Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Jésù Krístì Ni Ìṣura
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


Jésù Krístì Ni Ìṣura

Fojúsun lórí Jésù Krístì Òun ni Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, “àmì” náà sí ẹnití a níláti wo, àti ìṣura títóbi jùlọ wa.

Ní 1907, ọlọ́rọ̀ Ọkùnrin Òyìnbó kan tí a pè ní George Herbert, Earl ikarun ti Carnarvon,1 lọ sí Egypt ó sì ní ìfẹ́ nínú ẹ̀kọ́ àtijọ. Ó dé ọ̀dọ̀ ará Egypt kan tí a mọ̀ dáadáa, Howard Carter, ó sì daba àjọṣepọ̀. Carter yíò máa bójútó àwọn wíwá ẹ̀kọ́ àtijọ́, àti pé Carnarvon yíò pèsè owó ìlélẹ̀.

Lápapọ̀, wọ́n fi yíyege ṣàwárí onírurú àwọn ibikan. Nígbànáà, wọ́n gba àyè láti ṣe ìwúlẹ̀ nínú Òkè gíga àwọn Ọba, tí ó wà nítòsí ibi ìgbàlódé Luxor, níbití a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibojì àwọn paraoh. Wọ́n pinnu láti wá ibojì Ọba Tutankhamun. Tutankhamun gòkè sórí ìtẹ́ Egypt ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún ṣíwájú ó sì ṣe àkóso fún ọdún mẹwa ṣíwájú ikú àìròtẹ́lẹ̀ rẹ̀.2 A mọ̀ pé a sin ín sínú Òkè gíga àwọn Ọba,3 ṣùgbọ́n ibi ibòji rẹ̀ ni a kò mọ̀.

Carter àti Carnarvon lo ọdún marun àìyege ní wíwá ibojì Tutankhamun kiri. Ní ìgbẹ̀hìn Carnarvon wí fún Carter pé òun ti ṣetán pẹ̀lú iwadi àìyege. Carter bẹ̀bẹ̀ fún àkokò kan ti ìwúlẹ̀ si, Carnarvon sì kaanu ó sì faramọ owó ìlélẹ̀ náà.

Carter da mọ̀ pé gbogbo ilẹ̀ Òkè-gíga àwọn Ọba ni a ti wú bí ìlànà—yàtọ̀ sí agbègbè ti ibùdó àgọ́ ara wọn. Ní àárín àwọn ọjọ́ díẹ̀ ti gbígbẹ́ ibẹ̀, wọ́n rí àwọn àtẹ̀gùn àkọ́kọ́ tí ó darí lọ sílẹ̀ sí ibi ibòji.4

Nígbàtí Carter yọjú wo inú yàrá-àlejò ibojì Tutankhamun, ó rí wúrà níbigbogbo. Lẹ́hìn bíi oṣù mẹ́ta ti ṣíṣe ìwé-ìtàjà àwọn àkóónú ti yàrá-àlejò, wọ́n ṣí ìyẹ̀wù ìsìnkú bíbòmọ́lẹ̀ ní oṣù kejì 1923—ọgọrun ọdún sẹ́hìn. Èyí ni ẹ̀kọ́ àtijọ́ tí ó gbayì jùlọ tí a rí ní ogún sẹ́ntúrì náà.

Ní àwọn ọdún ti ìwákiri àìléso, Carter àti Carnarvon bí ọ̀rọ̀ ti fojúfo ohun tí ó wà lábẹ ẹsẹ̀ wọn. Àwọn sẹ́ntúrì marun ṣíwájú ìbí Olùgbàlà, wòlíì Ìwé ti Mọ́mọ́nì Jacob tọ́kasí mímú yẹpẹrẹ tàbí tẹ́mbẹ́lú ohun tí ó wà nítosí wa bíi “wíwò kọjá àmì.” Jacob ti ri tẹ́lẹ̀ pé àwọn ènìyàn Jerusalem kò ní dá ìlérí tí Messiah ṣe mọ̀ nígbàtí Ó bá wá. Jacob sọtẹ́lẹ̀ pé wọn yíò jẹ́ “ènìyàn kan [tí] wọ́n nkẹ́gàn àwọn ọ̀rọ̀ kedere … wọ́n ó sì [ṣe àfẹ́rí] àwọn ohun tí kò lè yé wọn. Nítorí-èyi, nítorí ìfọ́jú wọn, ìfọ́jú èyítí o bá wọn nípa àwojúmọ́, wọ́n níláti ṣubú.”5 Ní ọ̀rọ̀ míràn, wọn yíò ṣubú.

