Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwa ni Ọmọ Rẹ̀.
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


Àwa ni Ọmọ Rẹ̀.

A ní irú ìbí àtọ̀runwá kannáà a sì ní irú agbára àìlópin kannáà nípa oore-ọ̀fẹ́ Jésù Krístì.

Njẹ́ ẹ rántí ìrírí tí wòlíì Samuel ní nígbàtí Olúwa ran an lọ sí ilé Jesse láti fi àmì òróró yan ọba Ísráẹ́lì titun? Samuel rí Eliab, àkọ́bí Jesse. Eliab, ó dàbí, ó ga ó sì ní ìwò olórí. Samuel ri ìyẹn ó sì ti sọtán lọ́kàn rẹ̀. Ó jásí pé ó sọ àìtọ́ lọ́kan rẹ̀, Olúwa sì kọ́ Samuel pé: “Máṣe wo ojú rẹ̀, tàbí gíga rẹ̀; … nítorí ènìyàn a máa wo ojú, ṣùgbọ́n Olúwa nwo ọkàn.”1

Ṣé ẹ rántí ìrírí tí ọmọẹ̀hìn Ananias ní nígbàtí Olúwa ran lọ láti bùkún Saul? Orúkọ tí Saul ní ṣíwájú rẹ̀, Ananias ti gbọ́ nípa Saul àti ìwà ìkà, inúnibíni áìdúró rẹ̀ lórí àwọn Ènìyàn Mímọ́. Ananias gbọ́ ó sì sọtán lọ́kàn rẹ̀ pé bóyá kí òun ó máṣe ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí Saul. Ó jásí pé ó sọ àìtọ́ lọ́kan rẹ̀, Olúwa sì kọ́ Ananias pé: “Ohun èlò ààyò ni ó jẹ́ sí mi, láti gbé orúkọ mi, láti jẹri orúkọ mi níwájú àwọn Kèfèrí, àti àwọn ọba, àti àwọn ọmọ Isráẹ́lì.”2

Kíni ìdàmú náà pẹ̀lú Samuel àti Ananias nínú àwọn àpẹrẹ méjì wọ̀nyí? Wọ́n ri pẹ̀lú ojú wọn wọ́n sì gbọ́ pẹ̀lú etí wọn, àti pé bí àyọrísí, wọ́n ṣe ìdájọ́ lórí àwọn míràn nítorí dídálé ìwò àti ohun àhesọ.

Nígbàtí àwọn agbowódé àti Farisí rí obìnrin tí ó ṣe panṣágà, kíni wọ́n rí? Obìnrin búburú kan, ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó jẹ̀bi ikú. Nígbàtí Jésù rí i, kíni Ó rí? Obìnrin kan tí ó juwọ́lẹ̀ ránpẹ́ sí àìlera ti ẹran-ara ṣùgbọ́n tí a lè gbàlà nípa ìrònúpìwàdà àti ètùtù Rẹ̀. Nígbàtí àwọn ènìyàn rí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun, ẹnití ìránṣẹ́ rẹ nṣàárẹ̀ àrùn ẹ̀gbà, kíni wọ́n rí? Boyá wọ́n rí àfínràn kan, àjèjì kan, ẹnìkan tí a pẹ̀gàn. Nígbàtí Jésù rí i, kíni Ó rí? Àníyàn ọkùnrin kan fún àláfíà ọmọ ilé rẹ̀, ẹnití ó nwá Olúwa ní inúrere àti ìgbàgbọ́. Nígbàtí àwọn ènìyàn rí obìnrin náà pẹ̀lú àrùn ẹ̀jẹ̀, kíni wọ́n rí? Bóyá obìnrin aláìmọ́ kan, tí a ti lé jáde láti fi ṣẹ̀sín. Nígbàtí Jésù rí i, kíni Ó rí? Òbìnrin alaarẹ, adánìkanwà tí a sì patì nítorí àwọn ipò rẹ̀ tí kò yanjú, ẹnití ó nretí láti rí ìwòsàn kí ó sì wà pẹ̀lú wọn lẹ́ẹ̀kansi.

