Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Agbára Èdidì
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


Agbára Ìfi Èdidì Dì

Agbára ìfi èdidì dì nmú ìgbàlà olúkúlùkù àti ìgbéga ẹbí jẹ́ káríayé sí àwọn ọmọ Ọlọ́run.

A ti sọtẹ́lẹ̀ ó kéréjù láti ìgbà àwọn ọjọ́ Isaiah1 pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, àwọn ènìyàn májẹ̀mú àtijọ́ Olúwa, ilé Israel, ní a níláti “kojọ látinú ìfọ́nká pípẹ́ wọn, láti àwọn erékùṣù okun, àti láti apá mẹ́rin orí ilẹ̀ ayé”2 kí a sì mú wọn padàbọ̀sípò sí “àwọn ilẹ̀ ìní wọn.”3 Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ̀rọ̀ léraléra àti pẹ̀lú agbára nípa kíkójọ yí, ó pèé ní “ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ tí ó nṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní òní.”4

Kíní èrèdí kíkójọ yí?

Nípa ìfihàn sí Wòlíì Joseph Smith, Olúwa fi èrèdí kàn hàn bí ààbò àwọn ènìyàn májẹ̀mú. Ó wípé, “Kíkójọ pọ̀ lórí ilẹ̀ Síónì, àti lórí àwọn èèkàn rẹ̀ [ndi] ààbò kan, àti fún ààbò kúrò nínú ìjì, àti kúrò nínú ìbínú nígbàtí a ó bá dàá jáde láìní ìwọ̀n sórí gbogbo ayé.”5 “Ìbínú” nínú ọ̀rọ̀ yí ni a lè ní òye rẹ̀ bí àbájáde àdánidá ti ìtànká àìgbọ́ran sí àwọn àṣẹ àti òfin Ọlọ́run.

Ní pàtàkì jùlọ, kíkójọ wà fún èrèdí mímú àwọn ìbùkún ìgbàlà àti ìgbéga wá fún gbogbo àwọn ẹni tí yíò gbà wọ́n. Ó jẹ́ bí àwọn ìlérí májẹ̀mú tí a fún Ábráhámù ti di múmúṣẹ. Olúwa wí fún Ábráhámù pé nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ̀ àti oyè-àlùfáà “gbogbo àwọn ẹbí ti ilẹ̀ ayé [yío] di alábùkún fún, àní pẹ̀lú àwọn ìbùkún Ìhìnrere, èyí tí ó jẹ́ àwọn ìbùkún ìgbàlà, àní ti ìyè ayérayé.”6 Ààrẹ Nelson fihàn ní ọ̀nà yí: “Nígbàtí a bá tẹ́wọ́gba ìhìnrere tí a sì ṣe ìrìbọmi, à ngbé orúkọ mímọ́ Jésù Krístì lé orí ara wa. Ìrìbọmi ni ẹnu ọ̀nà tí ó darí sí dídi ajùmọ̀-jogún sí gbogbo àwọn ìlérí tí a fúnni ní àtijọ́ láti ọwọ́ Olúwa sí Ábráhámù, Isaac, Jákọ́bù, àti àtẹ̀lé wọn.”7

Ní 1836, Mósè farahàn sí Wòlíì Joseph Smith ní Tẹ́mpìlì Kirtland ó sì ṣe “ìfifúnni … àwọn kọ́kọ́rọ́ kíkójọ Israel láti apá mẹ́rin ilẹ̀ ayé.”8 Ní ìgbà ọ̀ràn kannáà, Elíásì fi ara hàn “ó sì fi ìgbà ìríjú ìhìnrere ti Abráhámù fúnni, ní wíwí pé nínù wa àti irú ọmọ wa ní gbogbo ìran lẹ́hìn wa yíò di alábùkún.”9 Pẹ̀lú àṣẹ yí, nísisìyí a gbé ìhìnrere Jésù Krístì—ìròhìn rere ti ìràpàdà nípasẹ̀ Rẹ̀—wá sí gbogbo apá àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé kí a sì kó gbogbo ẹni tí ò bá fẹ́ jọ sínú májẹ̀mú ìhìnrere. Wọ́n di “irú ọmọ Abraham, àti ìjọ àti ìjọba, àti ẹni yíyàn Ọlọ́run.”10

