Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Alàgbà, Awa Fẹ́ Rí Jésù
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


Alàgbà, Awa Fẹ́ Rí Jésù

A fẹ́ láti rí Jésù fún ẹnití Ó jẹ́ àti láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀.

Ìfọ́jú-Ìwò Ojú

Ní ọjọ́ kan ní ìgbà ìrúwé 1944, ọ̀dọ́mọkùnrin kan jí nínú ilè ìwòsàn ti àwọn ológun. Ó ṣe orí ire láti wà láàyè—wọ́n ti yin ìbọn fún un ní gẹ́rẹ́ lẹ́hìn etí, ṣùgbọ́n àwọn dókítà ti ṣe iṣẹ́ abẹ, àti pé nísisìyí ó le rìn ó sì le sọ̀rọ̀ dáradára.

Pẹ̀lú ìbànínújẹ́, ọta ibọn náà ti ṣe ìbàjẹ́ sí apákan ọpọlọ rẹ̀ tí ó máa ndá àwọn ojú mọ̀. Nísisìyí ó nwo ìyàwó rẹ̀ láì sí ìdámọ̀ tí ó kéré jùlọ; kò dá ìyá ara rẹ̀ mọ̀. Àní ojú tí ó nrí nínú jígí jẹ́ àjèjì sí i—kò le sọ bóyá ó jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin.1

Ó ti di afọ́jú-ojú—ipò kan tí ó nyọ mílíọ́nù àwọn ènìyàn lẹ́nu.2

Àwọn ènìyàn tí ìfọ́jú-ojú wọn bá le gan-an máa ngbìyànjú láti dá àwọn ẹlòmíràn mọ̀ nípa kíkọ́ àwọn ìlànà kan sórí—ìlànà fún dídá ọmọbìnrin kan mọ̀ nípa bátánì àwọn àmì tótòtó rẹ̀ tàbí ọ̀rẹ́ kan nípa ìgbésẹ̀ rẹ̀.

Dídàgbà Sókè

Ìtàn kejì nìyí, tó súnmọ́ ilé síi: Bíi ọ̀dọ́mọkùnrin, mo sáabà máa nrí màmá mi bíi àṣofin. Ó máa npinnu ìgbàtí mo le ṣeré àti ìgbàtí mo níláti lọ ibùsùn tàbí, bíburújù, fa àwọn koríko tu ní yáàdì.

Ó farahàn pé ó fẹ́ràn mi. Ṣùgbọ́n ní ìgbà púpọ̀jù àti sí ìtìjú mi, mo nrí i bí “Ẹni Náà Tí A Gbúdọ̀ Gbọ́ràn Sí.”

Ní àwọn ọdún díẹ̀ lẹ́hìnwá nìkan ni mo wá rí i bí ènìyàn gidi. Ojú ntìmí láti sọ pé èmi kò kíyèsí ẹbọ rẹ̀ nítòótọ́ tàbí kí nronú ìdí tí ó fi wọ àwọn síkẹ́ẹ̀tì gbígbó méjì kannáà nìkan fún ọ̀pọ̀ ọdún (nígbàtí èmi ní àwọn aṣọ titun fún ilé ìwé) tàbí ìdí tí, ní òpin ọjọ́, ó máa nrẹ̀ ẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ó sì maa nní ìtara fún èmi láti tètè lọ ìbùsùn.

A Le Di Afọ́jú-Ìwò Ojú

Bóyá ẹ ti kíyèsi pé àwọn ìtàn méjì wọ̀nyí jẹ́ ìtàn kan nítòótọ́—fún àwọn ọdún púpọ̀jù, mo jẹ́ afọ́jú-ìwò ojú, ní àyọrísí. Mo kùnà láti rí màmá mi bíi ènìyàn gidi. Mo rí àwọn òfin rẹ̀ ṣùgbọ́n èmi kò rí ìfẹ́ rẹ̀ nínú wọn.