Ní gbogbo ọ̀ràn, Olúwa rí àwọn olúkúlùkù wọ̀nyí fún ẹni tí wọ́n jẹ́ àti nípa bẹ́ẹ̀ ó ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Bí Néfì àti arákùnrin rẹ̀ Jacob ti kéde:

“Ó npè gbogbo wọn láti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ … , dúdú àti funfun, ìdè àti òmìnira, akọ àti abo; ó sì rántí àwọn abọ̀rìṣà; gbogbo wọn sì dàbí ọ̀kan sí Ọlọ́run.”3

“Àti pé ẹ̀dá kan níye lórí ní ojú rẹ̀ gẹ́gẹ́bí èkejì.”4

Njẹ́ kí àwa bákannáà maṣe jẹ́ kí ojú wa, etí wa, tàbí ẹ̀rù wa ṣì wá lọ́nà ṣùgbọ́n ṣí ọkàn àti inú wa kí a sì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú inú kan sí àwọn tí ó wà ní àyíká wa bí Ó ti ṣe.

Àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, ìyàwó mi, Isabelle, gba yíyànsíṣẹ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ àìwọ́pọ̀ kan. Wọ́n ní kí ó bẹ àgbàlagbà opó kan wo ní wọ́ọ̀dù wa, arábìnrin kan tí ó ní àwọn ìpenijà ìlera àti tí dídánìkanwà rẹ̀ ti mú ìkorò wá sínú ayé rẹ. A fa àwọn kọ́tìnì rẹ̀; ìyẹ̀wù rẹ̀ nmóoru; kò fẹ́ gba ìbẹ̀wò ó sì mu hàn kedere pé “kò sí ohunkankan tí mo lè ṣe fún ẹnikẹ́ni.” Láìmikàn, Isabelle fèsì, “bẹ́ẹ̀ni, ó wà! O lè ṣe ohunkan fún wa nípa fífi àyè gbà wá láti wá kí a sì bẹ̀ ọ́ wò.” Àti pé nítorínáà Isabelle lọ, pẹ̀lú òtítọ́.

Nígbàkan lẹ́hìn náà, arábìnrin rere yí ṣe iṣẹ́-abẹ lórí ẹsẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó gba yíyípadà àwọn bándéjì rẹ̀ ní ojojúmọ́, ohunkan tí kò lè ṣe fúnrarẹ̀. Fún àwọn ọjọ́ díẹ̀, Isabelle lọ sí ilé rẹ̀, ó fọ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì nyí àwọn bándéjì rẹ padà. Òun kò rí àbùkù; kò sì mí ẹ̀ẹ́mí burúkú. Ó rí ọmọbìnrin Ọlọ́run rírẹwà kan nígbàgbogbo nínú ìnílò ìfẹ́ àti ìtọ́jú jẹ́jẹ́ nìkan.

Ní àwọn ọdún tó kọjá, èmi àti àìlónkà àwọn ẹlòmíràn ti di alábùkún fún nípasẹ̀ ẹ̀bùn isabelle láti rí bí Olúwa ti rí. Bóyá ẹ jẹ́ ààrẹ èèkan tàbí olùkíni wọ́ọ̀dù, bóyá ẹ jẹ́ ọba England tàbí ẹ̀ ngbé ní ilé igi kékeré, bóyá ẹ̀ nsọ̀ èdè rẹ̀ tàbí òmíràn tó yàtọ̀, bóyá ẹ̀ npa àwọn òfin mọ́ tàbí ẹ̀ ntiraka pẹ̀lú àwọn kan, òun ó fún yín ni oúnjẹ́ dídáràjùlọ nínú àwo rẹ̀ dídárajùlọ. Ipò ọrọ̀-ajé, àwọ̀ ara, ọ̀làjú àtilẹ̀wá, orílẹ̀-èdè, ipò òdodo, ìdúró àwùjọ, tàbí eyikeyi ìdánimọ̀ míràn tàbí àlẹ̀mọ́ kò já mọ́ nkankan sí i. Ó nrí pẹ̀lú ọkàn rẹ̀, ó sì nrí ọmọ Ọlọ́run lára gbogbo ènìyàn.

Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni:

“Ọ̀tá nyayọ̀ nínú àlẹ̀mọ́ nítorí wọ́n npín wa níyà wọ́n sì ndín ọ̀nà tí a fi nronú nípa arawa àti sí ara wa kù. Bí ó ti burú tó nígbàtí a ba bu ọlá fún àlẹ̀mọ́ ju bí a ṣe nbu ọlá fún ara wa.

