2010–2019
Ìwà Mímọ́ àti Ètò Ìdùnnú
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Ìwà Mímọ́ àti Ètò Ìdùnnú

Ìdùnnú títóbijùlọ nwá látinú ìwàmímọ́ araẹni títóbijùlọ.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, Mo ti gbàdúrà fún agbára láti rànyínlọ́wọ́ nípa wíwá ti araẹni fún ìdùnnú. Àwọn kàn le ti ni ìmọ̀lára ìdùnnú tí ó tó, síbẹ̀ nítòótọ́ kò sí ẹnìkan ti o le kọ ìfúnni ní ìdùnnú púpọ̀ síi. Ẹnikẹ́ni máa ní ìtara láti tẹ́wọ́gba ìfúnni tó ni ẹ̀rí ti ìdùnnú pípẹ́.

Ìyẹn ni ohun ti Bàbá Ọ̀run; Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì; àti Ẹ̀mí Mímọ́ ti fifún gbogbo ọmọ ẹ̀mí Bàbá Ọ̀run ti o wa láàyè nísinsìyí, tí yìó wa, tàbí tí o tí wa láàyè nínu ayé yi. Ìfúnni yẹ̀n ni a má npè ní ètò ìdùnnú nígbàmíràn. A pèé bayi nípasẹ̀ wòlíì Álmà bí o ṣe kọ àwọn ọmọ rẹ̀, ẹni ti o ti wọ ẹrẹ̀ òṣì ẹ̀ṣẹ̀. Álmà mọ̀ wípé ìwà búburú kò lè jẹ ìdùnnú fún ọmọkùnrin rẹ̀—tàbí fún èyíkeyi ọmọ Bàbá Ọ̀run.1

Ó kọ́ ọmọkùnrin rẹ̀ wípé pípọ̀si ni ìwà mímọ́ ni ọ̀nà kan ṣoṣo si ìdùnnú. Ó jẹ́ kí o hàn gbangba wípé ìwàmímọ́ nlá ṣeéṣe nípa ìwẹnùmọ́ àti ṣíṣe wa ní pípé ti Ètùtù Jésù Krístì.2 Nípa ìgbàgbọ nínú Jésù Krístì, ìtẹ̀síwájú ìrònúpìwàdà, àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ ni a fi le gba ìdùnnú pípẹ́ ti a npongbẹ láti ní ìrírí àti láti mú dúró.

Àdúrà mi fún òní ni wípé kí nlè ràn yín lọ́wọ́ láti lóye wípé ìdùnnu nlá nwá látinú ìwàmímọ́ jùlọ nítorí kí ẹ le ṣe ìṣe lórí ìgbàgbọ́ náà. Nígbànáà emi yíò ṣe àbápín ohun tí mo mọ̀ fúnra mi nípa ohun tí a lè ṣe láti di yege fún ẹ̀bùn láti di mímọ́ títíláé.

Àwọn ìwé mímọ́ kọ wa pé láàrín àwọn ohun míràn,a lè di yíyà sí mímọ́ tàbí di mímọ́ síi nígbàtí a bá lo ìgbàgbọ́ nínú Krístì,3 fi ìgbọ́nran wa hàn,4 ìronúpìwàdà,5 yọ̀ọ̀da fún Un,6 gba àwọn ìlànà mímọ́, kí a sì pa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ pẹ̀lú Rẹ̀.7 Yíyege fún ẹ̀bùn ìwàmímọ́ nílò ìwà ìrẹ̀lẹ̀,8 ìwà tútù,9 àti sùúrù.10

Ìrírí kan nípa fífẹ́ ìwàmímọ́ síi wá fún mi ni Tẹ́mpìlì Salt Lake. Mo wọ inú tẹ́mpìlì fún ìgbà àkọ́kọ́ nígbà tí a ti sọ díẹ̀ nípa ohun kekeré tí mo nretí. Mo ti rí àwọn ọ̀rọ̀ lòrì ilé: “Ìwàmímọ́ sí Ọlọ́run” àti “Ilé Olúwa.” Mo ní ìmọ̀lára ìrònu nlá ti ìfojúsọ̀nà. Síbẹ̀ ó yàmílẹ́nu tí mo bá ti múrasílẹ̀ láti wọlé.

Ìyá àti bàbá mi rín síwájú mi bí a ti wọ tẹ́mpìlì. Wọn ní kí á fi àwọn ìdánimọ̀ wa hàn, tí ó tọ́ka íyege wa.

