Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìfẹ́ Ni À Nsọ̀rọ̀ Rẹ̀ Nihin
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


Ìfẹ́ Ni À Nsọ̀rọ̀ Rẹ̀ Nihin

Njẹ́ kí a kọ́ láti sọ̀rọ̀ kí a sì gbọ́ ìfẹ́ Rẹ̀ nihin, nínú ọkàn àti ilé wa, àti nínú àwọn ìpè ìhìnrere wa, ṣíṣe, iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti iṣẹ́ ìsìn.

Àwọn ọmọ Alakọbẹrẹ wa nkọrin, “Ìfẹ́ Ni À Nsọ̀rọ̀ Rẹ̀ Nihin.”1

Mo fún Arábìnrin Gong ní lọ́kẹ́tì kékeré kan nígbàkanrí. Mo kọ dọt-dọt, dọt-dọt, dọt-dọt-dash. Àwọn tí ó dá kóòdì Morse mọ yíò dá àwọn lẹ́tà I, I, U mọ̀. Ṣùgbọ́n mo fi kóòdì keji pẹlú rẹ̀. Ní Mandarin Chinese, “ai” túmọ̀ sí “ìfẹ́.” Nítorínáà, dìkódẹ́dì-méjì, ọ̀rọ̀ náà ni “Mo ní ìfẹ́ rẹ.” Susan Ẹnibíọkàn mi, “I, ai (爱), U.”

À nsọ̀rọ̀ ìfẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èdè. A wí fún mi pé ẹbí ènìyàn nsọ àwọn èdè ààyè 7,168.2 Nínú Ìjọ à nsọ kókó àwọn èdè 575 tí a kọ sílẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè-àbínibí. Bákannáà a o sọ èrò, àkóràn, àti ẹ̀dùn ọkàn nípasẹ̀ iṣẹ́-ọnà, orin, ijó, àmì ìmọ́gbọ́nwá, ìwò inú- àti ìtà araẹni, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.3

Ní òní, ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ nípa àwọn èdè mẹta ìfẹ́ ìhìnrere: èdè ìyárí àti ọ̀wọ̀, èdè iṣẹ́ ìsìn àti ìrúbọ, àti èdè wíwà nínú májẹ̀mú.

Àkọ́kọ́, èdè ìhìnrere ìyárí àti ọ̀wọ̀.

Pẹ̀lú ìyárí àti ọ̀wọ̀, Arábìnrin Gong bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ̀, “Báwo ni e ṣe nmọ́ pé àwọn òbí àti ẹbí yín nifẹ yín?”

Ní Guatemala, àwọn ọmọ wípé, “Àwọn òbí mi ṣiṣẹ́ kára láti bọ́ ẹbí wa.” Ní Àríwá America, àwọn ọmọ wípé, “Àwọn òbí mi nka àwọn ìtàn sí mi wọ́n sì ngbé mi sórí bùsùn ní alẹ́.” Ní Ilẹ̀ Mímọ́, àwọn ọmọ wípé, “Àwọn òbí mi pa mí mọ́ láìléwu.” Ní Ghana, Ìwọ̀-oòrùn Áfríkà, àwọn ọmọ wípé, “Àwọn òbí mi ràn mí lọ́wọ́ pẹ̀lú ìfojúsùn àwọn Ọmọ àti ọ̀dọ́.”

Ọmọ kan wípé, “Àní bíótilẹ̀jẹ́pé ó ti rẹ̀ ẹ́ gan lẹ́hìn ṣíṣe iṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́, ìyá mi ó wá síta láti ṣeré pẹ̀lú mi.” Ìyá rẹ nsọkún nígbàtí ó gbọ́ ọ̀ràn àwọn ìrúbọ rẹ̀ ojojúmọ́. Ọ̀dọ́ ìyá kan wípé, “Àní bíotilẹ̀jẹ́pé ìyá mi àti èmi nígbàmíràn kò gbọ́rawayé, mo nígbẹ́kẹlé nínú ìyá mi.” Ìyá rẹ̀ sọkún bákannáà.

