Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Ẹ̀kọ́ ti Ọ̀run Fún Ṣíṣe Òbí
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


Àwọn Ẹ̀kọ́ ti Ọ̀run Fún Ṣíṣe Òbí

Àwọn òbí wọnú àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Baba wọn Ọ̀run láti tọ àwọn ọmọ wọn iyebíye padà sí ọ̀run.

Njẹ́ ẹ ti gbé ọmọ titun dá ní rí? Ìmọ́lẹ̀ kan wà tó njáde wá láti ọ̀dọ̀ gbogbo ọmọ titun, tó nmú ìdè ìfẹ́ àkànṣe kan wá tí ó lè fi ayọ̀ kún ọkàn àwọn òbí wọn.1 Olùkọ̀wé ará Mẹ́síkò kan kọ̀wé pé, “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé nígbà tí ọmọ titun kan bá kọ́kọ́ tẹ ìka baba rẹ̀ sí ìkúnkù kékeré rẹ̀, ó ti dìí mú títí láé.”2

Jíjẹ́ òbí ni ọ̀kan nínú àwọn ìrírí yíyanilẹ́nu jùlọ ní ìgbésí ayé. Àwọn òbí wọnú àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Baba wọn Ọ̀run láti tọ àwọn ọmọ wọn iyebíye padà sí ọ̀run.3 Ní òní èmi yìó fẹ́ láti pín díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ Jíjẹ́ òbí tí a rí nínú àwọn ìwé-mímọ́ àti ìkọ́ni àwọn wòlíì alãye láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti gbé ogún-ìní òbí wa.

Gòkè Sí Ilẹ̀ Gíga ti Aṣà Ìhìnrere

A gbọ́dọ̀ gòkè sí ilẹ̀ gíga ti àṣà ìhìnrere pẹ̀lú àwọn ẹbí wa. Ààrẹ Russell M. Nelson kéde: “Àwọn Ẹbí yẹ fún ìtọ́sọ́nà láti ọ̀run. Àwọn òbí kò lè gba àwọn ọmọ ní ìmọ̀ràn dáradára tó láti inú ìrírí ti araẹni, ìbẹ̀rù, tàbí àánú.”4

Bótilẹ̀jẹ́ pé àwọn àṣà àtilẹ̀bá, àwọn ọ̀nà ṣíṣe òbí, àti ìrírí araẹni lè níyì fún jíjẹ́ òbí, àwọn agbára wọ̀nyí kò tó láti ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti padà sí ọ̀run. A nílò àyè sí láti gbé “àkójọpọ̀ àwọn iyì àti … àwọn ìṣe, sókè síi,”5 àṣà ti ìfẹ́ àti àwọn ìrètí, níbití a ti nṣe àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wa “ní ọ̀nà gígajù àti mímọ́jù.”6 Ààrẹ Dallin H. ​​Oaks ṣàpèjúwe àṣà ìhìnrere bí “ọ̀nà ìgbésí ayé kan tó yàtọ̀, àkójọpọ̀ àwọn iyì àti àwọn ìfojúsọ́nà àti àwọn ìṣe. … Ộlàjú ìhìnrere yí wá láti inú ètò ìgbàlà, àwọn òfin Ọlọ́run, àti àwọn ìkọ́ni ti àwọn wòlíì alãye. Ó ntọ́ wa sọ́nà ní ọ̀nà tí a ngbà tọ́ àwọn ẹbí wa tí a sì ngbé ìgbésí ayé ẹnì olúkúlùkù wa.”7

Jésù Krístì ni gbùngbun àṣà ìhìnrere. Gbígba ọ̀làjú ìhìnrere nínú àwọn ẹbí wa ṣe pàtàkì sí ṣíṣẹ̀dà agbègbè ọlọ́ràá níbití irúgbìn ìgbàgbọ́ lè ti gbilẹ̀. Láti gòkè sí ilẹ̀ gíga, Ààrẹ Oaks pè wa “láti jáwọ́ nínú ìṣàkóso ti araẹni tàbí ti àwọn ìṣe ẹbí tí ó lòdì sí àwọn ẹ̀kọ́ ti Ìjọ Jésù Krístì.”8 Ẹ̀yin òbí, ẹ̀rù ní apá ọ̀dọ̀ wa láti fì ìdí àṣà ìhìnrere múlẹ̀ lè gba ọ̀tá láyè láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú ilé wa tàbí, pàápàá jùlọ, nínú ọkàn àwọn ọmọ wa.

