Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Agbára Ìwòsàn Olùgbàlà lórí Erékùṣù Òkun
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


Agbára Ìwòsàn Olùgbàlà lórí Erékùṣù Òkun

Nípasẹ̀ àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì, Olùgbàlà nwo àwọn olúkúlùkù, ẹbí, àti orílẹ̀-èdè sàn.

Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ 1960 baba mi kọ́ni ní Kọ́lẹ́jì Ìjọ ti Hawaii, níbi tí a bí mi sí. Àwọn arábìnrin mi àgbà méje takú pé kí àwọn òbí mi ó sọ mi ní “Kimo,” orúkọ kan ní Hawaii. A gbé nítòsí Tẹ́mpìlì Laie Hawaii nígbàtí ó nṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ ní Agbègbè Asia Pacific, pẹ̀lú Japan.1 Ní àkokò yí, ẹgbẹ́jẹ́gbẹ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́ ará Japan bẹ̀rẹ̀ sí wá sí Hawaii láti gba àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì.

Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìjọ wọ̀nyí ni arábìnrin kan láti erékùṣù rírẹwà ti Okinawa. Ìtàn ìrìnàjò rẹ̀ sí tẹ́mpìlì Hawaii jẹ́ èyì tí ó lápẹrẹ. Ní àwọn dẹ́kéédì ṣíwájú, ó ti ṣe ìgbeyàwó nínú ètò gbígbéyàwó ní ọ̀nà àṣà ti Buddhist. Ní àwọn oṣù díẹ̀ kété lẹ́hìnnáà, Japan kọlu Pearl Harbor, Hawaii, wọ́n gbé United States wọnú ìjà pẹ̀lú Japan. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ogun bí irú ti Midway àti Iwo Jima, àwọn ìró ogun ti àwọn ọmọ-ogun Japan sẹ́hìn sí bèbè erékùṣù ilé rẹ̀ ní Okinawa, ìlà ìparí ti ààbò ní dídúró dojúkọ àwọn ọmọ-ogun Allied ṣíwájú àwọn ilẹ̀ ọkàn ti Japan.

Fún oṣù mẹta búburú ní 1945, Ogun ti Okinawa njà-rànìnrànìn. Flotilla 1,300 ti àwọn ọkọ̀ ogun àwọn Amẹ́rikà yíká wọ́n sì kọlu erékùṣù náà. Àwọn ológun àti ará-ìlù farapa pọ̀ jọjọ. Ní òní ohun ìrántí ọ̀wọ̀ kan ní Okinawa tí a tò sílẹ̀ ju ìgba-lé-lógójì ẹgbẹ̀rún orúkọ àwọn ènìyàn tí a mọ̀ tí wọ́n parun nínú ogun náà.2

Nínú àníyàn ìgbìyànjú láti sá àsálà kúrò nínú ìpanìyàn náà, obìnrin ara Okinawa yí, ọkọ rẹ̀, àti àwọn ọmọ kékèké méjì wọn wá ààbò nínú ihò àpàta kan. Wọ́n farada ìbànújẹ́ àìlèsọ nínú àwọn ọ̀sẹ̀ àti oṣù tó tẹ̀lé.

Ní alẹ́ àníyàn kan ní ààrin ogun náà, pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ tí ebi ti fẹ́rẹ̀ pa kú àti ọkọ̀ rẹ̀ nínú àárẹ̀, ó gbèrò píparí ìjìya wọn pẹ̀lú bọ́nbù ọlọ́wọ́, èyí tí àwọn aláṣẹ ti pèsè fún òun àti àwọn míràn fún èrèdí náà. Ṣùgbọ́n, bí ó ti nmúrasílẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ìrírí ìjinlẹ̀ ti ẹ̀mí kan farahàn tí ó fún un ní ọgbọ́n gidi ti òdodo Ọlọ́run àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún un, èyítí ó fún un ní okun láti tẹ̀síwájú. Ní àwọn ọjọ́ tó tẹ̀le, ó mú ọkọ rẹ̀ sọ jí ó sì bọ́ ẹbí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn koríko, oyin láti inú afárá ilé-oyin líle, àti àwọn ẹ̀dá tí ó rí mú nínú odò kan nítòsí. Sí ìyàlẹ́nu, wọ́n farada oṣù mẹ́fà nínú ihò àpáta títí tí àwọn ará ìletò ìbílẹ̀ fi sọ fún wọn pé ogun ti parí.

