ẹbí tí yíò tẹ̀síwájú lẹ́hìn ikú àti títí di àìlópin.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo dúpẹ́ láti wà pẹ̀lú yín ní abala àkọ́kọ́ ti ìpàdé gbogbogbò. Àwọn olùsọ̀rọ̀, orin, àti àdúrà ti mú Ẹ̀mí wá—bákannáà ni ìmọ̀lára ìmọ́lẹ̀ àti ìrètí.

Ìmọ̀lára náà ti mú ìrántí ọjọ́ tí mo rìn wọnú Tẹ́mpìlì Salt Lake padà wá. Mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin kan. Àwọn òbí mi nìkan ni ẹnìkejì mi lọ́jọ́ náà. Nínú ilé, wọ́n dúró fún àkokò kan kí òṣìṣẹ́ tẹ́mpìlì kí wọn. Mo dá nìkan rìn síwájú wọn, fún àkokò kan.

Obìnrin àgbà onírun-funfun kékeré nínú ẹ̀wù tẹ́mpìlì funfun kí mi. Ó wò mí lókè ó rẹrin nígbànáà ó wí jẹ́jẹ́ gidi pé, “Káàbọ̀ sí tẹ́mpìlì, Arákùnrin Eyring.” Mo ronú fún àkokò kan pé ó jẹ́ àngẹ́lì nítorí ó mọ orúkọ mi. Èmì kò tíì damọ̀ pé káàdì kékeré kan pẹ̀lú orúkọ mi ni a ti fi sí ara kóòtù súùtù mi.

Mo gbẹ́sẹ̀ kọjá rẹ̀ mo sì dúró. Mo wòkè níbi òrùlé funfun gíga tí ó mú kí iyàrá náà mọ́lẹ̀ tí ó dàbí i pé ó ṣí sílẹ̀ sí òfúrufú. Ati pé ní àkokò náà, èrò náà wá sínú mi ní àwọn ọ̀rọ̀ kedere wọ̀nyí: “Mo ti wà nínú ibi ìmọ́lẹ̀ yí tẹ́lẹ̀.” Ṣùgbọ́n ní kété lẹ́hìnnáà tí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá sínú ọkàn mi, kìí ṣe nínú ohùn arami pé: “Rárá, o kò dé ibi rí tẹ́lẹ̀. Ò nrántí àkokò kan ṣíwájú kí wọ́n tó bi ọ. O wà ní ibi mímọ́ bi ti èyí.”

Ní ìta àwọn tẹ́mpìlì wa, ni a fi àwọn ọ̀rọ̀ “Ìwàmímọ́” sí. Mo mọ fún arami pé àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì jẹ́ òtítọ́. Tẹ́mpìlì jẹ́ ibi mímọ́ tí ìfihàn ti nwá sọ́dọ̀ wa nírọ̀rùn bí ọkàn wa bá ṣí sí i àti tí a bá wà ní yíyẹ rẹ̀.

Lẹ́hìnnáà ní ọjọ́ àkọ́kọ́ mo nímọ̀lára irú Ẹ̀mí kannáà lẹ́ẹ̀kansi. Ayẹyẹ tẹ́mpìlì pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí ó mú ìmọ̀lára wíwọni lọ́kàn mi, fífi ẹsẹ̀múlẹ̀ pé ohun tí wọ́n fihàn jẹ́ òtítọ́. Ohun tí mo ní ìmọ̀lára rẹ̀ di òdodo ní ogójì ọdún lẹ́hìnnáà nípa ìpè kan láti sìn látọ̀dọ̀ Olúwa.

Mo ní ìrírí ìmọ̀lára irú kannáà nígbàtí mo ṣe ìgbeyàwó ní Tẹ́mpìlì Logan Utah. Ààrẹ Spencer W. Kimball ṣe èdidì náà. Nínú ọ̀rọ̀ díẹ̀ tí ó sọ, ó fún wa ní àmọ̀ràn yí, “Hal àti Kathy, ẹ gbé ìgbé ayé kí ẹ lè rìn lọ nírọ̀rùn, nígbàtí ìpè bá dé.”

Bí ó ti sọ ọ̀rọ̀ wọnnì, mo ri kedere nínú mi, ní àwọ̀ kíkún, àtẹ̀gùn òkè àti òpópónà tí ó darí lọ sókè lókè. Fẹ́nsì funfun kan lọ sọ́wọ́ òsì ti òpópónà ó sì lọ sínú ìlà àwọn igi ní orí òkè. Ilé funfun kan tí a kò rí dáadáa nínú àwọn igi.

