2010–2019
Àwọn Òfin Nlá Méjì
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Àwọn Òfin Nlá Méjì

Ní ìsisìyí a gbọdọ̀ gbìyànjú láti pa àwọn òfin nlá méjèèjì náà mọ́. Láti ṣe bẹ́ẹ̀, à nrìn ní ìlà ẹlẹ́wà ní àárín àṣẹ àti ìfẹ́.

Ẹyin arábìnrin mi ọ̀wọ́n nínú ìhìnrere Jésù Krístì, mo ki yín bíi alágbàtọ́ tí a yàn láti ọ̀run wá fún ẹbí ayérayé náà. Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ wa pé, “A mú Ijọ yìí padàbọ̀sípò kí àwọn ẹbí ó le jẹ́ gbígbékalẹ̀, fífi èdidi dì, àti gbígbéga ní ayérayé.”1 Ikọ́ni náà ní àwọn àyọrísí pàtàkì fún àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ara hàn bíi lẹ́síbíànù, géè, baisẹ́ṣúalì, tábí tiransigẹ́ndà, tí ó wọ́pọ̀ láti tọ́ka sí bíi LGBT.2 Ààrẹ Nelson ti rán wa létí bákannáà pé a kò “níláti [fi ìgbà gbogbo] wàni-ìbámu pẹ̀lú ara wa kí a tó fẹ́ràn ara wa.”3 Àwọn ìkọ́ni ti wòlíì wọ̀nyí ṣe pàtàkì fún àwọn ọ̀rọ̀ sísọ nínú ẹbí láti dáhùn àwọn ìbéèrè àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́. Mo ti fi pẹ̀lú àdúrà wá ìmísí láti bá ìjókòó yi sọ̀rọ̀ nítorípé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí kàn yín ní ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀, èyítí ó sì kan olukúlùkù ẹbí nínú Ijọ ní tààrà tàbí ní àìṣe-tààrà.

1.

Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tí Jésù kọ́ni pé wọ́n jẹ́ àwọn òfin nlá méjì.

“Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ.

“Èyí ni èkínní àti òfin ńlá.

“Èkejì sì dàbíi rẹ̀, Ìwọ yíò fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”4

Èyí túmọ̀ sí pé a pàṣẹ fún wa láti fẹ́ràn gbogbo ènìyàn, níwọ̀n ìgbà tí òwe Jésù ti Ará Samáríà rere kọ́ni pé gbogbo ènìyàn ni ọmọnìkejì wa.5 Ṣùgbọ́n ìtara wa láti pa òfin kejì yi mọ́ kò gbọdọ̀ mú wa láti gbàgbé ti àkọ́kọ́, láti fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo àyà, ọkàn, àti inú. A nfi ìfẹ́ náà hàn nípa “[síṣe]ìpamọ́ àwọn òfin [Rẹ̀].”6 Ọlọ́run fẹ́ kí a gbọ́ràn sí àwọn òfin Rẹ̀ nítorípé nípasẹ̀ ìgbọràn náà nìkan, pẹ̀lú ìrònúpìwàdà, ni a fi le padà láti gbé ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀ kí a sì di pípé bí Òun ti rí.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àìpẹ́ sí àwọn ọ̀dọ́ àgbà ti Ìjọ, Ààrẹ Russell M. Nelson sọ nípa ohun tí ó pè ní “ìfarakọ́ra líle ní ààrin ìfẹ́ Ọlọ́run àti àwọn àṣẹ Rẹ̀.”7 Òfin tí ó wúlò ní pàtàkì jùlọ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ní í ṣe sí àwọn wọnnì tí a mọ̀ bíi LGBT ni òfin Ọlọ́run ní ti ìgbéyàwó àti akẹgbẹ́ rẹ̀ tí í ṣe òfin ìpa-ara-ẹni-mọ́. Méjèèjì ni kókó nínú ètò ìgbàlà ti Baba wa ní Ọrun fún awa ọmọ Rẹ̀. Bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni, “àwọn òfin Ọlọ́run máa njẹ́ gbígbékalẹ̀ nipa ìfẹ́ àìlópin Rẹ̀ fún wa àti ìfẹ́-inú Rẹ̀ fún wa láti di ohun gbogbo tí a bá le dà.”8

