2010–2019
Ọ̀rọ̀ náà, Ìtumọ̀ náà, àti Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀-èrò náà
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Ọ̀rọ̀ náà, Ìtumọ̀ náà, àti Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀-èrò náà

Nínú àìdúró dínì àti ìlù dídún ni ọjọ́ wa, njẹ́ ki a tiraka láti ri Krístì ni gbùngbun ayé wa, ìgbàgbọ́ wa, àti ìsìn wa.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, Sammy Ho Ching nìyí, ọmọ oṣù méje, nwo ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ní ilé rẹ̀ ni oṣù kẹ́rin ti o kọja.

Àwòrán
Sammy Ho Ching ní àárín ìmúdúró

Nígbàtí àkokò tó láti ṣèmúdúró Ààrẹ Nelson àti àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò míràn, àwọn ọwọ́ Sammy nṣiṣẹ́ ni dídi ìgò rẹ̀ mú. Nítorínàà o ṣe ohun tí o dára jùlọ tótẹ̀lé.

Àwòrán
Sammy Ho Ching ní àárín ìmúdúró

Sammy fúnni ní ìtumọ̀ tuntun sí ìmọ̀ràn ti ìdìbò pẹ̀lú àwọn ẹsẹ̀ rẹ.

Ẹ káàbọ̀ sí Ìlàjì-ọlọ́dọdún ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn yí. Láti ṣètò ipele fún ìbánisọ̀rọ̀ mi fún ìtumọ̀ àwọn ìpéjọpọ̀ ìgbà-méjì-ọdọọdún wọ̀nyí, mo mú ìṣẹ̀lẹ̀ yí láti inú àkọsílẹ̀ Lúkù ti Májẹ̀mú Titun:1

“Ó sì ṣe, pé nígbàtí [Jésù] ó súnmọ́ Jẹ́ríkò, arákùnrin afọ́jú kan jókòó sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà o n bẹ̀bẹ̀:

“… Gbígbọ̀ àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ [kan] n kọjá, ó bèrè kíni ìtumọ̀ rẹ.

“… Wọ́n sọ fun, wípé Jésù ti Násárẹ́tì nkọjá lọ.

Ó sì kígbe, wípé, Jésù, Ọmọ Dáfídì, sàánú fún mi.”

Ìgboyà rẹ banilẹ́rù, àjọ èrò gbìyànjú láti dá ọkùnrin náà lẹ́kun, ṣùgbọ́n “o kígbe púpọ̀ síi,” ó wípé. Nítorí ìforítì rẹ̀,, wọ́n mu wá sọ́dọ̀ Jésù, ẹni tí o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ láti mu ìran rẹ̀ padà bọ̀ sípò kí o si wòó sàn.2

Èmi ní nmira nípasẹ̀ vígínẹ̀tì kékeré ní gbogbo ìgbà ti mo bá ka á. A lè ní òye ìpọ́nju arákùnrin náà. A fẹ́rẹ̀ lè gbọ́ bi o ti n paruwo fún àkíyèsí Olùgbàlà. A rẹrin si àìgba láti dákẹ́—nítòótọ́, ìpinnu rẹ láti gbé ohùn sókènígbàtí gbogbo ènìyàn nsọ fun ki o gbe sílẹ̀. Ó jẹ́, nínú àti òhun fúnrarẹ̀, ìtàn aládùn kan ti ìpinnu ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n bi ti gbogbo ìwé-mímọ́, bí a bá ṣe kàá sí ni a o rí i.

Èrò kan tí ó mú mi láìpẹ́ yi ni òye ti arákùnrin yí ni nípa níní àwọn tí o wà nípa ti ẹ̀mí ní àyíká rẹ. Gbogbo pàtàkì ìtàn yi dá lé orí àwọn ọkùnrin àti obìnrin àìmọ̀ ẹni, nígbàtí àwọn ọ̀gbà wọn bèèrè, “Kíni ìtumọ̀ ariwo yi?” ní ìran, tí o bá fẹ́, láti dá Krístì mọ̀ gẹ́gẹ́ bi ìdí ariwo; Òhun ni Ìtúmọ̀ ti Araẹni. Ẹ̀kọ́ kan wa nínú pàṣípàrọ́ kékeré yí fún gbogbo wa. Ní ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ìdánilójú, ó ma nràn wá lọ́wọ́ láti dojú ìbéèrè wa kọ àwọn ti wọ́n ni àwọn nkan gangan! Ǹjẹ́ afọ́jú le darí afọ́jú bi? Jésù fìgbà kan bèrè. “[Tí ó bá rí bẹ̀,] ṣé awọn méjèèji ki yíò ṣubú sínú ihò?”3