Mo sọ àwọn ìtàn mẹ́jì wọ̀nyí láti mú kókó kan jáde: mo fura pé ẹ mọ ẹnìkan (bóyá ẹ jẹ́ ẹnìkan) tí ó njìyà láti ọwọ́ irú ìfọ́jú-ìwò ojú ti ẹ̀mí kan.

Ẹ le máa tiraka láti rí Ọlọ́run bíi olùfẹ́ni Baba. Ẹ le wò sí ìhà ti ọ̀run kí ẹ sì rí, kìí ṣe ojú ti ìfẹ́ àti àánú, ṣùgbọ́n igbó dídí kan ti àwọn òfin nípasẹ̀ èyítí ẹ gbọ́dọ̀ tẹ̀síwájú ní ọ̀nà yín. Bóyá ẹ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run njọba nínú àwọn ọ̀run Rẹ̀, pé Ó nsọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀, àti pé Ó fẹ́ràn arabìnrin yín, ṣùgbọ́n ẹ nròó níkọ̀kọ̀ bóyá Ó fẹ́ràn yín.3 Bóyá ẹ ti ní ìmọ̀lára ọ̀pá irin náà ní ọwọ́ yín ṣùgbọ́n ẹ kò tíi mọ ìfẹ́ Olùgbàlà yín lára síbẹ̀ èyítí ó ntọ́ni sí.4

Mo fura pé ẹ mọ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ nítorípé fún ìgbà pípẹ́, èmi jẹ́ ẹnìkan bẹẹ̀—mo jẹ́ afọ́jú-ìwò ojú ní ti ẹ̀mí.

Mo rò pé ayé mi jẹ́ nípa títẹ̀lé àwọn òfin àti kíkún ojú òsùnwọ̀n sí àwọn òsùnwọ̀n àìfojúrí. Mo mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ràn yín ní pípé ṣùgbọ́n èmi kò le ní ìmọ̀lára rẹ̀ fúnra mi. Ó dàbí pé mo nrò púpọ̀ síi nípa dídé ọ̀run ju wíwà pẹ̀lú Baba mi Ọ̀run lọ.

Bí ẹ̀yín, bíi tèmi, bá le janu ní àwọn ìgbà míràn, ṣùgbọ́n tí ẹ kò kọ orin ìfẹ́ tí nràpadà,”5 kínni a le ṣe?

Ìdáhùn náà, bí Ààrẹ Nelson ti rán wa létí, ni Jésù nígbà gbogbo.6 Èyí sì jẹ́ ìròhìn rere.

Alàgbà, Awa Fẹ́ Rí Jésù

Ẹsẹ kúkúrú kan wà nínú Jòhánnù tí mo fẹ́ràn. Ó sọ nípa àwọn ara ita kan tí wọ́n wa ọ̀nà wọn dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ pẹ̀lú ìbéèrè pàtàkì kan. “Alàgbà,” ni wọ́n wí, “awa yío [fẹ́ láti] rí Jésù.”7

Èyí ni ohun tí gbogbo wa fẹ́—a fẹ́ láti rí Jésù fún ẹnití Ó jẹ́ kí a sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀. Èyí níláti jẹ́ ìdí fún púpọ̀jù ohun tí a nṣe nínú Ìjọ—àti dájúdájú ti gbogbo ìpàdé oúnjẹ Olúwa. Bí o bá nronú irú ẹ̀kọ́ wo láti kọ́ni, irú ìpàdé wo láti ṣètò, tàbí bóyá láti kàn rẹ̀wẹ̀sì lórí àwọn díákónì kí ẹ sì ṣe eré bọ́ọ̀lù-yíyẹ̀, o le mú ẹsẹ yìí bí atọ́nà rẹ: njẹ́ èyí yío ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti rí àti láti fẹ́ràn Jésù Krístì bí? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bóyá kí o gbìyànjú ohun míràn.

