2010–2019
Máṣe Tàn Mí
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Máṣe Tàn Mí

Bí a ṣe ngbọ́ran sí àwọn òfin Rẹ, a ó gba ìdarí nígbàgbogbo sí ọ̀nà totọ́ a kò sì ní gba ẹ̀tàn.

Loni, fi àwọn ọ̀rọ̀ àmọ̀ràn fún gbogbo ènìyàn , ṣùgbọ́n nípàtàkì fún ìran tó ndìde—àwọn ọmọ Alakọbẹrẹ, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin, àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin. Wòlíì fún ọjọ́ wa, Ààrẹ Russell M. Nelson nifẹ wa tọkàntọkàn—tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí o bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa sọ̀rọ̀ nínú ifúnkiri ifọkànsìn pàtàkì ọ̀dọ́ àgbàyè kan ní ọdún tó kọjá tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Irètí ti Isráẹ́lì.”1 Léraléra ni à ngbọ́ tí Ààrẹ Nelson npè yín bẹ́ẹ̀gẹ́gẹ́ pé—“irètí ti Isráẹ̀lì,” iran tó ndìde àti ọjọ́-ọ̀la ti ímúpadàbọ̀sípò Ijọ Jésù Krístì.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi kekere, èmi ó fẹràn láti bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣe àbápìn àwọn ìtàn òtítọ́ méjì.

Ti Ọgọ́ọ̀rún ólé méjì Dalmatian náà

Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hiǹ, mo dé ilé láti ibi iṣẹ́ ó sì bà mí lẹ́rù láti ri tí ọ̀dà fún dà síbi gbogbo—ní ilẹ̀, ilẹ̀kùn ibùdó-ọkọ̀, àti ilé wa oníbíríkì-rẹ́ẹ̀dì. Mo ṣábẹ̀wò ìran náà típẹ́típẹ́ si mo ṣàwárí pé ọ̀dọ̀ náà ṣì tutù, Ipa-ọ̀na ọ̀dà náà darí lọ sí ẹ̀hìnkùlé, nítorínáà mo sì tẹ̀lée. Níbẹ̀, mo rí ọmọdékùnrin mi ọdún marun pẹ̀lú búrọ́ṣì-ọ̀dà ní ọwọ́ rẹ̀, tó nsáré tẹ̀lé aja wa. Labrador wa ẹlẹ́wà dúdu ti gba ọ̀dà funfun sí ìlàjì ara.

Kíni ò nṣe? Mo bèèrè ní ohùn rara kan.

Ọmọdékùnrin mi dawọ́dúró, ó wò mí, ó wo ajá náà, ó wo búrọ́ọ̀ṣì-ìkunlé tí ó kánsílẹ̀ pẹ̀lú ọ̀dà funfun, ó wípé, “mo kan fẹ́ kí Milo dàbí àwọn ajá tó ní àwọ̀ míràn pẹ̀lú dúdú lára wọn tí mo wò nínú eré ni—o mọ, ọ̀kan pẹ̀lú Dalmatians ọgọ́ọ̀rún ólé kan.

Àwòrán
Labrador dúdú
Àwòrán
Dalmatian

Mo nifẹ aja wa. Mo ronú pé ó wà nípípé, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà ọmọdékùnrin mi ní èrò tóyàtọ̀.

Ológbò Kítì Aláìláṣọ

Ìtàn mi ìkejì dálè lórí Grover Ọnkù-nlá, tí ó ngbé nínú ilé kan níta orílẹ̀ èdè náà, tó jìnnà sí ìlú-nlá. Ọnkú Grover ti ndàgbà gan an. A ròó pé ó yẹ kí àwọn ọmọkùnrin wa mọ̀ọ́ kí ó tó kú. Nítorínáà, ní ọ̀sán kan, a wakọ̀ lọ ní ọ̀nà jínjìn sí ilé ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀. A joko papọ̀ láti ṣèbẹ̀wò àti láti fihan àwọn ọmọkùnrin wa. Láìpẹ́ sínú ìbárasọ̀rọ̀, àwọn ọmọdékùnrin wa méjì, bóyá ọmọ ọdún marun tàbí mẹ́fà, nfẹ́ lọ síta láti ṣere

Ọnkù Grover, ní gbígbọ́ ìbèèrè wọn, tẹ ojú rẹ̀ mọ́ tiwọn. Ó jẹ́ ojú híhunjọ gidi tí àwọn ọmọdékùnrin náà kò sì dámọ̀ tí ó nbàwọ́n lẹrù. Ó wí fún wọn pé, ní òun líle, “Ẹ ṣọ́ra—ọ̀pọ̀ ẹranko-rírùn lókùn ita. Gbígbọ́ Èyí, Lesa àti èmi níbẹ̀rù julọ; a nídàmú pé wọ́n lè gba ìkunni nípasẹ̀ ẹranko-rírùn kan! Àwọn ọmọdékùnrin náà lọ ṣeré níta láìpẹ́ bí a ṣe tẹ̀síwájú nínú ìbẹ̀wò.