Ọdún kan lẹ́hìnnáà, mo da òkè náà mọ̀ bí baba-ìyàwó mi ṣe wá wa lọ ní òpópónà náà. Ó wà kíníkíní bí ohun tí mo rí nígbàtí Ààrẹ Kimball fún wa ní àmọ̀ràn rẹ̀ nínú tẹ́mpìlì.

Nígbàtí a dé orí òkè, baba-ìyàwó mi dúró lẹgbẹ ilé funfun náà. Ó sọ fún wa pé òun àti ìyàwó òun nra ohun-ìní náà àti pé òhun fẹ́ kí ọmọbìnrin òhun àti èmi wá gbé ní ilé-àlejò. Wọn yíò gbé nínú ilé gangan, kìí ṣe ìṣíṣẹ̀ díẹ̀ síbẹ̀. Nítorínáà, ní ọdún mẹwa tí a fi gbé nínú àgbékalẹ̀ ẹbí olùfẹ́ni náà, ìyàwó mi àti èmi máa nwí ní ojoojúmọ́ pé, “Kí a jẹ́ tètè gbádùn èyí nítorí a kò ní pẹ níbí.”

Ìpè kan wá látọ́dọ̀ Kọmíṣọ́nà Ẹ̀kọ́ Ìjọ, Neal A. Maxwell. Ìkìlọ tí a fúnni látẹnu Ààrẹ Kimball láti lè “rìn kúrò ní ìrọ̀rùn” di òdodo. Ó jẹ́ ìpè kan láti fi ohun tó dàbí ipò ẹbí tó níbámu sílẹ̀ láti sìn ní ibi kan tí a yàn tí èmi kò mọ̀ ohunkankan nípa rẹ̀. Ẹbí wa ṣetán láti kúrò ní àkokò àti ibi ìbùkún nítorí wòlíì kan, nínú tẹ́mpìlì mímọ́, ibi ìfihàn kan, a rí ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú fún èyí tí a ti múrawásílẹ̀ nígbànáà.

Mo mọ̀ pé àwọn tẹ́mpìlì Olúwa jẹ́ ibi mímọ́. Èrèdí mi loni ní sísọ̀rọ̀ tẹ́mpìlì ni láti mú ìfẹ́ yín pọ̀ si àti tèmi láti jẹ́ yíyẹ kí a sì ṣetán fún àwọn ànfàní púpọ̀ si fún àwọn ìrírí tẹ́mpìlì tí ó n bọwá fún wa.

Fún mi, ìwúrí tó tóbijùlọ láti jẹ́ yíyẹ nípa ìrírí tẹ́mpìlì ni ohun tí Olúwa ti sọ nípa àwọn ilé mímọ́ Rẹ̀.

“Níwọ̀n bí àwọn ènìyàn mi bá kọ́ ilé kan sí mi ní orúkọ Oluwa, àti tí wọn fi ààyè gba ohun àìmọ́ kankan láti wá sí inú rẹ̀, kí ó ma bàá di àìmọ́, ògo mi yíò sì simi lé orí rẹ̀;

“Bẹ́ẹ̀ni, èmi yíò sì wà níbẹ̀, èmi tìkarami yíò wà níbẹ̀, nítorí èmi yíò wá sí inú rẹ̀, àti pé gbogbo àwọn ọlọ́kàn mímọ́ tí wọ́n bá wá sínú rẹ̀ yíò rí Ọlọ́run

“Ṣùgbọ́n bí ó bá di aláìmọ́ èmi kì yíò wá sí inú rẹ̀, ògo mi kì yíò sì wà níbẹ̀, nítorí èmi kì yíò wá sí inú àwọn tẹ́mpìlì àìmọ́.”1

Ààrẹ Russell M. Nelson mu hàn kedere fún wa pé a lè “rí” Olùgbàlà nínú tẹ́mpìlì nínú ọgbọ́n tí Òun kò ni di aláìmọ̀ sí wa mọ́. Ààrẹ Nelson sọ èyí: “A ní ìmọ̀ Rẹ̀. A ní òye iṣẹ́ Rẹ̀ ati ògo Rẹ̀. A sì bẹ̀rẹ̀ láti ní ìmọ̀lára ipa àìlópin ti ayé àìní-ìbámu Rẹ̀.”2

Bí ẹ̀yin tàbí èmi bá lọ sí tẹ́mpìlì tí kò mọ́ tó, a kò ní lè ri, nípa agbára ti Ẹ̀mí Mímọ́, ìkọ́ni ti-ẹ̀mí nípa Olùgbàlà tí a lè gbà nínú tẹ́mpìlì.