Nígbàmíràn a nílò láti mọ̀ pé ìfẹ́ ni à nṣọ̀rọ̀ rẹ̀ nihin ni à gbọ́ tí a sì mọyì rẹ̀ nihin.

Pẹ̀lú ìyárí àti ọ̀wọ̀, oúnjẹ Olúwa àti àwọn ìpàdé wa míràn ní ó dojúkọ Jésù Krístì. À nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ nípa Ètùtù Jésù Krístì, ti araẹni àti lódodo, kìí ṣe nípa ètùtù nìkan ní ìmúkúrò. A pe Ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò Jésù Krístì ní orúkọ Rẹ̀, Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. À nlo èdè àdúrà ọ̀wọ̀ nígbàtí a bá nbá Baba Ọ̀run sọ̀rọ̀ àti ìyárí ọ̀wọ̀ nígbàtí a bá nsọ̀rọ̀ sí ara wa. Bí a ti ndá Jésù Krístì mọ̀ ní oókan àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì, à ntọ́kásí “lílọ sí tẹ́mpìlì” ní dídínkù si àti pupọ̀ si ní “wíwá sí ọ̀dọ̀ Jésù Krístì nínú ilé Olúwa.” Májẹ̀mú kọ̀ọ̀kan nsọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́, “Ìfẹ́ ni à nsọ̀rọ̀ rẹ̀ nihin.”

Àwọn ọmọ ìjọ nwípé àkójọ ọ̀rọ̀ tí ó ní ìtumọ̀ Ìjọ nílò kí a la-ìdí rẹ nígbàgbogbo. A rẹrin ní èrò pé “ilé èèkan” lè túmọ̀ sí oúnjẹ alẹ́ ẹlẹ́ran; “ilé wọ́ọ̀dù” lè fi ilé-ìwòsàn hàn; “ṣíṣí àwọn ìṣe” lè pè wá láti ṣe orí, èjìká, eékún, àti ẹsẹ̀ ní ibùdó ọkọ̀ ìjọ. Ṣùgbọ́n, ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí a ní òye kí a sì ní inúrere bí a ti nkọ́ àwọn èdè titun ti ìfẹ́ papọ̀. Olùyípadà kan, titun ní ìjọ ni a wí fún pé síkẹ́tì rẹ̀ kéré jù. Dípò bíbínú,ó fèsì, ní ipa pé, “Ọkàn mi yípadà; jọ̀wọ́ ṣe sùúrù bí síkẹ̀tì mi ti nwá sókè.”4

Àwọn ọ̀rọ̀ tí a nlò lè fà wá súnmọ́ si tàbí mú wa jìnnà kúrò lọ́dọ̀ àwọn Krìstẹ́nì àti ọ̀rẹ́ míràn. Nígbàmíràn à nsọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere, iṣẹ́ tẹ́mpìlì, iṣẹ́ ìrannilọ́wọ́ àti àláfíà ní àwọn ọ̀nà tí ó lè mú àwọn ẹlòmíràn gbàgbọ́ pé a ròpé à nṣe àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí fúnra wa. Ẹ jẹ́ kí a máa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìmoore ìyárí àti ọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ àti ògo àti èrè, àánú, àti oore-ọ̀fẹ́ Jésù Krístì àti ìrúbọ̀ ètùtù Rẹ̀.5

Ìkejì, èdè ìhìnrere iṣẹ́ ìsìn àti ìrúbọ.

Bí a ti nkórajọ lẹ́ẹ̀kansi ní ilé-ìjọsìn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láyi bú-ọlá fún àti láti yọ̀ ní Ọjọ́ Sábbáótì, a lè fi ìfọkànsìn májẹ̀mú oúnjẹ Olúwa wa hàn sí Jésù Krístì àti ara wa nípasẹ̀ àwọn ìpè Ìjọ wa, ìjọ́sìn, ìbákẹ́gbẹ́, àti iṣẹ́ ìsìn.