Àwọn òbí mì mọ ọkùnrin tí ó wa ní tábìlì ìdánimọ̀. Nítorínáà wọ́n lọ́ra láti báa sọ̀rọ̀. Mo dá lọ ṣíwájú sínú ààyè nlá níbi tí gbogbo ǹkan ti funfun ringindin. Mo wòkè gíga gidi lórí mi ó dàbí òfúrufú tí a ṣí. Ní ìṣẹ́jú náà, àtẹ̀mọ́ kan wá sími wípé Mo ti wá síbẹ rí.

Ṣùgbọ́n lẹ́hìnnáà, mo gbọ́ ohun kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan gidi—kìí ṣe ti arami. Àwọn ọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́ tí a sọ nìwọ̀nyí: “O kòì ti wa síbí tẹ́lẹ̀ rí. Ò nrántí ìṣẹ́jú kan ṣíwájú kí wọ́n tó bi ọ. O wà ní ibi mímọ́ bi ti èyí. O ni ìmọ̀lára bi ẹni pé Olùgbàlà fẹ́ wá sí ibi tí o dúró si. O sì ní ìmọ̀lára ìdùnnú nítorí o nítara láti rí I.”

Ìrírí ní Tẹ́mpìlì Salt Lake yẹn wà fún ìgbà díẹ. Síbẹ̀ ìrántí rẹ ṣì nmú àlááfíà, ayọ̀, àti ìdùnnú ìdákẹ́rọ́rọ́ wá .

Mo kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ lọ́jọ́ náà. Ẹ̀mí Mímọ́ má nsọ̀rọ̀ ni ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, kékeré kan. Mo lè gbọ́ Ọ nígbàtí àlááfíà ti ẹ̀mí bá wà ní ọkàn mi. Ó mú ìmọ̀lára ìdùnnú àti ìdánilójú wípé mò di mímọ́ síi wá. Àti wípé ìyẹn nmú ìdùnnú wá nígbàgbogbo ti mo ní ìmọ̀lára rẹ̀ ní àwọn àkókò àkọ́kọ́ wọnnì nínú tẹ́mpìlì Ọlọ́run kan.

Ẹ ti ṣe àkíyèsí iṣẹ́ ìyanu ìdùnnú ti o nwa látinú ìwàmímọ́ tó ndàgbà nínú ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíràn, dídàbíi Olùgbàlà síi. Ní àwọn ọ̀sẹ̀ tó kojá, mo ti wà ní ẹ̀gbẹ́ ibùsùn àwọn ènìyàn tí ó lè dojúkọ ikú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ kíkún nínú Olùgbàlà àti àwọn ìwò ìdùnnú.

Ọ̀kan ni ọkùnrin tí àwọn ẹbí rẹ̀ yíká. Òun àti ìyàwó rẹ̀ nsọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ bí èmi àti ọmọ mi ọkùnrin ṣe wọlé. Mo ti mọ̀ wọ́n fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Mo ti ri tí Ètùtù Jésù Krístì ṣiṣẹ́ nínú ayé wọn àti nínú ayé àwọn ẹbí wọn.

Wọ́n ti yàn papọ̀ láti fòpin sí àwọn ìtiraka òògùn làti mú ẹ̀mí rẹ gùn. Ìdákẹ́rọ́rọ́ ìmọ̀lára wà bí ó ti nbá wa sọ̀rọ̀. Ó rẹ́rin bí ó ti fi ìmoore hàn fún ìhìnrere àti àwọn ipa ìyàsímímọ́ rẹ lórí òun àti ẹbí tí ó nifẹ sí. Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọdún ìdùnnú ìsìn rẹ̀ ní tẹ́mpìlì. Lórí ìbéèrè ọkùnrin yi, ọmọ mi ọkùnrin da òróró tí a yà sí mímọ́ si ní orí. Mo fi èdìdí di ìfàmì òròró yàn náà. Bí mo ti ṣe èyí, mo ní ìtẹ̀mọ́ra kedere wípé yìó rí Olùgbàlà rẹ̀, ní ojú-kojú.