Nígbàtí mo ríi pé mo jẹ́ afọ́jú-ìwò ojú ní ti ẹ̀mí, pé mo nrí àwọn òfin ṣùgbọ́n kìí ṣe ìwò ojú ti àánú Baba, mo mò pé kìí ṣe ẹ̀bi Ìjọ. Kìíṣe ti Ọlọ́run, kò sì túmọ̀ sí pé ohun gbogbo ti sọnù; ó jẹ́ ohun kan tí gbogbo wa níláti kọ́. Àní àwọn ẹlẹ́ri àkọ́kọ́ sí Àjínde náà ṣáábà nwà ní ojú-kojú pẹ̀lú Olúwa tó jínde wọn kò sì dá A mọ̀; láti inú Ọgbà Ibojì dé àwọn bèbè ti Gálílì, àwọn àtẹ̀lé Rẹ̀ àkọ́kọ́ “rí Jésù tí Ó ndúró, wọn kò sì mọ̀ pé Jésù ni.”8 Wọ́n níláti kọ́ láti dá A mọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni awa náà.9

Ìfẹ àìlẹ́gbẹ́

Nígbàtí mo ríi pé mo jẹ́ afọ́jú-ìwò ojú ní ti ẹ̀mí, mo bẹ̀rẹ̀ láti máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn Mọ́mọ́nì láti gbàdúrà “pẹ̀lú gbogbo agbára ọkàn” láti jẹ́ kíkún pẹ̀lú ìfẹ́ tí a ṣèlérí fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀—ifẹ́ mi fun Un àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún mi—àti láti “rí i bí òun ti rí … kí nsì ní ìrètí yí.”10 Mo gbàdúrà fún ọ̀pọ̀ ọdún láti le ní agbára láti tẹ̀lé òfin nlá láti fẹ́ràn Ọlọ́run àti láti ní ìmọ̀lára “òtítọ́ nlá àkọ́kọ́ … pé Ọlọ́run fẹ́ràn wa pẹ̀lú gbogbo ọkàn, agbára, iyè inú, àti okun Rẹ̀.” .11

Àwọn Ìhìnrere

Bákannáà mo kà mo sì tún àwọn Ìhìnrere mẹ́rẹ̃rin kà—ní àkókò yí kíkà kìí ṣe láti yọ àwọn òfin Rẹ̀ ṣùgbọ́n láti rí ẹnití Òun í ṣe àti ohun tí Ó fẹ́ràn. Àti pé, ní àkókò, mo di gbígbá lọ nípa odò ìfẹ́ tí ó nṣàn láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Jésù kéde ní ìbẹ̀rẹ̀ pé Òun ti wá “láti wo àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn sàn, láti kéde òmìnira sí àwọn òndè, àti ìgbàpadà ìríran fún àwọn afọ́jú.”12

Èyí kìíṣe ìtòsílẹ̀ láti-ṣe lásán tàbí àpọ́nlé dáradára; ó jẹ́ àwòrán ìfẹ́ Rẹ̀.

Ẹ ṣí àwọn Ìhìnrere láìlétò; ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ní gbogbo ojú ewé a rí I tí Ó nṣe ìtọ́jú fún àwọn ènìyàn tó njìyà—ní ti ìbákẹ́gbẹ́, ti ẹ̀mí, àti ti ara. Ó fi ọwọ́ kan àwọn ènìyàn tí a kà sí ẹlẹ́gbin àti aláìmọ́13 ó sì bọ́ àwọn tí ebi npa.14

Kíni ìtàn tí o fẹ́ràn jùlọ nípa Jésù? Mo fura pé ó fi ọmọ Ọlọ́run hàn tí ó nnawọ́ jáde láti ṣe ìgbamọ́ra tàbí fi ìrètí fún ẹnìkan ní ibi àwọn ààlà—adẹ́tẹ̀,15 ará Samáríà tí wọ́n kórĩra,16 ẹlẹ́ṣẹ̀ panṣágà,17 tàbí ọ̀tá orílẹ̀ èdè náà.18 Irú oore ọ̀fẹ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ yíyanilẹ́nu.

