2010–2019
Ìgbìdánwò Nlá Yín
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Ìgbìdánwò Nlá Yín

Olùgbàlà npè yín, ní ojoojúmọ́, láti fi àwọn ìtura àti ààbò yín sí ẹ̀gbẹ́ kan kí ẹ sì darapọ̀ mọ́ Ọ́ nínú ìrìn-àjò jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn.

Ti àwọn Iwin

Ìwé ìtàn àkàgbádùn ti àwọn ọmọdé kan ti a kọ ní ọdún púpọ̀ sẹ́hìn bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn “Ní inú ihò ní inú ilẹ̀ níbẹ̀ ni iwin kan ngbé.”1

Ìtàn ti Bilbo Baggins jẹ́ nípa iwin kan tí kò ní ìyàtọ̀ tí a gbé ànfààní kan tí kò tayọ kalẹ̀ fún—ààyè tó tayọ láti gbìdánwò ohun ìjìnlẹ̀, àti ìlérí èrè nlá.

Ìṣòro ìbẹ̀ ni pé púpọ̀ jùlọ àwọn iwin tí wọ́n fi ara wọn sí ipò ọ̀wọ̀ kò fẹ́ ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú àwọn ìgbìdánwò. Ìgbé ayé wọn gbogbo jẹ́ nípa ìtura. Wọ́n gbádùn jíjẹ oúnjẹ mẹ́fà ní ọjọ́ kan nígbàtí wọ́n bá le rí, wọn a sì máa lo àwọn ọjọ́ wọn nínú ọgbà wọn, ní jíju àwọn ìrù pẹ̀lú àwọn abẹniwò, kíkọrin, lílù àwọn ohun èlò orin, àti nínara nínú àwọn ìrọ̀rùn ayọ̀ ayé.

Ṣùgbọ́n, nígbàtí a gbé èrò ìgbìdánwò títóbi náà kalẹ̀ fún Bilbo, ohun kan tú jáde jinlẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀. Ó mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pé ìrìn-àjò náà yío ní ìdojúkọ. Àní yío léwu. Ó ṣeéṣe pàápàá pé kí ó má le padà.

Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ìpè náà sí ìgbìdánwò ti dé inú àwọn ibú ọkàn rẹ̀. Àti nítorínáà, iwin tí kò tayọ yí fi ìtura sílẹ̀ sẹ́hìn ó sì jáde lọ ní ojú ọ̀nà sí ìgbìdánwó nlá tí yío mú un ní gbogbo ọ̀ná dé “ibẹ̀ àti padà wá lẹ́ẹ̀kansíi.”2

Ìgbìdánwò Yín

Bóyá ọ̀kan nínú àwọn èrèdí tí ìtàn yí fi ndún sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ni nítorípé ó jẹ́ ìtàn tiwa náà.

Ní ìgbà pípẹ́, pípẹ́ sẹ́hìn, àní kí a tó bí wa, ní ọjọ́ orí tí àkókò sọ di òkúnkún àti ìkuùkù látinú ìrántí, a pe àwa náà láti wọ inú ìgbìdánwò kan. A pèrò rẹ̀ láti ọwọ́ Ọlọ́run, Baba wa Ọrun. Gbígba ìgbìdánwò yìí yío túmọ̀ sí fífi ìtura àti ààbò ti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sílẹ̀. Yío túmọ̀ sí wíwá sí ayé fún ìrìn-àjo kan tí ó kún pẹ̀lú ewu àti ìdojúkọ tí a kò mọ̀.

A mọ̀ pé kò níi rọrùn.