A`àrẹ Nelson kọ́ni pé: “Ọpọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè … ti fi ìgbeyàwó ẹ̀yà-kannáà sí abẹ́ òfin. Àwa bíi ọmọ Ijọ, a nbọ̀wọ̀ fún àwọn òfin ilẹ̀ …, nínú èyítí ìgbeyàwó abẹ́lé wà. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, ní ìbẹ̀rẹ̀ ... ìgbeyàwó jẹ́ ohun tí a yàn láti ọwọ́ Ọlọ́run! Àti títí di ìsisìyí ó di títúmọ̀ láti ọwọ́ Rẹ̀ ni pé ó jẹ́ láàrin ọkùnrin kan àti obìnrin kan. Ọlọ́run kò tíì yí ìtumọ̀ Rẹ̀ ti ìgbeyàwó padà.

Ààrẹ Nelson tẹ̀síwájú pé: “Ọlọ́run kò tíì yí òfin ìpa-ara-ẹni-mọ́ padà bákannáà. Àwọn ohun tí a nílò láti wọ inú tẹ́mpìlì kò tíì yípadà.”9

Ààrẹ Nelson rán gbogbo wa létí pé “àṣẹ wa bíi Àpóstélì ni láti máṣe kọ́ni ní ohunkóhun ṣùgbọ́n òtítọ́. Àṣẹ náà fún wa [àwọn Àpọ́stélì] ní ẹ̀tọ́ láti tún òfin àtọ̀runwá ṣe.”10 Báyi, ẹ̀yin arábìnrin mi, àwọn olóri Ijọ gbọdọ̀ fi ìgbà gbogbo kọ́ni ní pàtàkì àràọ̀tọ̀ ti ìgbeyàwó láàrin ọkùnrin kan àti obìnrin kan, àti òfin ìpa-ara-ẹni-mọ́ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú rẹ̀.

ll.

Iṣẹ́ ti Ijọ Jésù Krístì ti Àwọn Èniyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn ní iparí jẹ́ àníyàn pẹ̀lú pípèsè àwọn ọmọ Ọlọ́run fún ìjọba sẹ̀lẹ́síà, àti ní pàápàá jùlọ fún ògo rẹ̀ gíga jùlọ, ìgbéga tàbí ìyè ayérayé. Àyànmọ́-ìpín gíga jùlọ náà ṣeéṣe nípasẹ̀ ìgbeyàwó fún ayérayé nìkan.11 Nínú ìyè ayérayé ni àwọn agbára ìṣẹ̀dá wà tí ó jẹ́ kókó nínú ìdàpọ̀ akọ àti abo12—ohun tí ìfihàn òde òní júwe bíi “ìtẹ̀síwájú ti àwọn èso náà lae àti títí laelae.”13

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwọn ọ̀dọ́ àgbà, Ààrẹ Nelson kọ́ni pé, Gbígbé nípasẹ̀ àwọn àṣẹ Ọlọ́run yíò pa yín mọ́ bí ẹ ti nlọsíwájú ní òpin sọ̀nà ìgbéga”14—èyíinì ni,láti dàbíiti Ọlọ́run, pẹ̀lú ayé ìgbéga àti agbára tọ̀run ti àwọn Òbí Ọ̀run wa. Ìpín náà ni a fẹ́ fún gbogbo àwọn tí a fẹ́ràn. Nítorí ìfẹ́ náà, a kò le jẹ́ kí ìfẹ́ náà ó borí àwọn òfin àti èrò àti iṣẹ́ Ọlọ́run, èyítí a mọ̀ pé yío mú ìdùnnú wọn títóbi jùlọ wá fún àwọn wọnnì tí a fẹ́ràn.

Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà tí a fẹ́ràn, pẹ̀lú àwọn kan tí wọ́n ti ní ìhìnrere tí a mú padàbọ̀sípò, tí wọn kò gbàgbọ́ tàbí tí wọ́n yàn láti máṣe tẹ̀lé àwọn òfin Ọlọ́run nípa ìgbeyàwó àti òfin ìpa-ara-ẹni-mọ́. Kínni nípa wọn?