Gbìyànjú láti kọ gbogbo àkókò náà sílẹ̀ tí Ó gbé oríyìn tàbí ṣe ìwòsàn tàbí jẹun pẹ̀lú ará ìta kan, ohun ìkọ̀wé rẹ yío sì fẹ́rẹ̀ tán kí o tó kúrò ní Lúkù.

Bí mo ti rí èyí, ọ̀kàn mi fò ní dídámọ̀ ìfẹ́ni, mo sì bẹ̀rẹ̀sí ní ìmọ̀lára pé Ó le fẹ́ràn mi. Bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni, “Bí ẹ ti nkọ́ nípa Olùgbàlà síi, bẹ́ẹ̀ní yíò rọrùn síi láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àánú Rẹ̀, ìfẹ́ àìlópin Rẹ̀.”19 Àti pé bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó gbẹ́kẹ̀lé tí ẹ ó sì fẹ́ràn Baba yín Ọ̀run síi.

Alàgbà Jeffrey R. Holland ti kọ́ni pé Jésù wá láti fi hàn “wá ẹni àti ohun tí Ọlọ́run Baba wa Ayérayé jẹ́, bí Ó ti jẹ́ olùfọkànsìn pátápátá tó sí àwọn ọmọ Rẹ̀”20ní gbogbo ọjọ́ orí àti orílẹ̀ èdè.

Páùlù wí pè Ọlọ́run ni “Baba [gbogbo] àwọn àànú, àti Ọlọ́run gbogbo ìtùnú.”21

Bí ó bá rí I ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀, jọ̀wọ́ tẹramọ́ ìgbìyànjú.

Àwọn májẹ̀mú àti ìgbàmọ́ra ti Ọlọ́run.

Àwọn wòlíì pè wá láti wá ojú Rẹ̀.22 Mo gba èyí bíi ìránnilétí kan pé a njọ́sìn Baba wa, kìí ṣe ilànà ètò kan, àti pé a kò tíi ṣetán títí ìgbà tí a bá rí Jésù bíi ojú ìfẹ́ Baba wa;30 tí a sì tẹ̀lé Òun, kìí ṣe àwọn òfin Rẹ̀ nìkan.31

Nígbàtí àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì bá nsọ̀rọ̀ nípa àwọn májẹ̀mú, wọ́n kìí ṣe bíi àwọn olùkọ́ abẹ́ ilé tí npariwo jáde láti inú àwọn ààyè ìdúrósí (fẹ́lífẹ́ẹ̀tì pupa), ní sísọ fúnwa láti “gbìyànjú kárakára síi!” Wọ́n fẹ́ kí a ríi pé àwọn májẹ̀mú wa ní pàtàkì jẹ́ nípa àwọn ìbáṣepọ̀25 ó sì le jẹ́ ìwòsàn kan fún ìfọ́jú ìwò ojú ti ẹ̀mí.26 Wọn kìí ṣe àwọn òfin láti gba ìfẹ́ Rẹ̀; Òun ti fẹ́ràn yín ní pípé tẹ́lẹ̀. Ìpèníjà wa ni láti ní òye àti láti ṣe àtúnṣe ayé wa sí ìfẹ́ náà.27

A ngbìyànjú láti ríran láti inú àwọn májẹ̀mú wa, bíi ẹnipé láti inú fèrèsé kan, sí ìwò ojú àánú ti Baba lẹ́hìn.

Àwọn májẹ̀mú jẹ́ àwòrán ti ìgbàmọ́ra Ọlọ́run.

Odò ti Ìfẹ́ Ọlọ́run.

Ní ìparí, a lè kọ́ láti rí I nípa sísìn Ín “Nítorí báwo ni ènìyàn kan ṣe le mọ olúwa tí òun kò sìn?”28

Ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, mo gba ìpè kan tí èmi kò ní ìmọ̀lára pé mo tó bẹ́ẹ̀. Mo tètè jí, pẹ̀lú àìbalẹ̀ ara—ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbólóhùn kan ní inú mi tí èmi kò tíì gbọ́ rí: pé láti sìn nínú Ìjọ yí jẹ́ láti dúró nínú odò ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Ìjọ yí jẹ́ ikọ̀ iṣẹ́ kan ti àwọn ènìyàn pẹ̀lú àwọn ẹ̀mú àti àwọn sọ́bìrì, ní gbígbìyànjú láti ṣèránwọ́ tún ojúnà ṣe fún odò ti ìfẹ́ Ọlọ́run láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Rẹ̀ tí wọ́n wà ní ìparí ìlà.