Irú ìwákiri ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ àti ìdánilójú ni ìdí àwọn ìpàdé àpapọ́ wọ̀nyí, àti dídara pọ̀ mọ́ wa loni ẹ o ri wípé ìwákiri jẹ akitiyan gbígbòrò. Ẹ wo àyíka yín. Níbí lórí ilẹ̀ yí ẹ rí àwọn ẹbí gbogbo tíwọ̀n nwá láti gbogbo ìtọ́sọ́nà. Àwọn ọ̀rẹ́ àtijọ́ gbáramú nínú ayọ́nlá àtúnpọ̀, ẹgbẹ́ akọrin oníyàlẹ́nu ngbáradì, àti àwọn aṣojú kígbe láti àpótí àyànfẹ́ wọn. Àwọn ìránṣẹ́ Ìhìnrere ti ọjọ́ àkọ́kọ́ kan wa àwọn akẹgbẹ tẹ́lẹ̀, nígbà ti àwọn àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ti wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ padà dé wa pátápátá akẹgbẹ́ tuntun (tí ẹ bá mọ ohun tí mo pète!). Àti àwọn fọ́tò? Ọ̀run rànwá lọ́wọ́! Pẹ̀lu ẹ̀rọ alágbeká ní gbogbo ọwọ́, a ti kúrò làti “gbogbo ọmọ ìjọ ìránṣẹ́ ìhìnrere kan” sí “gbogbo ọmọ ìjọ olùyàwòrán kan.” Ni àárín ariwo dídùn yi, ẹnì kan lè fi àìdálẹ́bi bèère, “Kíni ìtumọ̀ gbogbo rẹ̀?”

Bi ti ìtàn Májẹ̀mú Tuntun wa, àwọn ti a bùkún pẹ̀lú ojú yi o da yẹn mọ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ohun míràn ti ìpàdé àtọwọ́dọ́wọ́ yi lè fún ni, o ni ìtumọ̀ díẹ̀ tàbí nkankan àyàfi tí a ba wá Jésù ni gbùngbun rẹ̀ gbogbo. Láti gbá ìran ti a nwá mú, ìwòsàn tí Ó ṣèlérí, pàtàkì ti a mọ wa níbí bákan, a gbọ́dọ̀ gé ariwo kúrò—bi ó ti ni ayọ̀ to—ki a fi àkíyèsí wa sí I. Àdúrà olùsọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan, ìrètí gbogbo àwọn to kọrin, ìbọ̀wọ̀ àlejò kọ̀ọ̀kan—ẹni gbogbo farajì láti pe ẹ̀mí Ẹni tí ìjọ jẹ́ tirẹ̀—alààyè Krístì, Ọ̀dọ́ Agùtàn Ọlọ́run, Ọmọ-Aládé Àláfíà.

Ṣùgbọ́n a kò gbọdọ̀ wa ni gbùngbun ìpàdé àpapọ̀ kí a to rí I. Nígbàtí ọmọ kékeré ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì lakọkọ tí ó sì fún ni pẹ̀lú ìgboyà Ábínádáì tàbi yíyan àwọn akọni alágbára ẹgbẹ̀rún méjì, a lè rọra fi kun wípé Jésù ni olùsiǹ àwòrán nínu ìtàn oníyanu yi, n duro bi àwọ̀ dídán lórí ojú ìwé kọ̀ọ̀kan rẹ̀ láti pèsè ọ̀nà àsopọ̀ fun gbogbo àwọn ohun míràn ti olùsin ìgbega-ìgbàgbọ́ inú rẹ̀.