Nígbàtí mo bèèrè lọ́wọ́ àwọn olórí ìbílẹ̀ nípa àníyàn wọn, àwọn arákùnrin àti arábìnrin méjèèjì wípé, “Àwọn kan lára àwọn ọmọ ìjọ wa kìí gba ìpè ìjọ.” Àwọn ìpè láti sin Olúwa àti ara wa nínú Ìjọ Rẹ̀ nfún wa ní ànfàní láti mú àánú, okun, àti ìrẹ̀lẹ̀ wa pọ̀ si. Bí a ti nyà wá sọ́tọ̀, a lè gba ìmísí Olúwa láti gbéga àti láti fún àwọn ẹlòmírán àti ara wa lókun. Bẹ́ẹ̀ni, yíyípadà àwọn ipò àti àwọn àkókò ìgbé ayé wa lè pa agbára wa láti sìn lára, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrètí ni kìí ṣe ìfẹ́ wa láéláé. Pẹ̀lú Ọba Benjamin, a ó wípé, “Bí mo bá ní èmi ó fúnni”7 kí a sì fúnni ní gbogbo ohun tí a lè.

Àwọn olórí èèkàn àti wọ́ọ̀dù, ẹ jẹ́ kí a sa ipá wa. Bí a ti npè (tí a sì ndá) àwọn arákùnrin àti arábìnrin sílẹ̀ láti sìn nínú Ìjọ, ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ kí a ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìwà-ọlá àti ìmísí. Ran ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìmoore àti kí wọ́n lè ṣe àṣeyege. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ dámọ̀ràn pẹ̀lú kí ẹ sì fetísílẹ̀ sí àwọn arábìnrin olórí. Njẹ́ kí a rántí, bí Ààrẹ J. Reuben Clark ti kọ́ni, nínú Ìjọ Olúwa à nsìn níbi tí a pè wá sí, “ibi èyí tí ọ̀kan kò lè wá tàbí kọ̀ sílẹ̀.”8

Nígbàtí Arábìnrin Gong àti èmi ṣe ìgbeyàwó, Alàgbà David B. Haight dá àmọ̀ràn pé: “Ẹ di ìpè kan mú nínú Ìjọ nígbàgbogbo. Nípàtàkì nígbàtí ìgbé ayé bá díjú,” ó wípé, “ẹ nílò láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Olúwa fún àwọn tí ẹ̀ nsìn àti fún yín bí ẹ ti nsìn.” Mo ṣe ìlérí pé ìfẹ́ ni à nsọ̀rọ̀ rẹ̀ nihin, níbẹ̀, àti níbigbogbo bi a ti ndáhùn pé bẹ́ẹ̀ni sí àwọn olórí Ìjọ láti sin Olúwa nínú Ìjọ Rẹ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Rẹ̀ àti àwọn májẹ̀mú wa.

Ìjọ Olúwa tí a mú padàbọ̀sípò lè jẹ́ sísàba fún ìlètò Síónì kan. Bí a ti njọ́sìn, sìn, gbádùn, àti kẹkọ ìfẹ́ Rẹ̀ papọ̀, à ndi ara wa mú nínú ìhìnrere Rẹ̀. A lè jaraníyàn níti-òṣèlú tàbí lórí àwọn ọ̀ràn ìbákẹ́gbẹ́ ṣùgbọ́n rí ìbámu bí a ti nkọrin papọ̀ nínú akọrin wọ́ọ̀dù. À nṣìkẹ́ ìsopọ̀ a sì nbá ìpati jà bí a ti nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ léraléra pẹ̀lú ọkàn wa nínú ilé ara wa àti ní àdúgbò.