Àwòrán
Ẹranko-rírùn

Lẹ́hìnnáà, nígbàtí a wọnú ọkọ̀ láti lọ sílé, mo bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọdékùnrin, “Ṣé ẹ rí eranko-rírùn?” Ọkàn lárá wọn dáhù, “Rárá, a ko rí ẹranko-rírùn kankan, ṣùgbọ́n a rí ajá kítì dúdú kan pẹ̀lú ìlà funfun ní ẹ̀hìn rẹ̀!”

Ẹlẹ́tàn Nlá

Àwọn ìtàn wọ̀nyí nípa àwọn ọmọdé aláìmọ̀kan ní wíwárí ohunkan nípa ìgbé ayé àti òdodo lè mú ẹnìkọ̀ọ̀kan wa rẹrin, ṣùgbọ́n bákannáà wọ́n njúwe ìrò tó jinlẹ̀ si,

Nínú ìtàn àkọ́kọ́, ọmọdékùnrin wa kékéré ní ajá tó rẹwà bí ohun ọ̀sìn; láìkasí, ó mú agolo ọ̀dà àti, pẹ̀lú búrọ́ṣìọ̀dọ̀ ní ọwọ́, ó pinnu láti dá ìrònú òdodo ti ararẹ̀ sílẹ̀.

Nínú àkọsílẹ̀ kejì, àwọn ọmọdékùnrin fi aláfíà ṣe àìnífura ìdẹ́rùbà tó ṣeéṣe kí wọ́n dojúkọ látọ̀dọ̀ ẹranko-rírùn kan. Láìlè ṣe àlàyé ohun tí wọ́n kojú dáadáa, wọ́n ní ewu ti jíjìyà àwọn àbájáde tó burú. Àwọn ìtàn wọ̀nyí jẹ́ àṣìṣe ìdánimọ̀—ríro ohunkan láti jẹ́ ohun míràn, Ní ọ̀ràn kọ̀ọkàn, àwọn àbájáde kéré.

Bákannáà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ loni nfi agbàra di àwọn ohun wọ̀nyí kannáà ní ìwọ̀n títóbijùlọ. Bóyá wọn kò rí àwọn ohunkan bí wọ́n ṣe wà tàbí jẹ́ aláìní-ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú òtítọ́. Jùbẹ́ẹ̀ lọ, àwọn agbára kan wà níta loni tí wọ́n ṣe láti mọ̀ọ́mọ̀ darí wa kúrò nínú òtítọ́ pátápátá. Àwọn ẹ̀tàn wọ̀nyí àti irọ́ kọjá àṣìṣe àìmọ̀ ìdámọ̀ àti tí ó ní àwọn àbájáde nlá, kíì ṣe kékeré nígbàkugbà.

Sátánì, babá àwọn irọ́ àti ẹlẹ̀tán nlá, yíò mú wa bèèrè àwọn ohun bí wọ́n ṣe wà lódodo àti bóyá ìpatì àwọn òtítọ́ ayérayé tàbí yí wọn padà sí ohunkan sínú ohunkan tó dàbí ó nwuni síi. “Ó njagun pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run”1 ó sì ti lo mìllẹ́níà ní ṣíṣírò àti ṣíṣe agbára láti rọ gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run tó gbàgbọ́ pé ire ni ibi àti pé ibi ni ire.

Ó ti ṣe òkìkí fúnrarẹ̀ nìpa yíyí ẹlẹ́ran ara lọ́kànpada pé ẹrànkò-rírùn kàn jẹ́ kítìn ni tàbí pé, pẹ̀lú lílo ọ̀dà, ẹ lè yí ajá Labrador padà sí Dalmatia tó lámì!