Ẹkọ́ ti Ọlọ́run fihàn pé gbogbo wa ni ọmọ Rẹ̀ àti pé Òun ti dá wa láti ní ayọ̀.15 Ìfihàn òde òní kọ́ni pé Ọlọ́run ti pèsè èrò kan fún ìrírí ayé kíkú nínú èyítí ẹni gbogbo le yàn ìgbọràn láti lépa àwọn ìbùkún Rẹ̀ gíga jùlọ, tàbí ṣe àwọn àṣàyàn tí ó ndarí sí ọ̀kan lára àwọn ìjọba tí ó kéré.16 Nítorí ìfẹ́ nlá Ọlọ́run fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀, àwọn ìjọba kékèké wọnnì ṣì jẹ́ ìyanu ju ohun tí àwọn ẹ̀dá kíkú le ní òye rẹ̀ lọ.17 Ètùtù ti Jésù Krístì mú kí gbogbo èyí ṣeéṣe, bí Ó ti “ṣe Baba lógo, tí Ó sì gba gbogbo àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lá.18

lll.

Mo ti sọ nípa òfin kínní, ṣùgbọ́n báwo ni ti ìkejì? Báwo ni a ti í pa òfin láti fẹ́ àwọn ọmọnìkejì wa? A nlépa láti rọ àwọn ọmọ ìjọ wa pé àwọn wọnnì tí wọ́n tẹ̀lé àwọn ìkọ́ni àti ìṣe lẹ́síbíànù, géè, baisẹ́ṣúalì, tábí tiransigẹ́ndà ni a nílati tọ́jú pẹ̀lú ìfẹ́ tí Olùgbàlà wa pàṣẹ fún wa lati fihàn sí gbogbo àwọn ọmọnìkejì wa. Báyìí, nígbàti wọ́n sọ ìgbeyàwó ẹ̀yà-irúkannáà dí títọ́, Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì kéde pé: “Ìhìnrere Jésù Krístì kọ́ wa láti nifẹ àti láti hùwà sí gbogbo ènìyàn pẹ̀lú inúrere àti ọ̀làjú—àní nígbàtí a bá takora. A fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn wọnnì tí wọ́n fi ara wọn sílẹ̀ fún àwọn òfin àti àwọn ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tí ó fi àṣẹ sí ìgbeyàwó ẹ̀yà-kannáà, ni a kò níláti tọ́jú pẹ̀lú àìbọ̀wọ̀ fún.”19

Ní àfikún, a kò gbọdọ̀ ṣe inúnibíni sí àwọn wọnnì tí wọn kò pín nínú àwọn ìgbàgbọ́ àti àwọn ìfọkànsìn wa.20 Pẹ̀lú ẹ̀dùn, àwọn ènìyàn díẹ̀ tí wọ́n ndojúkọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tẹ̀síwájú láti máa ní ìmọ̀lára pípatì àti kíkọ̀sílẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ọmọ ijọ àti àwọn olùdarí kan nínú àwọn ẹbí, àwọn wọ́ọ̀dù, àti àwọn èèkàn wa. A gbọdọ̀ tiraka láti jẹ́ aláànú àti ẹni rere síi.

IV.

Fún àwọn ìdí tí kò yé wa, a ní àwọn ìpèníjà tí ó yàtọ̀ síra nínú àwọn ìrírí wa ní ayé ikú. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé Ọlọ́run yío ran olukúlùkù wa lọ́wọ́ láti borí àwọn ìpèníjà wọ̀nyí bí a bá fi òtítọ́ lépa ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀. Lẹ́hìn jíjìyà àti ríronúpìwàdà fún rírú àwọn òfin tí a ti kọ́ wa, gbogbo wa ní ìpín fún ìjọba ògo kan. Ìdájọ́ tí ó gbẹ̀hìn tí ó sì jẹ́ ìparí yío jẹ́ láti ọwọ́ Olúwa, ẹni nìkan tí ó ní ìmọ̀, ọgbọ́n, àti oore ọ̀fẹ́ tí a nílò láti dá ẹnikọ̀ọ̀kan wa lẹ́jọ́.