Ní ìgbà ìbẹ̀wò ọmọ ìjọ pẹ̀lú àwọn ààrẹ èèkàn, mo ní ìmọ̀lára ìfẹ́ ìjìnlẹ̀ fún àwọn ọmọ ìjọ nínú gbogbo ipò. Bí a ti nwakọ̀ kọjá ilé àwọn ọmọ ìjọ ní èèkàn rẹ̀, ààrẹ èèkan kan kíyèsi pé bóyá a gbé ní ilé kan pẹ̀lú adágún omi wíwẹ̀ tàbí ilè kan pẹ̀lú ilẹ̀ dídọ̀tí, iṣẹ́ ìsìn Ìjọ ni ànfàní tí ó wà pẹ̀lú ìrúbọ. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣe àkíyèsí ọlọ́gbọ́n pé, nígbàtí a bá sìn tí a sì ṣe ìrúbọ nínú ìhìnrere papọ̀, a ó rí àwọn aìṣedéédé díẹ̀ àti àláfíà púpọ̀jùlọ. Nígbàtí a bá fi àyè gbà Á, Jésù Krístì nṣerànwọ́ fún wa láti sọ̀rọ̀ ìfẹ́ Rẹ̀ nihin.

Ní àkókò ìrúnwé yí, ẹbí wa pàdé àwọn ọmọ ìjọ àti ọ̀rẹ́ oníyanu ní Loughborough àti Oxford, England. Àwọn ìkórajọ onítumọ̀ wọ̀nyí rán mi létí bí àwọn ìṣe ìbákẹ́gbẹ́ àti iṣẹ́ ìsìn wọ́ọ̀dù ṣe lè gbé àwọn ìsopọ̀ pípẹ́ ìhìnrere titun ga. Fún ìgbà díẹ̀ mo ti ní ìmọ̀lára pé, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ibi nínú Ìjọ, díẹ̀ nínú àwọn ìṣe wọ́ọ̀dù, bẹ́ẹ̀ni ṣíṣe ètò àti mímuṣe pẹ̀lú èrèdí ìhìnrere, lè so wá papọ̀ pẹ̀lú wíwà pẹ̀lú pùpọ̀ si àti ìrẹ́pọ̀.

Olórí àwọn ìṣe onímísí wọ́ọ̀dù àti ìgbìmọ̀ kan ṣìkẹ́ olúkúlùkù àti ìletò àwọn ènìyàn mímọ́ kan. Ṣíṣètò àwọn ìṣe wọn dáadáa nran gbogbo ènìyàn lọ́wọ́ láti ní iyì, wà nínú, kí a sì pè láti ṣe ojúṣe tí a ti nílò wa. Irú àwọn ìṣe bẹ́ẹ̀ ndí ọjọ́ orí àti ilẹ̀-ìbí papọ̀, dá àwọn ìrántí pípẹ́ sílẹ̀, kí a sì jẹ́ gbigbé jáde pẹ̀lú kíkéré tàbí àìsí oye. Gbígbádùn ìhìnrere bákannáà npe àwọn aladugbo àti ọ̀rẹ́.

Bíbákẹ́gbẹ́ àti iṣẹ́ ìsìn máa nlọ papọ̀ nígbàkugbà. Àwọn ọ̀dọ́ àgbà mọ̀ pé bí ẹ bá fẹ́ láti mọ ẹnìkan, nígbànáà kí ẹ kun àkàbà lẹ́gbẹ̀gbẹ́ lórí nínú iṣẹ́ ìsìn.

Àwòrán
Àwọ ọ̀dọ́ àgbà nkunlé níbí iṣẹ́ ìsìn ṣíṣe.

Bẹ́ẹ̀ni, kò sí ẹnìkankan àti ẹbíkankan tí ó pé. Gbogbo wa nílò ìrànlọ́wọ́ dídàra si láti sọ̀rọ̀ ìfẹ́ nihin. “Ìfẹ́ Pípé Nlé Ẹ̀rù Jáde.”9 Ìgbàgbọ́, iṣẹ́ ìsìn, àti ìrúbọ nfà wá kọjá arawa súnmọ́ Olùgbàlà wa. Bí aanu, otitọ, àti àìní-ìmọtara-ẹni nínú iṣẹ́ ìsìn àti ìrúbọ wa bá ti pọ̀ sí nínú Rẹ̀, ni a ó lè bẹ̀rẹ̀ sí mọ̀ àìlópin àti ètùtù ayérayé àánú àti oore-ọ̀fẹ́ Jésù Krístì fún wa.