Bí a ṣe nyàn láti sọ ọ̀làjú ìhìnrere di ọ̀làjú tí ó ga jùlọ nínú ẹbí wa, nígbànáà nípasẹ̀ ipa agbára Ẹ̀mí Mímọ́9 àwọn ọ̀nà ṣíṣe òbí, àwọn àṣà, àti àwọn ìṣe wa lọ́wọ́lọ́wọ́ yìó wa ní títọ́, ní ìbámu, ní ìtumọ̀, ati mímúdàgbà.

Mú kí Ilé jẹ́ Gbùngbùn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìhìnrere

Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé ilé gbọ́dọ̀ jẹ́ “ gbùngbùn ìkẹ́kọ̀ọ́ ìhìnrere.”10 Ìdí kíkẹ́kọ́ọ̀ ìhìnrere ni láti “mú ìyípadà wa jinlẹ̀ sí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì kí a sì rànwá lọ́wọ́ láti dàbí Wọn síi.”11 Ẹ jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ojúṣe mẹ́ta pàtàkì tí a ṣàpèjúwe wọn nípasẹ̀ àwọn wòlíì àti àpọ́sítélì tí ó lè rànwá lọ́wọ́ láti fi àṣà ìhìnrere kan múlẹ̀ nínú ilé wa.

Àkọ́kọ́: Kọ́ni Lọ́fẹ̀ẹ́

Baba Ọ̀run fún Ádámù ní ìtọ́ni nípa Jésù Krístì àti ẹ̀kọ́ Rẹ̀. Ó kọ́ ọ “láti fi àwọn ohun wọ̀nyí kọ́ àwọn ọmọ [rẹ̀] lọ́fẹ̀ẹ́.”12 Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, Baba Ọ̀run kọ Ádámù láti kọ́ni ní àwọn nkan wọ̀nyí ní ọ̀fẹ́, pẹ̀lú oore, àti láìsí ìdádúró.13 Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé “Ádámù àti Éfà fi ìbùkún fún orúkọ Ọlọ́run, wọ́n sì sọ ohun gbogbo di mímọ̀ fún àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn.”14

A máa nkọ́ àwọn ọmọ wa pẹ̀lu lílawọ́ nígbàtí a bá lo àkókò tó nítumọ̀ pẹ̀lú wọn. À nkọ́ni láìsí ìdádúró nígbàtí a bá njíròrò àwọn kókó ọ̀rọ̀ àkànṣe bíi “àkókò àwo,” ní lílo àwọn ohun èlò tí Ìjọ ti fi sí àrọ́wọ́tó.15 À nkọ́ni lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbàtí a bá ka àwọn ìwé-mímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ wa nípa lílo Wá, Tẹ̀lé Mi tí a sì gba Ẹ̀mí láàyè láti jẹ́ olùkọ́.

Èkejì: Àwòkọ́ṣe Jíjẹ́-ọmọlẹ̀hìn

Nínú ìwé Jòhánnù, a kà pé nígbàtí ọ̀pọ̀ àwọn Júù béèrè lọ́wọ́ Olùgbàlà nípa ìwà Rẹ̀, Jésù darí àfiyèsí sí àwòkọ́ṣe Rẹ̀, Baba Rẹ̀. Ó kọ́ni pé, “Ọmọ kò lè ṣe nkankan fúnrarẹ̀, bí kò ṣe ohun tí ó rí tí Baba nṣe: nítorí ohunkóhun tí ó bá nṣe, ìwọ̀nyí pẹ̀lú ni Ọmọ nṣe.”16 Ẹ̀yin òbí, kíni a nílò láti ṣe àwòkọ́ṣe fún àwọn ọmọ wa? Jíjẹ́-ọmọlẹ́hìn.