Ìsọtẹ́lẹ̀ Jacob jẹ déédé. Ní ìgbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé ikú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wò kọjá àmì, kọjá Rẹ̀. Wọ́n wò kọjá Olùgbàlà aráyé. Dípò dídá ojúṣe Rẹ̀ mọ̀ ní mímú ètò Baba Ọ̀run ṣẹ, wọ́n dalẹ́bi wọ́n sì kàn Án mọ́ àgbélèbú. Wọ́n wòó wọ́n sì ndúró de ẹnìkan láti mú ìgbàlà wá fún wọn.

Bí àwọn ènìyàn Jerusalem, àti bí Carter àti Carnarvon, àwà náà lè ní ìtẹ́sí láti wò kọjá àmì. A nílò láti jẹ́ olùṣọ́ ní ìlòdì sí ìtẹ́sí yí kí a má baa sọ Jésù Krístì nù nínú ìgbé ayé wa kí a sì kùnà láti dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbùkún tí Ó fún wa mọ̀. A nílò Rẹ̀. A gbà àmọ̀ràn láti gbẹ́kẹ̀lé “gbogbo àṣepé rẹ̀ pátápátá nípa ẹni tí ó jẹ́ alágbára láti gbàlà.”6

Òun ni àmì wa. Bí a bá ronú láìtọ́ pé ìnílò wà fún ohunkan kọjá ohun tí Ó fúnni, a ó sẹ́ tàbí dín àyè àti agbára tí Ó lè ní nínú ìgbé ayé wa kù. Ó ti gba ẹ̀tọ́ àánú ó sì nawọ́ àánú náà sí wa.7 Òun ni “orísùn ìgbẹ̀hìn [ẹnití a gbúdọ̀ wò fún ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ [wa].”8 Òun ni alágbàwí wa pẹ̀lú Baba ó sì nṣe aṣíwájú ohun tí Baba ti fẹ́ láti ìgbà pípẹ́: fún wa láti padà sọ́dọ̀ Rẹ̀ bí ajogun nínú ìjọba Rẹ̀. Ní àwọn ọ̀rọ̀ Álmà, a nílò láti, “fi ojú [wa] wò kí a sì bẹ̀rẹ̀sí gbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run, pé ó nbọ̀ wá láti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, àti pé yíò jìyà yíò sì kú fún ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ [wa]; àti pé yíò tún jínde kúrò nínú ipò òkú, èyí tí yíò mú àjínde-òkú náà ṣẹ.”9 Jésù Krístì ni ìṣura wa.

Olùgbàlà ti fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà láti mọ̀ọ́mọ̀ dojúkọ Ọ́, pẹ̀lú ànfàní ojojúmọ́ láti ronúpìwàdà. Nígbàmíràn à nfoju pa bí ìbùkún tí a fi fúnni yí ti tóbi tó rẹ́. Nígbàtí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́jọ, mo ṣe ìrìbọmi láti ọwọ́ baba mi. Lẹ́hìnwá, mo di ọwọ́ rẹ mú bí a ṣe nsọdá òpópónà kan tí àwọn ènìyàn pọ̀ sí. Èmi ko fojúsi mo sì gbé ẹsẹ̀ látinú ìjánú gẹ́gẹ́bí ọkọ̀-akólẹ̀ ti nkọjá lọ̀. Baba mi fà mí sẹ́hìn, kúrò ní òpópónà náà sínú ìjánú. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọkọ̀-akólẹ̀ náà ìbá ti gbá mi. Mímọ ìwa ìkà ti ara mi, mo ronú pé, “Bóyá ìbá ti dára fún mi kí nkú nípasẹ̀ ọkọ̀-akólẹ̀ náà nítorí èmì kì bá ti di mímọ́ bí mo ti wà lọ́wọ́lọ́wọ́ bayi lẹ́hìn ìrìbọmi mi.”