Mo ṣèlérí fún un wípé yìó ni ìmọ̀lára ìdùnnú, ìfẹ, àti ìfọwọ́sí Olùgbàlà. Ó rẹrin músẹ́ bí a ti nlọ. Àwọn ọ̀rọ̀ ìparí rẹ̀ sí mi ni “Sọ fún Kathy pé Mo nifẹ rẹ.” Ìyàwó mi, Kathleen, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ti gbà àwọn ìran ẹbí rẹ̀ níyànjú láti gba ipè Olùgbàlà láti wa sọ́dọ̀ Rẹ, kí wọ́n ṣe àti kí wọ́n pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́, kí a si yege fún ìdùnnú ti o nwá bí àbájáde ti ìwàmímọ́ títóbijùlọ.

Ó kú ni wákàtí díẹ̀ lẹ́hìnnáà. Láarín àwọn ọ̀sẹ̀ ìkọjá rẹ, opó rẹ mú ẹ̀bùn kan wá fún èmi àti ìyàwó mi. Ó rẹrin músẹ́ bí a ti nsọ̀rọ̀. Ó sọ tayọ̀tayọ̀, “Mo ni èrò wípé èmi ó ní ìmọ̀lára ìbànújẹ́ àti àdáwà. Mo ní ìmọ̀lára ìdùnnú. Ṣé ẹ ro wípé ìyẹn dára?”

Mímọ bí o ti nifẹ ọkọ rẹ̀ tó àti bí àwọn méjèèjì ti wá mọ, ní ìfẹ, àti sísin Olúwa, mo wí fun pé ìmọ̀lára ìdùnnú rẹ jẹ́ ẹ̀bùn ìlérí ti ó ní, nípa iṣẹ́ ìsìn òtítọ́ rẹ, tí ó di mímọ́ síi. Ìwà mímọ́ rẹ ti mu yege fún ìdùnnu náà.

Àwọn tí wọ́n nfetísílẹ̀ lóní lè níyanu pé: “Kílódé tí èmi kò ní ìmọ̀lára àlááfíà àti ìdùnnu tí a ṣe ìlérí rẹ̀ fún àwọn tí o n ṣe òtítọ́? Mo ti jẹ́ olótitọ́ nínú ìpọ́njú búburú, ṣùgbọ́n nkò ní ìmọ̀lára ìdùnnú.”

Wòlíì Joseph Smith pàápàá dojúkọ àdánwo yi. Ó gbàdúra fún ìrànlọ́wọ́ nígbàtí o wà ní ìhámọ́ túbú ní Liberty, Missouri. Ó ti jẹ́ olótitọ́ sí Olúwa. Ó ti dàgbà nínú ìwàmímọ́. Síbẹ̀ o ní ìmọ̀lára wípé a ti sẹ́ẹ ní ìdùnnu.

Olúwa kọ ni ẹ̀kọ́ sùúrù tí gbogbo wa yìó nílò ní àwọn àkókò kan, àti bóyá fún àwọn ìgbà pípẹ́, ní ìdánwò ayé ikú wa. Èyí ni ìfiránṣẹ́ Olúwa sí àwọn olótitọ ati wòlíì Rẹ̀ tí ó njìyà:

“Àti pé tí wọ́n bá jù ọ́ sí kòtò, tàbí sí ọwọ́ àwọn apànìyàn, tí a sì ṣe ìdájọ́ ikú fún ọ; tí a sì jù ọ́ sínú ibú; bí èèyà bá gbáradì sí ọ; tí afẹ́fẹ́ líle bá di ọ̀tá rẹ; tí ọ̀run bá pe àwọ̀ dúdú, pẹ̀lú iná àti omi kórajọpọ̀ làti ṣe ọ̀nà; àti pé ju gbogbo rẹ̀ lọ, tí ọ̀run àpáàdì bá la ẹnu rẹ̀ sí ọ, mọ̀, ọmọ mi, pé àwọn nkan wọ̀nyí yíò fún ọ ní ìrírí, àti fún dídára rẹ.

“Ọmọ Ènìyàn ti sọ̀kalẹ̀ kọjá gbogbo wọn. Ṣé ìwọ tóbi jùú lọ?