Nígbà ọ̀ràn kannáà nínú Tẹ́mpìlì Kirtland, ìránṣẹ́ kẹ́ta tọ̀run wà tí ó farahàn sí Joseph Smith àti Oliver Cowdery. Mo sọ̀rọ̀ nípa wòlíì Elijah, ó sì jẹ́ ti àṣẹ àti kọ́kọ́rọ́ tí ó múpadàbọ̀sípò ni mo fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní òní.11 Agbára tí ó fi àṣẹ sí gbogbo àwọn ìlànà oyè-àlùfáà tí ó sì mú wọn di sísopọ̀ lórí ilẹ̀ ayé àti ní ọ̀run—agbára fífi èdidì dì—ṣe pàtàkì fún kíkójọ àti mímúrasílẹ̀ àwọn ènìyàn májẹ̀mú ní ẹ̀gbẹ́ méjèjì ìkelè.

Ní àwọn ọdún tó ṣíwájú, Moroni ti mu hàn kedere sí Joseph Smith pé Elijah yíò mú kókó àṣẹ oyè-àlùfáà wá: “Èmi ó fì Oyè-àlùfáà hàn sí yín, láti ọwọ́ Elijah wòlíì.”12 Joseph Smith ṣe àlàyé lẹ́hìnnáà: “Kínìdí tí a fi rán Elijah? Nítorí ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ àṣẹ láti ṣe ìpínfúnni nínú gbogbo àwọn ìlànà Oyè-àlùfáà; àti pé [àyàfi] tí a bá fúnni ní àṣẹ, àwọn ìlànà ni a kò lè pínfúnni nínú òdodo”13—ìyẹn ni pé, àwọn ìlànà náà yíò ní àṣẹ ní ayé àti àìlópin.14

Nínú ìkọ́ni tí a sọ̀ dì ìwé mímọ́ nísisìyí nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, Wòlíì wípé: “ó lè dàbí ẹ̀kọ́ híhàn gidi tí à nsọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwọn kan nípa—agbára èyí tí ó nkọsílẹ̀ tàbí tí ó nsopọ̀ lórí ilẹ̀-ayé tí ó sì nsopọ̀ ní ọ̀run. Bíòtilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, ní gbogbo àwọn ọjọ́ ayé, nígbàkugbà tí Olúwa bá ti fúnni ní ìgbà ìríjú oyè-àlùfáà kan sí ẹnikẹ́ni nípa ìfihàn tòótọ́, tàbí ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ ti àwọn ènìyàn, ni a ti fúnni ní agbára yí nígbàgbogbo. Nítorínáà, ohunkóhun tí àwọn ọkùnrin wọnnì bá ṣe nínú àṣẹ, ní orúkọ Olúwa, tí wọ́n sì pa àkọsílẹ̀ tótọ́ àti òtítọ́ ti ọ̀kannáà mọ́, ti di àṣẹ ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ọ̀run, a kò sì lè paá rẹ́, gẹ́gẹ́bí àwọn òfin Jehofa nlá.”15

À nní ìtẹ́sí láti ronú nípa àṣẹ ìfi èdidì dì bí ó ti wúlò sí àwọn ìlànà tẹ́mpìlì kan pàtó, ṣùgbọ́n àṣẹ náà ṣe kókó sí mímú kí ìlànà eyikeyi ní àṣẹ àti sísopọ̀ kọjá ikú.16 Agbára ìfi èdidì dì nfi ìdì olófin lé orí ìrìbọmi yín, fún àpẹrẹ, kí ó lè dì dídámọ̀ nihin àti ní ọ̀run. Nígbẹ̀hìn, gbogbo àwọn ìlànà oyè-àlùfáà ni à nṣe lábẹ́ àwọn kọ́kọ́rọ́ ti Ààrẹ Ìjọ, àti bí Ààrẹ Joseph Fielding Smith ti ṣàlàyé pé, “Òun [Ààrẹ Ìjọ] ti fúnni ní àṣẹ, ó ti fi àṣẹ fún wa, ó ti fi agbára ìfi èdidì dì sínú oyè-àlùfáà, nítorí òun ni ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ wọnnì mú.”17