Nígbàtí ẹbí padà sílé tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tún ìgbé ayé wọn ṣe, obìnrin ará Japan yí bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwákiri àwọn ìdáhùn nípa Ọlọ́run. Ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ mú ìgbàgbọ́ kan gbóná nínú Jésù Krístì àti ìnílò láti jẹ́ rírìbọmi. Ṣùgbọ́n, ó ní àníyàn nípa àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ti kú láìsí ìmọ̀ Jésù Krístì àti ìrìbọmi, pẹ̀lú ìyà rẹ̀ tí ó ti kú nígbà tí ó nbí i.

Fi ojú inú wo ayọ̀ rẹ̀ nígbàtí àwọn arábìnrin òjíṣẹ́ ìhìnrere méjì láti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn wá sí ilé rẹ̀ ní ọjọ́ kan tí wọ́n sì kọ́ ọ pé àwọn ènìyàn lè kọ́ nípa Jésù Krístì ninú ayé ẹ̀mí lẹ́hìn ikú. Ó ní ìdùnmọ́nínú púpọ̀ nípa ìkọ́ni pé àwọn òbí rẹ̀ lè yàn láti tẹ̀lé Jésù Krístì lẹ́hìn ikú kí wọ́n ó sì gba ìrìbọmi ṣíṣe ní ìtìlẹhìn wọn ní àwọn ibi mímọ́ tí à npè ní tẹ́mpìlì. Òun àti ẹbí rẹ̀ di yíyípadà sí Olùgbàlà wọ́n sì ṣe ìrìbọmi.

Ẹbí rẹ̀ ṣiṣẹ́ kárakára wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe rere, wọ́n ní ọmọ mẹta síi. Wọ́n jẹ́ olotitọ wọ́n sì nṣe déédéé nínú Ìjọ Lẹ́hìnnáà, láìròtẹ́lẹ̀, ọkọ rẹ̀ jìyà àrùn rọpárọsẹ̀ ó sì kú, tí ó mu un ní dandan láti ṣe iṣẹ́ fún àwọn wákàtí gígùn ní oríṣiríṣi àwọn ibi iṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láti pèsè fún àwọn ọmọ rẹ̀ marun.

Àwọn ènìyàn kan nínù ẹbí rẹ̀ àti àdúgbò ṣe òfíntótó rẹ̀. Wọ́n da àwọn ìdàmú rẹ̀ lẹ́bi lórí ìpinnu rẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ ìjọ Krìstẹ́nì. Láìṣeyọnu nípa ìjinlẹ̀ àjálù àti òfíntótó líle, ó di ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Jésù Krístì mú, ó ní ìpinnu láti tẹ̀síwájú, ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run mọ̀ ọ́ àti pé àwọn ọjọ́ dídán wà níwájú.3

Ní ọdún díẹ̀ lẹ́hìn ikú àìtọ́jọ́ ọkọ rẹ̀, ààrẹ míṣọ̀n ti Japan ní ìmọ̀lára ìmísí láti gba àwọn ọmọ ìjọ ara Japan níyànjú láti ṣiṣẹ́ lórí lílọ sí tẹ́mpìlì. Ààrẹ iṣẹìránṣẹ́ ìhìnrere náa jẹ́ ara Amẹ́ríkà olùtọ́jú ní ibi Ogun Okinawa, nínú èyí tí arábìnrin ara Okinawa náà àti ẹbí rẹ̀ ti jìyà lọ́pọ̀lọpọ̀.4 Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, arábìnrin onírẹ̀lẹ̀ náà wí nípa rẹ̀ pé: “Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀tá tí a kórĩra nígbànáà, ṣùgbọ́n nísisìyí ó wà nihin pẹ̀lú ìhìnrere ìfẹ́ àti àláfíà. Sí èmi, èyí jẹ́, ìyanu kan”5

Ní gbígbọ́ ọ̀rọ̀ ààrẹ míṣọ̀n arábìnrin opó náà ní ifẹ inú láti jẹ́ fífi èdìdi dì sí ẹbí rẹ̀ nínú tẹ́mpìlì ní ọjọ́ kan. Ṣùgbọ́n, kò ṣeéṣe fún un, nítorí àìsí owó àti àwọn ìdíwọ́ èdè.