Bí òbí, a lè kọ́ni nípa pàtàkì fífi Ọlọ́run sí àkọ́kọ́ nígbàtí a bá njíròrò òfin àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n kí a jẹ́ àwòkọ́ṣe rẹ̀ nígbà tí a bá npa àwọn ìdíwọ́ ayé ti sí ẹ̀gbẹ́ kan, tí a sì npa ọjọ́ Sábóàtì mọ́ ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. A lè kọ́ni ní pàtàkì àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì nígbàtí a bá sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ti ìgbéyàwó sẹ̀lẹ́stíà, ṣùgbọ́n kí a jẹ́ àwòkọ́ṣe rẹ̀ nígbàtí a bá bu ọlá fún àwọn májẹ̀mú wa, ní títọ́jú lọ́kọ-láya wa pẹ̀lú ọlá.

Ìkẹ́ta: Ìpè láti ṣe Ìṣe

Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì gbọ́dọ̀ jẹ́ kókó ẹ̀rí àwọn ọmọ wa, àwọn ẹ̀rí wọ̀nyí sì gbọ́dọ̀ dé bá ọmọ kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ìfihàn olúkúlùkù.17 Láti ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ pẹ̀lú mímú àwọn ẹ̀rí wọn dàgbà, a gbà wọ́n níyànjú láti lo agbára wọn láti yan ohun tí ó tọ́18 kí á sì múra wọn sílẹ̀ fún ìgbà ayé wọn ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú Ọlọ́run.19

Yíò mọ́gbọ́n wá láti gba ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọwa láti tẹ́wọ́gba ìpè Ààrẹ Nelson láti bójútó ẹ̀rí tiwọn nípa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀—láti ṣiṣẹ́ fun, láti tọ́ ọ kí ó lè dàgbà, láti fi òtítọ́ bọ́ ọ, àti láti má ṣe sọ ọ́ di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn ìmọ̀ èké àìgbàgbọ́ ti àwọn ọkùnrin àti obìnrin.20

Jíjẹ́ Òbí Ìmọ̀ọ́mọ̀-ṣe, Òdodo

Àwọn èrò inú àtọ̀runwá ti Baba wa Ọ̀run bíi òbí kan ni a sọ di mímọ̀ nínú ìfihàn tí a fifún Mósè: “Nítorí kíyèsĩ, èyí ni iṣẹ́ mi àti ògo mi—láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ènìyàn ṣẹ.”21 Ààrẹ Nelson ti fi kún un pé, “Ọlọ́run yíò ṣe ohun gbogbo tí Ó bá lè ṣe, láì tako agbára láti yàn yín, láti ràn yín lọ́wọ́ láti má ṣe pàdánù àwọn ìbùkún títóbi jùlọ ní gbogbo ayérayé.”22

Bí òbí, a jẹ́ aṣojú Ọlọ́run nínú ìtọ́jú àwon ọmọ wa.23 A gbọ̀dọ́ ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti ṣẹ̀dá àyíká níbití àwọn ọmọ wa ti lè ní ìmọ̀lára ipa àtọ̀runwá Rẹ̀.

Baba Ọ̀run kò ní in lọ́kàn fún wa bí òbí láti jókòó sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà bí olùwòran, ní wíwo bí ìgbé ayé àwọn ọmọ wa ní ti ẹ̀mí ṣe nfarahàn. Ẹ jẹ́ kí nṣe àpèjúwe èrò ìmọ̀ọ́mọ̀ ṣe òbí yí pẹ̀lú ìrírí araẹni kan. Nígbàtí mo nlọ sí Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní ẹ̀ka kékeré kan ní Guatemala, àwọn òbí mi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ nípa iyì ìbùkún àwọn baba-nlá. Ìyá mi lo àkókò láti ṣe àbápín ìrírí tirẹ̀ nípa gbígba ìbùkún àgbàyanu ti baba-nlá rẹ̀. Ó kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ tí ó bá àwọn ìbùkún baba-nlá mu, ó sì jẹ́ ẹ̀rí àwọn ìbùkún tí a ṣèlérí. Ìmọ̀ọ́mọ̀ ṣe òbí rẹ̀ ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìfẹ́ láti gba ìbùkún baba-nlá mi.