Ẹnikẹ́ni tí o jẹ́, ohunkóhun tí àtẹ̀hìnwá rẹ jẹ́, ààyè wà fún ọ nínú Ìjọ yí.29

Mú ẹ̀mú àti sọ́bìrì kan kí o sì darapọ̀ mọ́ ikọ̀ náà. Ṣèrànwọ́ láti gbé ìfẹ́ Rẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Rẹ̀, díẹ̀ nínú rẹ̀ yío sì dà sí ara rẹ.30

Ẹ jẹ́kí a wá ojú ìfẹ́ni Rẹ̀, ìgbàmọ́ra májẹ̀mú Rẹ̀, àti lẹ́hìnnáà kí a darapọ̀ ní ọwọ́ nínú ọwọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ Rẹ̀, àti lápapọ̀ a ó kọ orin “Olùràpadà Isráẹ́lì”;

Mú padàbọ̀sípò, Olùgbàlà mi ọ̀wọ́n,

Ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ;

Fún wa ní ìtùnú dídùn Rẹ

Sì jẹ́kí ìlàkàkà dídùn.

Fún ibi mímọ́ rẹ

Mú ìrètí wá fún ọkàn ahoro mi.31

Njẹ́ kí a lè wá ojú ìfẹ́ni Rẹ̀ àti lẹ́hìnnáà kí a jẹ́ ohun èlò ti àánú Rẹ̀ sí àwọn ọmọ Rẹ̀.32 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Wo Hadyn D. Ellis and Melanie Florence, “Bodamer’s (1947) Paper on Prosopagnosia,” Cognitive Neuropsychology, vol. 7, no. 2 (1990), 84–91; Joshua Davis, “Face Blind,” Wired, Nov. 1, 2006, wired.com.

  2. Dennis Nealon, “Báwo ni Ìfọ́jú-Ìwò Ojú Ṣe Wọ́pọ̀ Tó?,” Harvard Medical School, Feb. 24, 2023, hms.harvard.edu; see also Oliver Sacks, “Face-Blind,” The New Yorker, Aug. 23, 2010, newyorker.com.

  3. “Àwọn ọmọ Ìjọ kan gbà ẹ̀kọ́, àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́, àti àwọn ẹ̀rí tí a nkéde ní àsọtúnsọ láti orí aga ìwàásù yi ní Gbàgede Ìpàdé Àpapọ̀ àti nínú àwọn ìpéjọpọ̀ abẹ́lé káàkiri àgbáyé bíi òtítọ́—àti síbẹ̀ wọ́n le máa tiraka láti gbàgbọ́ pé àwọn òtítọ́ ayérayé wọ̀nyí ní í ṣe nínú ìgbé ayé wọn ní pàtó àti sí àwọn ipò wọn” (David A. Bednar, “Ẹ Máa Gbé nínú Mi àti Èmi nínú Yín; Nítorínáà Ẹ Rìn Pẹ̀lú Mi,” Làìhónà, Oṣù Karũn 2023, 125).

  4. Wo 1 Néfì 8:19; 15:23 “Ó le láti pa àwọn òfin Olúwa mọ́ láìsí ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀” (Henry B. Eyring, “Ìgbàgbọ́ láti Bèèrè àti Lẹ́hìnnáà láti Ṣe,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2021, 75).

  5. Álmà 5:26.