Bákannáà, nígbàtí ọ̀rẹ́ kan bá nkẹkọ nípa ìgbàgbọ́, obìnrin tàbi ọkùnrin le rẹ̀wẹ̀sì díẹ̀ nípa àwọn ẹ̀yà aláìlẹ́gbẹ́ àti àròkọ tí a kò mọ̀ ti àsà ẹ̀sìn wa— àwọn ìhámọ́ àìjẹun, àwọn ìpèsè ti ìgbẹ́kẹ̀lé ara ẹni, àwọn ìrinsẹ̀ aṣaájú, pẹ̀lú àìlesọ iye àwọn gbùngbun èèkàn níbi tí àwọn kan láìṣeyèméjì nretí láti pín fún ṣabrọ́íli sirloin, alábọ̀dé-tòṣọ̀wọ́n. Nítorínáà, bi àwọn ọ̀rẹ́ wa tuntun ṣe ní ìrírí àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìwò àti ìrò, a gbọ́dọ̀ kọjá títì sihin-sọhun àti ariwo ki a si dojú kọ ìtumọ̀ rẹ̀ gbogbo, lórí lílu ọkàn ti ìhìnrere ayérayé—ìfẹ́ àwọn Òbí Ọ̀run, ẹ̀bùn ètùtù Ọmọ ọ̀run, ìtùnú ààbò ti Ẹ̀mí Mímọ́, ìmúpadàbọ̀sípò ọjọ́-ìkẹhìn gbogbo àwọn òtítọ́ àti síwájú si.

Nígbàtí ẹni kan bá lọ si tẹ́mpìlì fún ìgbà àkọ́kọ́, ọkùnrin tàbi obìnrin náà le ní ìbẹ̀rù nípa ìrìrì náà. Iṣẹ́ wa ni lati ri dájú wípé àwọn àmì mímọ́ àti àwọn ìlànà ẹ̀sìn ti a fi hàn, aṣọ ìsìn àti àwọn ìfihàn àgbékalẹ̀, kò yẹsẹ̀ kúrò ṣùgbọ́n o tọ́ka wa si Olùgbàlà, ẹni tí a wà níbẹ̀ láti sìn. Tẹ́mpìlì jẹ́ ilé Rẹ̀, ó sì yẹ ki o wà níbi gígajù lọ ní iyè àti ọkàn wa—ẹ̀kọ́ títóbi ti Krístì nla ẹ̀dá wa já gẹ́gẹ́ bi o ti la àwọn ìlànà tẹ́mpìlì ja—láti ìgbà ti a kà àkọ́lé lókè ilẹ̀kùn títí dé òpin àkókò tí a lò ni ilé náà. Láàrín gbogbo ìyanu tí a bá pàdé, a ní láti ri, ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìtumọ̀ Jésù ni tẹ́mpìlì.

Gbèrò ìyára ìgboyà ìpìlẹ̀ àti àwọn ìkéde tuntun ni ìjọ ní àwọn oṣù àìpẹ́. Bí a ṣe nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ si ara wa, tàbí bí a ṣe n tún ìrírí Ọjọ Ìsinmi ṣe, tàbí gbá ètò titun fùn àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ mọ́ra, a máa pàdánù ìdí gangan ti ìfihàn àwọn àtúnṣe tí a bá ri wọn bíi àìdọ́gba, ìpilẹ̀ṣẹ̀ tì kò báramu sànju pe bí ìbáṣepọ̀ akitiyan láti ràn wá lọ́wọ́ láti dúróṣinṣin si orí Àpáta Ìgbàlà wa.4 Dájú, dájú, èyí ni ohun tí Ààrẹ Russell M. Nelson pinnu ní mímú wa lo ìfihan orúkọ Ìjọ.5 Tí Jésù—Orúkọ Rẹ̀, ẹ̀kọ́ Rẹ̀, àpẹrẹ Rẹ̀, ìwà-ọ̀run Rẹ̀—lè wà ní gbùngbun ẹ̀sìn wa, a lè fì agbára kún òtítọ́ ti Álmà kọ́ nígbà kan: “Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun ni o mbọ̀wá; [ṣùgbọ́n] ẹ kíyèsíi, ohun kan wà èyítí o ṣe pàtàkì ju gbogbo wọn lọ— … Olùgbàlà [ẹni] tí ó gbé àti mbọ̀wá gbé àárín àwọn ènìyàn rẹ̀.”5

