Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ju Akọni Kan Lọ
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


Ju Akọni Kan Lọ

Jésù Krístì kìí ṣe akọni wà nìkan; Òun ni Olúwa àti Ọba wa, Olùgbàlà àti Olùràpadà gbogbo ènìyàn.

Láti 1856 sí 1860, ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn olùlànà Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ti àwọn ohun ìní wọn nínú ọkọ̀ akẹ́rù àfọwọ́yí fún ó ju ẹgbẹ̀rún máìlì (1,600 km) bí wọ́n ti nrin ìrìnàjò lọ sí Àfonífojì Salt Lake. Ní Ọgọ́rũn ọdún àti àadọ́rin ó dín mẹ́ta sẹ̀hìn ní ọ̀sẹ̀ yí, ní Ọjọ́ Kẹrin Oṣù Kẹ́wàá, 1856, ó ya Ààrẹ Brigham Young lẹ́nú láti gbọ́ pé àwọn ẹgbẹ́ ọkọ̀ akẹ́rù àfọwọ́yí méjì, tí a darí nípasẹ̀ Edward Martin àti James Willie, ṣì wà ní ọgọgọ́rún àwọn máìlì kúrò ní Salt Lake, pẹ̀lú àkokò òtútù tí ó ti nsúnmọ́ gidi.1 Ní ọjọ́ tí ó tẹ̀le gan, láì jìnnà sí ibi tí a ti pàdé ní òní, Ààrẹ Young dúró níwájú àwọn ènìyàn mímọ́ ó wípé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa wà ní orí pẹ̀tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ọkọ̀ akẹ́rù àfọwọ́yí wọn, a sì níláti mú wọn wá sí ihin. … Ẹ lọ kí ẹ sì mú àwọn enìyàn wọnnì wá láti orí pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà nísisìyí.”2

Ní ọjọ́ méjì péré lẹ́hìnnáà, àwọn ọ̀gbà agbanisílẹ̀ àkọ́kọ́ lọ wá ọkọ̀ akẹ́rù àwọn olùlànà náà.

Ọmọ ẹgbẹ́ ti Willie kan júwe ipò ìtara náà ṣíwájú kí àwọn agbanisílẹ̀ gan tó dé. Ó ṣe àbápín pé: “[Kété] nígbàtí ó dàbí gbogbo ìrètí ti sọnù, … tí ó sì dàbíi pé díẹ̀ lókù láti dúró fún láyé, bí òkúta mànàmáná láti kedere ojú ọ̀rùn, Ọlọ́run dáhùn àwọn àdúrà wa. Ọ̀gbà agbanilà kan, tí wọ́n nmú oúnjẹ àti ìpèsè … , wá sí ìwò. … Bí a ṣe dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìgbàlà wa.”3

Àwọn agbànisílẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ akọni sí àwọn olùlànà, wọ́n fi ayé ti ara wọn sínú ewu ní àwọn àkókò líle láti mú àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí ó ti ṣeéṣe láìléwu wá sílé. Irú akọni kan bẹ́ẹ̀ ni Ephraim Hanks.

Ní àárín Oṣù Kẹ́wàá, àti láìní ìfura ewu ọkọ̀-akẹrù náà, Hanks npadàbọ̀ sílé ní Salt Lake lẹ́hìn ìrìnàjò kan nígbàtí, a jì nípa ohùn kan, ní òru, tí ó wípé, “Àwọn ènìyàn ọkọ̀-akẹ́rù wà nínú ìdàmú a sì nílò rẹ̀; ṣe ìwọ ó lọ kí o sì ràn wọ́n lọ́wọ́?”

Pẹ̀lú ìbèèrè náà tí ó ndún ní inú rẹ̀, ó tètè padà sí Ìlú Salt Lake. Àti pé ní gbígbọ́ tí Ààrẹ Heber C. Kimball gbọ́ ó pè fún àfikún àwọn ayọ̀ọ̀da, Hanks jáde síta ní ọjọ́ tó tẹ̀le, fún ararẹ̀, láti gbàlà. Ní rírìn kíakía, ó ṣaájú àwọn agbànisílẹ̀ míràn ní ọ̀nà, àti pé ní dídé ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ Martin, Hanks ṣe ìrantí pé, “Ojú tí ó pàdé ìwò mi bí mo ti wọnú àgọ́ wọn kò lè kúrò ní ìrántí mi títí láé ó … [sì] tó láti wọ inú ọ̀kàn tó lágbára jùlọ.”4

Ephraim Hanks lo àwọn ọjọ́ díẹ̀ ní lílọ láti abà sí abà ní bíbùkún àwọn alaisan. Ó sọ èyí pé “nínú ọ́pọ̀ àwọn àpẹrẹ, nígbàtí a bá ṣe ìpínfúnni sí àwọn aláìsàn, tí a sì bá àwọn àìsàn náà wí ní orúkọ Olúwa Jésù Krístì, àwọn tó njìyà náà á kọ́rajọ lójúkannáà; wọ́n á di wíwòsàn ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”5 Ephraim Hanks yíó jẹ́ akọni sí àwọn olùlànà ọkọ̀-akẹ́rù wọnnì títí láé.