Bí ọmọ ọdún mẹ́jọ, mo ti fi àṣìṣe ròó pé omi ìrìbọmi nfọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ nù. Kò rí bẹ́ẹ̀. Ní àwọn ọdún látigbà ìrìbọmi mi, mo ti kọ́ pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ni à nwẹ̀nù nípa agbára Jésù Krístì nípasẹ̀ ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ bí a ti ndá tí a sì npa májẹ̀mú ti ìrìbọmi mọ́.10 Lẹ́hìnnáà, nípasẹ̀ ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà, a lè dúró ní mímọ́. Bákannáà mo ti kọ́ pé oúnjẹ Olúwa nmú ìyípo ìwarere alágbára kan wá sínú ayé wa, ìlèṣe wa láti mú ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa dúró.11

Gẹ́gẹ́bí ìṣura tí ó wà lábẹ́ ẹsẹ̀ Carter àti Carnarvon, àwọn ìbùkún ìṣúra ti oúnjẹ Olúwa wà fún wa ní ìgbà kọ̀ọ̀kan tí a bá lọ sí ìpàdé oúnjẹ Olúwa. A ṣe ìlérí fún wa pé Ẹ̀mí Mímọ́ yíò jẹ́ alabarin wa nígbàgbogbo bí a bá lọ ibi oúnjẹ Olúwa ní ọ̀nà tí olùyípadà kan fi ndébi ìrìbọmi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀, pẹ̀lú ọ̀kan ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìpinnu kan láti gbé ìgbé májẹ̀mú ìrìbọmi. Ẹ̀mí Mímọ́ nbùkún wa pẹ̀lú agbára yíyasínimímọ́ Rẹ̀ kí a lè mú ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa dúró, ní ọ̀sẹ̀ sí ọ̀sẹ̀.12

Ìpìlẹ̀ ti ẹ̀mí wa ni à nfún lókun nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà àti nípa fífi taratara múrasílẹ̀ fún àti ní ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ní yíyẹ. Pẹ̀lú agbára ìpìlẹ̀ ti ẹ̀mí nìkan ni a lè ṣe ìdìmú àfiwé òjò, ìjì, àti àgbàrá tí ó ndojúkọ wa nínú ayé wa.13 Ní sísọ̀rọ̀, ìpìlẹ̀ ti ẹ̀mí wa ni ó nní ìrẹ̀wẹ̀sì nígbàtí a bá mọ̀ọ́mọ́ fo ìpàdé oúnjẹ Olúwa tàbí ìgbàtí a kò bá fojúsí Olùgbàlà ní ìgbà oúnjẹ Olúwa. A lè fi àìmọ̀ọ́mọ̀ “fa [arawa] kúrò nínú Ẹ̀mí Olúwa, kí ó lè má ní àyè kankan nínú [wa] láti tọ́ [wa] sọ́nà ní ipa ọ̀nà ọgbọ́n kí [a] lè di alábùkún, ṣe rere, kí a sì wà nípamọ́.”14

Nígbàtí a bá ní Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú wa, a ó gba ìmísí àti ìtọ́sọ́nà láti dá àti láti pa àwọn májẹ̀mú míràn mọ́, bí irú àwọn tí à nṣe ní tẹ́mpìlì. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nmú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run jinlẹ̀.15 Ẹ lè ti ṣe àkíyèsí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tẹ́mpìlì titun ni a ti kéde ní àwọn ọdún àìpẹ́, ní mímú àwọn tẹ́mpìlì súnmọ́ àwọn ọmọ ìjọ si.16 Ní ọ̀rọ̀ jíjọra, bí àwọn tẹ́mpìlì ti nwà ní àrọ́wọ́tó si, ó lè rọrùn si fún wa láti mú lílọ sí tẹ́mpìlì yẹpẹrẹ. Nígbàtí àwọn tẹ́mpìlì bá jìnà, à nṣetò àkokò wa àti ohun èlò láti rin ìrìn àjò lọ sí tẹ́mpìlì láti jọ́sìn níbẹ̀. À nṣe ìṣíwájú-ipò fún àwọn ìrìn àjò wọ̀nyí.

Pẹ̀lú tẹ́mpìlì kan nítòsí, ó lè rọrùn láti jẹ́ kí àwọn ohun kékèké dí wa lọ́wọ́ ní lílọ, bí a bá sọ fún arawa pé, “Bẹ́ẹ̀ni, èmi ó lọ ní ìgbà míràn.” Gbígbé nítosí tẹ́mpìlì nmú ìlò títóbi jùlọ wá ní ṣíṣe ètò àkokò nínú tẹ́mpìlì, ṣùgbọ́n ìlò náà lè mu rọrùn láti mú tẹ́mpìlì yẹpẹrẹ. Nígbàtí a bá ṣe é, a o “sọ àmì nù,” a ó rẹ ànfàní sílẹ̀ láti fa súnmọ́ Olùgbàlà nínú ilé mímọ́ Rẹ̀. Ìfarasìn wa láti lọ níláti jẹ́ lílókun ó kéréjù nígbàtí tẹ́mpìlì bá wà nítòsí bí ìgbà tó jìnnà.