  6. Russell M. Nelson, “Ìdáhùn náà ni Jésù Krístì Nígbagbogbo,” Liahona, May 2023, 127–28.

  7. Jòhánnù 12:21

  8. Jòhánnù 20:14 Wọ́n rí ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ Ọ ní ojú ọ̀nà sí Ẹmmáusì (wo Lúkù 24:16), nínú yàrá tí a tì pa (wo Lúkù 24:37), ní àwọn bèbè Gálílì (wo Jòhánnù 21:4), àti ní ibi Ọgbà Ibojì (wo Jòhánnù 20:14).

  9. Bí a bá wá A pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, tí a sì ntẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́, Òun yío di àwárí.

    “Nítorí èmi mọ àwọn èrò tí mo rò sí i yín, ni Olúwa wí, àwọn èrò àlàáfíà, kìí sì ṣe ti ibi. …

    “Ẹyin yío sì wá mi, ẹ ó sì rí mi, nígbàtí ẹ̀yin bá wá mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín” (Jeremiah 29:11, 13

    “Ọjọ́ náà yío dé nígbàtí ẹ̀yin ó ní òye Ọlọ́run pàápàá, ní dídi ààyè nínú rẹ̀ àti nípasẹ̀ rẹ̀.

    “Nígbànã ni ẹ̀yin yíò sì mọ̀ pé ẹ̀yin ti rí mi, pé Èmi ni” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 88:49–50).

    “Olúkúlùkù àwọn ọkàn tí ó bá kọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, àti tí ó ké pe orúkọ mi, tí ó sì gbọràn sí ohùn mi, àti tí ó pa àwọn òfin mi mọ́, yíò rí ojú mi yíò sì mọ̀ pé Èmi ni.” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 93:1).

  10. Mórónì 7:48 Páùlù bákannáà so ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ pẹ̀lú agbára wa láti ríran kedere. Ní ìparí ìwàásù nlá rẹ̀ lórí ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, ó kọ sílẹ̀ pé bíótilẹ̀jẹ́pé “nísisìyí a nrí láti inú jígí, ní síṣú,” a ó rí lẹ́hìnwá “ní ojú kojú: … nígbànáà ní èmi ó mọ̀ àní bákannáà bí a ti mọ̀ mí” (1 Kọ́rintì 13:12).

  11. Jeffrey R. Holland, “Ní Ọ̀la Olúwa Yóò Ṣe Àwọn Ìyanu Láarín Yín,,” LiahonaMay 2016, 127. “Ìtumọ̀ títóbijù fún ‘ìfẹ́ aláìlábàwọ́n ti Krístì’… kìí ṣe ohun tí àwa bíi Kristiẹnì ngbìyànjú ṣùgbọ́n tí a kùnà láti fihàn sí àwọn ẹlòmíràn ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ ohun tí Krístì ṣe àṣeyọrí rẹ̀ pátápátá ní fífihàn sí àwa. Ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ tòótọ́ ni a ti mọ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo rí. A fi hàn ní pípé àti ní àìlábàwọ́n nínú ètùtù ìfẹ́ Krístì fún wa tí kìí kùnà, ti ìgbẹ́hìn” (Jeffrey R. Holland, Krístì àti Májẹ̀mú Titun: The Messianic Message of the Book of Mormon [1997], 336).

  12. Lúkù 4:18, New King James Version.

  13. Wo Matteu 8:3; 9:25.

  14. Wo Máttéù 14:13–21.

  15. Wo Máttéù 8:1–3.

  16. Wo Jòhánnù 4:7–10; Ó yin Ara Samáríà náà (wo Lúkù 10:25–37).

  17. Wo Matthew 21:31; Luke 7:27–50; 15:1–10; Jòhánnù 8:2–12.

  18. Wo Máttéù 8:5–13.

  19. Russell M. Nelson, “Krísti Ti Jínde; Ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ Yíò Ṣí Àwọn Òkè-nlá Ní Ìdí,” Làìhónà, Oṣù Karũn 2021, 103.

  20. Jeffrey R. Holland, “Ọlánlá ti Ọlọ́run,” LiahonaNov. 2003. “Ẹni tí ó bá ti rí mi ó ti rí Baba” (Jòhánnù 14:9).

  21. 2 Kọ́ríntì 1:3.