Kókó èrèdí míràn wà nínú kíkójọ Israel tí ó ní ìtumọ̀ pàtàkì nígbàtí a bá nsọ̀rọ̀ nípa ìfi èdidì dì ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ọ̀run—tí ó jẹ́ kíkọ́ àti ṣíṣe àwọn tẹ́mpìlì. Bí Wòlíì Joseph Smith ti ṣàlàyé: “Kíni àkórí ìkórajọ … àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ọjọ́ orí eyikeyi ní ayé? … Kókó àkọ́rí ni láti kọ́ ilé kan fún Olúwa níbití Òun ti lè fi àwọn ìlànà ilé Rẹ̀ àti ògo ìjọba Rẹ̀ hàn sí àwọn ènìyàn Rẹ̀, kí ó sì kọ́ àwọn ènìyàn ní ọ̀nà ìgbàlà; nítorí àwọn ìlànà àti ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kan pàtó wà, nígbàtí a bá kọ́ wọn tí a sì ṣeé, a gbọ́dọ̀ ṣeé ní ibi tàbí ilé tí a kọ́ fún èrèdí náà.”18

Àṣẹ tí agbára ìfi èdidì dì nfi fún àwọn ìlànà oyè-àlùfáà pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ni, ìrọ́pò àwọn ìlànà tí a ṣe ní ibi tí a yàn nípasẹ̀ Olúwa ní—tẹ́mpìlì Rẹ̀. Nihin a rí ọlánlá àti wíwà ní mímọ́ ti agbára ìfi èdidì dì—ó mu kí ìgbàlà olúkúlùkù àti ìgbéga ẹbí wà káríayé sí àwọn ọmọ Ọlọ́run níbikíbi àti níbigbogbo tí wọ́n ti lè gbé ní orí ilẹ̀ ayé. Kò sí ẹ̀kọ́ ìhìnrere míràn tàbí ẹ̀kọ́ ènìyàn tàbí àṣẹ tí ó lè dọ́gba irú gbogbo ànfàní tí ó ní nínú. Agbára ìfi èdidì dì yí ni ìfihàn pípé ti ìdáláre, àánú, àti ìfẹ́ Ọlọ́run.

Pẹ̀lú ààyè sí agbára ìfi èdidì dì, ọkàn wa ní àdánidá nyípadà sí àwọn wọnnì tí wọ́n ti lọ̀ ṣíwájú. Kíkójọ ọjọ́-ìkẹhìn sínú májẹ̀mú wà káàkiri ìkelè. Nínú èrò pípé Ọlọ́run, alààyè kò lè ní ìrírí ìyè ayérayé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀ láìsí títẹ̀síwájú àwọn ìsopọ̀ pípẹ́ sí “àwọn baba,” àwọn babanla wa. Bákannáà, ìlọsíwájú àwọn ẹni tí wọ́n ti wà ní ẹ̀gbẹ́ míràn tẹ́lẹ̀, tàbí ẹni tí ó lè sọdá síbẹ̀síbẹ̀ nínú ìkelè ikú láìsí èrè àwọn ìfi èdidì dì, kò pé títí tí a ó fi ṣe àwọn ìlànà ìrọ́pò tí ó so wọ́n pọ̀ sí wa, àwọn àtẹ̀lé wọn, àti àwa sí wọn nínú èrò tọ̀run.19 Ìfarasìn láti ti ara wọn lẹ́hìn nínú ìkelè ni a lè kà sí ìlérí májẹ̀mú kan, ara májẹ̀mú titun àti ayérayé. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ Joseph Smith, a fẹ́ láti “ṣe ìfi èdidì di àwọn òkú wa láti wá síwájú [pẹ̀lú wa] nínú àjìnde àkọ́kọ́.”20

Ìfihàn gíga jùlọ àti mímọ́ jùlọ ti agbára ìfi èdidì dì wà nínú ìdàpọ̀ ayérayé ti ọkùnrin àti obìnrin kan nínú ìgbeyàwó àti sísopọ̀ ẹlẹ́ran-ara nínú gbogbo àwọn ìran wọn. Nítorí àṣẹ láti ṣiṣẹ́ nínú àwọn ìlànà wọ̀nyí jẹ́ mímọ́ gidi, Ààrẹ Ìjọ níti ararẹ̀ nbojùtó yíyàn rẹ̀ sí àwọn ẹlòmíràn. Ààrẹ Gordon B. Hinckley ti sọ nígbà ọ̀ràn kan pé, “Mo ti sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà pé tí ohun kankan míràn kò bá jáde látinú gbogbo ìkorò àti ìjìyà àti ìrora ti ìmúpadàbọ̀ sípò ju agbára ìfi èdidi dì ti oyè àlùfáà mímọ́ láti so àwọn ẹbí papọ̀ títí láé, ìbá ti yẹ fún gbogbo ohun tí ó gbà.”21