Nígbàtí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá, àwọn òbí mi ràn mí lọ́wọ́ láti lọ wá baba-nlá kan. Èyí ṣe pàtàkì nítorí pé kò sí baba-nlá ní àgbègbè tí a ngbé. Mo rìnrìn àjò lọ sí ọ̀dọ̀ baba-nlá kan tó wà ní èèkàn tó jìnnà tó kìlómítà 156 (máìlì 97) sí wa. Mo rántí dáadáa nígbà tí baba-nlá náà gbé ọwọ́ lé orí mi láti súre fún mi. Mo mọ̀ nípasẹ̀ ìfẹsẹ̀múlẹ̀ tó lágbára ti ẹ̀mí, láìsí iyèméjì, pé Baba mi Ọ̀run mọ̀ mí.

Fún ọmọ ọdún méjìlá láti ìlú kékeré kan, èyí túmọ̀ sí ohun gbogbo fún mi. Ọkàn mi yípadà sí Baba mi Ọ̀run lọ́jọ́ náà nítorí ìmọ̀ọ́mọ̀ ṣe òbí ti ìyá àti bàbá mi, èmi yíò sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn títíláé.

Arábìnrin Joy D. Jones, Ààrẹ Gbogbogbò Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, kọ́ni pé: “A kò lè dúró kí ìyípadà máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ wa lásán. Ìyípadà ọkàn àìròtẹ́lẹ̀ kìí ṣe ẹ̀kọ́ ìpilẹ̀ ìhìnrere ti Jésú Krìstì.”24 Ìfẹ́ wa àti àwọn ìpè onímìísí lè ṣe ìyàtọ̀ nínú bí àwọn ọmọ wa ṣe nlo agbára láti yàn wọn. Ààrẹ Nelson tẹnu mọ́ ọn pé, “Kò sí iṣẹ́ míràn tí ó kọjá òdodo, ìmọ̀ọ́mọ̀ ṣe òbí!”25

Ìparí

Ẹ̀yin òbí, ayé yìí kún fún àwọn ìmọ̀ ènìyàn, àwọn àṣà, àti àwọn èrò tó ndíje fún àkíyèsí àwọn ọmọ wa. Ilé nlá àti àyè títóbi npolówó ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ lójoójúmọ́ ní lílo àwọn ìkànnì ìròhìn lọ́wọ́lọ́wọ́ jùlọ. “Ṣùgbọ́n nínú ẹ̀bùn ti Ọmọ rẹ̀,” wòlíì Mórónì kọ́ni, “ni Ọlọ́run ti pèsè ọ̀nà dídára jùlọ kan.”26

Bí a ṣe nṣe àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú tí a sì di aṣojú Rẹ̀ nínú ìtọ́jú àwọn ọmọ wa, Òun yíò ya àwọn èrò inú wa sí mímọ́, yío mísí àwọn ìkọ́ni wa, yío sì mú àwọn ìpè wa yẹ kí “àwọn ọmọ wa lè mọ orísun wo ni wọ́n lè wò fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”27 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Wo Psálmù 127:3.

  2. Johnny Welch, “Pọ́pẹ́tì Náà,” ti a tun ṣe ni inspire21.com/thepuppet; see also Johnny Welch, Lo que me ha enseñado la vida (1996).

  3. Èyí lè dàbí iṣẹ́ tí ó léwu, ṣùgbọ́n bí Alàgbà Jeffrey R. Holland ti wí, “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Baba Ọ̀run kan a lè fi ogún-ìní òbí sílẹ̀ díẹ̀ síi ju bí a ti rò lọ” ” (“Ọw´ Àwọn Baba,” Liahona, July 1999, 18).