Nígbànáà oríṣiríṣi àwọn ojútũ àṣeyọrí yọjú. Iye owó lè dínkú sí ìlàjì bí àwọn ọmọ ìjọ ní Japan bá ṣáátà ọkọ̀-òfúrufú kan láti fò lọ sí Hawaii ní àkókò ọ̀wọ́n èrò.5 Àwọn ọmọ ìjọ ṣe àkásílẹ̀ wọ́n sì ta àwọn orin tí wọ́n kọ sílẹ̀ nínú vínalì náà tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ará Japan Kọrin. Àni àwọn ọmọ ìjọ míràn tilẹ̀ ta àwọn ilé. Àwọn míràn pa iṣẹ́ wọn tì láti lọ sí ìrìnàjò náà.6

Ìpèníjà míràn fún àwọn ọmọ ìjọ ni pé àgbékalẹ̀ tẹ́mpìlì kò sí ní àrọ́wọ́tó ní èdè Japan. Àwọn olórí Ìjọ pe arakùnrin ara Japan kan láti rin ìrìnàjò lọ sí tẹ́mpìlì ti Hawaii láti ṣe ìyírọ̀padà-èdè ayẹyẹ ẹ̀bùn tẹ́mpìlì.8 Òun ni ara Japan àkọ́kọ́ tí ó yí ọkàn padà lẹ́hìn ogun, lẹ́hìn tí ó ti jẹ́ kíkọ́ àti rírìbọmi láti ọwọ́ olõtọ́ àwọn ológun ara Amẹ́ríkà.7

Nígbàtí àwọn ọmọ ìjọ ará Japan, tí wọ́n ti gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, tí wọ́n ngbé ní Hawaii, kọ́kọ́ gbọ́ ìyírọ̀padà náà, wọ́n sọkún. Ọmọ ìjọ kan ṣe àkọsílẹ̀ pé: “A ti lọ sí tẹ́mpìlì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà. A ti gbọ́ àwọn ayẹyẹ ní èdè Òyìnbó. [Ṣùgbọ́n] a kò tíì ní ìmọ̀lára ẹ̀mí ti … iṣẹ́ tẹ́mpìlì rí bí a ti mọ̀ ọ́ lára nísisìyí [ní gbígbọ ọ] ní èdè àbínibí ti ara wa.”8

Lẹ́hìnwá nínú ọdún kannáà, àwọn àgbà àti ọmọdé 161 gbéra láti Tokyo láti mú ọ̀nà wọn pọ̀n lọ sí Tẹ́mpìlì Hawaii. Arákùnrin ará Japan kan ronú lórí ìrìnàjò náà pé: “Bí mo ti wo ìta ọkọ̀-òfúrufú tí mo sì rí Píálì Harbor, tí mo sì rántí ohun tí orílẹ̀-èdè wa ti ṣe sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Oṣù Kejìlá Ọjọ́ Kéje, 1941, mo bẹ̀rù nínú ọkàn mi. Njẹ́ wọn ó tẹ́wọ́gbà wá? Ṣùgbọ́n sí ìyàlẹ́nu mi wọ́n fi ìfẹ́ àti inúrere títóbi-jùlọ hàn ju bí mo ti rí rí nínú ayé mi lọ.”9

Àwòrán
Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Japan ni a kí káàbọ̀ pẹ̀lú òdòdó lẹ́ìsì.