Ní ìsisìyí, a gbọdọ̀ gbìyànjú láti pa àwọn òfin nlá méjèèjì náà mọ́. Láti ṣe bẹ́ẹ̀ a nrin ní ìlà dídán ní ààrin méjì òfin àti ìfẹ́—pípa àwọn òfin mọ́ àti rírìn ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú, nígbàtí a nfẹ́ràn àwọn ọmọnìkejì wa ní ojú ọ̀nà náà. Ìrìn yí gba pé kí a lépa ìmísí àtọ̀runwá lórí ohun tí a níláti tìlẹ́hìn àti ohun tí a níláti dojúkọ àti bí a ti le fẹ́ràn kí a tẹ́tísílẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ kí a sì kọni nínú síṣe bẹ́ẹ̀. Ìrìn wa gbà pé kí a máṣe ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ lórí àwọn òfin ṣùgbọ́n kí a fi òye àti ìfẹ́ hàn jáde ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ìrìn wa gbọ́dọ̀ nírònú ti àwọn ọmọ tí kò ní ìdánilójú nípa ìdánilẹ́ẹ̀kọ́ ìbálòpọ̀ wọn, ṣùgbọ́n ó nfa ìrẹ̀wẹ̀sì ìlẹ̀mọ́ àìgbó nítorí, ní púpọ̀jù àwọn ọmọ, irú àìní-ìdánilójú bẹ́ẹ̀ ndínkù dáadáa ní ìgbà pípẹ́.21 Ìrìn wa tako ìgbàwọlé kúrò ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú, ó sì sẹ́ àtìlẹ́hìn sí ẹnikẹ́ni tí ó bá darí àwọn ènìyàn kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa, Nínú gbogbo èyí a rántí pé Ọlọ́run ṣe ìlérí ìrètí àti ayọ̀ àti àwọn ìbùkún ìkẹhìn fún gbogbo ẹnitẹ́ ó bá pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.

V.

Ẹyin ìyá àti ẹ̀yin bàbá àti gbogbo wa ni a ní ojúṣe láti kọ́ni ní àwọn òfin nlá méjì náà. Fún a`wọn obìnrin Ìjọ, Ààrẹ Spencer W. Kimball júwe pé ojúṣe nínú àṣọtẹ́lẹ̀ nlá yi: “Púpọ̀ nínú ìdàgbàsókè pàtàkì tí ó nwá sí Ijọ ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn yío wá nítorípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin rere inú ayé … yío jẹ́ fífà sí Ijọ ní àwọn oye púpọ̀. Èyí yío ṣẹlẹ̀ dé ibi tí àwọn obìnrin Ijọ bá ronú òdodo àti kétékété hàn nínú ìgbé ayé wọn àti dé ibi tí a bá ti rí àwọn obìnrin Ijọ bíi ẹni ọ̀tọ̀ àti yíyàtọ̀ … kúrò nínú àwọn obìnrin ti ayé. … Báyìí yío jẹ́ pé àwọn obìnrin alápẹrẹ inú Ijọ yío jẹ́ ipa pàtàkì kan nínú oùnkà àti ìdàgbàsókè ti ẹ̀mí Ìjọ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn.”21

Ní sísọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ náà, Ààrẹ Russell M. Nelson sọ pé “ọjọ́ tí Ààrẹ Kimball rí ṣaájú ni òní yi. Ẹ̀yin ni àwọn obìnrin tí ó rí ṣíwájú!”22 Díẹ̀ ni ó kù kí awa tí a gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ náà ní ogójì ọdún sẹ́hìn mọ̀ pé nínú àwọn wọnnì tí àwọn obìnrin Ijọ yí le gbàlà yío jẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ wọn ọ̀wọ́n, àti ẹbí tí wọ́n wà ní abẹ́ àkóso àwọn ohun ti ayé àti àwọn irọ́ ti èṣù. Ǎdúrà àti ìbùkún mi ni pé kí ẹ ó kọ́ni ẹ ó sì ṣiṣẹ́ láti mú ìsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.