Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìrètí nínú Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Ìrètí nínú Krístì

A fẹ́ láti ran gbogbo ẹni tí ó nìmọ̀lára àdáwà tàbí tí wọ́n nímọ̀lára àìwà pẹ̀lú lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí ndárúkọ̀, ní pàtàkì, àwọn ẹnití wọ́n jẹ́ ọ̀kanṣoṣo lọ́wọ́lọ́wọ́.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ní àkókò Ọdún Àjínde yi a fi ojú sùn sóri Àjínde ológo ti Olúwa àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. A nrántí ìfipè ìfẹ́ni Rẹ̀ láti “wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó nṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.

“Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmí: ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.

“Nítorí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.”1

Ìpè Olùgbàlà láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ jẹ́ ìpè sí gbogbo ènìyàn kìí ṣe láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n bákannáà láti jẹ́ ti Ìjọ Rẹ̀.

Nínú ẹsẹ tí ó ṣaájú ìpè olùfẹ́ni yi, Jésù nkọ́ni bí èyí ti le jẹ́ ṣíṣe nípa lílépa láti tẹ̀le E. Ó kéde pé, “Kò sí ọkùnrin [tàbí obìnrin] kan tí ó mọ Ọmọ, bíkòṣe Baba; bẹ́ẹ̀ni kò sí ọkùnrin [tàbí obìnrin] náà tí ó mọ Baba, bíkòṣe Ọmọ, àti ọkùnrin [tabí obìnrin] náà tí Ọmọ fẹ́ fi í hàn fún.”2

Jésù fẹ́ kí a mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ olùfẹ́ni Baba Ọrun.

Mímọ̀ pé a jẹ́ fífẹ́ràn nípasẹ̀ Baba wa Ọrun yío rànwálọ́wọ́ láti mọ ẹnití awa íṣe àti láti mọ̀ pé a jẹ́ ti ẹbí nlá ayérayé Rẹ̀.

Ilé Ìwòsàn Máyo sọ láìpẹ́ pé: “Níní èrò orí ti jíjẹ́ ti ibikan ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀. … Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo abala ìgbé ayé wa ni a ṣètò sí àyíká jíjẹ́ ti ohun kan.” Ìròhìn yí fikún pé: “a kò le ya patàki jíjẹ́ ti ohun kan kúrò lára ìlera àgọ́ ara àti ti ọpọlọ wa”3—àti pé, èmi ó fikun, ìlera ti-ẹ̀mí wa.

Ní ìrọ̀lẹ́ tí ó ṣaájú ìjìyà Rẹ̀ ní Gethsemane àti ikú lórí àgbélèbú, Olùgbàlà pàdé pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ fún Ounjẹ Alẹ́ Ìgbẹ̀hìn. Ó wí fún wọn pé, “Nínú ayé ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”5 Kí oorun tó wọ̀ ní ọjọ́ kejì, Jésù Krístì ti jìyà ó sì ti “kú [ní orí àgbélebú] fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”6

Mo ro irú dídánìkanwà tí àwọn onígbàgbọ́ obìnrin àti ọkùnrin tí wọ́n ti tẹ̀lé E gbọ́dọ̀ ti ní ìmọ̀lára ní Jérúsálẹ́mù bí oorùn ti íwọ̀ àti bí òkùnkùn àti ẹ̀rù ti bò wọ́n.7

Bíi àwọn ọmọ ẹ̀hìn àtijọ́ wọ̀nyí ní bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sẹ́hìn, púpọ̀ nínú yín bákannáà le máa ní ìmọ̀lára dídáwà láti ìgbà dé ìgbà. Èmi ti ní ìrírí dídánìkanwà yí láti ìgbà ikú ìyàwó mi iyebíye, Barbara, ó lé ní ọdún méjì àbọ̀ sẹ́hìn. Mo mọ ohun tí ó jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹbí yí wa ká, àwọn ọ̀rẹ́, àti olùbárìn ṣùgbọ́n kí a ṣì nnímọ̀lára àdánìkanwà—nítorí ìfẹ́ ayé mi kò sí nihin lẹgbẹ́ mi mọ́.

Àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 ti ṣe àmì àsọyé ti yíyàsọ́tọ̀ àti dídánìkanwà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìpèníja tí a nkojú ní ìgbé ayé, bíi ti òwúrọ̀ ọjọ́ Àjínde àkọ́kọ́ náà, a le jí sí ìgbé ayé titun nínú Krístì, pẹ̀lú àwọn ìṣeéṣe titun àti yíyanilẹ́nu àti àwọn òtítọ́ titun bí a ti nyí sí ọ̀dọ̀ Olúwa fún ìrètí àti wíwà pẹ̀lú.