Ṣùgbọ́n a mọ̀ bákannáà pé a ó ní àwọn ìṣúra iyebíye, nínú wọn ni agọ́ ara àti níní ìrírí àwọn ayọ̀ púpọ̀ gidi àti àwọn ìkorò ti ayé kíkú. A ó kọ́ láti tiraka, láti lépa, àti láti gbìyànjú. A ó ṣe àwárí àwọn òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti ara wa

Ní tòótọ́, a mọ̀ pé a ó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àṣìṣe ní ipa ọ̀nà. Ṣùgbọ́n bákannáà a ní ìlérí kan: pé nítorí ẹbọ-ọrẹ nlá ti Jésù Krístì, a le di wíwẹ̀mọ́ kúrò nínú àwọn àìṣedéédé wa, kí a di títúnṣe àti sísọdi mímọ́ nínú ẹ̀mí wa, àti ní ọjọ́ kan, kí a di jíjínde àti ki a tún-dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí a fẹ́ràn.

A kọ́ ẹ̀kọ́ nípa bí Ọlọ́run ti fẹ́ràn wa tó. Ó fún wa ni ìyè, Ó sì fẹ́ kí a ṣe àṣeyege. Nítorínáà, Ó pèsè Olùgbàlà kan fún wa. “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀,” Bàba wa ní Ọrun sọ pé, “ìwọ le yàn fún ara rẹ, nítorí a fi fún ọ.”3

Àwọn abala kan ti ìgbìdánwò ayé kíkú yí gbọdọ̀ ti wà tí ó dààmú tàbí ba àwọn ọmọ Ọlọ́run lẹ́rù, níwọnbí iye púpọ̀ ni àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa ti ẹ̀mí tí wọ́n pinnu takò ó.4

Nípa ẹ̀bùn àti agbára yíyàn fún ara ẹni, a pinnu pé ohun tí ó ṣeéṣe kí a le kọ́ àti tí a le dà ní ayérayé yẹ dáradára tó fún ewu náà.5

Àti nítorínáà, ní gbígbẹ́kẹ̀lé àwọn ìlérí àti agbára Ọlọ́run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, a gba ìpènijà náà.

Mo ṣe bẹ́ẹ̀

Ẹ̀yin náà sì ṣe

A gbà láti fi ààbò ipò àkọ́kọ́ wa sílẹ̀ kí a sì wọ inú ìgbìdánwò nlá ara wa ti “ibẹ̀ àti padà wá lẹ́ẹ̀kansíi.”

Ìpè Náà sí Ìgbìdánwò

Àti síbẹ̀, ayé kíkú ní ọ̀nà ti dídààmú wa, àbí kò ní? A máa ngbàgbé ìbéèrè nlá wa, ní fífẹ́ ìtura àti ìrọ̀rùn ju ìdàgbàsókè àti ìtẹ̀síwájú lọ.

Síbẹ̀, ohun kan wà tí kò ṣeé sẹ́, jinlẹ̀ ní ààrin ọkàn wa, tí ó nkébi fún èrò gíga jù àtí tí ó ní ọlá jù. Ebi yìí ni ọ̀kan nínú àwọn ìdí tí àwọn ènìyàn fi fà sí ìhìnrere àti Ìjọ Jésù Krístì. Ìhìnrere tí a múpadàbọ̀ sípò jẹ́, ní èrò kan, ìsọdọ̀tun ipè náà sí ìgbìdánwò tí a gbà ní ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn. Olùgbàlà npè yín, ní ojojúmọ́, láti fi àwọn ìtura àti ààbò yín sí ẹ̀gbẹ́ kan kí ẹ sì darapọ̀ mọ́ Ọ́ nínú ìrìn-àjò jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọ́nà ni ó wà ní ọ̀nà yí. Àwọn òkè, àwọn àfonífojì, àti àwọn ìyànà wà. Àní àfijọ àwọn alántakùn, àwọn abàmì ẹ̀dá, àti dírágónì kan tàbí mejì le wà níbẹ̀ pàápàá. Ṣùgbọ́n bí ẹ bá dúró ní ipa ọ̀nà náà tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, ní ìparí ẹ ó rí ọ̀nà sí àyànmọ́ ológo yín, àti padà sí ilé yín ọ̀run.

Nítorínáà, báwo ni ẹ ó ti bẹ̀rẹ̀?

Ó rọrùn púpọ̀.