Ní ìfarajọ sí ìgbanisílẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ náà, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n farakan àwọn ìgbésí ayé wa àti pàápàá ipa ọ̀nà ti ìtàn máa nfi léraléra jẹ́ àyorísí ti àwọn ìpinnu àti àwọn àṣeyọrí ti ọ̀kọ̀ọ̀kan ọkùnrin àti obìnrin—àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ nlá, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀, àwọn ọ̀gá okoòwò, àti àwọn olóṣèlú. Àwọn olúkúlùkù ẹni tí kò wọ́pọ̀ wọ̀nyí ni a nbu-ọlá fún bí àwọn akọni, pẹ̀lú àwọn ohun àràbarà àti àwọn ìránnilétí ní kíkọ́ láti ṣe ìrántí àwọn ìwà akin wọn.

Nígbàtí mo wà ní ọ̀dọ́mọkùnrin, àwọn akọni mi àkọ́kọ́ ni àwọn eléré. Àwọn ìrántí mi ṣíwájú ni kíkó àwọn káàdì bọ́ọ̀lù-afọwọ́gbá pẹ̀lú àwọn àwòrán àti àwọn ìṣirò ti Kókó ẹgbẹ́ ìṣeré Bọ́ọ̀lù-àfọwọ́gbá. “Ìjọ́sìn akọni” bí ọmọdé kan ṣe lè jẹ́ ìgbádùn àti àìmọ̀kan, bí ìgbàtí àwọn ọmọ nmúra gẹ́gẹ́bí ààyò akọni-àgbà wọn fún Halloween. Bíótilẹ̀jẹ́pé a fẹ́ràn tí a sì bọ̀wọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹ́bùn àti olókìkí ọkùnrin àti obìnrin fún àwọn okun àti ìdásí wọn, ipò òye èyí tí wọ́n nbọlá-fún, bí ṣíṣe àṣejù, ni ó lè jẹ́ ìbámu bíiti àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ní jíjọ́sìn ère wúrà ní aginjù Sinai.

Gẹ́gẹ́bí àgbàlagbà, ohun tí ó jẹ́ ìgbádùn àìmọ̀kan ìgbàkan lè di ìdènà nígbàtí “ìjọ́sìn akọni” àwọn òṣèlú, búlọ́gà, influẹ́nsà, òṣèré, tàbí àwọn olórin bá nfa kí a wò “kọjá àmì”6 kí a sì sọ ìran ohun tí ó ṣe pàtàkì nu lotitọ.

Fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì, ìpènijà náà kìí ṣe wúrà tí wọ́n mú wá pẹ̀lú wọn ní ọ̀nà ìrìnàjò wọn lọ sí ilẹ ìlérí ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n fi àyè gba wúrà náà láti dà: ère kan, èyí tí ó di ohun ìjósìn wọn, ní yíyí àfiyèsí wọn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófàh, ẹnití ó ti pín Òkun Pupa níyà tí ó sì ti gbà wọ́n là kúrò nínú ìgbèkùn. Ìdojúkọ wọn lórí ère wúrà pa okun wọn láti jọ́sìn Ọlọ́run òtítọ́ lára.7

Akọni náà—akọni wa, nísisìyí àti nígbàgbogbo—ni Jésù Krístì, àti pé ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni tí ó ndarí wa kúrò nínú àwọn ìkọ́ni Rẹ̀, bí a ti ri nínú àwọn ìwé mímọ́ àti nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, lè ní ipa àìdára lórí ìlọsíwájú wa ní ipá-ọ̀nà májẹ̀mú. Ṣíwájú ṣíṣe ẹ̀dá ayé yí, a wo Jésù Krístì nígbàtí ó di híhàn kedere pé ètò tí a dábàá nípasẹ̀ Baba ní Ọ̀run, èyí tí ó pẹ̀lú ànfàní wa láti lọsíwájú kí a sì dàbí Rẹ̀, di pípènijà.

Kìí ṣe pé Jésù Krístì nìkan ni olórí náà ní dídá ààbò bo ètò Baba wa, ṣùgbọ́n Òun bákannáà ṣe ojúṣe pàtàkì jùlọ nínú ìmúṣẹ rẹ̀. Ó fèsì sí Baba ó sì yọ̀ọ̀da láti fi Ararẹ̀ ṣe “ìràpadà fún gbogbo ènìyàn,”8 láti san gbèsè tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa jẹ nípa ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n tí a kò lè san fún ara wa.