Nígbàtí a bá yẹ láti gba irú ìkọ́ni bẹ́ẹ̀, ìdàgbà, ayọ̀, àti ìgbàgbọ́ fún rere lè wá nípasẹ̀ ìrírí ìrètí tẹ́mpìlì wa ní gbogbo ìgbé ayé wa. Ìrètí náà, ayọ̀, àti ìgbàgbọ́ fún rere wà nìkan nípasẹ̀ ìtẹ́wọ́gbà àwọn ìlànà tí a ṣe nínú tẹ́mpìlì mímọ́ nìkan. Inú tẹ́mpìlì nìkan ni a ti lè gba ìdánilójú àwọn ìsopọ̀ olùfẹ́ni ẹbí tí yíò tẹ̀síwájú lẹ́hìn ikú àti títí di àìlópin.

Àwọn ọdún sẹ́hìn, nígbàtí mo nsìn bí bíṣọ́ọ̀pù, ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó dùnrí kọ ìpè mi láti di yíyẹ láti gbé pẹ̀lú Ọlọ́run nínú àwọn ẹbí títíláé. Ní ọ̀nà ìdogunsílẹ̀ ó wí fún mi nípa àwọn ìgbà rere tí òun ní pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Mo jẹ́ kó sọ̀rọ̀. Lẹ́hìnnáà ó wí fún mi nípa àkokò kan nínú ọ̀kan lára àwọn ijó rẹ̀, ní àárín aruwo, nígbàtí ó dédé damọ̀ pé òun ní ìmọ̀lára àdáwà. Mo bèère lọ̀wọ́ rẹ̀ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Ó wípé òun ti rántí ìgbà kan bí ọmọdékùnrin, tí òun joko lorí ẹsẹ̀ ìyá òun, pẹ̀lú apá rẹ yíká rẹ̀. Fún àkokò náà nígbàtí ó sọ ìtàn náà, ó bínú. Mo wí fun ohun tí mo mọ̀ pé òtítọ́ ni: “Ọ̀nà kanṣoṣo tí o fi lè ní ìmọ̀lára ti ìdìmọ́ra ẹbí náà títíláé ni láti di yíyẹ fúnrarẹ àti láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti gba èdidì àwọn ìlànà tẹ́mpìlì.”

A kò mọ ìsopọ̀ ẹbí ní kíníkíní nínú ayé ẹ̀mí tàbí ohun tí ó lè wá lẹ́hìn tí a ti jínde. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé wólíì Èlíjàh wá bí a ti ṣèlérí láti yí àwọn ọkàn baba padà sí àwọn ọmọ àti àwọn ọmọ sí baba.3 A sì mọ̀ pé ìdùnnú ayérayé wa dá lórí ṣíṣe dáradára wa jùlọ láti fi irú ìdùnnú pípẹ́ kannáà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbátàn wa bí a ti lè ṣe.

Mo ní ìmọ̀lára irú ìfẹ́ kannáà láti yege ní pípe àwọn ọmọ ẹbí láti nifẹ láti di yíyẹ láti gbà àti láti bu-ọlá fún àwọn ìlànà èdidì ti tẹ́mpìlì. Ìyẹn ni ara ìlérí ìkórajọ Ísráẹ́lì ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ méjì ìbòjú.

Ọ̀kan lára àwọn ànfàní wa títóbi jùlọ ni ìgbàtí àwọn ọmọ ẹbí wa bá kéré. A bí wọn pẹ̀lú Ìmọ́lẹ̀ Krístì bí ẹ̀bùn kan. Ó jẹ́ kí wọ́n ní ọgbọ́n ohun tí ó dára àti ohun búburú. Fún èrèdí náà, àní rírí tẹ́mpìlì kan tàbí àwòrán tẹ́mpìlì kan lè mú ìfẹ́ wá sínú ọmọ kan láti ní ànfàní níjọ́kan láti wọ inú rẹ̀.

Nígbànáà ọjọ́ náà lè wá, gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́, kí wọ́n gba ìkaniyẹ sí tẹ́mpìlì láti ṣe arọ́pò àwọn ìrìbọmi nínú tẹ́mpìlì. Nínú ìrírí náà, ìmọ̀lára wọn lè dàgbà pé àwọn ìlànà tẹ́mpìlì nnàwọ́ sí Olùgbàlà àti Ètùtù Rẹ̀ nígbàgbogbo. Bí wọ́n ṣe nní ìmọ̀lára pe wọ́n nfún ẹnikan ní ayé ẹ̀mí ní ààyè láti gba ìwẹ̀nùmọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ìmọ̀lára wọn yíò dàgbà nípa ríran Olùgbàlà lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ mímọ́ Rẹ̀ nípa bíbùkún ọmọ Baba wa Ọ̀run.

