Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Ìṣílétí Ẹ̀mí
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


Àwọn Ìṣílétí Ẹ̀mí

Alabarin ìgbàgbogbo ti Ẹ̀mí Mímọ́ ni ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn ti-ẹ̀mí tí ó tóbijùlọ tí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ngbádùn.

Ọ̀rọ̀-ìṣíwájú

Láìpẹ́ yi, ojú ìṣeré àgbáyé dojúkọ Eré Kọ́ọ̀pù Àwọn Obìnrin Àgbáyé 2023 tí Australia àti New Zealand ṣe agbẹ́tẹrù rẹ̀. Àwọn olùṣeré kílásì-àgbáyé nṣe aṣojú síi ju bí igba àwọn ẹgbẹ́ orílẹ̀-èdè láti àyíká àgbáyé ṣe njúwe ìgboyà, ìfọ̀kànsìn, ẹ̀bùn, àti ṣíṣeré wọn bí wọ́n ṣe ndíje fún iyì bọ́ọ̀lù gígajùlọ ní ayé.

A ní ìyàlẹnu nípa àwọn olùṣeré nínú onírurú àwọn òṣeré àti àwọn oníṣẹ́ míràn tí wọ́n ti ṣe àṣeyege ipele gígajùlọ nípa iṣẹ́-ọnà wọn. A nsọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀bùn tàbí ẹ̀bùn àbínibí tí Ọlọ́run-fúnni. Èyí pẹ̀lú àwọn wọnnì tí a fún ní ẹ̀bùn ijó, ìdárayá, orin, iṣẹ́-ọnà, eré-ìtàgé, ìṣirò, síyẹ́nsì, àti jíjù bẹ́ẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan bẹ́ẹ̀ njúwe àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run-fúnni tí à ntúnṣe tí a sì mú dára nípa iṣẹ́ àṣekára ìgbé-ayé, àṣàrò, àti ìgbáradì. Àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run-fúnni ndi àwọn ènìyàn tó lẹ́bùn.

Lílo Àwọn Ẹ̀bùn Ti-ẹ̀mí

Wíwò nínú àwọn jígí ìhìnrere, Ọlọ́run nfún àwọn ọmọ Rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbára ti-ẹ̀mí, tí ó nmú wọn di àwọn ènìyàn tó lẹ́bùn. Àwọn ọmọ Ìjọ Olùpamọ́-májẹ̀mú ni à nfún ní àwọn ẹ̀bùn ti Ẹmí, èyí tí ó pẹ̀lú ẹ̀bùn ti ẹ̀rí Jésù Krístì bí Olùgbàlà wa, ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí Mímọ́, ẹ̀bùn ti ìgbàgbọ́ láti wòsàn àti láti gba ìwòsàn, ẹ̀bùn ti mímọ ìyàtọ̀, ẹ̀bùn ti gbígbá àwọn ìyanu, àti àwọn ẹ̀bùn ọgbọ́n àti ìmọ̀.1 Olúwa npè wá láti fi taratara wá àwọn ẹ̀bùn dídárajùlọ, àní àwọn ẹ̀bùn ti-ẹ̀mí. Ó nfi àwọn ẹ̀bùn ti-ẹ̀mí fúnni láti bùkún wa àti láti lòó ní bíbùkún àwọn ẹlòmíràn.2

Ní pípadà sí àfiwé ti àwọn ẹlẹ́bùn olùṣeré, ó ṣe pàtàkì láti rántí pé ẹ̀bùn kan nìkan kò lè sọni di ọ̀gá kan. Ẹ̀bùn àbínibí títayọ bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, jẹ́ nípasẹ̀ ìṣé aápọn àti làálàá àti ìtiraka tí àwọn olùṣeré ntúnṣe àti dídára iṣẹ́-ọnà wọn làti dé ipò gígajùlọ ti ṣíṣé iṣẹ́-ọnà wọn. Àní àwọn ẹ̀bùn wọnnì tí a gbà tí a kò sì wé ni ó máa nbá èdè ìbẹ̀rùbojo wá nígbàkugbà “tí a bá nílò àwọn àpèjọ kan.”

