Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Jíjẹ́ Ẹ̀rí nípa Jésù Krístì nínú Ọ̀rọ̀ àti Àwọn Ìṣe
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


Jíjẹ́ Ẹ̀rí nípa Jésù Krístì nínú Ọ̀rọ̀ àti Àwọn Ìṣe

Bí a ṣe ngbìyànjú láti gbé ìgbé ayé wa ní ìbámu pẹ̀lú ìhìnrere Jésù Krístì, ìwà wa yíò jẹ́ ẹ̀rí alààyè ti Olùràpadà wa.

Níbi ìrìbọmi ọ̀kan lára àwọn ìlérí tí a ṣe ni pé a gbà láti gbé orúkọ Jésù Krístì lé ara wa. Èrèdí mi lónìí ni láti ránwa létí pé a lè fi han Ọlọ́run pé a gbé orúkọ Ọmọ Rẹ̀ lé ara wa nípa jíjẹ́ ẹ̀rí nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe, àti ní gbogbo ìgbà tí a bá ti lè ṣe é, pé Jésù ni Krístì náà.

Nígbàtí Ó nṣe ìṣẹ ìránṣẹ́ fún tí ó sì nkọ́ àwọn ènìyàn ní Àmẹ́ríkà lẹ́hìn Àjínde Rẹ̀, Olùgbàlà kéde pé:

“Njẹ́ wọn kò ha ti ka àwọn ìwé-mímọ́, èyítí ó wí pé ẹ̀yin nílati gbé orúkọ Krístì lé ara yín, èyítí í ṣe orúkọ mi? Nítorí nípa orúkọ yĩ ni a ó máa pè yín ní ọjọ́ ìkẹhìn;

“Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì gba orúkọ mi, tí ó sì forítì dé òpin, ohun kannã ni a ó gbàlà ní ọjọ́-ìkẹhìn.”1

Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ wa pé “gbígbé orúkọ Olùgbàlà lé ara wa ní kíkéde àti jíjẹ́ ẹ̀rí fún àwọn ẹlòmíràn nínú—nípasẹ̀ àwọn ìṣe wa àti àwọn ọ̀rọ̀ wa—pé Jésù ni Krístì náà.”2

Bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, a ní ìbùkún àti ànfàní láti dúró bí ẹlẹ́rìí ti Olúwa àti orúkọ Rẹ̀ níbi gbogbo tí a bá wà.3 Bí a ṣe ngbìyànjú láti gbé ìgbé ayé wa ní ìbámu pẹ̀lú ìhìn rere Jésù Krístì, ìwà wa yíò jẹ́ ẹ̀rí alààyè ti Olùràpadà wa àti orúkọ Rẹ̀. Síwájú síi, a njẹ́ ẹ̀rí nípa Krístì nínú ọ̀rọ̀ nípa pípín ohun tí a gbàgbọ́, ní ìmọ̀lára, tàbí tí a mọ̀ nípa Krístì

Nígbàtí a bá fi ìrẹ̀lẹ̀ pín ẹ̀rí wa nípa Olúwa nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, Ẹ̀mí Mímọ́ nfi ìdí rẹ̀ múlẹ̀4 sí àwọn tí wọ́n ní èrò gidi, ọkàn tó ṣí sílẹ̀, tí wọ́n sì ṣetán tinútinú pé Jésù ni Krístì náà ní tòótọ́.5

Yío wù mi láti pín àwọn àpẹrẹ méjì ti àìpẹ́ yí àti onimisi nípa àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n fi han Ọlọ́run pé àwọn gbé orúkọ Jésù Krístì lé ara wọn nípà sísọ̀rọ̀ nípa Rẹ̀ àti jíjẹ́ ẹ̀rí àìlábàwọ́n nípa Olúwa nínú àwọn ìpàdé Ìjọ.