Lẹ́hìn tí Carter àti Carnarvon wú ibòmíràn ní Òkè gíga àwọn Ọba ní wíwo ibojì Tutankhamun, wọ́n dá ìfojúdá wọn mọ̀. A kò nílò láti ṣiṣẹ́ láìṣe àṣeyege, bí wọn ti ṣe fún àkokò kan, láti wá ìṣura wa. Tàbí kí a nílò láti wá àmọ̀ràn látinú àwọn orísun nlá, ní ọrẹ ìyìn orísun àti ríronú pé irú àmọ̀ran bẹ́ẹ̀ yíò ní òye si ju èyí tí a lè gba láti ọ̀dọ̀ onírẹ̀lẹ̀ wòlíì Ọlọ́run.

Bí a ti kọ́sílẹ̀ nínú Májẹ̀mú Láéláé, nígbàtí Naaman wá láti wo àrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sàn, ó ṣoríkunkun nígbà tí a sọ fún kí ó ri ara rẹ̀ sílẹ̀ nígbà méje nínú odo lásán. Ṣùgbọ́n a rọ̀ọ́ láti tẹ̀lé àmọ̀ràn Elisha sànju kí ó gbẹ́kẹ̀lé èrò àwọn ìmọ̀ bí iṣẹ́-ìyanu ó ti ṣẹlẹ̀. Gẹ́gẹ́bí àyọrísí, ó ní ìwọ̀sàn.17 Nígbàtí a bá gbẹ́kẹ̀lé wòlíì Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé ní òní tí a sì ṣe ìṣe lórí àmọ̀ràn rẹ̀, a ó rí ìdùnnú, àwa náà ó sì gba ìwòsàn pẹ̀lú. A kò nílò láti wo iwájú si

Ẹ̀yin arákùnrin àti aràbìnrin, mo gbà yín níyuànjú láti rántí àti láti fojúsu`n lórí Jésù Krístì nígbàgbogbo. Òun ni Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, “àmì” náà sí ẹnití a níláti wo, àti ìṣura títóbi jùlọ wa. Bí ẹ ti nwá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ẹ ó gba èrè pẹ̀lú okun láti dojúkọ́ àwọn ìpènijà, ìgboyà láti ṣe ohun tí ó tọ́, àti agbára ayé láti mú iṣẹ́ ìránṣẹ́ yín ṣẹ nínú ayé ikú. Ẹ gba ìṣúra ànfàní láti ronúpìwàdà, ànfàní ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa, ìbùkún ti dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì mọ́, àti ìdùnnú jíjọ́sìn nínú tẹ́mpìlì, àti ayọ̀ níní wòlíì àlààyè kan.

Mo jẹri òwọ̀ mi àti ẹ̀rí dídájú pé Ọlọ́run, Baba Ayérayé, ni Baba Ọ̀run wa àti pé Ó wà láàyè; Jésù ni Krístì; Oùn ni Ọ̀rẹ́ rere, ọlọgbọ́n wa tọ̀run,18 èyí ni sì ni Ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò rẹ̀. Ẹ ṣe fún ìgbàgbọ́ àti òtítọ́ yín. A gbàdúrà pé ẹ ó di alábùkún, ṣe rere, àti pípamọ́ ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Orúkọ kíkún ti Earl karun ti Carnarvon ni George Edward Stanhope Molyneux Herbert.

  2. Àwòrán ayélujára kan tí a ṣe ní 2005 fihàn pé Ọba Tutankhamun lè ti jìyà kíkán káàkiri àwọn egungun ẹsẹ̀ rẹ̀ kan, bóyá ó jásí àkóràn àti ikú.

  3. Ọ̀pọ̀ Ìjọba Titun àwọn pharaoh ti Egypt ni a sin sí Òkè-gíga àwọn Ọba. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ibojì wọnnì ni a rí tí a sí fi sínú ohun àtijọ́.

  4. Àkọsílẹ̀ yí nípa àwárí ibojì ti Tutankhamen nípàtàkì dá lórí Eric H. Cline, “King Tut’s Tomb,” ní Archaeology: An Introduction to the World’s Greatest Sites (2016), 60–66.