Bákannáà, mo ṣe àkíyèsí kíkọ́ ohun títẹ̀ tí ó wà pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn ti-ẹ̀mí. Lílo àwọn ẹ̀bùn nílò ìlò ti ẹ̀mí “Níní ìtọ́nisọ́nà ti Ẹ̀mí Mímọ́ nínú ayé yín gba iṣẹ́ ti-ẹ̀mí. Iṣẹ́ yí pẹ̀lú àdúrà àti àṣàrò ìwé mímọ́ léraléra. Bákannáà ó pẹ̀lú pípa àwọn májẹ̀mú àti àwọn òfin Ọlọ́run wa mọ́. … Ó pẹ̀lú ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ní yíyẹ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.”3

Kíni èso lílo àwọn ẹ̀bùn ti-ẹ̀mí? Wọ́n pẹ̀lú àwọn ìṣílétí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí tí ó nràn wá lọ́wọ́ láti dojúkọ àwọn ìlò ojojúmọ́ tí ó sì nfi ohun tí a ó ṣe àti sọ hàn wá àti àwọn ìbùkún àti ìtùnú. Bí a ti nfetísílẹ̀ tí a sì nṣe ìṣe lórí àwọn ìṣílétí ti-ẹ̀mí, Ẹ̀mí Mímọ́ ngbé àwọn agbára àti okun wa ga láti ṣe kọjá ohun tí a lè ṣe fún ara wa. Àwọn ẹ̀bùn oníyebíye ti-ẹ̀mí wọ̀nyí yíò ràn wá lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbé ayé wa.4

Alabarin ìgbàgbogbo ti Ẹ̀mí Mímọ́ ni ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn ti-ẹ̀mí tí ó tóbijùlọ tí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ngbádùn.

Báwo ni ẹ̀bùn yí ti ṣe pàtàkì tó? Ààrẹ Russell M. Nelson dáhùn ìbèèrè yí gangan nígbàtí ó wípé “ní àwọn ọjọ́ tí nbọ̀, kò ní ṣeé ṣe láti wà láàyè nípa ti ẹ̀mí, láìsí ìtọ́nisọ́nà, dídarí, títùninínú àti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ léraléra.”5

Bí a ti lè Pè kí a sì Dá àwọn Ìṣílétí ti Ẹ̀mí Mọ̀

Ní àkokò iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi, mo rí ìfẹ́ káríayé nípa gbogbo ènìyàn tí wọ́n nfẹ́ mọ̀ tí wọ́n sì nfẹ́ pè tí wọ́n sì ndá àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí Mímọ́ mọ̀. Àwọn ìṣílétí ti Ẹ̀mí jẹ́ ti araẹni ó sì nwá ní oríṣiríṣi àwọn ọ̀nà. Bákannáà, àwa, di alábùkún láti ní àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, méjèèjì ti àtijọ́ àti òde-òní, nfún wa ní àwọn ìwòye oníyì nípa bí a ó ti gba ìdarí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí.

Ẹ jẹ́ kí nfún yín ní àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìtọ́ni mẹrin tí ó lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún yín ní pípè àti dídá àwọn ìṣílétí ti Ẹ̀mí mọ̀.

Ẹ dúró ní Àwọn Ibi Mímọ́.

