Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Nítorí Ìrandíran Yín
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


Nítorí Ìrandíran Yín

Ẹ máṣe jẹ́ ìsopọ̀ aláìlágbára nínú okùn ìgbàgbọ́ rírẹwà yí tí ẹ bẹ̀rẹ̀, tàbí tí ẹ gbà, bí ogún-ìní kan. Jẹ èyítí ó lágbára.

Ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, nígbàtí mo nsìn ní Agbègbè Gúúsù Amẹ́ríkà Àríwá Ìwọ̀ Oòrùn tí mo sì ngbé ní Peru, mo ní ìrírí rírẹwà kan tí èmi yíò fẹ́ láti pín pẹ̀lú yín.

Ó ṣẹlẹ̀ nígbàtí mo npadà sílé lẹ́hìn òpin ọ̀sẹ̀ iṣẹ́-àṣekára fún àwọn iṣẹ́ yíyàn. Lẹ́hìn píparí àwọn ìlànà ìwọlé-jáde ní pápákọ̀ òfúrufú níkẹhìn, mo rí awakọ̀ takisí ọ̀rẹ́ kan tí ndúró fún mí láti ilé iṣẹ́-ìsìn takisi wa. Ó mú mi lọ sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀, mo sì jókòó lẹ́hìn, ní ṣíṣetán láti sinmi àti láti gbádùn ìrìn àjò ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí ilé. Lẹ́hìn wíwakọ̀ fún ìwọ̀n àwọn búlọ́kì díẹ̀, awakọ̀ náà gba ìpè fóònù kan láti ọ̀dọ̀ alábojútó rẹ̀ ó sọ fún un pé mo gbé takisi tí kò tọ́. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó yàtọ̀ ni a ti ṣètò sílẹ̀ fún mi, àti pé alábojútó náà sọ fún un pé kí ó gbé mi padà sí pápákọ̀ òfúrufú bí mo bá fẹ́ pààrọ̀ àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Mo sọ fun pé kò ṣe dandan, àti pé a lè tẹ̀síwájú. Lẹ́hìn ìdákẹ́jẹ́ẹ́ fún ìṣẹ́jú díẹ̀, ó wò mí láti dígí tó fi nwo ẹ̀hìn, ó sì béèrè pé, “Ìwọ ni Mọmọnì, àbí?”

Ó dára, lẹ́hìn ìbéèrè ìfipè náà, mo mọ̀ pé àwọn àkókò ìdákẹ́jẹ́ẹ́ mi ti parí. Èmi ò lè mú ara dúró ní ṣíṣe àwárí ibití ìbéèrè rẹ̀ yíò mú wa lọ.

Mo kọ́ pé Omar ni orúkọ rẹ̀, orúkọ ìyàwó rẹ̀ ni Maria Teresa, wọ́n sì bí ọmọ méjì—Carolina, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, àti Rodrigo, ọmọ ọdún mẹ́wàá. Omar ti jẹ́ ọmọ Ìjọ láti ìgbà ọmọdé rẹ̀. Ẹbí rẹ̀ nṣe déédé tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà kan, àwọn òbí rẹ̀ dáwọ́ dúró ní lílọ sí ilé ìjọsìn. Omar di aláìṣedéédé pátápátá nígbàtí ó di ọdun márùndínlógún. Ó jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà náà.

Ní àkókò náà mo ri pé èmi gbé takisi tí kò tọ́. Kìí ṣe pé ó ṣèèṣì! Mo sọ ẹni tí mo jẹ́ fún un àti pé mo wà nínú ọkọ̀-èrò rẹ̀ nítorí pé Olúwa npè é padà sí agbo rẹ̀.

Lẹ́hìnnáà, a sọ̀rọ̀ nípa àkókò tí òun àti ẹbí rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ìjọ tó nṣedéédé. Ó ní àwọn ìrántí ìfẹ́ni ti àwọn àkókò aládùn fún ìpàdé ẹbí-ilé-ìrọ̀lẹ́, àti díẹ̀ nínú àwọn orin alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Lẹ́hìnnáà ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ nínú “Ọmọ Ọlọ́run ni mí.”1

Lẹ́hìn gbígba àdírẹ́sì rẹ̀, nọ́mbà fóònù, àti ìyọ̀nda láti pín wọn pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀pù rẹ̀, mo sọ fún un pé èmi yíò wá ọ̀nà kan láti wà nínú ilé ìjọsìn náà ní ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ó ba padà sí ìjọ. A parí ìrìn àjò wa láti pápákọ̀ òfúrufú lọ sí ilé mi, bákan náà pẹ̀lú ìrìn àjò wa díẹ̀ sí ìgbé ayé rẹ̀ àtẹ̀hìwá, a sì lọ ní ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wa.

Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́hìn náà bíṣọ́ọ̀pù rẹ̀ pè mí, ó sọ fún mi pé Omar npinnu láti wa sí ilé ìjọsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi kan. Mo wí fún un pé èmi yìó wà níbẹ̀. Ní ọjọ́ ìsinmi náà, Omar wà níbẹ̀ pẹ̀lú ọmọkùnrin rẹ̀. Ìyàwó àti ọmọbìnrin rẹ̀ kò tíì nifẹ si. Ní oṣù díẹ̀ lẹ́hìn náà, bíṣọ́ọ̀pù rẹ̀ tún pè mí, lọ́tẹ̀ yìí láti sọ fún mi pé Omar yíò ṣe ìrìbọmi fún ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, ó sì pè mí láti wá síbẹ̀. Nihin ni àwòrán Ọjọ́-ìsinmi náà níbi tí wọ́n ti fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ bí ọmọ ìjọ.

Àwòrán
Alàgbà Godoy pẹ̀lú ẹbí Omar ní Ọjọ́-ìsinmi tí a ṣe ìfẹsẹ̀múlẹ̀ wọn.

Ní ọjọ́ ìsinmi kannáà, mo sọ fún Omar àti ẹbí rẹ pé tí wọ́n bá múrasílẹ̀, ní ọdún kan èmí yìó ni ọlá láti ṣe èdìdí wọn ní Tẹ́mpìlì Lima. Nihin ni àwòrán ti àkókò mánigbàgbé náà fún gbogbo wa, tí a yà ní ọdún kan lẹ́hìnnáà.

Àwòrán
Alàgbà Godoy pẹ̀lú ẹbí Omar ní tẹ́mpìlì.

Kínni ìdí tí mo fi nṣe àbápìn àwọn ìrírí wọ̀nyí pẹ̀lú yín? Mo npin in fún àwọn ìdí méjì.

Lakọkọ, láti bá àwọn ọmọ ìjọ rere wọ̀nnì sọ̀rọ̀ tí wọ́n ti torí àwọn ìdí kan ṣubú kúrò nínú ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Kristi. Èkejì, láti tún bá àwọn ọmọ ìjọ tí wọn nkópa lónìí sọ̀rọ̀ tí bóyá wọ́n lè ma jẹ́ olõtọ́ sí àwọn májẹ̀mú wọn bí ó ti yẹ kí wọ́n jẹ́. Ní àwọn ọ̀ràn méjèèjì, àwọn ìran ìṣaájú wọn ní ipa, àwọn ìbùkún àti àwọn ìlérí tí ó wà ní ìpamọ́ fún àwọn ìrandíran wọ́n sì wà nínú ewu.

Jẹ́ kí á bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ àkọ́kọ́, àwọn ọmọ ìjọ rere ti wọ́n ti kúrò ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú, bí ó ti ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ará Peru ọ̀rẹ́ mi Omar. Nígàtí mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ìdí tí ó fi pinnu láti padà, ó wípé nítorí pé òun àti ìyàwó rẹ̀ ní ìmọ̀lára pé àwọn ọmọ wọn yìó ní ìdùnnú ní ayé pẹ̀lú ìhìnrere Jésù Krístì. Ó ní ìmọ̀lára pé ó tó àkókò láti padà sí ìjọ nítorí àwọn ọmọ wọn.

Ó jẹ́ ìbànújẹ́ nígbàtí a bá pàdé àwọn ọmọ ìjọ aláìṣedéédé tàbí àwọn tí kìí ṣe ọmọ Ìjọ tí wọ́n ní ìhìnrere nígbà kan nínú àwọn ẹbí wọn tí wọ́n sì pàdánù rẹ̀ nítorí ìpinnu àwọn òbí wọn tàbí àwọn òbí àgbà láti gba ìsinmi kúrò nínú Ìjọ. Ìpinnu náà lè ní ipa lórí ìrandíran wọn láéláé!