Ní dídé àwọn Ènìyàn Mímọ́ Japan, àwọn ọmọ ìjọ Hawaiia kí wọn pẹ̀lú àìlónkà àwọn òdòdò lẹ́ìsì nígbàtí wọ́n npààrọ̀ ìgbàmọ́ra àti ìfẹnuko ní ẹ̀rẹ̀kẹ́, àṣà tí ó ṣe àjèjì sí ọ̀làjú Japan. Lẹ́hìn lílo àwọn ọjọ́ mẹwa ayínipadà ní Hawaii, àwọn Ènìyàn Mímọ́ ara Japan sọ ó dàbọ̀ wọn sí adùn orin “Aloha Oe” tí a kọ látẹnu àwọn Ènìyàn Mímọ́ ara Hawaii.10

Ìrìnàjò tẹ́mpìlì kejì tí a ṣètò fún àwọn ọmọ ìjọ ará Japan ní arábìnrin opó ará Okinawa nínú. Ó ṣe ìrìnàjò ẹgbẹ̀rún mẹwa máìlì (ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún-kílò) náà, ọpẹ́ fún ẹ̀bùn nlá láti ọ̀dọ̀ àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere tí wọ́n ti sìn ní ẹ̀ka rẹ̀ tí wọ́n sì tì jẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ ní tábìlì rẹ̀. Nígbàtí a wà nínú tẹ́mpìlì, ó ní omíjé bí ó ti ṣe arọ́pò fún ìrìbọmi ìyá rẹ̀ àti bí ó ti njẹ́ fífi èdìdi dì sí olóògbé ọkọ rẹ̀.

Ìrìn àjò sí tẹ́mpìlì láti Japan sí Hawaii tẹ̀síwájú léraléra títí tí Tẹ́mpìlì Tokyo Japan fi di yíyà-sí- mímọ́ ní 1980, tí ó jẹ́ tẹ́mpìlì ìkejìdínlógún tí ó nṣiṣẹ́. Ní Oṣù Kọkànlá ọdún yí, a ó ya tẹ́mpìlì ọ́gọ́sán áti ìkẹ́fà sí mímọ́ ní Okinawa, Japan. Ó wà ni ibi tí kò jìnnà sí ìhò àpáta ní ààrin gbùngbùn Okinawa níbití obìnrin yí àti ẹbí rẹ̀ fi ṣe ibùgbé.13

Bíótilẹ̀jẹ́pé èmi kò pàdé arábìnrin ìyanu láti Okinawa yí rí, ogun ìní rẹ̀ wà títí nípasẹ̀ ìràn olotitọ́ rẹ̀, ọ́pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn tí mo mọ̀ tí mo sì fẹ́ràn.11

Baba mi, tí ó jẹ́ Olùtọ́jú nínú Ogun Àgbáyé Kejì ti Pacific, ní inú dídùn púpọ̀ nígbàtí mo gba ìpè mi láti sìn ní Japan bíi ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere. Mo dé Japan ní kété lẹ́hìn tí a ya Tẹ́mpìlì Tokyo sí mímọ́ mo sì rí ìfẹ́ wọn fún tẹ́mpìlì náà tààrà.

Àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì jẹ́ àwọn ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run sí àwọn olotitọ àtẹ̀lé Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Nípasẹ̀ tẹ́mpìlì, Baba wa Ọ̀run nso olúkúlùkù àti ẹbí pọ̀ sí Olùgbàlà àti sí ara wọn.

Ààrẹ Russell M. Nelson kéde ní ọdún tó kọjá pé:

“Ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó ndá àwọn májẹ̀mú nínú àwọn àwo ìrìbọmi àti nínú àwọn tẹ́mpìlì—tí ó sì npa wọn mọ́—ní àlékún àyè sí agbára Jésù Krístì. …

“Èrè fún pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni agbára àtọ̀runwá—agbára tí ó nfún wa lokun láti kojú àwọn ìpèníjà, ìdánwò, àti ìrora-ọkàn dáadáa. Agbára yí nmú ọ̀nà wa rọrùn.”12