Àkọ́kọ́ ni láti dúró ní àwọn ibi mímọ́.6 Láìpẹ́ mo kópa nínú ìṣílé Tẹ́mpìlì Tokyo Japan. Ní Ìdáhùn sí àwọn ìfipè bí ìṣe tí a firánṣẹ́ sí àwọn oníròhìn àti àwọn àlejo gíga kọjá bí a ti rò lọ. Ọgọgọrun ti darapọ̀ nínú ìkáàkiri ìtọ́nisọ́nà tẹ́mpìlì wọ̀nyí. Àwọn àlejò ní ìfọwọ́tọ́ tó jinlẹ̀ nípa ẹwà tẹ́mpìlì náà, pẹ̀lú àwọn àwòrán àti mótífù pẹ̀lú àwọn ìsopọ̀ àṣà ìjìnlẹ̀ ara Japan. Pàtàkì jùlọ síbẹ̀ ni ọlá àti ọ̀wọ̀ àdẹ́hìnbọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àlejò bí a ti júwe àwọn ìlànà babanla ní àwọn yàrá níbití wọ́n ó ti ṣẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun tó wọnilọ́kan jùlọ ni ìrusókè ti Ẹ̀mí.

Ọ̀kan lára àwọn àkokò bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú olókìkí òṣìṣẹ́ ìjọba kan dúró ní inú mi. Títẹ̀lé àkokò ríronú-jinlẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́ nínú yàrá sẹ̀lẹ́stíà, ní ẹ̀dùn ọkàn àti ìfọwọ́tọ́ jíjinlẹ̀, tí ó sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sínú etí mi pé, “Àní atẹ́gùn tí mò nmí nínú yàrá yí yàtọ̀.” Mo damọ̀ pé ó ngbìyànjú láti júwe wíwà ti Ẹ̀mí Mímọ́, èyí, tí ó ngbé ní ààyè mímọ́, nítòótọ́. Bí ẹ bá ní ìrètí láti nímọ̀lára Ẹ̀mí, wà ní ibi tí ẹ̀mí ti lè gbé nírọ̀rùn.

Àwọn tẹ́mpìlì àti ilé ni mímọ́ jùlọ nínú àwọn ààyè yíyàsímímọ́ wọ̀nyí. Nínú wọn ni à ti npe nírọ̀rùn tí a sì ndá Ẹ̀mí mọ̀. Àwọn ibi mímọ́ míràn pẹ̀lú ilé-ìjọsìn, ilé-ikẹkọ àti idanilẹkọ, àti àwọn ibi àkọọ̀lẹ̀-ìtàn àti gbàgede àwọn àlejo. Ẹ dúró ní àwọn ibi ímọ́.

Ẹ Dúró pẹ̀lú Àwọn Ènìyàn Mímọ́

Ìkejì, ẹ dúró pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́. Èmi ó júwe ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kejì pẹ̀lú ìrántí míràn.

Èmi kò ní gbàgbé kíkópa nínú ìfọkànsìn tí a ṣe ní àrẹnà ìṣeré olókìkí. Ó wọ́pọ̀ pé, àrẹnà yí kún pẹ̀lú wúruwùru àwọn olùfẹ́ tí wọ́n nyọ̀sí ẹgbẹ́ ilé tiwọn àti bóyá wọ́n ntàbùkù àwọn alátakò wọn. Ṣùgbọ́n ní alẹ́ yí, ojú ọjọ́ yàtọ̀ gan. Àrẹnà náà kún fún ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn tí wọ́n kórajọ láti bú ọlá fún kí wọ́n sì ṣe àjọyọ̀ ìgbé ayé Wòlíì Joseph Smith. Ọ̀wọ̀ wọn, ìsọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́, ìmoore, àti àdúrà àtinúwá kún inú àrẹnà náà pẹ̀lú wíwà ti Ẹ̀mí Mímọ́. Èmi lè ri níti ọ̀rọ̀ nínú ojú wọn. Ó jẹ́ ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí Mímọ́ nínú ìṣe, tí ó ntẹnumọ́ àwọn ẹ̀rí tí Joseph Smith jẹ́ àti Ìpadàbọ̀sípò ìhìnrere.