“Nítorínáà, di ọ̀nà rẹ mú, àti pé oyèàlúfà yíò wà pẹ̀lú rẹ; nítorí a ti ṣètò àlà wọn, wọn kò lè kọjá. A mọ àwọn ọjọ́ rẹ, àti wípé a kì yíò dín ọjọ́ rẹ kù; nítorínáà, máṣe bẹ̀rù ohun tí ènìyàn lè ṣe, nítorí Ọlọ́run yíò wà pẹ̀lú rẹ láé àti láéláé.”11

Ìyẹn jẹ́ ẹ̀kọ́ kannáà tí Olúwa fún Jóbù, ẹni ti ó san iye ti o tóbi láti gba Ètùtù láàyè láti mu ki o di mímọ́ síi A mọ̀ wípé Jóbù jẹ́ mímọ́, nípa ìfimọ̀ tí a ní nípa rẹ: “Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Úsì, orúkọ ẹnití íjẹ́ Jóbù; ọkùnrin na si jẹ olótítọ́ àti olùdúróṣinṣin, ẹnití o sì bẹ̀rù Ọlọ́run, tí o sì kórira ìwà búburú.”12

Nígbànáà Jóbù pàdánù ọrọ̀ rẹ̀, ẹbí rẹ, àní ati ìlera rẹ . E lè rántí wípé Jóbù ṣiyèméjì wípé ìwà mímọ́ gíga rẹ̀, tí o jèrè nípa ìpọ́njú gíga, ti mu yege fún ìdùnnú gíga. Fún Jóbù o dàbí ẹni wípé ìwà mímọ́ náà ti mú ìpọ́njú wa.

Síbẹ̀ Olúwa fún Jóbù ni ẹ̀kọ́ àtúnṣe kan náà ti Ó fun Joseph Smith. Ó jẹ́ kí Jóbù wo ipò ìbànújẹ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ojú ìgbàgbọ́. Ó wípé:

“Di àmùrè rẹ bí ọkùnrin; nítorí èmi yíò bèrè lọ́wọ́ rẹ, ìwọ sì dámi lóhùn.

“Níbo ni ìwọ́ wà nígbàtí mo fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀? sọ, bí ìwọ bá ní òye.

Ta ni ó fi àwọn ìdí rẹ̀ lélẹ̀, bí ìwọ bá mọ̀? Tàbi tani ó fa ìlà sí oríi rẹ̀?

“Níbo ni a fi àwọn ìpìnlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ si? Tàbí tani o fi òkúta igun ilé náà lélẹ̀;

“Nígbà tí ìràwọ̀ òwúrọ̀ nkọrin papọ̀, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run pariwo fún ayọ̀?”13

Nígbànáà, lẹ́yìn tí Jóbù jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ pípe Ọlọ́run ní àìṣedédé, a gba Jóbù láàyè láti rí àwọn ìdánwo ni ọ̀nà gíga àti mímọ́ síi. Ó ti ronúpìwàdà.

“Nígbànáà Jóbù dá Olúwa lóhun, wípé,

“Èmi mọ̀ pé ìwọ́ lè ṣe ohun gbogbo, àti pé kò sí èrò tí a lè fàsẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

“Tani ẹnití nfi àmọ̀ràn pamọ́ láìní ìmọ̀? Nítorínâ ni èmi ṣe kí nsọ èyí tí èmi kò mọ̀; àwọn ohun tí o ṣe ìyanu jọjọ níwájú mi, tí èmi kò mọ̀.

Èmí bẹ̀ ọ́, gbọ́, èmi ó sì wípé: èmi ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ, kí ìwọ kí o sì wí fún mí.

“Èmí ti fi gbígbọ́ etí gburo rẹ: ṣùgbọ́n nísisìyí ojú mi ti rí ọ.

“Njẹ́ nítorínà èmi korira ara mí, mo sì ronúpìwàdà ṣe nínú èkuru àti eérú.”14

Lẹ́yìn tí Jóbù ronúpìwàdà tí ó sì di mímọ́ síi, Olúwa bùkun rẹ̀ ju gbogbo ohun tí ó ti pàdánù. Ṣùgbọ́n bóyá ìbùkún tí ó tóbi jùlọ fún Jóbù ni kí ìwà mímọ́ rẹ̀ pọ̀si nínú ìpọ́njú àti ìrònúpìwàdà. Ó di ẹni yíyege láti ní ìdùnnú gíga ní àwọn ọjọ́ tí kòì tíì gbé.

Ìwàmímọ́ gígajùlọ kò lè dédé wá nípa bíbèèrè fun. Yíò wá nípa ṣíṣe ohun tí a nílò fún Ọlọ́run láti yíwa padà.