  22. Wo Orin Dáfídì 27:8; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 88:68.

  23. Wo 2 Kọ́ríntì 4:6; Pope Francis, “Misericordiae Vultus: Bull of Indiction of the Extraordinary Jubilee of Mercy,” Apostolic Letters, vatican.va.

  24. Èyí jẹ́ àkòrí pàtàkì kan. Kìí ṣe iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga náà nìkan ṣùgbọ́n iṣẹ́ Rẹ̀ wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbo: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn; 1.2, Ibi Ìkàwé Ìhìnrere). Èmi kìí kàn lọ sí tẹ́mpìlì ṣùgbọ́n sí ilé Olúwa; kìí ṣe Ìjọ Mọ́mọ́nì ṣùgbọ́n Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn (wo Russell M. Nelson, “Orúkọ Ìjọ Bí Ó Ti Tọ́,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2018, 87–89). Àwọn olùdarí wa ntọ́ka wa sí I àní wọ́n sì nránwa létí pé “kò sí ohun àìláwòrán kan tí a pè ní ‘Ètùtù náà’ èyítí a lè pè fún ìrànlọ́wọ́, ìwòsàn, ìdáríjì, tàbí agbára. Jésù Krístì ni orísun náà” (Russell M. Nelson, “Fífa Agbára Krístì Sínú Ayé Wa,” Làìhónà, Oṣù Karũn 2017, 40).

  25. “Ipa ọ̀nà májẹ̀mú jẹ́ nípa ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run”; ó jẹ́ “ipa ti ìfẹ́— … fífi ìkãnú ṣe ìtọ́jú fún àti nínawọ́ jáde sí ara wa” (Russell M. Nelson, “Májẹ̀mú Àìlópin Náà,” LàìhónàOṣù Kẹwàá 2022, 11).

    Wo David A. Bednar, “Ipò Alábùkún fún àti Ìdùnnú” (ọ̀rọ̀ tí a fúnni níbi ìdanilẹkọ fún àwọn ààrẹ tuntun míṣọ̀n, June 24, 2022); Scott Taylor, “Alàgbà Bednar Ṣe Ìpínfúnni Àwọn Ẹkọ́ Méje lóri ‘Ipò Alábùkún fún àti Ìdùnnú’ ti Ìgbọràn,” Ìròhìn Ìjọ, 27 Oṣù Kẹfà, 2022, thechurchnews.com.

    “Wíwọnú àwọn májẹ̀mú mímọ́ àti gbígba àwọn ìlànà oyèàlùfáà ní yíyẹ nmú wa dàpọ̀ pẹ̀lú ó sì nso wá mọ́ Olúwa Jésù Krístì àti Baba Ọ̀run. Èyí kan túmọ̀ sí pé a ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olùgbàlà bí Alágbàwí àti Onílàjà wa kí a sì gbaralé èrè, àánú, àti oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ nínú ìrìn àjò ìgbé-ayé. …

    Gbígbé ìgbé ayé àti fífẹ́ràn àwọn ìfọkànsìn májẹ̀mú nṣẹ̀dá ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa tí ó jẹ́ ìjinlẹ̀ níti-ara ẹni àti tí ó jẹ́ alágbára níti-ẹ̀mí. … Jésù nígbànáà di púpọ̀ síi ju òṣèré pàtàkì náà nínú àwọn ìtàn ìwé-mímọ́ lọ; àpẹrẹ àti àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ ní ipá lórí gbogbo ìfẹ́ inú, èrò, àti ìṣe wa” (David A. Bednar, “Ṣùgbọ́n A Kò Fétísí Wọn,” Làìhónà ,Oṣù Karũn 2022, 15).

    Wo D. Todd Christofferson, “Ìbáṣepọ̀ Wa pẹ̀lú Ọlọ́run,” Làìhónà, Oṣù Kárũn 2022, 78–80.