Èmi funra ara mi ní ìmọ̀lára ìrora ti àwọn wọnnì tí wọn kò ní èrò wíwà pẹ̀lú. Bí mo ti nwo ìròhìn káàkiri ní àyíká ayé, mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹni tí ó dábì wọ́n nní ìrírí àdánìkanwà. Mo ronú pé, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó jẹ́ nítorí wọ́n kò lè mọ̀ pé Baba Ọ̀run nifẹ wọn àti pé gbogbo wa wà pẹ̀lú ẹ̀bí ayérayé Rẹ̀. Gbígbàgbọ́ pé Ọlọ́run fẹ́ràn wa àti pé àwa jẹ́ ọmọ Rẹ̀ ntu ni nínú ó sì nfúnni ní ìdánilójú.

Nítorípé àwa jé ọmọ ẹ̀mí ti Ọlọ́run, olukúlùkù wa ní orísun, àdánidá, àti agbára ti ọ̀run. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa jẹ́ “àyànfẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin ẹ̀mí ti àwọn òbí ọ̀run.”8 Ìdánimọ̀ wa ni èyí! Ẹni tí a jẹ́ gan an ni èyí!

Ìdánimọ̀ wa ni ti ẹ̀mí ni a mú dára síi bí a ti nní òye ọ̀pọ̀ àwọn ìdánimọ̀ wa ti ayé ikú, pẹ̀lú ẹ̀yà, ti àṣà, tábí ohun ìní ti orílẹ̀èdè.

Èrò orí yi ti ìdánimọ̀ níti ẹ̀mí àti ti àṣà, ìfẹ́, àti jíjẹ́ ti ibikan le mí sí ìrètí àti ìfẹ́ fún Jésù Krístì.

Mo nsọ nípa ìrètí nínú Krístì kìí ṣe bíiti rírònú ìfẹ́ inú. Dípò bẹ́ẹ̀, mo nsọ̀rọ̀ nípa ìrètí bí ohun tí a nretí tí a ó rí gbà. Irú ìrètí bẹ́ẹ̀ ṣe kókó sí bíborí ọ̀tá, síṣe ìmúdàgbà ìfaradà àti okun ní ti ẹ̀mí, àti wíwá sí ìmọ̀ pé a jẹ́ fífẹ́ràn nípasẹ̀ Baba wa Ayérayé àti pé àwa ni ọmọ Rẹ̀, tí a wà pẹ̀lú ẹbí Rẹ̀.

Nígbàtí a bá ní ìrètí nínú Krístì, a ó wá sí ìmọ̀ pé bí a ṣe nílò láti dá kí a sì ṣe ìpamọ́ àwọn májẹ̀mú mímọ́, àwọn ìfẹ́ inú àti àwọn àlá wa tí a ṣàníyàn jùlọ lè di mímúṣẹ nípasẹ̀ Rẹ̀.

Iyejú Àwọn Àpóstélì Méjìlá ti dámọ́ràn papọ̀ nínú ẹ̀mí àdúrà àti pẹ̀lú ìpòngbẹ láti ní òye bí a ṣe le ran gbogbo awọn tí wọ́n nní ìmọ̀lára àdánìkanwà tàbí ìmọ̀lára pé wọn kò wà pẹ̀lú. À nfẹ́ láti ran gbogbo ẹni tí wọ́n ní ìmọ̀lára ní ọ̀nà yí. Ẹ jẹ́ kí ndárúkọ̀, ní pàtàkì, àwọn ẹnití wọ́n jẹ́ ọ̀kanṣoṣo lọ́wọ́lọ́wọ́.

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin, ó jù ìlàjì àwọn àgbàlagbà nínú Ìjọ lọ lóni tí wọ́n jẹ́ opó, tí wọ́n ti ṣe ìkọ̀sílẹ̀, tàbí tí wọn kò tíì ṣe ìgbéyàwó rí rárá. Díẹ̀ nínú wọn nronú nípa àwọn ànfàní àti ààyè nínú ètò Ọlọ́run àti nínú Ìjọ. A níláti mọ̀ pé ìyè ayérayé kìí ṣe ọ̀rọ̀ ìbéèrè kan lásán nípa ipò ìgbeyàwó lọ́wọ́lọ́wọ́ ṣùgbọ́n nípa ọmọlẹ́hìn àti ti níní “ìgboyà nínú ẹ̀rí ti Jésù.”10 Ìrètí gbogbo àwọn tí wọ́n nìkan wà jẹ́ ìkannáà bíi ti gbogbo ọmọ Ijọ Olúwa tí a mú padàbọ̀ sípò—ẹ̀tọ́ sí ore ọ̀fẹ́ Krístì nípasẹ̀ “ìgbọràn sí àwọn òfin àti àwọn ìlànà Ìhìnrere.”11

Njẹ́ kí n dába pé àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì díẹ̀ kan wà tí a nílò láti mọ̀.