“Àwọn àlẹ̀mọ́ lè darí sí dídájọ́ àti aáwọ̀. Ẹ̀yíkéyí ìlòkulò tàbí ẹ̀tanú síwájú ẹlòmíràn nítorí orílẹ̀ èdè, ẹ̀yà, ohun tí a mọ̀ nípa ìbálòpọ̀, lákọlábo, àwọn oyè ẹ̀kọ́, ọlàjú, tàbí àwọn ìfidánimọ̀ pàtàkì míràn jẹ́ ìwà ìbàjẹ́ sí Ẹlẹ́dã wa!”5

French kìí ṣe ẹni tí mo jẹ́; ìbẹ̀ ni a ti bí mi ni. Funfun kìí ṣe ẹni tí mo jẹ́; àwọ̀ ara mi ni, tàbí àìsí níbẹ̀. Kòfẹ́sọ̀ kìí ṣe ẹni tí mo jẹ́; ó jẹ́ ohun tí èmi nṣe láti ti ẹbí mi lẹ́hìn ni. Aláṣẹ Àádọ́rin Gbogbogbò kìí ṣe ẹni tí mo jẹ́; ibi tí mo ti nsìn nínú ìjoba ní àkokò yí ni.

“Àkọ́kọ́ àti ṣíṣíwájú,” bí Ààrẹ Nelson ti rán wa létí, èmì jẹ́ “ọmọ Ọlọ́run.”6 Bẹ́ẹ̀náà ni ẹ̀yin; bẹ́ẹ̀náà sì ni gbogbo ènìyàn míràn ní àyíká wa. Mo gbàdúrà pé kí a lè wá sí ìmoore púpọ̀jùlọ nípa òtítọ́ ìyanu yí. Ó nyí ohungbogbo padà!

A lè ti tọ́ wa ní oríṣiríṣi àwọn ọ̀làjú; a lè ti wá láti oríṣiríṣi àwọn ìpò ọrọ̀-ajé àwujọ; ogun ayé ikú wa, pẹ̀lú orílẹ̀-èdè wa, àwọ̀ ara, ààyò oúnjẹ́, ìkọ́ni òṣèlú, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, lè yàtọ̀ gidigidi. Ṣùgbọ́n a jẹ́ ọmọ Rẹ̀, gbogbo wa, láìsi yíyọkúrò. A ní irú ìbí àtọ̀runwá kannáà a sì ní irú agbára àìlópin kannáà nípa oore-ọ̀fẹ́ Jésù Krístì.

C.S. Lewis sọ ọ́ ní ọ̀nà yí: “Ó jẹ́ ohun tí ó ṣe kókó láti gbé nínú àwùjọ àwọn tí ó ṣeéṣé láti jẹ́ ọlọ́run àti ọlọ́runbìnrin, láti rántí pé ẹnìkan tí kò jáfáfá jùlọ tí ko sì wuni jùlọ láti bá sọ̀rọ̀ le fi ọjọ́ kan jẹ́ ẹ̀dá kan èyítí ó jẹ́ pé, bí o bá rí i nísisìyí, ìwọ ó ní àdánwò lílágbára láti jọ́sìn rẹ̀. … Kò sí ènìyàn lásán. Ẹ kò ì tíì sọ̀rọ̀ sí ẹni kíkú yẹpẹrẹ kan rí. Àwọn orílẹ-èdè, ọ̀làjú, iṣẹ́-ọnà, ọ̀làjú-ìgbàlódé—ìwọ̀nyí ni ẹni kíkú, àti pé ayé wọn sí tiwa jẹ́ ayé kátikàti. Ṣùgbọ́n àwọn ẹni àìkú ni à nba ṣeré, ṣiṣẹ́ pẹ̀lú, ṣe ìgbeyàwó, patì, tí a sì nyànjẹ.”7

Ẹbí wa ní ànfàní láti gbé ní oríṣiríṣi àwọn orílẹ̀-èdè àti ọ̀làjú; àwọn ọmọ wa ti di alábùkún fún láti gbéyàwó nínú àwọn ìran. Mo ti wá damọ̀ pé ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì ni olùbámu nlá. Bí a bá gbà á mọ́ra, “Ẹ̀mí fúnra rẹ̀ ó jẹ́ ẹ̀rí pẹ̀lú ẹ̀mí wa, pé a jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.”8 Òtítọ́ yíyanilẹ́nu yí nmú wa di òmìnira, àti pé gbogbo àlẹ̀mọ́ àti títayọ tí ìbá ti pa wá lára àti àwọn ìbáṣepọ̀ wa sí ara wa ni a ó “gbé mi nínú … Krístì.”9 Ó hàn kedere láìpẹ́ pé àwa, bákannáà bí àwọn ẹlòmíràn, “kìí ṣe àjèjì àti àtìpó, ṣùgbọ́n àjùmọ̀ jẹ́ olootọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn aráilé Ọlọ́run.”10