Ẹ Tẹ Ọkàn Yín sí Ọlọ́run

Ní àkọ́kọ́, ẹ nílò làti yàn láti tẹ ọkàn yín sí Ọlọ́run. Ẹ tiraka ní ojojúmọ́ láti ṣe àwárí Rẹ̀. Ẹ kọ́ láti fẹ́ràn Rẹ̀ Àti lẹ́hìnnáà ẹ jẹ́kí ìfẹ́ náà ó mí sí yín láti kọ́ ẹ̀kọ́, ní òye, àti lati tẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ àti láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. A fi ìhìnrere Jésù Krístì tí a múpadàbọ̀sípò fún wa ní ọ̀nà tí ó ṣe kedere tí ó sì rọrùn tí ó le yé ọmọdé. Síbẹ̀ ìhìnrere Jésù Krístì ní àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí ó díjú jùlọ nínú ayé, ó sì ní irú ìjìnlẹ̀ ibú àti dídíjú tó bẹ́ẹ̀ tí àní pẹ̀lú àṣàrò àti ìwádìí fún ìgbésí ayé, ó pẹ́ kí a tó ní òye apákan tó kéré jùlọ.

Bí ẹ bá dá ara dúró nínú ìgbìdánwò yí nítorípé ẹ ṣiyèméjì agbára yín, ẹ rántí pé jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn kìí ṣe nípa síṣe àwọn nkan ní pípé; ó jẹ́ síṣe àwọn nkan pẹ̀lú èrò inú. Àwọn yíyàn yín ni ó nfi ohun tí ẹ jẹ́ nítòótọ́ hàn, jìnnà ju àwọn agbára yín lọ.6

Àní nígbàtí ẹ bá kùnà, ẹ le yàn lati máṣe jáwọ́, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ ẹ ṣe àwárí ìgboyà yín, ẹ tẹ̀síwájú, ẹ sì dìde sókè. Èyíinì jẹ́ ìdánwò nlá ti ìrìn-àjò náà.

Ọlọ́run mọ̀ pé ẹ kò pé, pé ẹ ó kùnà ní àwọn àkókò kan. Ọlọ́run fẹ́ràn yín láì dínkù nígbàtí ẹ bá ntiraka jú ìgbà tí ẹ bá borí.

Bíi olùfẹ́ni òbí, Ó kàn fẹ́ kí ẹ máa gbìyànjú pẹ̀lú èrò inú ni. Jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn dàbí kíkọ́ ẹ̀kọ́ láti tẹ dùrù. Bóyá gbogbo ohun tí ẹ le ṣe ní àkọ́kọ́ ni láti tẹ orin tí a fẹ́rẹ̀ má le dámọ̀ bí “àwọn pẹ̀pẹ́ ìjẹun.” Ṣùgbọ́n bí ẹ bá tẹ̀síwájú ní dídánrawò, ohùn orin rírọrùn tí ẹ kò le tẹ̀ jáde báyi yío ṣí ọ̀na ní ọjọ́ kan fún àwọn sónátà, rápúsódì, àti kọnsátò yíyanilẹ́nu.

Nísisìyí, ọjọ́ náà lè má dé ní àkókò ìgbé ayé yìí, ṣùgbọ́n yío dé. Ohun tí Ọlọ́run nbèèrè ni pé kí ẹ máa tiraka pẹ̀lú ìtiraka.

Ẹ Nawọ́ jáde nínú Ìfẹ́ sí àwọn Ẹlòmíràn

Ohun kan wà tí ó dùnmọ́ni, tí ó fẹ́rẹ̀ jọra, nípa ipa ọ̀nà tí ẹ ti yàn yí: ọ̀nà kanṣoṣo fún yín láti tẹ̀síwájú nínú ìgbìdánwò ìhìnrere yín ni láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ tẹ̀síwájú bákannáà.

Láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ni ipa ọ̀nà jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn. Ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́, àánú, àti iṣẹ́ ìsìn máa ntún wa ṣe bíi ọmọlẹ́hìn.