Èyí sì nmú wa wá sínú èdè ìhìnrere ti wíwá nínú májẹ̀mú.

À ngbé nínú ayé gbùngbùn ìmọtara-ẹni nìkan. Nítorínáà púpọ̀ ni pé “Mo yan ara mi.” Ó dàbíi pé a gbàgbọ́ pé a mọ ìfẹ́-araẹni dídarajùlọ̀ arawa àti bí a ó ti lépa rẹ̀.

Ṣùgbọ́n nígbẹ̀hìn kìí ṣe òtítọ́. Jésù Krístì ṣe àfiwé òtítọ́ alágbára àìlọ́jọ́ yí:

“Nítorí ẹnìkẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là yíò sọọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù nitorì mi yíò ri.

“Nítorí èrè kíni ó jẹ́ fún ọkùnrin [tàbí obìnrin], bí ó bá jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù?”10

Jésù Krístì fúnni ní ọ̀nà dídára—àwọn ìbáṣepọ̀ tí ó dá lórí májẹ̀mú tọ̀run, tí ó lágbára ju ìdè ikú lọ. Wíwà nínú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run àti ara wa lè wòsàn ó sì lè yà wá símímọ́ àti àwọn ìbáṣepọ̀ wà tí à nṣìkẹ́ jùlọ. Ní òtítọ́, Ó mọ̀ wá dáradára Ó sì fẹ́ràn wa jù bí àwa ti mọ̀ tàbí fẹ́ràn ara wa. Ní òtítọ́, nígbàtí a bá dá májẹ̀mú gbogbo ohun tí a jẹ́, a lè dà ju bí a ṣe wa. Agbára Ọlọ́run àti ọgbọ́n lè bùkún wa pẹ̀lú gbogbo ẹ̀bùn rere, ní àkókò àti ọ̀nà Rẹ̀.

Ìmújáde àfọgbọ́nṣe Òye (IA) ti ṣe ìnasẹ̀ nlá nínú ìyírọ̀padà èdè. Lílọ kọjá ni àwọn ọjọ́ nígbàtí ayélujára lè ṣe ìyírọ̀padà gbólóhùn ọ̀rọ̀ òwe “Ẹ̀mí nfẹ́, ó ṣàìlera fún ara” bí “Wáìní dára, ṣùgbọ́n ẹran náà ti bàjẹ́.” Ní dídùnmọ́ni, àwọn àpẹrẹ àtúnsọ gígùn ti èdè nkọ́ ayélujára ní èdè kan dídára si ju bí kíkọ́ ayélujára ní àwọn òfin gírámà.

Bẹ́ẹ̀náà, àwọn ìrírí tààrà ara wa, lè jẹ́ ọ̀nà ti ẹ̀mí dídára jùlọ láti kọ́ àwọn èdè ìhìnrere ti ìyárí àti ọ̀wọ̀, iṣẹ́ ìsìn àti ìrúbọ àti wíwà nínú májẹ̀mú.

Nítorínáà, níbo àti báwo ni Jésù Krísti ti nsọ̀rọ̀ sí yín nínú ìfẹ́.

Níbo àti báwo ni ẹ ti ngbọ́ tí ìfẹ́ Rẹ̀ nsọ̀rọ̀ nihin?

Njẹ́ kí a kọ́ láti sọ̀rọ̀ kí a sì gbọ́ ìfẹ́ Rẹ̀ nihin, nínú ọkàn àti ilé wa, àti nínú àwọn ìpè ìhìnrere wa, ṣíṣe, iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti iṣẹ́ ìsìn.

Nínú ètò Ọlọ́run, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ó papòdà ní ọjọ́ kan kúrò nínú ayé yí lọ sí ayé tó nbọ̀. Nígbàtí a bá pàdé Olúwa, mo nronú nípa Rẹ̀ tí Ó nwípé, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ àṣẹ àti ìlérí , “Ìfẹ́ mi nsọ̀rọ̀ nihin.” Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.