Àpẹrẹ àkọ́kọ́: Nígbàtí ìyàwó mi, Elaine, àti èmi lọ sí Spain ní 2022, a lọ sí àwọn ìpàdé Ọjọ́ Ìsinmi ní ẹ̀ka kékeré kan ti Ìjọ níbẹ̀. Bí mo ti jókòó sórí pẹpẹ àti ìyàwó mi láàrin àwọn olùjọ́sìn, mo ṣe àkíyèsí pé ó jókòó sí ẹ̀gbẹ́ obìnrin àgbàlagbà kan. Nígbàtí ìpàdé oúnjẹ Olúwa parí, mo rìn lọ sọ́dọ̀ Elaine mo sì wí pé kí ó ṣe àfihàn mi sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ titun. Ó ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì fihàn pé obìnrin yìí, tí kì í ṣe ọmọ Ìjọ, ti nṣèbẹ̀wò sí Ìjọ fún nkan bí ọdún méjì. Nígbà tí mo gbọ́ ìyẹn, mo bèèrè lọ́wọ́ obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run yìí pé kí ló mú kó padà wá sípàdé fún àkókò gígùn bẹ́ẹ̀. Obìnrin náà fèsì tìfẹ́tìfẹ́ pé, “Mo fẹ́ wá síbí torí pé ẹ nsọ̀rọ̀ nípa Jésù Kristi nínú àwọn ìpàdé yín.”

Ní kedere, àwọn ọmọ ìjọ ní ẹ̀ka náà ní Spain sọ̀rọ̀, kọ́ni, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀rí nípa Krístì nínú àwọn ìpàdé wọn.

Àpẹrẹ kejì: Lẹ́hìn ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn ní Agbègbè Brazil, mo gba ìpínfúnni iṣẹ́ titun kan láti sìn ní olú-ílé-iṣẹ́ ti Ìjọ. Nígbàtí a kó lọ sí Ilú Salt Lake, ní òpin Oṣù Kéje ti ọdún yí, a lọ sí àwọn ìpàdé Ọjọ́ Ìsinmi ní wọ́ọ̀dù wa titun àti oníyànílẹnu. Ọ̀kan nínú àwọn ìpàdé wọ̀nyí jẹ́ ìpàdé ààwẹ̀ àti ìjẹ́rìí. Lẹ́hìn fífi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ jẹ oúnjẹ Oúwa, àwọn ọmọ ìjọ dìde wọ́n sì jẹ́ ẹ̀rí àtọkànwá nípa Olùgbàlà ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Îpàdé náà dá lórí Jésù Krístì, àti pé a lè ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí ní gidi. A múwa gbèrú síi, a sì fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Bí àwọn ọ̀rẹ́ Ìjọ, tí wọ́n nwá òtítọ́ lọ́nà tòótọ́, bá wà ní ìpàdé náà, wọn ì bá ti ríi pé èyí ni Ìjọ Jésù Krístì.

Ó ti jẹ́ ìbùkún tó láti rí i pé àwọn ìpàdé ìjọ wa jẹ́ àwọn ànfàní yíyàn fún wa láti jẹ́ ẹ̀rí nípa Krístì àti láti ṣe àmì sí Ọlọ́run pé a yọ̀ ní gbígbé orúkọ Ọmọ Rẹ̀ lé ara wa.

Nísisìyí, ẹ jẹ́ kí nmẹ́nu ba àpẹrẹ alágbára kan ti gbígbé orúkọ Jésù Krístì lé ara wa nípa jíjẹ́ ẹ̀rí nípa Rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ìṣe.

Ní Oṣù Kẹ́jọ tí ó kọjá, mo ba Alàgbà Johnathan Schmitt lọ sí ilé ṣíṣí ti Tẹ́mpìlì Feather River California ní Ìlú Yuba. Níbẹ̀ mo ní ìbùkún ti dídarí àwọn ẹgbẹ́ tí wọn wá síbi ìbẹ̀wò sí tẹ́mpìlì. Ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyi ní ọmọ Ìjọ kan nínú, Virgil Atkinson, àti àwọn ọ̀rẹ́ méje ti àwọn ìgbàgbọ̀ míràn. Nígbàtí ìbẹ̀wò náà nparí lọ, nínú yàrá ìsopọ̀ tẹ́mpìlì kan, Arákùnrin Atkinson ní ìmí ẹ̀dùn bí ó ṣe nfi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n wá sí tẹ́mpìlì lọ́jọ́ náà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ lójúkannáà lẹ́hìn tí ó ti ṣe bẹ́ẹ̀, obìnrin kan nínú àwùjọ náà dìde ó sì wí pé, “Gbogbo wa fẹ́ràn Virgil. Kò fi tipà gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lé wa lórí rí. Ṣùgbọ́n kò tijú nípa rẹ síbẹ̀. Ó kàn ngbé ìgbé ayé ohun tí ó gbàgbọ́.”