Nípa àwọn aápọn yín láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn aláìní àti tálákà, láti nawọ́ jáde sí àwọn wọnnì nínú ìjìyà, ìwà tiyín ndi sísọ di mímọ́ àti ọ̀tun, ẹ̀mí yín ndi gbígbòrò, ẹ nrìn ní gíga díẹ̀ síi.

Ṣùgbọ́n ìfẹ́ yí kò le wá pẹ̀lú ìrètí sísan padà. Kò le jẹ́ irú iṣẹ́ ìsìn tí ó nretí ìdánimọ̀, ìyìn, tàbí ojú rere.

Àwọn ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì nítòótọ́ fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Rẹ̀ láìsí ìrètí ohunkóhun ní àsanpadà. A fẹ́ràn àwọn wọnnì tí wọ́n já wa kulẹ̀, tí wọn kò fẹ́ràn wa. Àní àwọn tí wọ́n fi wá ṣe ẹlẹ́yà, tí wọ́n bú wa, tí wọ́n sì lépa láti ṣe wá níbi.

Nígbàtí ẹ bá kún ọkàn yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlábàwọ́n ti Krístì, ẹ kì yío fi ààyè sílẹ̀ fún odì, ìdájọ́, àti ìdójútì. Ẹ npa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ nítorípé ẹ fẹ́ràn Rẹ̀. Ní síṣe bẹ́ẹ̀, ẹ nfi díẹ̀díẹ̀ dàbí Krístì síi nínú àwọn èrò àti ìṣe yín.7 Irú ìgbìdánwò wo ni ó sì le tobí ju èyí lọ?

Ṣe Àbápín Ìtàn Rẹ

Ohun kẹta tí a ntiraka láti mọ̀ dáradára nínú ìrìn-àjò yí ni láti gba orúkọ Jésù Krístì sórí ara wa kí a má si tijú jíjẹ́ ọmọ Ìjọ Jésù Krístì.

A kò fi ìgbàgbọ́ wa pamọ́.

A kò bò ó mọ́lẹ̀.

Sí ìlòdì, a nsọ nípa ìrìn-àjò wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ní àwọn ọ̀nà tí ó yẹ àti àdánidá. Èyíinì ni ohun tí àwọn ọ̀rẹ́ nṣe—wọn a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì sí wọn. Àwọn ohun tí ó súnmọ́ ọkàn wọn tí ó sì mú ìyàtọ̀ wá sí wọn.

Èyíinì ni ẹ̀yin ó ṣe. Ẹ sọ àwọn ìtàn àti àwọn ìrírí yín bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ti Ọjọ́-ìkẹhìn.

Nígbà míràn àwọn ìtàn yín nmú àwọn ènìyàn rẹ́rĩn. Nígbà míràn wọn á mú omi wá sí ojú wọn. Nígbà míràn wọn á ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú nínú sùúrù, ìrọ́jú, àti ìgboyà láti kojú wákàtí míràn, ọjọ́ míràn àti ní sísúnmọ́ Ọlọ́run díẹ̀ síi.

Ẹ ṣe àbápín àwọn ìrírí yín bí ènìyàn, lórí ẹ̀rọ ìbákẹ́gbẹ́, nínú àwọn ẹgbẹ́, níbi gbogbo.

Ọ̀kan lára àwọn ohun tí Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́hìn Rẹ̀ ni pé kí wọn ó lọ jákèjádò àgbáyé kí wọn ó sì ṣe àbápín ìtàn Krístì tó jínde.8 Lónìí a fi tayọ̀tayọ̀ gba àṣẹ nlá náà.

Irú ọ̀rọ̀ ológo wo ni a ní láti ṣe àbápín: nítorí ti Jésù Krístì, olukúlùkù ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọde le padà láiléwu sí ilé wọn ọ̀run àti níbẹ̀ kí wọn ó gbé nínú ògo àti òdodo!

Àwọn ìròhìn rere míràn wà síi tí ó yẹ ní bíbápín.