    Oríṣiríṣi àwọn ohun tí ó fa àwọn àṣàyàn Carter àti Carnarvon nípa ibití wọn ó wú—àti ibi tí wọn kò ní wú—ní Òkè-gíga àwọn Ọba. Agbègbè yíká ibùdóàgọ́ kò wuni kíákíá fún ìhúlẹ̀. Igun mẹ́ta tí a pèsè fún àyè sí ibojì Ramses VI, pé kí àwọn ìhùlẹ̀ ibẹ̀ lè fọ́nká nípàtàkì. Agbègbè tí wọ́n bò, ní àwọn ọ̀rọ̀ Carter, “oye abà àwọn òṣìṣẹ́ kan tí wọ́n kàn jágajàga, tí ó dàbí àwọn lébìrà nlò nínú ibojì ti àwọn Rames, [àti] ìṣísẹ̀ mẹ́ta erùpẹ̀ tí ó wà lábẹ́ wọn.” Kò dàbíi pé àwọn abà naà ni a kọ́ sórí ẹnu ọ̀nà sí ibojì (wo Howard Carter àti A. C. Mace, The Tomb of Tut-ankh-Amen: Discovered by the Late Earl of Carnarvon and Howard Carter, vol. 1 [1923], 124–28, 132).

    Fún àwọn àkọsílẹ̀ míràn nípa ibojì Tutankhamun’s tomb, wo Zahi Hawass, Tutankhamun and the Golden Age of the Pharaohs (2005); Nicholas Reeves, The Complete Tutankhamun: The King, the Tomb, the Royal Treasure (1990), 80–83; and Nicholas Reeves and Richard H. Wilkinson, The Complete Valley of the Kings: Tombs and Treasures of Egypt’s Greatest Pharaohs (1996), 81–82.

  5. Jákọ́bù 4:14.

  6. 2 Néfì 31:19.

  7. Wo Mórónì 7:27–28.

  8. 2 Néfì 25:26.

  9. Álmà 33:22.

  10. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 76:52.

  11. Wo David A. Bednar, “Kọ́ láti gbé ìgbàgbọ́ ga nínú Jésù Krístì” (address given at the seminar for new mission leaders, June 23, 2023); Rachel Sterzer Gibson, “Teach to Build Faith in Jesus Christ, Elder Bednar Instructs,” Church News, June 23, 2023, thechurchnews.com.

  12. Bákannáà, oúnjẹ́ Olúwa, ni a kò gbé kalẹ̀ bí ọ̀nà fífi ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa dúró (wo James E. Talmage, A Study of the Articles of Faith48th edition, Salt Lake City, Utah, 1967, page 175). Ẹnì kan kò lè mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ Sátidé kí a retí pé gbogbo ohun tí ọkùnrin tàbí obìnrin nílò láti ṣe ni kí ó jẹ ẹ̀là kan búrẹ́dì àti mu omi ago ní Ọjọ́-ìsinmi kí ó sì di mímọ́ pẹ̀lú idán. Ṣùgbọ́n àbájáde ìyasímímọ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́ lè wẹ gbogbo ẹni tí ó ronúpìwàdà pẹ̀lú ọkàn òtítọ́ àti ìronújinlẹ̀.

  13. Wo 3 Néfì 18:12–13.

  14. Mòsíàh 2:36.

  15. Ààrẹ Nelson wípé: “Ọlọ́run ní ìfẹ́ pàtàkì fún ẹnì kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ndá májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀ nínú omi ìrìbọmi. Àti pé ìfẹ́ tọ̀run náà njinlẹ̀ bí a ti ndá àwọn àfikún májẹ̀mú tí a sì npa wọ́n mọ́ ” (“Àwọn Àṣàyàn Fún Àìlópin” [worldwide devotional for young adults, May 15, 2022], Gospel Library). The multiple covenants on the covenant path are not just sequential but additive and even synergistic. They facilitate a closer and stronger connection with God. Irú ìsopọ̀ tí ó fi àyè gab` wá láti yípadà dé àmì pé àwòrán Rẹ̀ wà nínú ìrísí wa àti pé ọkàn wa ti yípadà pàtápátà àti ní púpọ̀ jọjọ (wo Alma 5:14).

  16. Ààrẹ Nelson ṣe àlàyé pé Olúwa “nmú kí àwọn tẹ́mpìlì Rẹ̀ wà ní àrọ́wọ́tó. Ó nyára àyè nínú èyítí à nkọ́ àwọn tẹ́mpìlì. Ó nṣe àníkún ìlèṣè wa láti ṣèrànwọ́ ní kíkójọ Isráẹ́lì. Bákannáà ó nmu rọrùn fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti di àtúnṣe níti-ẹ̀mí” (“Fojúsùn Lórí Tẹ́mpìlì,” Liahona, Nov. 2022, 121).

  17. Wo 2 Àwọn Ọba 5:9–14.

  18. Wo “Mo Mọ̀ Pé Olùràpadà Mi Wà Láàyè,” Hymns, no. 136.