Èrò Ìparí kan:Sẹ́ntúrì kọkàndínlógún Joseph Smith àyíká iwájú gbóná pẹ̀lú àwọn èrò ti wọ́n n díje fún àwọn ẹlẹri krìstìẹ́nì.6 Ṣùgbọ́n nínú ariwo ti wọ́n dá sílẹ̀, àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ onísọjí wọ̀nyi wà, ni ìránpọ, n ṣókùnkùn si Olùgbàlà gan tí ọ̀dọ́mọdé Joseph fi taratara wá. Nja ogun pẹ̀lú ohun tí ó pè ní “òkùnkùn àti ìdàmú,”7 o wá ibi isinmi idakẹrọrọ si igbó ṣúúrú igi kan níbi ti o ti ri ti o si gbọ ẹ̀ri ológo ti Olùgbala si ìhìnrere ju èyíkeyi ti a ti fẹnu ba níbí ní àárọ̀ yí. Pẹ̀lú ẹ̀bùn ìran àìrònú àti àìròtẹ́lẹ̀, Joseph wo nínú ìran ti Bàbá rẹ Ọ̀run, Ọlọrun títóbi àgbáyé, àti Jésù Krístì, Ọmọ Rẹ̀ pípé Nìkanṣoṣo. Nígbànâ Bàbá fi àpẹrẹ lélẹ̀ ti a yìn ni àárọ̀ yí: Ó nawọ́ sí Jésù, wípé, “Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ ti Rẹ̀!”8 Kò sí ìwò ti ọ̀run mímọ̀dájú ti Jésù, alákọbẹ̀rẹ̀ nínú ètò ìgbàlà, àti ìdúró Rẹ ní ojú Ọlọ́run lè kọjá àwọn ọ̀rọ̀ kúkurú méje sísọ náà.

Ìrúkèrúdò àti rúdurùdu? Èrò àti ìjà? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn yi ni o wa ni ayé wa. Nítòótọ́, àwọn onígbọ̀wọ́ àti onígbàgbọ́ ṣi njìjàdù lórí ìran yi àti gbogbo ohun ti mo tọ́ka sí loni. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé lè máa tiraka làti rí síi kedere àti láti wa ìtumọ̀ ni àárín ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn èrò, Mo tọ́ka yín si Jésù kannáà mo si jẹ ẹ̀rí àpóstélì nípa ìrírí Joseph Smith, bí o ti nwá bí ó ti wa ni ẹgbẹ̀rún ọdún méjì o dín díẹ̀ sẹ́yìn lẹ́yìn ti ọ̀rẹ́ wa afọ́jú ti gba ìran rẹ̀ ni ojú Ọ̀nà Jẹ́ríkò ìgbàanì. Mo jẹri pẹ̀lú àwọn méjèèjì yi àti àwọn púpọ míràn titi dé akoko wipe lóòtọ́ ohun ìwò ti o móríwú ju tí o sì ndún ni ayé ni wípé Jésù ko kọjá lásán9 ṣùgbọ́n kíkọjá Rẹ̀ wa, dídúró lẹgbẹ wa, n ṣe ibùgbé Rẹ̀ pẹ̀lú wa.10

Ẹ̀yin arabìnrin àti arakùnrin, nínú àìdúró dínì àti ìlù dídún ni ọjọ́ wa, ki a tiraka láti ri Krístì ni gbùngbun ayé wa, ìgbàgbọ́ wa, àti iṣẹ́ ìsìn wa. Ibi ti ìtumọ̀ tòótọ́ wa nìyẹn. Àti bí a bá rí àwọn ọjọ́ ti ìran wa dínkù, tàbí ìgboyà wa ti dínkù, tàbi a n dán ìgbàgbọ́ wa wò tí a sì n túnṣe—dájúdájú bi yíó ti ri—kí á kígbe sókè, “Jésù, ọmọ Dáfídì, ṣàánú fúnmi.”11 Mo ṣe ìlérí pẹ̀lú ìtara àpóstéli pẹ̀lú àti ìgboyà wòlíì wípé Yíò gbọ́ yín yi o si wipe, nípípẹ́ tàbí yíyá, “Gba ìran rẹ: ìgbàgbọ́ rẹ̀ tí gbà ọ́ là.”12 Ẹ káàbọ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.