Ọlọ́run ti fi ara hàn sí ènìyàn ní ìgbà tiwa! A ní wòlíì alààyè.

Njẹ́ kí èmi ó rán yín létí pé Ọlọ́run kò nílò yín láti “ta” ìhìnrere tí a mú padàbọ̀ sípò àti Ìjọ Jésù Krístì.

Ó kàn ní ìretí pé ẹ kò ní fi pamọ́ sí abẹ́ ẹrù kan ni.

Àti pé bí àwọn ènìyàn kan bá pinnu pé Ìjọ náà kìí ṣe fún wọn, ìpinnu tiwọn ni èyíinì.

Kò túmọ̀ sí pé ìwọ ti kùnà. Ìwọ tẹ̀síwájú láti máa ṣe dáradára sí wọn. Bẹ́ẹ̀ni kò yọ pé kí ẹ tún pè wọ́n lẹ́ẹ̀kansíi sílẹ̀.

Ìyàtọ̀ láàrin ìbákẹ́gbẹ́ lásán pẹ̀lú àwọn alábàápàdé àti jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn aláàánú, onígboyà ni—ìfipè!

A fẹ́ràn à sì bu ọ̀wọ̀ fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run, láìka ipò wọn nínú ayé sí, láìka ẹ̀yà tàbí ẹ̀sìn wọn sí, láìka àwọn ìpinnu ti ayé wọn sí.

Fún ipa tiwa, àwa ó sọ pé. “Wá wò ó! Ṣe àwárí fún ara rẹ bí rírìn ipa ọ̀nà ti jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn yío ṣe jẹ́ fífúnni ní èrè àti fífúnni ní ọlá.”

A pe àwọn ènìyàn láti “wa ṣe ìrànlọ́wọ́, bí a ti ngbìyànjú láti sọ ayé di ibi tí ó dára síi.”

A sì wípé, “Wá dúró! Àwa ni arákùnrin àti aábìnrin rẹ. A kò pé. A gbẹ̀kẹ̀lé Ọlọ́run a sì nlépa láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́

“Darapọ̀ pẹ̀lú wa, ìwọ yío sì mú wa dára síi. Àti, ní ọ̀nà yí, ìwọ yío dára síi bákanná. Jẹ́kí a jọ ṣe ìgbìdánwò yi papọ̀.”

Nígbàwo ni Kí Èmi ó Bẹ̀rẹ̀

Ngbàtí ọ̀rẹ́ wa Bilbo Baggins ní ìmọ̀lára pé ìpè sí Ìgbìdánwò náà rú nínú rẹ̀, ó pinnu láti ní ìsinmi dáradára ní òru, ó gbádùn oúnjẹ àárọ̀ tọkàn-tọkàn, ó sì bẹ̀rẹ̀ ní àárọ̀ kùtù.

Nígbàtí Bilbò ji, ó kíyèsíi pé ilé òun kò wà létò, ó sì fẹ́rẹ̀ jẹ́ dídààmú kúrò ní èrò rẹ̀ tí ó lọ́lá.

Ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ rẹ̀ Gandalf wá ó sì béèrè, “Nígbàwo ni ìwọ yío wá?”9 Láti dọ́gba pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, Bilbò níláti pinnu kínni síṣe fún ara rẹ̀.

Àti nítorínáà, iwin gãn tí kò yàtọ̀ náà rí ara rẹ̀ ní fífò jáde ní ibi ìlẹ̀kùn àbájáde rẹ̀ sí ipa ọ̀nà ìgbìyànjú ní kíákíá tó bẹ́ẹ̀ tí ó gbàgbé fìlà, ọ̀pá ìtìlẹ̀, àti aṣọ ìnujú rẹ̀. Àní ó fi oúnjẹ àárọ̀ rẹ̀ kejì sílẹ̀ ní àìparí.

Bóyá ẹ̀kọ́ kan wà ní ìhín fúnwa bákannáà.