Láti ọ̀pọ̀ ọdún, gbígbé ìgbé ayé bíi Krístì ti Arákùnrin Atkinson ṣiṣẹ́ bí ẹ̀rí kan tó lágbára sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àpẹrẹ rẹ̀ jẹ́ àfihàn líle pé ó ti gbé orúkọ Krístì lé orí ara rẹ̀.

Ní ìparí, ẹ jẹ́ kí nṣe àjọpín ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ nípa bí a ṣe lè gbé orúkọ Krístì lé ara wá kí a sì jẹ́ ẹ̀rí Rẹ̀ nípa lílo orúkọ títọ́ ti Ìjọ.

Ààrẹ Nelson, alààyè wòlíì Ọlọ́run, nínú ọ̀rọ̀ ìpàdé àpàpọ̀ gbogbogbò 2018 kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Orúkọ Títọ́ ti Ìjọ,” wí pé: “Ó jẹ́ àtúnṣe kan. Ó jẹ́ àṣẹ Olúwa. Joseph Smith kò sọ Ìjọ tí a mú padà bọ̀ sípò nípasẹ̀ rẹ̀ lórúkọ; bẹni Mọ́mọ́nì ko ṣe. Olùgbàlà Fúnrarẹ̀ ni ó wipe, ‘Nítorí báyìí ni a ó pe orúkọ ìjọ mi ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, àní Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn’ [Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 115:4].”6

Gbogbo wa ni a fi ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò sílẹ̀ ní ọjọ́ náà pẹ̀lú ìfaramọ́ tí a sì pinnu láti tẹ̀lé wòlíì àti láti lo orúkọ Ìjọ ti a ti fihàn láti ìgbà náà lọ. Mo wo ara mi gidi láti ríi dájú pé mo lo orúkọ títọ́ ti Ìjọ. Ní ìgbà díẹ̀ àkọ́kọ́, mo níláti kíyèsára gidigidi kí nmá sì gba ara mí láàyè láti padà sí àwọn ọ̀nà àtijọ́. Lẹ́hìn àwọn ìgbìyànjú díẹ̀ àkọ́kọ́, Mo ní ìtura díẹ̀ si nípa lílo orúkọ Ìjọ tí a fihàn. Mo gbà pé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, èmi yíò sọ orúkọ Ìjọ ní kíákíá. Mo ní ìmọ̀lára àníyàn pé àwọn ènìyàn kò ní fiyè sí orúkọ Ìjọ ní kíkún àti pé wọ́n le rò pé ó gùn díẹ̀.

Bíótilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo mọ̀ lẹ́hìnwá pé sísọ orúkọ Ìjọ ní kíkún pẹ̀lú èrò fún mi ní àwọn ànfàní iyebíye láti sọ orúkọ Jésù Krístì àti ní tòótọ́ láti jẹ́ ẹ̀rí nípa Olùgbàlà nípasẹ̀ pípe orúkọ Rẹ̀ nínú orúkọ Ìjọ Rẹ̀. Mo tún ṣe àkíyèsí pé nígbà tí mo bá sọ orúkọ títọ́ ti Ìjọ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, mo máa nrántí Jésù Krístì lemọ́lemọ́ síi, mo sì nní ìmọ̀lára ipa Rẹ̀ nínú ìgbésí ayé mi.

Nípa títẹ̀lé wòlíì, gbogbo wa lè kọ́ láti jẹ́ ẹ̀rí síi nípa Jésù Krístì nípa lílo orúkọ títọ́ ti Ìjọ, nípa báyìí a ngbé orúkọ Olúwa lé arawa ní kíkún síi.

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ ìsinmi yìí, mo fi ayọ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé Ààrẹ Nelson jẹ́ alààyè wòlíì Ọlọ́run àti pé Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn ni Ìjọ Krístì tí a múpadàbọ̀ sípò. Mo fi ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí nípa Ọmọ Ọlọ́run àti jíjẹ́ ti ọ̀run Rẹ̀. Òun ni Àkọ́bí àti Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Ọlọ́run, Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, Ẹ̀mánúẹ́lì náà.7 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.