Nípasẹ̀ àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì, Olùgbàlà nwo àwọn olúkúlùkù, ẹbí, àti orílẹ̀-èdè sàn—àní àwọn wọnnì tí wọ́n fì ìgbàkan dúró bí ọ̀tá kíkorò. Olúwa tó jínde kéde sí àwùjọ kan tí ó kún fún asọ̀ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì pé sí àwọn tí wọ́n bu-ọlá fún “orúkọ mi, ni Ọmọ Òdodo yíò dìde sí pẹ̀lú ìwòsàn ní apá rẹ̀.”13

Mo dúpẹ́ láti jẹ́ ẹlẹri ìmúṣẹ tí ó nlọ lọ́wọ́ nípa ìlérí Olúwa pé “àkokò náà yíó dé nígbàtí ìmọ̀ Olùgbàlà kan yíò tàn jákèjádò gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti àwọn ènìyàn,”14 pẹ̀lú sí àwọn wọnnì “lórí erékùṣù òkun.”15

Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa Olùgbàlà Jésù Krístì àti wòlíì Rẹ̀ àti àwọn àpóstélì ní àwọn ọjọ́-ìkẹhìn wọ̀nyí. Mo jẹ́ ẹ̀rí mi pẹ̀lú ọ̀wọ̀ nípa agbára tọ̀run láti di ní ọ̀run ohun tí a dì ní orí ilẹ̀ ayé.

Èyí ni iṣẹ́ Olùgbàlà, àwọn tẹ́mpìlì jẹ́ ilé mímọ́ Rẹ̀.

Pẹ̀lú ìdánilójú àìyẹsẹ̀, mo kéde àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. The Laie Hawaii Temple was dedicated in 1919 by President Heber J. Grant. As an Apostle, he opened the Church in Japan in 1901. It was the fifth operating temple and the first temple built outside the continental United States.

  2. As of March 2, 2023, there were 241,281 names inscribed on the monument.

  3. Wo Gordon B. Hinckley, “Keep the Chain Unbroken” (Brigham Young University devotional, Nov. 30, 1999), 4, speeches.byu.edu.

  4. Dwayne N. Andersen was wounded in the Battle of Okinawa. He served as mission president in Japan from 1962 to 1965 and was the first president of the Tokyo Japan Temple, from 1980 to 1982.

  5. I met members of her family while my wife and I served as mission leaders in Tokyo. They provided me with this information from her personal family history accounts.

  6. Wo Dwayne N. Andersen: An Autobiography for His Posterity, 102–5, Church History Library, Salt Lake City.

  7. Wo Dwayne N. Andersen, 104.

  8. Wo Edward L. Clissold, “Translating the Endowment into Japanese,” Stories of the Temple in Lā‘ie, Hawai‘i, comp. Clinton D. Christensen (2019), 110–13.

  9. The translator, Tatsui Sato, was baptized July 7, 1946, by a US serviceman, C. Elliott Richards. Tatsui’s wife, Chiyo Sato, was baptized on the same day by Boyd K. Packer. Separately, Neal A. Maxwell fought in the Battle of Okinawa, and L. Tom Perry was among the first wave of Marines to go ashore in Japan following the peace treaty. Àwọn Alàgbà Packer, Maxwell, àti Perry yíò di ọmọ ẹgbẹ́ Iyejú Àwọn Àpóstélì Méjìlá.

  10. Ní Clissold, “Translating the Endowment into Japanese,” 112.

  11. In Dwayne N. Andersen, “1965 Japanese Excursion,” Stories of the Temple in Lā‘ie, Hawai‘i, 114.

  12. Wo Andersen, “1965 Japanese Excursion,” 114, 117.

  13. Later in this session of the October 2023 general conference, President Russell M. Nelson announced 20 new temples, including the Osaka Japan Temple, which will be the fifth temple in Japan.

  14. During our mission in Tokyo from 2018 to 2021, amid the challenges of the COVID pandemic, her family extended love and care for me and my family, which we will forever be grateful for.

  15. Russell M. Nelson, “Ẹ Ṣẹ́gun Ayé kí ẹ sì Wá Ìsinmi,” Liahona, Nov. 2022, 96.

  16. 3 Néfì 25:2.

  17. Mòsíàh 3:20.

  18. 2 Néfì 29:7.