  26. “Àti láìsí àwọn ìlànà ibẹ̀, àti àṣẹ ti oyè-àlùfáà, agbára ìwàbí-Ọlọ́run ni a kò lè fi hàn fún àwọn ènìyàn nínú ẹran ara;

    “Nítorí láì sí èyí ènìyàn kan kò le rí ojú Ọlọ́run, àní Baba, kí ó sì wà láàyè” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 84:21–22.

  27. Patricia Holland, “Ọjọ́ Iwájú Kan Tí Ó Kún Fún Ìrètí” (káríayé ìsìn àkàṣe kan fún àwọn ọ̀dọ́ àgbà, 8 Oṣù Kínní, 2023), Ibi Ìkàwé Ìhìnrere:

    “Ẹ kò níláti sáré káàkiri ní lílépa ìrètí pé Òun yío ràn yín lọ́wọ́; ẹ kò ṣeé ẹ kò sì le ṣe ẹ̀dá rẹ̀. Like so much in the realm of grace, you won’t acquire it by leaning on your own strength or on that of another person. There are no secret formulas or any magical mantras involved. …

    “In fact, the part we play is important but actually very small; God has the larger portion of the task. Our part is to come unto Him in lowliness and simplicity, then we should worry not and fear not.”

  28. Mòsíà 5:13; bákannáà wo Jòhánnù 17:3.

  29. Ààrẹ Russell M. Nelson ti pè wá ní àsọtúnsọ pé “ẹ mú agbo ìfẹ́ wa gbòòrò láti gba gbogbo ẹbí ẹlẹ́ran-ara mọ́ra.” (“Ìbùkún Ni Fún Àwọn Onílàjà,” Liahona, Nov. 2002, 41). In May 2022 he told young adults that “labels can lead to judging and animosity. … Ẹ̀yíkéyí ìlòkulò tàbí ẹ̀tanú sí ẹlòmíràn nítorí orílẹ̀ èdè, ẹ̀yà, ohun tí a mọ̀ nípa ìbálòpọ̀, lákọlábo, àwọn oyè ẹ̀kọ́, ọlàjú, tàbí àwọn ìfidánimọ̀ pàtàkì míràn jẹ́ ìwà ìbàjẹ́ sí Ẹlẹ́dã wa!” (“Àwọn Àṣàyàn fún Ayérayé” [worldwide devotional for young adults, May 15, 2022], Gospel Library). Àti nípàtàkì, ó sọ pé: Mo banújẹ́ pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa dúdú ní gbogbo ayé nfarada ìrora ẹlẹ́yàmẹ̀yà àti ẹ̀tanú. Ní òní mo pe àwọn ọmọ ìjọ̀ níbigbogbo láti jẹ́ àpẹrẹ nípa pípa àwọn ìwà àti ìṣe ẹ̀tànú ti. Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti gbé ọ̀wọ̀ ga fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (“Ẹ Jẹ́kí Ọlọ́run Borí,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2020, 94).

    “Ẹtanú kò báramu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a ti fihàn. Ojúrere tàbí àìní-ojúrere pẹ̀lú Ọlọ́run dá lórí ìfọkànsìn sí Òun àti àwọn òfin Rẹ̀, kìí ṣe lórí àwọ̀ ara ẹnìkan tàbí àwọn ohun míràn.

    “… Nínú èyí ni ẹtanú wà tí ó dá lórí ẹ̀yà, ti ibi tí a jẹ́, ti orílẹ̀ èdè wo, ẹ̀yà èdè, ẹ̀yà lákọ-lábo, ọjọ́ orí, àlẹ́bù ara, ipò ìbákẹ́gbẹ́ ọrọ̀ ajé, ẹ̀sìn gbígbàgbọ́ tàbí àìgbàgbọ́, àti ẹ̀kọ́ nípa ìbálòpọ̀” (Ìwé Ìléwọ́ Gbogbogbò, 38.6.14, Ibi Ìkàwé Ìhìnrere).

  30. Wo 1 Néfì 11:25

  31. Olùràpadà Ísráẹ́lì,” Àwọn Orin Ìsìn, no. 6.

  32. Wo Romù 9:23