Àwòrán
Mósè rí Ọlọ́run lójúkojú

Ẹ jẹ́ kí a yípadà báyìí sí àpẹrẹ ti ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ yí gan an tí a rí nínú àwọn ìwé mímọ́, nígbàtí àwọn wòlíì Olúwa wá fojúkojú pẹ̀lú irú ọ̀ràn kannáà. “A gbé Mósè lọ sí òkè gíga jùlọ̀[;] ... ó rí Ọlọ́run lójukojú, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”1 Ọlọ́run kọ́ Mósè nípa ìdánimọ̀ ayérayé. Bíótilẹ̀jẹ́pé Mósè jẹ́ ẹlẹ́ran ara àti àìpé, Ọlọ́run kọ́ni pé Mósè wà “ní ẹ̀yà ti Ọmọ Bíbí mi Nìkanṣoṣo: Ọmọ Bíbí mi Nìkanṣoṣo ... tí yíò jẹ́ Olùgbàlà.”3

Mósè, nínú ìran oníyanu yí, wo Ọlọ́run, bákannáà ó sì kọ́ ohun pàtàkì kan nípa ararẹ̀: bíótilẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́ran ara ni, o jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.

Fetísílẹ̀ dáadáa sí ohun tó ṣẹlẹ̀ bí ìran oníyanu náà ṣe parí. “Ó sì ṣe tí … Sátánì wá dàn wò,” ó wípé, “Mósè, ọmọ ènìyàn, jọ́sìn fún mi!”4 Mósè fi tìgboyàtìgboyà fèsì: “Tani ọ́? Nítorí kíyèsíi, èmi jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, nínú àwòrán ti Ọmọ Bíbí rẹ̀ Nìkan; níbo ni ògo rẹ, tí èmi ó fi sìn ọ́?”5

Ní ọ̀rọ̀ míràn, Mósè wípé, “Ìwọ kò lè tàn mí, nítorí mo mọ ẹni tí mo jẹ́. A dá mi ní Àwòrán Ọlọ́run. Ìwọ kò ní ìmọ́lẹ̀ àti ògo Rẹ̀. Nítorínáà kíni ìdí tí èmi ó fi sìn ọ́ tàbí ṣubú sí ẹ̀tàn rẹ?”

Báyìí ẹ fetísílẹ̀ sí bí Mósè ṣe fèsì síwájú si. Ó kéde, “Padà lẹ́hìn mi, Sátánì; máṣe tàn mí.6

Ọ̀pọ̀ wà tí a lè kọ́ látinú ìfèsì alágbara Mósè sí àdánwò ọ̀tá. Mo pè yín láti fèsì lọ́nà kannáà nígbàtí ẹ bá ní ìmọ̀lára agbára nípasẹ̀ àdánwò. Pàṣẹ fún ọ̀tá ẹ̀mí rẹ̀ nípa wíwí pé, “Lọ kúrò! Ìwọ kò ní ògo kankan. Máṣe dán mi wò tàbí parọ́ fún mi! Nítorí mo mọ̀ ẹni tí mo jẹ́ ọmọ Ọlọ́run kan. Èmi ó sì máa képe Ọlọ́run mi fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀.”

Ọ̀tá, bákannáà, kìí fìrọ̀rùn pa ète ìparun rẹ̀ láti tanni àti láti múwa relẹ̀ ti. Dájúdájú ko ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Mósè, dípò bẹ́ẹ̀ ó nfẹ́ mu kí Mosè gbàgbé ẹni tí ó jẹ́ ní ayérayé.

Bíì ipé ó nju ìrunú ọmọdé kan, “Sátánì kígbe pẹ̀lú ohùn rara, ó rábàbà lórí ilẹ̀, ó pàṣẹ, ó wípé: Èmi ni Ọmọ Bíbí Nìkanṣoṣo, sìn mí.”7

Ẹ jẹ́ kí a tunṣe. Ṣe ẹ gbọ́ ohun tí Sátánì ṣẹ̀ sọ? Èmi ni Ọmọ Bíbí Nìkanṣoṣo. Sìn !”

Ẹlẹ́tàn nla náà wípé, ní àbádé, “Ẹ máṣe dààmú; èmi kò ní pa ọ́ lára—èmi kìí ṣe ẹranko-rírùn; èmi kàn jẹ́ ológbò kítì àìláṣọ aláìmọ̀kan dúdú-àti-funfun kan ni.”

Àwòrán
Mósè ju Sátánì síta

Nígbànáà Mósè képe Ọlọ́run ó sì gba okún àtọ̀runwá Rẹ̀. Àní bíótilẹ̀jẹ́pé ọ̀tá gbọ̀n ó sì mi ilẹ̀, Mósè kò gbà. Ohùn rẹ̀ hàn kedere ó sì dájú. “Padà lẹ́hìn mi, Sátánì,” ó kéde, “nítorí Ọlọ́run kan nìkan ní èmi ó sìn, èyí tí ó jẹ́ Ọlọ́run ògo.”8

Nígbẹ̀hìn, ó “kúrò … ní iwájú Mósè.”9

Lẹ́hìnnáà Olúwa farahàn Ó sì bùkún Mósè fún ìgbọ́ran Rẹ̀, Olúwa wípé:

“Alábùkún ni ìwọ, Mósè, nítorí ... a ó mú ọ lágbára ju ọ̀pọ̀ omi. ...

“Àti pé, Èmi wà pẹ̀lú rẹ̀, àní di opin ayé rẹ.”10

Kíkọ̀ ọ̀tá Mosè ni kòrókòró apẹrẹ ìfúnni-lóye fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, bíótiwù kí ìgbéga wa nínú ayé tó. Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ alágbára fún ara yín gàn an—láti mọ ohun tí ẹ ó ṣe nígbàtí Sátánì bá tiraka láti tàn yín. Fún yín, bíiti Mósè, jẹ́ alábùkún pẹ̀lú ẹ̀bùn ti ìrànlọ́wọ́ tọ̀run.

Àwọn òfin àti Ìbùkún

Báwo ni ẹ ṣe lè rí ìrànlọ́wọ́ tọ̀run, àní bí Mósè ti ṣe, tí ẹ kòní gba ẹ̀tàn tàbi fàyèsílẹ̀ fún àdánwò? Ọ̀nà kedere kan fún ìrànlọ́wọ́ ni láti tunsọ ní àkokò yí nípasẹ̀ Olúwa Fúnrarẹ̀ nígbàtí Ó kéde: “Nítorínáà, Èmi Olúwa, mọ àjálù èyí tí yíò wá sórí olùgbé ayé, mo sì pe ìránṣẹ́ mi Joseph Smith, Kékeré, mo sì sọ fun látọ̀run, mo sì fun ní àwọn òfin.”11 Lílo àwọn ọ̀rọ̀ tó rọrùn, a lè sọ pé Olúwa, ẹnití ó ọ “òpin láti ìbẹ̀rẹ̀,”12 mọ àwọn ìṣòro tó tayọ ní ọjọ́ wa.. Nítorínáà, Ó ti pèsè ọ̀nà kan láti kọ àwọn ìpènijà àti àdánwò, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èyí tí ó nwá bí èsì tààrà ti àwọn agbára ẹ̀tàn ọ̀tá àti àwọn ìkọlù rẹ̀.

Ọ̀nà náà rọrùn. Nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ Rẹ̀, Ọlọ́run nbá wa sọ̀rọ̀, àwa ọmọ Rẹ̀, Ó sì nfún wa ní àwọn òfin. A kò lè tún àwọn ẹsẹ wọnnì tí mo ṣe àyọsọ rẹ̀ sọ tí ó wípé, “Èmi Olúwa, ... képe ìránṣẹ́ mi [Ààrẹ Russell M. Nelson], Ó sì ba sọ̀rọ̀ látọ̀run, Ó sì fun ní àwọn òfin.” Èyí kìí ha ṣe òtítọ́ ológo bí?

Mo jẹ́ ẹ̀rí ọ̀wọ̀ mi pé Olúwa nínú òdodo bá Joseph Smith sọ̀rọ̀ látọ̀run, ní bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ìràn Àkọ́kọ́ nlá. Bákannáà Ó nsọ̀rọ̀ sí Ààrẹ Nelson ní ìgbà wa. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn wòlíì àtijọ́ Ó sì fún wọn ní àwọn òfin ṣíṣe láti darí àwọn ọmọ Rẹ̀ sí ìdùnnnú nínú ayé yí àti ògo nínú èyí tó nbọ̀.

Ọlọ́run ntẹ̀síwájú láti fún wòlíì alààyè wa loni ní òfin. Àwọn àpẹrẹ wà—gbùngbun-ilé kan síi, àtìlẹhìn-Ìjọ nmú àṣẹ ìhìnrere wá sí ìbámu; ìrọ́pò ti ìbẹ̀wò àti ìkọ́ni ilé pẹ̀lú ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́; àwọn àtúnṣe sí ṣíṣe àwọn àkóso àti ìlànà tẹ́mpìlì; àti ètò titun àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́.. Mo níyanu ní inúrere àti àánú ti olùfẹ́ni Bàbá Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ẹnití ó mú ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Rẹ̀ sí ayé lẹ́ẹ̀kansi tí ó sì pe wòlíì kan lọ́jọ́ wa. Ìmúpadàbọ̀sípò ti ìhìnrere Jésù Krístì ti mú ìgbà ewu kúrò pẹlú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ìgbà.