Ààrẹ Dallin H. Oaks ti kọ́ni pé, “[Jésù Krístì] ti ṣe ohun gbogbo tó ṣe kókó fún ìrìnàjò wa nínú ayé ikú yi já sí ọ̀nà àyànmọ́ tí a ti là sílẹ̀ nínú ètò ti Baba wa Ọrun.”9

Nínú ọgbà Gethsemane, nígbàtí Ó dojúkọ irú iṣẹ́ bíbonimọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀, Olùgbàlà fi ìgboyà sọ̀rọ̀ pé, “Kìí ṣe ìfẹ́ mi, ṣùgbọ́n tìrẹ, ni ká ṣe” ó sì tẹ̀síwájú láti gbé àpapọ̀ àwọn ìrora, àìsàn, àti ìjìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ti gbogbo ènìyàn tí yíò gbé rí nílé ayé lé orí Ararẹ̀.10 Nínú ìṣe pípé ìgbọràn àti ìfọkànsìn, Jésù Krístì ṣe àṣetán ìṣe akọni ọlọ́lá nínú ìṣẹ̀dá gbogbo ènìyàn, tí ó parí sí Àjínde ológo Rẹ̀.

Nínú ìpàdé apapọ̀ gbogbogbò àìpẹ́ jùlọ, Ààrẹ Russell M. Nelson rán wa létí pé: “Eyikeyi àwọn ìbèèrè tàbí àwọn ìdàmú tí ẹ ní, ìdáhùn náà ni à nrí nígbàgbogbo nínú ayé àti àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì. Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ si nípa Ètùtù Rẹ̀, ìfẹ́ Rẹ̀, àánú Rẹ̀, ẹ̀kọ́ Rẹ̀, àti ìmúpadábọ̀sípò ìhìnrere ìwòsàn àti ìlọsíwájú Rẹ̀. Yípadà sí I! Tẹ̀lé E!”11 Èmi ó sì fikun pé, “Yàn Án.”

Nínú ayé àìrọrùn wa, ó lè jẹ́ ìdánniwò láti yípadà sí àwọn akọni àwùjọ nínú ìtiraka kan láti pèsè ìtumọ̀ híhàn kedere sí ayé nígbàtí ó lè dàbí rúdurùdu tàbí bíbonimọ́lẹ̀. À nra àwọn aṣọ tí wọ́n ṣe onígbọ̀wọ́ fún, à nrọ̀mọ́ òṣèlú tí wọ́n gbà, a sì ntẹ̀lé àwọn àbá wọn tí wọ́n pín lórí ìròhìn ìbákẹ́gbẹ́. Èyí lè dára fún ìyapa ránpẹ́, ṣùgbọ́n a gbúdọ̀ ṣọ́ra kí irú ìjọ́sìn akọni yí má baà di ère wúrà wa. Yíyan akọni òótọ́ ní àwọn àbájáde ayérayé.

Nígbàtí ẹbí wa dé sí Spain láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn wa bí àwọn olórí míṣọ̀n, a rí àyọsọ kan nínú férémù láti ọwọ́ Alàgbà Neal A. Maxwell tí ó ní í ṣe sí àwọn akọni tí a yàn láti tẹ̀lé. Ó wípé, “Bí ẹ kò bá tíì yan ìjọba Ọlọ́run ní àkọ́kọ́, ní ìgbẹ̀hìn ohun tí ẹ bá yàn kò ní mú ìyàtọ̀ wá.”12 Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, nípa yíyan Jésù Krístì, Ọba àwọn Ọba, ni a nyan Ìjọba Ọlọ́run. Àṣàyàn míràn eyikeyi ni ìdọ́gba yíyan apá eléran ara, tàbí ère wúrà, tí yíò sì mú wa kùnà nígbẹ̀hìn.

Nínú Ìwé ti Daniel Májẹ̀mú Láéláé, a ka àkọsílẹ̀ Shadrach, Meshach àti Abednego, tí wọ́n mọ̀ akọni eyí tí wọn ó yàn kedere—àti pé kìí ṣe eyikeyi àwọn ọlọ́run ti Ọba Nebuchadnezzar. Wọ́n fi pẹ̀lú ìgbóyà kéde pé:

“Ọlọ́run wa ẹnití àwa nsìn ní agbára láti gbà wá lọ́wọ́ iná ìléru. …

“Ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó yé ọ, Ọba, pé àwà kì yíò sin àwọn òrìṣà rẹ, bẹ́ẹ̀ni àwà kì yíò tẹríba fún ère wúrà.”13

Bí Àpóstélì Paul ti kọ́ni, “àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọlọ́run wà,”14 àti pé, kí nfikun pé, àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ akọni sí àwọn tí à npè láti tẹríba, láti jọ́sìn, àti láti rọ̀mọ́. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rẹ́ Daniel mẹta ti mọ̀, Ọ̀kanṣoṣo ni a mọ̀dájú pé ó lè gbàlà—nítorí Ó ti nṣe é tẹ́lẹ̀ yíò sì máa ṣe é nígbàgbogbo.