Bí ẹ̀yin àti èmi bá ti ní ìmọ̀lára àjọṣe láti darapọ̀ mọ́ ìgbìyànjú nlá ti ìgbé ayé àti ṣíṣe àbápín ohun tí olùfẹ́ni Bàbá wa Ọrun ti pèsè fún wa ní ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn, mo fi dáa yín lójú, òní ni ọjọ́ náà láti tẹ̀lé Ọmọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà wa ní ipa ọ̀nà Rẹ̀ ti iṣẹ́ ìsìn àti jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn.

A le lo gbogbo ìgbésí ayé ní dídúró fún àkókò náà nígbàtí ohun gbogbo yío tò lẹ́sẹsẹ ní pípé. Ṣùgbọ́n ìsisìyí ni àkókò náà láti fi ara jì ní kíkún sí wíwá Ọlọ́run, ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn, àti ṣíṣe àbápín àwọn ìrírí wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.

Ẹ fi fìlà, ọ̀pá ìtìlẹ̀, aṣọ ìnujú, àti ilé yín tí kò wà létò sílẹ̀ lẹ́hìn.10

Sí àwa wọnnì tí ó ti nrin ipa ọ̀nà náà, ẹ ní ìgboyà, ẹ lo àánú, ẹ ní ìgbẹkẹ̀lé, kí ẹ sì tẹ̀síwájú!

Sí àwọn wọnnì tí wọ́n ti fi ipa ọ̀nà náà sílẹ̀, ẹ jọ̀wọ́ ẹ padà wá, ẹ darapọ̀ lẹ́ẹ̀kansíi pẹ̀lú wa, ẹ mú wa ní agbára síi.

Àti sí àwọn wọnnì tí wọn kò tíì bẹ̀rẹ̀, kí ló fa ìdádúró? Bí ẹ bá fẹ́ ní ìrírí àwọn ìyanu ti ìrìn-àjò nlá ti ẹ̀mí yi, ẹ fi ẹsẹ̀ lé ìgbìdánwò nlá tìyín! Ẹ bá àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere sọ̀rọ̀. Ẹ bá àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ọ̀rẹ́ yín sọ̀rọ̀. Ẹ bá wọn sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìyanu àti yíyanilẹ́nu yìí.11

Àkokò tó láti bẹ̀rẹ̀!

Ẹ Wá, Ẹ Darapọ̀ pẹ̀lú Wa!

Bí ẹ bá ríi pé ayé yín le ní ìtumọ̀ síi, ó le ní èrèdí gígajù kan, àwọn ìdàpọ̀ ẹbí tí ó le síi, àti sísúnmọ́ síi ní ìṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run; ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá, darapọ̀ pẹ̀lú wa.

Bí ẹ bá nwá àgbájọ àwọn ènìyàn tí wọ́n nṣiṣẹ́ láti dára síi ní ti ara wọn, láti ran àwọn wọnnì nínú àìní lọ́wọ́, àti láti mú kí ayé yí da ibi dídára síi, wá darapọ̀ pẹ̀lú wa!

Wá wo ohun tí ìrìn-àjò ìyanu, yíyanilẹ́nu, àti gbígbìdánwò yìí dá lé lórí.

Ní ojú ọ̀nà náà ẹ ó ṣe àwárí ara yín.

Ẹ ó ṣe àwárí ìtumọ̀.

Ẹ ó ṣe àwárí Ọlọ́run

Ẹ ó ṣe àwárí àwọn ìrìn-àjò ìgbé ayé yín tí ó ní àwọn ìgbìdánwò àti tí ó lógo jùlọ.

Ti èyí ni mo jẹ́rìí ni orúkọ Olùgbàlà Jésù Krístì, àmín.

Àwọn àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. J. R. R. Tolkien, The Hobbit or There and Back Again (Boston: Houghton Mifflin, 2001), 3.

  2. Subtitle of The Hobbit.

  3. Moses 3:17.

  4. Wo Job 38:4–7 (the sons of God shouted for joy); Isaiah 14:12–13 (“exalt my throne above the stars of God”); Revelation 12:7–11 (there was a war in heaven).