Ìwà-búburú Kìí Ṣe Ìdùnnú Rárá

Ìgbọ́ran sí àwọn òfin tí a fún wòlíì wa jẹ́ kọ́kọ́rọ́ kìí ṣe láti yẹra fún agbára àti ẹ̀tàn ọ̀tá nìkan ṣùgbọ́n bákannáà ní níní ìrírí ayọ̀ pípẹ́ àti ìdùnnú. Ìlàsílẹ̀ tọ̀run yí ṣì jẹ́ ìrọ̀rùn: òdodo, tàbí ìgbọràn sí àwọn òfin, nmú àwọn ìbùkún wa, àti pé àwọn ìbùkún nmú ìdùnnú wá, tàbí ayọ̀, sínú ayé wa.

Bákannáà, ní ọ̀nà kannáà ọ̀tá ntiraka láti tan Mósè, ó nwá láti tàn yín. Ó máa ndíbọ́n láti jẹ́ ohun tí kò jẹ́ nígbàgbogbo. Ó ngbìdánwò nígbàgbogbo láti fi ẹni tí ó jẹ́ nítòótọ́ pamọ́. Ó gbà pé ìgbọràn yíò mú ìgbé ayé yín korò àti pé yíò gba ìdùnnú yín kúrò.

Ṣe ẹ lè ronú nípa àwọn ètè rẹ̀ láti tanni? Fún àpẹrẹ, ó ndojú ewu tí àbájáde egbòogi olóró tàbí ìmutín nmúwa délẹ̀ àti dípò bẹ́ẹ̀ ó ndaba pé yíò mú ìdùnmọ́ni wá. Òun nrì wá sínú onírurú àwọn ohun ibi tí ó lè wà nínú ìbánikẹ́gbẹ́ ìròhìn, pẹ̀lú àfiwé bíbàjẹ́ àti lílérò òdodo. Ní àfikún, òun nbojú ohun òkùnkùn míràn, ohun ìpanilára tí a ri lórí ayélujára, bí irú ponográfì, ìkolù nlá lórí àwọn ẹlòmíràn nípa ìrẹ́nijẹ-kọ̀mpútà, àti gbígbin ìwífúnniàìtọ́ láti fa iyèméjì àti ẹ̀rù sínú ọkàn àti inú wa. Ó fi àrékérekè kùn pé, “Kàn tẹ̀lé mi, ìwọ ó sì nídùnnú dájúdájú.”

Àwọn ọ̀rọ̀ tí a kọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ cẹ́ntúrì sẹ́hìn nípasẹ̀ wòlíì Ìwé Mọ́mọ́nì ṣe kókó pàtàkì fún ọjọ́ wa: “Ìwa-búburú kìí ṣe ìdùnnú rárá.”15 A lè dá àwọn ẹ̀tàn Sátánì mọ̀ fún ohun tí wọ́n jẹ́. Njẹ́ kí a takò kí a sì rí àwọn irọ́ àti agbára ẹnìkan tí ó nfẹ́ láti pa àwọn ẹ̀mí wa run àti láti jà wá lólè ayọ̀ ìsisìyí wa àti ògo ọjọ́-ọ̀la.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, a gbọ́dọ̀ tẹ̀síwájú nínú òdodo àti ìṣọ́ra, nítorí bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà kanṣoṣo láti lóye òtítọ́ àti láti gbọ́ ohún Olúwa nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. “Nítorí Ẹ̀mí nsọ̀rọ̀ òtítọ́ kò sì parọ́. .. nítorí-èyi, a fi àwọn nkan wọ̀nyí hàn wá ní kedere, fún ìgbàlà ọkàn wa. Nítorítí Ọlọ́run bákannáà sọ wọ́n fún àwọn wòlĩ àtijọ́.”14 Àwa ni àwọn Ènìyàn Mímọ́ ti Ọlọ́run Elédùmarè, ìrètí Ísráẹ́lì! Ṣé a ó Ṣàṣìṣe? “Ṣe a ó lọ́ra tàbí kọ ìjà náà? Rárá! ... Sí àṣẹ Ọlọ́run , ẹ̀mí, ọkàn, àti ọwọ́, òdodo àti òtítọ́ ni a ó dúró títíláé.”16

Mo jẹ́ ẹ̀rí mi pàtàkì nípa Ẹni Mímọ́ Ísráẹ́lìàní Jésù Krístì. Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa ìfẹ́ ìbánigbé Rẹ̀, òtítọ́, àti ìdùnnú tí ó ṣeéṣe nípasẹ̀ ìrúbọ ayérayé àti àìlópin Rẹ̀. Bí a ṣe ngbọ́ran sí àwọn òfin Rẹ, a ó gba ìdarí nígbàgbogbo sí ọ̀nà totọ́ a kò sì ní gba ẹ̀tàn. Ní orúkọ mímọ́ ti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, àmín