Láìsí àwọn ìfi èdidì dì tí ó dá ẹbí ayérayé sílẹ̀ àti ìsopọ̀ àwọn ìràn nihin àti lẹ́hìnwá, a ó di fífisílẹ̀ nínú àìlópin pẹ̀lú bóyá gbòngbò tàbí ẹ̀ká—bẹ́ẹ̀ni, bóyá ti babanla tàbí ìran. Fífòká-ọ̀fẹ́ yí ni ó jẹ́, ipò àìní-ìsopọ̀ àwọn olúkúlùkù, ní ọ̀nà kan, tàbí àwọn ìsopọ̀ tí ó sẹ́ ìgbeyàwó àti àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbi tí Ọlọ́run ti yàn,22 ní ọ̀nà míràn, tí yíò já èrèdí ìṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé kulẹ̀. Tí èyí bá di ìṣe, yíò di ìnira sí jíjẹ́ lílu ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ẹ̀gún tàbí “ṣíṣòfò pátápátá” ní bíbọ̀ Olúwa.23

A lè rí ìdí tí “ìgbeyàwó ní àárín ọkùnrin àtì obìnrin kan fi jẹ́ yíyàn nípasẹ̀ Ọlọ́run pé ẹbí jẹ́ gbúngbun sí ètò Ìṣẹ̀dá fún àyànmọ́ ìpín ayérayé ti àwọn ọmọ Rẹ̀.”24 Ní àkokò kannáà, a damọ̀ pé nínú àìpé ìsisìyí, èyí kìí ṣe òdodo tàbí àní dídájú ìṣeéṣe fún àwọn kan. Ṣùgbọ́n a ní ìrètí nínu Krístì. Nígbàtí a bá dúró dé Olúwa, Ààrẹ M. Russell Ballard rán wa létí pé “àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn wòlíì ọjọ́-ìkẹhìn yíò fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pé gbogbo ènìyàn tí wọ́n bá jẹ́ olotitọ ní pípa àwọn májẹ̀mú ìhìnrere mọ́ yíò ní ànfàní fún ìgbéga.”25

Àwọn kan ti ní ìrírí àìní ìdùnnú àti àìlera àwọn ipò ẹbí tí wọ́n sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ díẹ̀ fún ìbáṣepọ̀ ẹbí ayérayé. Alàgba David A. Bednar ṣe àkíyèsí yí: “Sí ẹ̀yin tí ẹ ti ní ìrírí ìrora ọkàn ti ìkọ̀sílẹ̀ nínú ẹbí yín tàbí ní ìmọ̀lára ìrora rírú ìfọkàntán, ẹ jọ̀wọ́ ẹ rántí [pé àwòṣe Ọlọ́run fún àwọn ẹbí] bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú yín lẹ́ẹ̀kansi! Ìsopọ̀ kan nínú okùn àwọn ìran yín lè ti di jíjá, ṣùgbọ́n àwọn ìsopọ̀ òdodo míràn àti àwọn ohun tí ó kù nípa okùn náà bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀ jẹ́ pàtàkì ti ayérayé. Ẹ lè fi okun kún ìsopọ̀ yín àti pé àní bóyá ìrànlọ́wọ́ láti mú àwọn ìsopọ̀ jíjá padàbọ̀sípò. Iṣẹ́ náà yíò di ṣíṣe yọrí ní ọ̀kan sí ọ̀kan.”26

Ní ibi ìsìn ìsìnkú fún Arábìnrin Pat Holland, ìyàwó Alàgbà Jeffrey R. Holland, ní Oṣù Kéje tó kojá, Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé: “Ní àkokò, Patricia àti Jeffrey yíò tún darapọ̀. Wọn yíò darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ wọn àti àtẹ̀lé olùpamọ́-májẹ̀mú wọn láti ní ìrírí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ tí Ọlọ́run ti fi sí ìṣura fún olódodo àwọn ọmọ Rẹ. Mímọ̀ pé, a ní òye pé ọjọ́ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ní ìgbé ayé Patricia kìí ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀ tàbí ọjọ́ ikú rẹ̀. Ọjọ́ rẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni ọjọ́ kéje, 1963, nígbàtí a ṣe ìfi èdidì di òun àti Jeff ní Tẹ́mpìlì St. George. … Kínídí ti èyí fi ṣe pàtàkì gidi? Nítorí èrèdí náà gan tí a fi dá ilẹ̀ ayé ni kí a lè dá àwọn ẹbí kí a sì lè ṣe ìfi èdidì dì wọn sí ara wọn. Ìgbàlà jẹ́ ọ̀ràn ẹnìkọ̀ọ̀kan, ìgbéga jẹ́ ọ̀rán ẹbí. Kò sí ẹni tí a lè dá gbéga.”