Àwọn ọmọ àti àwọn ọmọ-ọmọ wọn ti di yíyọ kúrò nínú ààbo àti àwọn ibùkún ti ìhìnrere Jésù Krístì nínú ayé wọn. Àní ó jẹ́ ìbànújẹ́ ọkàn díẹ̀ síi, wọ́n ti pàdánù àwọn ìlérí ti ẹbí ayérayé kan tí ó wà níbẹ̀ ni ọjọ́ kan. Ìpinnu ẹnìkan ti ní ipa lórí gbogbo àsopọ̀ àwọn àtẹ̀lé. Ogún-ìní ti ìgbàgbọ̀ kan ti di bíbàjẹ́.

Síbẹ̀síbẹ̀, bí a ti mọ̀, ohunkóhun tí ó bá bàjẹ́ lè di títunṣe nípasẹ̀ Jésù Krístì. Nítorí ìdí èyí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ ṣe àgbéyẹ̀wò ìfipè yìí láti ọ̀dọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson pé: “Nísisìnyí, bí ẹ bá ti yẹ̀ kúrò ní ipa ọ̀nà náà, njẹ́ mo lè pè yín pẹ̀lú gbogbo ìrètí tí ó wà nínú ọ̀kàn mi láti jọ̀wọ́ padà wá Ohunkóhun tí àwọn àníyàn yín jẹ́, ohunkóhun tí àwọn ìpènijà yín jẹ́, ìbì kan wà fún yín nínú Ìjọ Olúwa yí. Ẹ̀yin àti àwọn ìran tí a kò tíì bí yíò di alábùkún fún nípa àwọn ìṣe yín nísisìnyí láti padà sí ipa ọ̀nà májẹ̀mú.”2

Nísisìyí, ẹ jẹ́ kí á kojú ìṣẹ̀lẹ̀ kejì, àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n nkópa lónìí bóyá tí wọn kò ṣe olõtọ́ bí ó ti yẹ. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìpinnu ti àná ṣe nnípa lórí àwọn ohun gidi ti òní, àwọn ìpinnu ti òní yíò nípa lórí ọjọ́ ọ̀la wa àti ọjọ́ ọ̀la àwọn ẹbí wa.

Ààrẹ Dallin H. Oaks ti kọ́ni pé:

“Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krísti gbà wá níyànjú láti ronú nípa ọjọ́-ọ̀la. … Ó kọ́ni ní àwọn èrò nlá nípa ọjọ́ ọ̀la láti ṣe ítọ́nisọ́nà àwọn ìṣe wa loni.

“Ní ìfiwéra, gbogbo wa mọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àníyàn pẹ̀lú ìsisìyí nìkan: lò ó ní òní, gbádùn rẹ̀ ní òní, kí o ma sì ro ti ọjọ́ ọ̀là.

“… Bí a ti nṣe àwọn ìpinnu lọ́wọ́lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ máa fì ìgbà gbogbo béèrè pé, ‘Níbo ni èyí yíò já sí?’”3 Njẹ́ àwọn ìpinnu wa lọ́wọ́lọ́wọ́ yíò darí wa lọ sí àyọ nísisìyìí àti ní ayérayé, tàbí njẹ́ wọn yíò darí wa sí ìbànújẹ́ àti àwọn omijẹ́?

Àwọn kan lè rò pé, “A kò nílò láti máa lọ sí ilé ìjọsìn ní gbogbo Ọjọ́ Ìsinmi,” tàbí “A máa san ìdámẹ́wàá nígbàtí nkan bá dára síi,” tàbí “Èmi kò ní ti àwọn olórí Ìjọ lẹ́hìn lórí àkòrí yìí.”

“Ṣùgbọ́n,” wọ́n a wí pé, “a mọ̀ pé Ìjọ jẹ́ òtítọ́, a kò sì ní fi ìhìnrere Jésù Krístì sílẹ̀ láé.”