A kò lè dá Ẹ̀mí dúró ní wíwà nínú ìkórajọ àwọn ènìyàn mímọ́. Bí ẹ bá ní ìrètí láti nímọ̀lára Ẹ̀mí, ẹ wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní ibi tí Ẹ̀mí ti lè gbé nírọ̀rùn. Olùgbàlà wi ní ọ̀nà yí pé: “Nítorí ibi tí méjì tàbí mẹta bá ti kórajọ papọ̀ ní orúkọ mi, níbẹ̀ ni èmi ó wà ní àárín wọn.”7 Fún àwọn ọ̀dọ̀ ènìyàn, e yẹ ìkórajọ yín wo nípa àwọn ènìyàn mímọ́, iyejú àti kílásì, FSY àti ilé-ikẹkọ, àti ìṣe wọ́ọ̀dù àti èèkan—àní àwọn akọrin wọ́ọ̀dù. Ẹ yàn láti wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn kí ẹ sì lọ sí àwọn ibi tí a ti nrí òdodo. Ẹ wa agbára yín nínú oye. Ẹ wá àwọn ọ̀rẹ́ rere. Ẹ jẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rere. Ẹ ti ara yín lẹ́hìn níbikíbi tí ẹ wà. Ẹ dúró pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́.

Ẹ Jẹri Àwọn Òtítọ́ Mímọ́

Ìkẹ́ta, ẹ jẹri àwọn òtítọ́ mímọ́ bí ẹ tilè ṣeé léraléra. Olùtùnú npín ohùn Rẹ̀ léraléra nígbàtí a bá jẹri pẹ̀lú ohùn wa. Ẹ̀mí njẹ́ ẹ̀rí sí olùsọ̀rọ̀ àti olùfetísílẹ̀ bákannáà.

Mo rántí gbígbé ọkọ̀-èrò àrúndínláádọ́ta ìṣẹ́jú lọ sí Ilú New York. Ní níní ìbánisọ̀rọ̀ ìyárí ìhìnrere pẹ̀lú awakọ̀ fún àkokò ìwakọ lọ sí ibùdókọ̀-ọkọ̀ òfúrufú, mo sanwó fún un mo sì múra láti jáde nínú ọkọ-èrò. Nmo rántí pé èmi kò tíì jẹ́ ẹ̀rí mi nípa ohun tí mo ṣe àbápín rẹ̀. Lórí ìdúró, mo ṣe àbápín ẹ̀rí, kúkurú ìrọ̀rùn kan, ní pípé Ẹ̀mí tí ó sì mú omije wá sí ojú mi méjèèjì.

Bí ẹ ti nwá tí ẹ sì ngba ànfàní láti ṣe àbápín ẹ̀rí yín pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ẹ ó dá àwọn àkokò sílẹ̀ láti dá Ẹ̀mí mọ̀ fúnra yín.

Ẹ Fetísílẹ̀ sí Ẹ̀mí Mímọ́

Ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tó parí ni láti fetísílẹ̀ sí Ẹ̀mí Mímọ́. Òun lè jẹ́ alabarin ìgbàgbogbo wa, ṣùgbọ́n ó nsọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́, pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ nínú ohùn. Wòlíì Elijah ri pé ohùn Olúwa kò sí nínú ìjì, iṣẹ́lẹ̀, tàbí iná—ṣùgbọ́n ó jẹ́ “ohùn jẹ́jẹ́ àti kékeré.”8 Kìí ṣe “ohùn àrá,” ṣùgbọ́n ó jẹ́ “ohùn jẹ́jẹ́ ti ìrọ̀rùn pípé, bíi pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,” àti pé síbẹ̀ ó lè “wọ inú ọkàn lọ gan.”9