Kò pẹ́ púpọ̀, tí ìyàwó mi àti èmi darapọ̀ mọ́ ọ̀rẹ́ olólùfẹ́ kan nínú yàrá ìfi èdidì dì ti Tẹ́mpìlì Bountiful Utah. Mo kọ́kọ́ pàdé ọ̀rẹ́ yí nígbàtí ó wà ní ọmọdé ní Córdoba, Argentina. Ojúgbà òjíṣẹ́ ìhìnrere mi àti èmi nkànsí àwọn ènìyàn ní àdúgbò kan tí kò jìnà sí ilé-iṣẹ́ míṣọ̀n, ó sì dáhùn níbi ilẹ̀kùn nígbàtí a wá sí ilé rẹ̀. Ní àkokò, òun àti ìyá àti àwọn arákùnrin/arábìnrin rẹ̀ darapọ̀ mọ́ Ìjọ, wọ́n sì ti dúró títí bí olotitọ ọmọ ìjọ. Ó jẹ́ olùfẹ́ni obìnrin kan nísisìyí, àti pé ní ọjọ́ yí a wà nínú tẹ́mpìlì láti ṣe ìfi èdidì dì sí àwọn òbí rẹ̀ olóògbé sí ara wọn àti nígbànáà láti ṣe ìfi èdidì dì rẹ̀ sí wọn.

Tọkọtaya kan tí wọ́n ti di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ní àwọn ọdún pípẹ́ ṣe aṣojú àwọn òbí rẹ̀ níbi pẹpẹ. Ó jẹ́ àkokò ẹ̀dùn ọkàn tí ó di àdùn àní nígbàtí a ṣe ìfi èdidì dì ọ̀rẹ́ wa Argentine sí àwọn òbí rẹ̀. Àwa mẹ́fà pére ni ó wà ní ọ̀sán jẹ́jẹ́ kan kúrò nínú ayé, àti pé síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀kan nípa àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí ó ti ṣẹlẹ̀ rí lórí ilẹ̀ ayé ṣẹ̀ nṣẹlẹ̀. Mo ní inú dídùn pé ojúṣe àti ìbáṣepọ̀ mi ti dé ìyípo kíkún látinú kíkàn ilẹ̀kùn rẹ̀ bí ọ̀dọ́ òjíṣẹ́ ìhìnrere di ìsisìyí, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́hìnnáà, ní ṣíṣe àwọn ìlànà ìfi èdidì dì tí ó soó pọ̀ mọ́ àwọn òbí rẹ̀ àti àwọn ìràn tó kojá.

Èyí ni ìran kan tí ó nṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ ní gbogbo ayé nínú àwọn tẹ́mpìlì. Èyí ni ìgbésẹ̀ ìgbẹ̀hìn ní kíkójọ àwọn ènìyàn májẹ̀mú. Ó jẹ́ ànfàní gígajùlọ ti jíjẹ́ ọmọ ìjọ yín nínú Ìjọ Jésù Krístì. Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ti nwá ànfàní náà pẹ̀lú òtítọ́, ní àkokò tàbí àìlópin yíò jẹ́ tiyín dájúdájú.

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé agbára ìfi èdidì dì àti àṣẹ ìmúpadàbọ̀sípò sí ayé nípasẹ̀ Joseph Smith jẹ́ òdodo, pé ohun eyikeyi tí a bá sopọ̀ ní ilẹ̀ ayé lótítọ́ ni a sopọ̀ ní ọ̀run. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ààrẹ Russell M. Nelson, bí Ààrẹ Ìjọ, ni ọkùnrin kan ní ilẹ̀ ayé ní òní tí ó ndarí lílo agbàra títayọ yí nípa àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ̀. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ètùtù Jésù Krístì ti mú àìkú jẹ́ òtítọ́ àti ìṣeéṣe ti ìgbéga àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí jẹ́ òdodo. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.