Mo ti rí agbára ìyípadà ìrírí náà ní ayé ọ̀dọ́ kan. Àwọn ọdún sẹ́hìn mo lọ pẹ̀lú ọmọbìnrin kan sí tẹ́mpìlì ní ọ̀sán pípẹ́. Òun ni ó kẹ́hìn láti sìn bí arọ́pò nínú ìrìbọmi. A bi ọmọbìnrin mi léèrè bí ó bá lè dúró pẹ́ si láti parí àwọn ìlànà fún gbogbo ènìyàn wọnnì tí a ti múra orúkọ wọn sílẹ̀. Ó sọ pé bẹ́ẹ̀ni.

Mo wòó bí ọmọbìnrin mi ṣe gbẹ́sẹ̀ wọnú ibi ìrìbọmi. Àwọn ìrìbọmi bẹ̀rẹ̀. Ọmọbìnrin mi kékeré ni omi nṣàn sílẹ̀ ní ojú rẹ̀ ní ìgbà kọ̀ọ̀kan tí a bá gbé jáde nínú omi. A bií léèrè lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kansi, “Ṣé o lè ṣe si?” Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ó sì wípé bẹ́ẹ̀ni.

Bí baba tó laniyan, mo bẹ̀rẹ̀ sí nretí pé a lè yọ̀nda rẹ̀ ní ṣíṣe si. Ṣùgbọ́n mo ṣì rántí ìdúróṣinṣin rẹ̀ nígbàtí wọ́n bií léèrè bí ó bá lè ṣe si tí ó sì wí nínú ìpinnu ohùn kékeré pé, “Bẹ́ẹ̀ni” Ó dúró títí ẹni tó kẹ́hìn lórí ìtò ní ọjọ́ náà fi gba ìbùkún ìrìbọmi ní orúkọ Jésù Krístì.

Nígbàtí mo rìn jáde nínú tẹ̀mpìlì pẹ̀lú rẹ̀ ní alẹ́ náà, ó yà mi lẹ́nu ohun tí mo ti rí. A ti gbé ọmọ kan ga a sì ti yipadà ní ojú mi nípa sísin Olúwa nínú ilé Rẹ̀. Mo ṣì rántí ìmọ̀lára ìmọ́lẹ̀ àti àláfíà bí a ṣe rìn papọ̀ látinu tẹ̀mpìlì.

Àwọn ọdún ti kọjá. Ó ṣì nwípé bẹ́ẹ̀ni sí ìbèèrè láti ọ̀dọ̀ Olúwa bí òun ó bá ṣe si fún Un nígbàtí ó bá le gidi. Ìyẹn ni ohun tí iṣẹ́-ìsìn tẹ́mpìlì lè ṣe láti yípadà àti láti gbé wa ga. Ìyẹn ni ìdí tí ìrètí mi fún yín àti fún gbogbo olólùfẹ́ ẹbí yín fi jẹ́ pé kí ẹ dàgbà nínú ìfẹ́ àti ìpinnu láti yẹ láti lọ sínú ilé Olúwa léraléra bí àwọn ipò yín ti fi ààyè gbà.

Ó nfẹ́ láti kí wa káàbọ̀ níbẹ̀. Mo gbàdúrà pé ẹ ó gbìyànjú láti gbé ifẹ́ ga nínú ọkàn àwọn ọmọ Baba Ọ̀run láti lọ síbẹ̀, níbi tí wọ́n ti lè ní ìmọ̀lára láti súnmọ Ọ, àti pé ìwọ yio pe àwọn bàbá nla rẹ láti di yíyẹ láti wà pẹ̀lú Rẹ̀ àti pẹ̀lú rẹ títí láé.

Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lè jẹ́ tiwa:

Mo fẹ́ láti rí tẹ́mpìlì.

Mò nlọ síbẹ̀ níjọkan.

Láti ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí Mímọ́.

Láti fetísílẹ̀ àti láti gbàdúrà.

Nítorí tẹ́mpìlì jẹ́ ilé Ọlọ́run,

Ibi ìfẹ́ àti ẹ̀wà kan.

Èmi ó múra arami sílẹ̀ nígbàtí mo wà léwe.

Èyí ni ojúṣe mímọ́ mi.4

Mo jẹ̀rí ọ̀wọ̀ pé a jẹ́ ọmọ olùfẹ́ni Baba Ọ̀run. Ó yan Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, láti jẹ́ Olùgbàlà àti Olùràpadà wa. Ọ̀nà kanṣoṣo láti padà lọ gbé pẹ̀lú Wọn àti pẹ̀lú ẹbí wa ni nípasẹ̀ àwọn ìlànà ti tẹ́mpìlì mímọ́. Mo jẹ̀rí pé Ààrẹ Russell M. Nelson dìmú ó sì nlo gbogbo kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà tí ó mú ìyè-ayérayé ṣeéṣe fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.