  4. Russell M. Nelson, “Ìwọ Kò Gbọdọ̀ Ní Àwọn Ọlọ́run Míràn,” Ẹ́nsáìn, Oṣù karun 1996, 15.

  5. Dallin H. Oaks, “Ọ̀làjú Ìhìnrere Náà,” Ẹ́nsáìn, Oṣù Kẹ́ta 2012, 42.

  6. Russell M. Nelson, “A Nílò Àwọn Onílàjà,” Làìhónà, Oṣù karun 2023, 99.

  7. Dallin H. Oaks, “Ọ̀làjú Ìhìnrere Náà,” 22.

  8. Dallin H. Oaks, “Ọ̀làjú Ìhìnrere Náà,” 22.

  9. Wo Mórónì 10:5.

  10. Russell M. Nelson, “Dída àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn Alápẹrẹ,” Liahona, Nov. 2018, 113.

  11. Ìyípadà Jẹ́ Ibi-afẹ́dé Wa,” ní Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún olúkúlùkù àwọn ẹbí: Májẹ̀mú Titun 2023, v.

  12. Mósè 6:58.

  13. Wo American Dictionary of the English Language, “lọfẹ,” webstersdictionary1828.com/Dictionary/freely.

  14. Mósè 5:12.

  15. Gbígba agbára ìmọ̀-ẹ̀rọ” àti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́: Ìtọ́nisọ́nà kan fún Ṣíṣe àwọn Àṣàyàn (2022), Ibi-ìkàwé ìhìnrere.

  16. Jòhánnù 5:19.

  17. Wo “Máttéù 16:17–18 A nílò Ìfihàn Olúkúlùkù fún Ẹ̀rí Jésù Krístì,”ní Ìwé Akẹ́kọ̀ọ́ Májẹ̀mú Titun (2018), 52.

  18. Wo Dale G. Renlund, “Yàn ní Òní,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2018, 104: “Ibiafẹ́dé Baba wa Ọ̀run nínú ọmọ títọ́ kìí ṣe kí àwọn ọmọ Rẹ̀ ṣe ohun tí ó tọ́; ó jẹ́ láti jẹ́ kí àwọn ọmọ Rẹ̀ yàn láti ṣe ohun tí ó tọ́ kí wọn sì dàbí Rẹ̀ níkẹhìn.”

  19. Wo “Gbígbaradì fún Àwọn Ọmọ Yín Fún Ìgbé Ayé ní Ipa Ọnà Májẹ̀mú ti Ọlọ́run,” Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ẹnikọ̀ọ̀kan àti Àwọn Ẹbí: Májẹ̀mú Titun 2023, Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

  20. Wo Russell M. Nelson, “Ẹ Ṣẹ́gun Ayé kí ẹ sì Rí Ìsinmi,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2022, 97.

  21. Mósè1:39. Nínú ẹsẹ yìí, Jésù Kristi nsọ̀rọ̀ fún Bàbá Ọ̀run.

  22. Russell M. Nelson, “Àwọn Yíyàn Fún Ayérayé” (worldwide devotional for young adults), Oṣù karun Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

  23. Russell M. Nelson, “Ìgbàlà àti Ìgbéga,” Làìhónà, Oṣù Kárún 2008, 10: “Máṣe gbìyànjú láti ṣàkóso àwọn ọmọ yín. Dípò bẹ́ẹ̀, tẹ́tí sí wọn, rànwọ́n lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ìhìnrere, ẹ mísí wọn, kí ẹ sì darí wọn sí ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ̀yin ni àwọn aṣojú Ọlọ́run ní bíbojútó àwọn ọmọ tí Ó ti fi lé yín lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí ipa àtọ̀runwá Rẹ̀ wà nínú ọkàn yín bí ẹ ṣe nkọ́ni tí ẹ sì nyí padà.”

  24. Joy D. Jones, “Àwọn Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì,” Làìhónà, Oṣù Karun 2022, 12.

  25. Russell M. Nelson, “Ọjọ́ Ìsinmi Jẹ́ Ayọ̀,” Làìhónà, Oṣù Karun 2016, 131.

  26. Etérì 12:11.

  27. 2 Néfì 25:26.