Àkọ́kọ́, àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn wòlíì ọjọ́-ìkẹhìn fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pé olukúlùkù ẹnití ó bá jẹ́ olõtọ́ ní pípa àwọn májẹ̀mú ìhìnrere mọ́ yío ní ànfàní fún ìgbéga. Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé: “Ní ọ̀nà àti àkókò ti Olúwa, kò sí ìbùkún kan tí a ó mú sẹ́hìn kúrò fún àwọn olódodo Ènìyàn Mímọ́ Rẹ̀. Olúwa yio dá olukúlùkù ẹnìkọ̀ọ̀kan lẹ́jọ́ yío sì san àn fún wọn ní ìbámu sí ìfẹ́ inú àtọkànwá àti ohun ṣíṣe pẹ̀lú.”12

Èkejì, a ko ti fi àkokò pàtó àti ọ̀nà nínú èyí tí a fi nfúnni ní àwọn ìbùkún ìgbéga hàn tán, bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n wọ́n nidaniloju.11 Ààrẹ Dallin H. Oaks ṣàlàyé pé àwọn ipò “ti ayé ikú kan ní a ó ṣe bo titọ́ ní Mìllẹ́níúmù, èyí ni àkokò fún mímúṣẹ gbogbo ohun tí kò pé nínú ètò nlá ti ìdùnnú fún gbogbo àwọn ọmọ yíyẹ Baba wa.”12

Èyínnì kò túmọ̀ sí pé gbogbo ìbùkún ni a ó sún síwájú títí di àkokò Mìllẹ́níúmù; àwọn kan ti di gbígbà tẹ́lẹ̀ àwọn miran ni a ó sì máa gbà títí di ọjọ́ náà.13

Ẹkẹta, dídúró de Olúwa túmọ̀ sí títẹ̀síwájú nínú ìgbọràn àti ìlọsíwájú níti ẹ̀mí sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Dídúró de Olúwa kò túmọ̀ sí ìṣesí àkokò ẹnìkan. Ẹ kò níláti ní ìmọ̀lára bí ẹnipé ẹ ndúró ní yàrá ìdúródeni kan.

Dídúró dé Olúwa túmọ̀ sí ìṣe. Mo kẹkọ ní àwọn ọdún kan pé ìrètí wa nínú Krístì npọ̀ si nígbàtí a bá sin àwọn míràn. Ní sísìn bí Jésù ti sìn, à npọ̀si ní ìrètí ìwà-ẹ̀dá wa sí I.

Ìdàgbásókè ara ẹni tí a lè ṣe yọrí nísisìyí bí a ti ndúró de Olúwa àti àwọn ìlérí Rẹ̀ jẹ́ ara ètò àìdíyelé, ohun mímọ́ nípa ètò Rẹ̀ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Àwọn ìlọ́wọ́sí tí ẹnikan bá le ṣe nísisìyí láti ṣe ìrànlọ́wọ́ gbé Ìjọ sókè ní orí ilẹ̀ ayé ni a nílò púpọ̀. Ipò ìgbeyàwó kò ní íṣe pẹ̀lú okun ẹnìkan láti sìn. Olúwa nbu ọlá fún àwọn wọnnì tí wọ́n nsìn tí wọ́n sì ndúró de É nínú sùúrù àti ìgbàgbọ́.18

Ìkẹrin, Ọlọ́run fi ìyè ayérayé sílẹ̀ fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀. Gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n gba ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà ológo Olùgbàlà tí wọ́n sì ngbé ìgbé ayé àwọn òfin Rẹ̀ yío gba ìyè ayérayé, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò le ṣe gbogbo ìhùwàsí àti àwọn pípé rẹ̀ nínú ayé ti ikú. Àwọn wọnnì tí wọ́n bá ronúpìwàdà yío ní ìrírí ṣíṣetán Olúwa láti dáríjì, bí Òun ti fi dáni lójú pé, “Bẹ́ẹ̀ni, ní gbogbo ìgbà tí àwọn ènìyàn mi bá ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ ni èmi yíò dárí àwọn ìrékọjá wọn sí mi jì wọ́n.”20

Nínú àyẹ̀wò tó gbẹ̀hìn, agbára ẹnìkan, àwọn ìfẹ́ inú, àti àwọn ànfàní nínú àwọn ọ̀ràn ìṣojú ara ẹni àti yíyàn, nínú èyítí àwọn ohun tí a nílò wà fún àwọn ìbùkún ayérayé, jẹ́ àwọn ọ̀ràn tí Olúwa nìkan le dá ẹjọ́ rẹ̀.