Ààrẹ Boyd K. Packer Wípé: “Ẹ̀mí kìí gbá ìfojúsùn wa nípa kíkígbe tàbí gbígbọ́n wa pẹ̀lú ọwọ́ tó wúwo. Ṣùgbọ́n ó nsọ̀rọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́. Ó nṣìkẹ́ ní jẹ́jẹ́ gan tí ó fi jẹ́ pé bí a bá tilẹ̀ nṣiṣẹ́ míràn a lè mátilẹ̀ ní imọ̀lára gbogbo rẹ̀.”10 Mo ti ṣe àkíyèsí pé nígbàmíràn ohùn Rẹ̀ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ́lẹ́ gan, tàbí mo níṣẹ́ míràn gan, tí olùfẹ́ni kan nyàwòrán rẹ̀ fún mi. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti jẹ́ àwọn ìgbà tí àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí Mímọ́ nwá sí ọ̀dọ̀ mi nípasẹ̀ ìyàwó mi, Lesa. Àwọn òbí olódodo tàbí olórí lè gba ìtọnisọ́nà ìmísí fún yín.

Ohùn náà, ariwo, àti ìjà tí ó wà nínú ayé lè borí síbẹ̀, ìwọ̀lọ́kan jẹ́jẹ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ wá ibi jẹ́jẹ́, ibi mímọ́ tí ẹ ti lè wá láti gba ìdarí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí.

Àwọn ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ kan

Bí ẹ ti nyẹ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí wo láti pè àti láti dá Ẹ̀mí mọ̀, ẹ yẹ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wo nípa ìkìlọ̀ ìtọ́nisọ́nà.11

Fi ẹsẹ̀ ìwọ̀lọ́kan ti ẹ̀mí yín múlẹ̀. Àwọn ìwọ̀lọ́kan láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí yíò wa ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìwé-mímọ́ àti àwọn ìkọ́ni ti àwọn wòlíì alààye.

Ri dájú pé àwọn ìmọ̀lára tí ẹ gbà wà ní ìbámu pẹ̀lú ìyànsíṣẹ́ yín. Àyàfi tí a bá pè yín láti ọwọ́ aláṣẹ tótọ́, àwọn ìwọ̀lọ́kan láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kìí ṣe fún yín láti gbàmọ̀ràn tàbí bá àwọn míràn wí.

Àwọn ọ̀ràn ti ẹ̀mí ni a kò lè kàn nípá. Ẹ lè mú ìwà àti àyíká kan tí ó npe Ẹ̀mí gbèrú, ẹ sì lè múra ara yín sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kòlè sọ bí tàbí ìgbàtí ìmísí yíò wá. Ẹ ní sùúrù kí ẹ sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ẹ ó gba ohun tí ẹ nílò nígbàtí àkokò bá tọ́.

Ẹ lo èrò ara yín dídára jùlọ. Nígbàmíràn à nfẹ́ ìdarí nípasẹ̀ Ẹ̀mí nínú ohun gbogbo. Bákannáà, Olúwa nfẹ́ kí a lo òye tí Ọlọ́run-fúnni kí a sì ṣe ìṣe ní àwọn ọ̀nà tí ó wà níbámu pẹ̀lú lílóye dídárajùlọ wa. Ààrẹ Dallin H. Oaks ti kọ́ni pé:

“Ìfẹ́ láti jẹ́ dídarí nípasẹ̀ Olúwa ni agbára, ṣùgbọ́n ó nílò láti wà pẹ̀lú òye pé Baba wa Ọ̀run nfi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpinnu sílẹ̀ fún àwọn àṣàyàn araẹni wa. … Àwọn ẹni tí wọ́n bá gbìyànjú làti yí gbogbo ìpinnu ṣíṣé sí Olúwa tí wọ́n sì nbẹ̀bẹ̀ fún ìfihàn lórí gbogbo yíyàn wọn yíò rí àwọn ipò láìpẹ́ nínú èyí tí wọ́n ó gbàdúrà fún ìtọ́nisọ́nà kí wọ́n sì máṣe ri gbà. …

“A níláti ṣe àṣàrò àwọn nkan jáde ní inú wa. … Nígbànáà a níláti gbàdúrà fún ìtọ́nisọ́nà àti ṣíṣe ìṣe lórí rẹ̀. … Tí a kò bá gba ìtọ́nisọ́nà, a níláti ṣe ìṣe lórí èrò dídárajùlọ wa.”12