Àwọn tí wọ́n ní irú àwọn èrò wọ̀nyi kò mọ ipa àìdára tí irú ọmọ-ẹgbẹ́ “kògbóná-kòtutù” yí yíò ní lórí ìgbésí ayé wọn àti lórí ayé àwọn àtẹ̀lé wọn. Àwọn òbí lè dúró ní ṣíṣe déédé, ṣùgbọ́n ewu ti pípàdánù àwọn ọmọ wọn ga púpọ̀—ní ayé yìí àti ní ayérayé.

Nípa àwọn tí kì yíò jogún ògo sẹ̀lẹ́stíà pẹ̀lú àwọn ẹbí wọn, Olúwa wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí kò ṣe akíkanjú nínú ẹ̀rí Jésù; nítorínáà, wọn kò gba adé lórí ìjọba Ọlọ́run wa.”3 Ṣé èyí ni ohun tí a fẹ́ fún arawa tàbí àwọn ọmọ wa? Njẹ́ kò ha yẹ kí a jẹ́ akíkanjú sí i kí a sì dínkù ní kògbóná-kòtutù nítorí ti ara wa àti nítorí àwọn ìran wa bí?

Ààrẹ M. Russell Ballard bákannáà sọ irú àníyàn kannáà:

“Fún àwọn kan, ìfipè Krístì láti gbàgbọ́ àti láti dúró tẹ̀síwájú láti jẹ́ líle. … Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn kan ntiraka láti ní òye ìlànà tàbí ìkọ́ni Ìjọ kan pàtó. Àwọn míràn rí àwọn àfiyèsí nínú àkọọ́lẹ̀-ìtàn wa tàbí nínú àwọn àìpé ti díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ìjọ àti àwọn olórí, ti àtẹ̀hìnwá àti ti lọ́wọ́lọ́wọ́. …

“… Ìpinnu láti ‘má rìn mọ́’ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ìjọ àti àwọn olórí tí Olúwa yàn yíò ní ipa ìgbà-pípẹ́ tí a kò lè fi ìgbà gbogbo rí nísisìyí.”4

Ó ti jẹ́ ogún-ìní ìbànújẹ́ kan tó láti máa fi léni lọ́wọ́—àti fún ìdí wo? Ohunkóhun tí ó jẹ́, kò tó láti fojú fo ipa àìdára ti ẹ̀mí tí yíò dá sílẹ̀ fún àwọn ìrandíran ọjọ́ iwájú.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, bí ẹ̀ bá nla ọ̀kan nínú àwọn ipò méjì tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ mi kọjá, ẹ jọ̀wọ́ ẹ ṣe àtúnyẹ̀wò ipa ọ̀nà ti ìṣe yín. Ẹ mọ̀ pé ètò kán wà fún wa ní ayé yi. Ẹ mọ̀ pé àwọn ẹbí lè jẹ́ ti ayérayé. Kílódé tí ẹ fi tiyín sínú ewu? Ẹ máṣe jẹ́ ìsopọ̀ aláìlágbára nínú okùn ìgbàgbọ́ rírẹwà yí tí ẹ bẹ̀rẹ̀, tàbí tí ẹ gbà, bí ogún-ìní kan. Jẹ èyítí ó lágbára. Àkókò yín nìyí láti ṣe é, Olúwa sì lè rànyín lọ́wọ́.

Láti ìsàlẹ̀ inú ọkàn mi, mo pè yín láti ronú nípa rẹ̀, láti wo ìwájú kí ẹ sì ṣe àgbéyẹ̀wò “ibi tí èyí yíò yọrísí,” àti, bí ó bá jẹ́ dandan, láti jẹ́ akíkanjú tó láti tún ipa ọ̀nà yín ṣe nítorí írandíran yín. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. “Ọmọ Ọlọ́run Ni Mí,” Hymns, no. 301.

  2. Russell M. Nelson, “Bí A Ti Nlọ Síwájú Papọ̀,” Làìhónà, Oṣù kẹrin 2018, 7; àfikún àtẹnumọ́.

  3. Dallin H. Oaks, “Níbo Ni Èyí Yìó Jásí?,” Làìhónà, Oṣù Karun 2019, 60; àfikún àtẹnumọ́.

  4. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 76:79; àfikún àtẹnumọ́.

  5. M. Russell Ballard, “Ọ̀dọ̀ Tani A Ó Lọ?,” Làìhónà, Nov. 2016, 90–91; àfikún àtẹnumọ́.