Ikarun, ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú àwọn ìdánilójú wọ̀nyí ní ó ní gbòngbò nínú ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì, nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ ẹnití gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ayé ikú ni a gbékalẹ̀ ní títọ́.16 Gbogbo àwọn ìlérí ìbùkún ní a mú ṣeéṣe nípasẹ̀ Rẹ̀, ẹnití, “ó sọ̀kalẹ̀ kọjá ohun gbogbo”17 nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀, tí ó sì “borí ayé.”18 Ó “ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, láti gba ẹ̀tọ́ àánú rẹ̀ èyítí ó ní lórí àwọn ọmọ ènìyàn lọ́wọ́ Baba tí ó ní sí àwọn ọmọ ènìyàn … ; nítorí èyí tí a máa ṣe alágbàwí fún èyítí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ ènìyàn.”19 Ní ìparí, “àwọn ènìyàn mímọ́ ni aó kún pẹ̀lú ògo rẹ̀, wọn ó sì gba ogún ìní wọn”20 bíi “àjùmọ̀-jogún pẹ̀lú Krístì.”21

Ìfẹ́ inú wa ni pé àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí yío ràn gbogbo wá lọ́wọ́ láti ní àlékún ìrètí nínú Krístì kí a sì ní ìmọ̀lára èrò orí ti jíjẹ́ ti ibikan.

Ẹ máṣe gbàgbé pé ẹ jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, Baba wa Ayérayé, nísisìyí àti títí láé. Ó fẹ́ràn yín, àti pé Ìjọ náà fẹ́ yín wọ́n sì nílò yín. Bẹ́ẹ̀ni, a nílò yín! A nílò ohùn yín, àwọn ẹ̀bùn, àwọn iṣẹ́ ọwọ́, inú rere, àti àwọn ìwà ìṣòdodo yín.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, a ti sọ̀rọ̀ nípa “ọ̀dọ́ àgbà ànìkanwà,” “àwọn àgbà ànìkanwà,” àti “àwọn àgbàlagbà.” Àwọn àpèlé wọnnì le ṣe ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ ní ti iṣẹ́ ìkọ̀wé nígbàmíràn ṣùgbọ́n ó le ṣèèṣì mú ìyípadà bá bí a ti nwo àwọn ẹlòmíràn.

Njẹ́ ọ̀nà kan wà láti yẹra fún ìtẹ̀sí ti ẹ̀dá ènìyàn yi tí ó le ya wá kúrò ní ọ̀dọ̀ ara wa?

Ààrẹ Nelson sọ pé kí a máa tọ́ka sí ara wa bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Èyínnì dàbí pé ó bo gbogbo wa mọ́lẹ̀, àbí kò ṣe bẹ́ẹ̀?

Ìhìnrere Jésù Krístì ní agbára láti sọ wa di ọ̀kan. Ní ìgbẹ̀hìn a jọ ara wa jù bí a ti yàtọ̀ sí ara wa lọ. Gẹ́gẹ́bí ọmọ ẹgbẹ́ ti ìdilé Ọlọ́run, a jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin nítòótọ́. Paulù sọ pé, “[Ọlọ́run] sì ti fi ẹ̀jẹ̀ kannáà dá gbogbo orílẹ̀ èdè ti àwọn ènìyàn láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé.”22

Sí ẹ̀yin ààrẹ èèkàn, bíṣọ́pù, àti ẹyin olùdári iyejú àti olórí arábìnrin, mo sọ fun yín láti gbèrò olukúlùkù ọmọ ìjọ ní èèkàn, wọ́ọ̀dù, iyejú, tàbí ní ìṣètò bíi àwọn ọmọ ijọ tí wọ́n le lọ́wọ́sí tí wọn sì le sìn nínú àwọn ìpè àti kópa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà.

Olukúlùkù ọmọ ìjọ nínú àwọn iyejú, àwọn ìṣètò, àwọn wọ́ọ̀dù, àti àwọn èèkàn wa ní àwọn ẹ̀bùn àti tálẹ́ntì tí ó le ṣe ìrànwọ́ láti kọ́ ìjọba Rẹ̀ nísisìyí.

Ẹ jẹ́kí a ké pe àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n nìkanwà láti sìn, láti gbé sókè, àti láti kọ́ni. Ẹ pa àwọn èrò orí àti ìrònú àtijọ́ tì, èyítí ó ti fi ìgbàmíràn ṣèèṣì dá kún àwọn ìmọ̀lára dídánìkanwà wọn àti pé wọn kò wà pẹ̀lú tàbí pé wọn kò le sìn.

Mo jẹ́ ẹ̀rí mi ní òpin ọ̀sẹ̀ Ọdún Àjínde yi nípa Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, àti ìrètí ayérayé tí Ó nfún èmi àti gbogbo ẹnití ó bá gbàgbọ́ nínú orúkọ Rẹ̀. Mo sì jẹ́ ẹ̀rí mi pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ní orúkọ mímọ́ Rẹ̀, àní Jésù Krístì, àmín.