Ìparí pẹ̀lú Ìfipè kan

Ní ìparí, àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn níláti jẹ́, àwọn ènìyàn olùpa-májẹ̀mú mọ́ tí a fún ní ẹ̀bùn. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, ó kù fún wa láti wá ìlò àwọn ẹ̀bùn ti-ẹ̀mí wa àti nígbànáà láti pè àti láti kọ́ láti dá àwọn ìṣílétí ti Ẹ̀mí mọ̀. Àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìtọ́nisọ́nà mẹrin láti ràn wá lọ́wọ́ nínú ìṣe pàtàkì tì-ẹ̀mí ni:

  1. Ẹ dúró ní àwọn ibi ímọ́.

  2. Ẹ dúró pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́.

  3. Ẹ jẹri àwọn òtítọ́ mímọ́

  4. Ẹ fetísílẹ̀ sí Ẹ̀mí Mímọ́.

Agbára yín láti pè àti láti dá àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí mọ̀ yíò gbèrú ní ìṣísẹ̀ kan ní àkokò kan. “Wíwà ní ìbámu sí èdè ti Ẹ̀mí síi dàbí kíkọ́ èdè míràn. Ó jẹ́ ètò díẹ̀díẹ̀ tí ó gba aápọn, ìtiraka sùúrù.”13

Pìpadà sí ibi tí a ti bẹ̀rẹ̀, ẹ jọ̀wọ́ ẹ rántí pé bí àwọn Ènìyàn Mímọ́ ẹ ní ẹ̀bùn. Ẹ yẹ àwòrán ìran àwẹ̀ Ọjọ́-ìsinmi yí wò, tí a ṣe àpejúwé láìpẹ́ sí mi. Ọ̀dọ́mọdé kan, dúró lórí sítúlù kan, tí a fẹ́rẹ̀ má tilẹ̀ rí lórí pẹpẹ. Baba rẹ̀ dúró nítosí rẹ̀, ó nfún ní ìyànjú ó sì nràn an lọ́wọ́ pẹ̀lú sisọ ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí etí rẹ̀ bí ó ti nfi ìgboyà ṣe àbápín, “Ọmọ Ọlọ́run ni mi.”

Ẹ̀rí tótẹ̀ lée tí ó wá láti ọ̀dọ̀ àgbà ọ̀dọ́ àdánìkanwà ẹnití ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ara gbígbọ̀n wípé: “Èmi ò bá fẹ́ pé mo ní ẹnìkan tí ó nsọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí etí mi bíiti èyí.” Lẹ́hìnnáà ó ní ìsọdá ìmísí ó sì jẹri pé, “Mo ní ẹnìkan tí ó nsọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí etí mi bí èyí—Ẹ̀mí Mímọ́!”

Mo parí pẹ̀lú ìfipè kan nípàtàkì fún gbogbo àwọn ọ̀dọ́! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín nbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ yín nípa dídúró ní iwájú jígí. Ní ọ̀la, ọ̀sẹ̀ yí, ọdún yí, nígbàgbogbo, ẹ dúró bí ẹ ti nwo arayín nínú jígí. Ẹ ronú fún ara yín, tàbí kí ẹ sọ̀rọ̀ sókè bí ẹ ti fẹ́, “Aah, wò mí! Èmí ni ìyàlẹ́nu! Èmi Jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run! Ó mọ̀ mi! Ó fẹ́ràn mi! Mo ní ẹ̀bùn—ẹ̀bùn pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́ bí alabarin mi nígbà gbogbo!”

Mo fi ẹ̀rí mi kun fún yín, ẹ̀yin Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí a fún lẹ́bùn, ti Ọlọ́run Baba, Jésù Krístì, àti Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀rí nípa Wọn. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.