Láìpẹ́ mo gbọ́ tí ààrẹ ẹ̀ka kan lára ẹ̀ka èdè ọ̀pọ̀-ọ̀làjú tí ó tọ́ka sí èyí, bí Alàgbà Gerrit W. Gong ti ṣe, bí wíwà nínú májẹ̀mú.11 Èrò dídára kan ni èyí! A wà nínú ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn tí gbogbo wọn ngbìyànjú láti fi Olùgbàlà àti àwọn májẹ̀mú wọn sí gbùngbun ìgbé ayé wọn àti láti gbé ìgbé ayé ìhìnrere tayọ̀tayọ̀. Látìhín lọ, sànjú rírí arawa nínú lílọ́po àwọn jígí ayé ikú, ìhìnrere nmú ìwò wa ga ó sì nfi àyè gbà wá láti rí arawa nínú àwọn jígí àìlábàwọ́n, àìyípadà ti àwọn májẹ̀mú mímọ́ wa. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a nbẹ̀rẹ̀ láti mú ẹ̀tanú àdánidá ti ara wa àti ìtẹ́sí síwájú àwọn ẹlòmíràn kúrò, èyí nígbànáà nṣèrànwọ́ fún wọn láti dín àwọn ẹ̀tanú wọn àti ìtẹ́sí síwájú wa kù,12 nínú ìyípò ìwàrere oníyanu. Nítòótọ́, a tẹ̀lé ìpè wòlíì wa ọ̀wọ́n: “Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, bí a ti nṣe sí ara wa ṣe kókó lódodo! Bí a ṣe nsọ̀rọ̀ sí àti nípa àwọn ẹlòmíràn ní ilé, ní ilé ìjọsìn, ní ibi iṣẹ́, àti ní orí ayélujára ṣe kókó lódodo. Ní òní, mò nba wa sọ̀rọ̀ kí a ba àwọn elòmíràn ṣe ní ọ̀nà gíga si, mímọ́ si.”13

Ní ọ̀sán yí, nínú ẹ̀mí ìpè náà, mo fẹ́ láti fi ẹ̀jẹ́ mi kún ti àwọn ọmọ Alakọbẹrẹ oníyanu:

Bí ìwọ kò bá rìn bí àwọn ènìyàn púpọ̀ ti ṣe,

Àwọn ènìyàn kan a rìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ.

Ṣùgbọ́n èmì kò ní ṣe é! Èmì kò ní ṣe é!

Bí ìwọ kò bá sọ̀rọ̀ bí àwọn ènìyàn púpọ̀ ti ṣe,

Àwọn ènìyàn kan a sọ̀rọ̀ wọ́n a sì fi ọ́ rẹrin,

Ṣùgbọ́n èmì kò ní ṣe é! Èmì kò ní ṣe é!

Èmi ó rìn pẹ̀lú rẹ̀ Èmi ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀

Bayi ni èmi ó fi ìfẹ́ hàn fún ọ.

Jésù kò rìn kúrò lọ́dọ̀ ẹnìkankan.

Ó fi ìfẹ́ rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn.

Nítorínáà èmi ó ṣé! Èmi ó ṣe é!14

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Òun ẹnití a npè ní Baba wa ní Ọ̀run nítòótọ́ ni Baba wa, pé ó nifẹ́ wa, pé Òun mọ ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ tímọ́tímọ́, pé ó nṣìkẹ́ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan wa jinlẹ̀jinlẹ̀, àti pé gbogbo wà jẹ́ bákannáà sí I. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé ọ̀nà tí a fi nbá ara wa ṣe jẹ́ ìfihàn tààrà nípa lílóye ti àti ìmoore fún ìrúbọ ìgbẹ̀hìn àti ètùtù Ọmọ Rẹ̀, Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Mo gbàdúrà pé, bíi Tirẹ̀, a lè nifẹ àwọn ẹlòmíràn nítorí ìyẹn ni ohun tótọ́ láti ṣe, nítorí wọ́n nṣe ohun tótọ́ tàbí wà ní ìbámu sí àpẹrẹ-títẹ̀lé “tótọ́”. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.