Fún àwa nínú ìrìn àjò wa padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, sí ilẹ̀ ìlérí wa, kìí ṣe òṣèlú, olórin, eléré sísá, tàbí búlọ́gà ni ó jẹ́ ọ̀ràn náà ṣùgbọ́n, jù bẹ́ẹ̀ lọ, yíyàn láti fi àyè gbà wọ́n láti di kókó ohun èlò ìfiyèsí àti ìfojúsùn wa ní ipò Olùgbàlà àti Olùràpadà wa.

A yàn Án, Jésù Krístì, nígbàtí a bá yàn láti bu-ọlá fún ọjọ́ Rẹ̀ bóyá a wà nílé tàbí à nrin ìrìnàjò níbi ìsinmi. A yàn Án nígbàtí a bá yan àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ìwé mímọ́ àti ìkọ́ni àwọn wòlíì alààyè. A yàn Òun nígbàtí a bá yàn láti di ìkaniyẹ tẹ́mpìlì mú tí a sì gbé ìgbé ayé yíyẹ fún lílò rẹ̀ A yàn Án nígbàtí a bá jẹ́ olùlàjà tí a sì kọ láti jà, “nípàtàkì nígbàtí a bá ní ìmọ̀ ẹ̀nìyàn yíyàtọ̀.”15

Kò sí olórí tí ó ti fi ìgboyà hàn jùlọ, kò sí arannilọ́wọ́ tí ó nínúrere jùlọ, ko sí olùwòsàn tí ó ti wò àrùn jùlọ, kò sì sí ayàwòrán tí ó ti jẹ́ alátinúdá ju Jésù Krístì lọ.

Nínú ayé àwọn akọni, pẹ̀lú àwọn ohun ìrántí àti mùsíọ̀mù tí a fi jì fún àwọn ìwà akin ti àwọn ọkùnrin àti obìnrin ayé kíkú, Ẹnikan wà tí ó dúró tayọ gbogbo àwọn míràn. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù Krístì kìí ṣe akọni wà nìkan; Òun ni Olúwa àti Ọba wa, Olùgbàlà àti Olùràpadà gbogbo ènìyàn. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Studies devoted to the Willie and Martin handcart companies include LeRoy R. Hafen and Ann W. Hafen, Handcarts to Zion: The Story of a Unique Western Migration, 1856–1860 (1960); Rebecca Cornwall and Leonard J. Arrington, Rescue of the 1856 Handcart Companies (1981); Howard K. Bangerter and Cory W. Bangerter, Tragedy and Triumph: Your Guide to the Rescue of the 1856 Willie and Martin Handcart Companies, 2nd ed. (2006); and Andrew D. Olsen, The Price We Paid: The Extraordinary Story of the Willie Martin Handcart Pioneers (2006).

  2. Brigham Young, “Remarks,” Deseret News, Oct. 15, 1856, 252.

  3. John Oborn, “Brief History of the Life of John Oborn, Pioneer of 1856,” 2, in John Oborn reminiscences and diary, circa 1862–1901, Church History Library, Salt Lake City.

  4. Ephraim K. Hanks’s narrative as published in Andrew Jenson, “Church Emigration,” The Contributor, Mar. 1893, 202–3.

  5. Ephraim Hanks, in Andrew Jenson, “Church Emigration,” 204.

  6. Jákọ́bù 4:14.

  7. Wo Ẹksódù 32.

  8. 1 Tímotèù 2:6; bákannáà wo Matteu 20:28.

  9. Dallin H. Oaks, “What Has Our Savior Done for Us?,” Liahona, May 2021, 75.

  10. Wo Lúkù 22:39–44.

  11. Russell M. Nelson, “Ìdáhùn náà ni Jésù Krístì Nígbagbogbo,” Liahona, May 2023, 127.

  12. Attributed to 18th-century English clergyman William Law; quoted in Neal A. Maxwell, “Response to a Call,” Ensign, May 1974, 112.

  13. Wo Daniel 3:13–18.

  14. 1 Àwọn Ará Kọ́ríntì 8:5.

  15. Russell M. Nelson, “A Nílò Àwọn Olùlàjà,” Làìhónà, May 2023, 98.