  5. “Wòlíì Joseph Smith ṣe àpéjúwe agbára láti yàn bíi ‘òminira ọ̀fẹ́ ti inú náà èyítí ọ̀run ti fi sí ara ẹbí ẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ògo bíi ọ̀kan nínú àwọn àṣàyàn ẹ̀bùn’ [Àwọn ìkọ́ni ti Joseph Smith, comp. Joseph Fielding Smith (1977), 49]. ‘Òmìnira ọ̀fẹ́ ti inú’ yìí, tàbí agbára láti yàn, ni agbára tí ó fi ààyè gba àwọn olúkúlùkù láti jẹ́ ‘aṣojú fún ara wọn’ (D&C 58:28). Ó ṣe àkópọ̀ méjéèjì ti lílo ìfẹ́ láti yàn láàrin ire àti ibi, tàbí síṣe àwọn ìpele ìyàtọ̀ ti ire tábí ibi, àti bákannáà, ànfààní láti ní ìrírí àwọn àyọrísí ti yíyàn náà. Baba Ọrun fẹ́ràn àwọn ọmọ Rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí Ó fẹ́ kí a dé ibi agbára ìleṣe wa ní kíkún—láti dà bí Òun ṣe wà. Láti tẹ̀síwájú, ènìyàn gbọ́dọ̀ ní agbára àtinúwá láti yan èyítí ó fẹ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Agbára láti yàn jẹ́ ìpilẹ̀sẹ̀ sí èrò Rẹ̀ fún àwọn ọmọ Rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ‘àní Ọlọ́run kò le ṣe àwọn ènìyàn bíi ara rẹ̀ láì mú kí wọn ó jẹ́ òmìnira’ [David O. McKay, “Níbo Ni Àwa Ó Lọ? Tàbí Ìpinnu Ìgbé-ayé Ọlọ́lá,” Deseret News, June 8, 1935, 1]” (Byron R. Merrill, “Agency and Freedom in the Divine Plan,” in Roy A. Prete, ed., Window of Faith: Latter-day Saint Perspectives on World History [2005], 162).

  6. Nínú iwé rẹ̀ Harry Potter and the Chamber of Secrets, author J. K. Rowling has Hogwarts headmaster Dumbledore say something quite similar to young Harry Potter. Ó jẹ́ àmọ̀ràn ìyanu sí wá bákannáà. Mo ti lòó nínú àwọn ọ̀rọ̀ mo sì ronú pé ó yẹ ní títúnsọ.

  7. “Olùfẹ́, ọmọ Ọlọ́run ni àwa í ṣe nísisìyí, a kò sì tíì fihàn wá bí àwa ó ti rí: ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé, nígbàtí a bá fihàn, a ó dàbí rẹ̀; nítorí àwa ó rí i bí òun ti rí” (1 Johannu 3:2; àfikún àtẹnumọ́).

    Nígbàtí irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ le jẹ́ títayọ agbára wa láti mọ̀, “Ẹ̀mí tikararẹ̀ ni ó nbá ẹ̀mí wa jẹ́rìí, pé ọmọ Ọlọ́run ni àwa í ṣe:

    “Bí àwa ba sì jẹ́ ọnọ, njẹ́ àjogun ni àwa; ajogún Ọlọ́run, àti àjùmọ̀-jogún pẹ̀lú Krístì; bíóbáṣepé àwa bá a jìyà, kí a sì le ṣe wá lógo pẹ̀lú rẹ̀.

    “Nítorí mo sírò rẹ̀ pé ìyà ìgbà ìsisìyí kò yẹ láti fi ṣe àkàwé ògo tí a ó fihàn nínú wa” (Romu 8:16–18; àfikún àtẹnumọ́).

  8. Wo Matteu 2:1-2.

  9. Tolkien, The Hobbit, 33.

  10. Wo Lúkù 2:22–38.

  11. Wo LeGrand Richards, A Marvelous Work and a Wonder, rev. ed. (1966).