Ààrẹ Russell M. Nelson ti fún wa ni ohun ti o dabí ìmọ̀ràn dídárajùlọ sími nípa rírìn ní ọ̀nà májẹ̀mú sí ìwàmímọ́ gígajùlọ. Ó nawọ́ sí ọ̀nà ígbàtí o rọ̀ni pé:

Ẹ ní ìrírí agbára ìfúnnilókun ti ìrònúpìwàdà ojoojúmọ́—ti ṣíṣe àti jíjẹ́ dídára si díẹ̀díẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan.

Nígbàtí a bá yàn láti ronúpìwàdà, a lè yàn láti yípadà! A nfàyè gba Olùgbàlà láti yí wa padà sínú ẹ̀yà arawa tó dárajùlọ. A yàn láti dàgbà níti ẹ̀mí àti láti gba ayọ̀—ayọ̀ ìràpadà Rẹ̀. Nígbàtí a bá yàn láti ronúpìwàdà, a yàn láti dàbí Jésù Krístì jùlọ!”

Ààrẹ Nelson tẹ̀síwájú láti fún wa ní ìyànjú ní gbígbà wá níyànjú láti di mímọ́ síi: “Olúwa kò retí kí a di pípé ní àmì yi. … Ṣùgbọ́n Ó fẹ́ kí a di mímọ́ síi. Ìrònúpìwàdà ojoojúmọ́ ni ipa-ọ̀nà si ìwàmímọ́.”15

Ọ̀rọ̀ Ààrẹ Dallin H. Oaks, ni ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ti o kọjá, bákannáà rànmílọ́wọ́ láti ri kedere bí a ti ndàgbà nínú ìwàmímọ́ àti bí a ṣe lè mọ pé à nsúnmọ́ ọ. Ó wípé: “Báwo ni a ṣe lè ṣe àṣeyọrí ti ẹ̀mí? Báwo ni à ṣe lè dé ipò ìwà mímọ́ níbi ti a ti le ní ìbákẹ́gbẹ́ nígbàgbogbo ti Ẹ̀mí Mímọ́? Báwo ni a ṣè le wá láti wò àti láti ṣe ìṣirò àwọn ayé yí pẹ̀lú ìrísí ayérayé?”16

Ìdáhun Ààrẹ Oaks bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ gíga nínú Jésù Krístì bí olùfẹ́ni Olùgbàlà wa. Ìyẹn darí wa láti wá ìdárìjì ẹ̀ṣẹ̀ lójojúmọ́ àti láti rántí Rẹ̀ lójoojúmọ́ nípa pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Ìgbàgbọ́ gíga yẹn nínú Jésù Krístì nwá bí a ṣe nṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ lójojúmọ́.

Orin “Fún Mi Ní Ìwà Mímọ́ Síi” dába ọ̀nà kan láti gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ ní dídi mímọ́ síi. Olùkọ fi òye dába wípé ìwà mímọ́ tí à n wá jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ olùfẹ́ Ọlọ́run kan, tí a fún wa nígbàgbogbo, lẹ́hìn gbogbo ohun ti a lè ṣe. Ẹ rántí ẹsẹ tí o kẹ́hìn:

Fún mi ní ìwà mímọ́ síi,

Okun síi láti borí,

Òmìnira síi kúrò nínú àwọn ìdè-ayé,

Ìpòngbẹ síi fùn ilé.

Ìbámu síi fún ìjọba náà,

Èmi yíò di lílò síi,

Di ẹni ìbùkun àti mímọ́ síi—

Olùgbàlà, bíì Rẹ, síi.17

Ohunkóhun yíó wù kí ipò araẹni wa, nibikíbi ti a lè wà ni ipa-ọ̀nà májẹ̀mú lọ sílé, ki àdúrà wa fún ìwàmímọ́ gígajùlọ lè gbà. Mo mọ̀ pé bí àdúrà wa ti ngbà, ìdùnnú wa yìó pọ̀ si. Ó lè wá díẹ̀díẹ̀, ṣùgbọ́n yìó wa. Mo ní ìdánilójú yẹn láti ọdọ olùfẹ́ni Bàbá Ọ̀run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì.

Mo jẹri pé Joseph smith jẹ́ wòlíì Ọlọ́run, pé Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì alààyè loni. Ọlọ́run Bàbá wa láàyè àti wípé Ó nifẹ wa. Ó fẹ́ kí á wá sílé lọdọ Rẹ̀ ni àwọn ẹbí. Olùfẹ́ni Olùgbàlà wa pè wá láti tẹ̀lé E ni ìrìnàjò síbẹ̀. Wọ́n ti múra ọ̀nà sílẹ̀. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín