2010–2019
Ní igbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Ní igbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.

Igbọ́kànlé wa tó dájú ni láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa àti ifẹ́ Rẹ̀ fún àwọn ọmọ Rẹ̀.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, lẹ́ta kan tí mo gbà nígbà díẹ̀ sẹ́hìn fi àkọlé ọ̀rọ̀ mi hàn. Olùkọ̀wé náà ngbèrò ìgbeyàwó tẹ́mpìlì sí ọkùnrin kan ẹnití ojúgba ayérayé rẹ̀ ti kú. Yíò di ìyàwó kejì. Ó bèèrè ìbèèrè yí: Ṣé yíò lè ní ilé ara rẹ̀ ní ayé tó nbọ̀, tàbí ṣe yíò gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ àti ìyàwó àkọ́kọ́? Mo kàn sọ fun kí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

Mo tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìrírí tí mo gbọ́ látẹnu oníyì ẹlẹgbẹ́ kan, èyí tí èmi yíò ṣe àbápín pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀. Lẹ́hìn ikú àyànfẹ́ aya àti ìyá àwọn ọmọ rẹ̀, bàbá kan tún ìgbéyàwó ṣe. Àwọn kan tó dàgbà lára ọmọ rẹ̀ yarí sí àtúnṣe-ìgbeyàwó wọ́n sì wá ìmọ̀ràn ìbátan tó sún mọ́ wọn lọ tí ó jẹ́ ẹni-ọ̀wọ̀ olóri Ìjọ. Lẹ́hìn gbígbọ́ àwọn èrèdí fún yíyarí wọn, èyí tí ó dá lórí àwọn ipò àti ìbáṣepọ̀ nínú ẹ̀mí ayé tàbí ní àwọn ìjọba ológo tí ó tẹ̀lé Ìdájọ́ Ìgbẹ̀hìn, olórí yí wípé: “Ẹ̀ ndàmú nípa àwọn ohun àṣìṣe. Ẹ ma dàmú nípa bóyá ẹ̀yin yíò dé àwọn ibi wọnnì. Ẹ tẹramọ́ ìyẹn. Tí ẹ bá dé bẹ́, gbogbo rẹ̀ yíò di ìyanu ju bí ẹ ti rò lọ.”

Ìkọ́ni onítura kan ni! Ní igbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa!

Látinú àwọn lẹ́tà tí mo gbà, mo mọ̀ pé àwọn ẹlòmíràn ndàmú nípa àwọn ìbèèrè nípa ayé ẹ̀mí tí a ó gbé lẹ́hìn tí a bá kú àti ṣíwájú kí a tó jíìnde. Àwọn kan ṣèbí ayé ẹ̀mí yíò tẹ̀síwájú nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ipò ti ara àti àwọn ìrírí ohun tí a ní nínú ayé-ikú. Kíni ohun tí a mọ̀ ní òtítọ́ nípa àwọn ipò nínú ayé ẹ̀mí? Mo gbàgbọ́ pé ọ̀rọ̀ Ọ̀jọ̀gbọ̀n BYU kan lórí àkọlé yí jẹ́ yíyẹ: “Nígbàtí a bá bèèrè lọ́wọ́ ara wa ohun tí a mọ̀ nípa ayé ẹ̀mí látinú ìdiwọ̀n àwọn iṣẹ́, ìdáhùn náà kìí ‘ṣe bí a ti ròó lemọ́lemọ́.’”1

Bẹ́ẹ̀ni, a mọ̀ látinú àwọn ìwé-mímọ́ pé lẹ́hìn tí ara wa bá kú a o tẹ̀síwájú láti gbé bí àwọn ẹ̀mí nínú ayé ẹ̀mí. Àwọn ìwé-mímọ́ kọ́ni pé a pín ayé ẹ̀mí yí sí àárín àwọn wọnnì tí wọ́n ti jẹ́ “olódodo” tàbí “olóòtítọ́” ní ìgbé ayé wọn àti àwọn wọnnì tí wọ́n ti jẹ́ ìkà. Wọ́n júwe bí àwọn olódodo ẹ̀mí ṣe nkọ́ ìhìnrere sí àwọn wọnnì tí wọ́n ti jẹ́ ìkà tàbí olóríkunkun (wo 1 Pétèrù 3:19; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 138:19–20, 29, 32, 37). Pàtàkì jùlọ, ìfihàn òde-òní fihàn pé iṣẹ́ ìgbàlà nlọ síwájú nínú ayé ẹ̀mí (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 138:30–34, 58), bíótilẹ̀jẹ́pé wọ́n rọ̀wá kí a máṣe sún ìrònúpìwàdà wa sìwàjú nínú ayé ikú (wo Alma 13:27), wọ́n kọ́ wa pé àwọn ìrònúpìwàdà kan ṣeéṣe níbẹ̀ (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 138:58).

Iṣẹ́ ìgbàlà ní ayé ẹ̀mí wàpẹ̀lú àwọn ẹ̀mí dídásílẹ̀ látinú ohun tí àwọn ìwé-mímọ́ júwe léraléra bí “ìgbèkùn.” Gbogbo ènìyàn nínú ayé ẹ̀mí wa nínú irú àwọn ìgbèkùn kan. Ìfihàn nlá ti Àarẹ Joseph F. Smith, tí ó wà nínú ìwé ìrántí ní ipa 138 ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, sọ wípé àwọn òkú olódodo, tí ó wà ní ipò “àláfíà” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 138:22) bí wọ́n ṣe ngbìrò Àjíìnde (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú138:16), “ti wò bí wọ́n ṣe pẹ́ tó tí ẹ̀mí wọn ti kúrò nínú àgọ́ ara wọn bíi àkokò ìgbẹ̀kùn” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 138:50).

Àwọn ìkà bákannáà a jìyà àlékún ìgbẹ̀kùn. Nítorí àìronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n wà nínú ohun tí Àpọ́stélì Pétérù tọ́ka sí bí ẹ̀mí “túbú” (1 Pétérù 3:19; bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 138:42). Ẹ̀mí wọ̀nyí ní a júwe bí “ìdè” tàbí bí “oko-ẹrú” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 138:31, 42) tàbí bí “lé jáde sínú òkùnkùn òde” pẹ̀lú “ẹkún, àti ipohùnréré-ẹkún, àti ìpahìn keke” bí a ṣe ndúró de àjíìnde àti ìdájọ́ (Álmà 40:13–14).

Àjíìnde fún gbogbo ènìyàn ní ayé ẹ̀mí mudájú nípasẹ̀ Àjíìnde Jésù Krístì (wo 1 Kọ́ríntì 15:22), bíótilẹ̀jẹ́pé ó ṣẹlẹ̀ ní àkokò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún àwọn ẹgbẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Títí di àkokò tí a yàn, ohun tí àwọn ìwé mímọ́ sọ fún wa nípa ìṣe nínú ayé ẹ̀mí fi taratara gbélé iṣẹ́ ìgbàlà. Díẹ̀ ni a tún fihàn. A wàásù ìhìnrere sí aláìmọ̀kan, aláìronúpìwàdà, àti olóríkunkun kí wọ́n lè bọ́ nínú ìgbèkùn wọn láti lọ síwájú sí àwọn ìbùkún tí olùfẹ́ni Bàbá Ọ̀run kan ní sí ìṣura fún wọn.

Ìgbèkùn ayé-ẹ̀mí tó wà fún olódodo olùyípadà ẹ̀mí ni ìnílò wọn láti dúró dè—àti bóyá kí wọ́n gbààyè láti ṣí—ṣíṣe arọ́pò àwọn ìlànà wọn ní ilẹ̀ ayé kí wọ́n lè ṣe ìrìbọmi kí wọ́n sì gbádùn àwọn ìbùkún Ẹ̀mí Mímọ́ (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 138:30–37, 57–58).2 Àwọn ìlànà arọ́pò ayè ikú wọ̀nyí bákannáà fún wọn lágbára láti lọ síswáju lábẹ́ àṣẹ oyèàlùfáà láti mú àwọn ọ̀gọ́ọ̀rọ̀ olódodo tí ó lè wàású ìhìnrere sí àwọn ẹ̀mí ní túbú gbòòrò si.

Kọjá àwọn kókó wọ̀nyí, ìrántí ìwé mímọ́ wa wà nínú díẹ̀ kékeké nípa ayé ẹ̀mí tí ó tẹ̀lé ikú tí ó ṣíwájú Ìdájọ́ Ìgbẹ̀hìn.3 Nítorínáà kíni a ó tún ṣe nípa ayé ẹ̀mí? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Ìjọ ti ní àwọn ìran tàbí àwọn ìmísí míràn láti sọ fún wọn nípa bí àwọn ohun kan ti nṣiṣẹ́ tàbí bí a ti ṣètò nínú ayé ẹ̀mí, ṣùgbọ́n àwọn ìrírí ti araẹni wọ̀nyí kò ní yéni tàbí kọ́ni bí iṣẹ́ ẹ̀kọ́ ti Ìjọ. Àti pé, bẹ́ẹ̀ni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwíkiri nípa àwọn ọmọ ìjọ àti àwọn ẹlòmíràn nínú àwọn àtẹ̀jáde bíiti àwọn ìwé lórí àwọn ìrírí ìsúnmọ́-ikú.4

Sí gbogbo ìwọ̀nyí, àwọn ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ ọgbọ́n àwọn Alàgbà D. Todd Christofferson àti Neil Andersen nínú àwọn ìpàdé àpapọ̀ tó ṣíwájú ṣe pàtàkì láti rántí. Alàgbà Christofferson kọ́ni: “A gbọ́dọ̀ rántí pé kìí ṣe gbogbo ẹ̀là-ọ̀rọ̀ tí olórí Ìjọ kan bá sọ, lọ́wọ́lọ́wọ́ tàbí kọjá, ló jẹ́ ẹ̀kọ́. Ó wọ́pọ̀ ní ìmọ̀ nínú Ìjọ pé gbólóhùn-ọ̀rọ̀ tí olórí kan bá sọ ní ìgbà kan fi èrò araẹni hàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbèrò dáadáa ni, kìí ṣe ti gbogbogbò tàbí òfin fún gbogbo Ìjọ.”5

Nínú ìpàdé àpapọ̀ tó tẹ̀le, Alàgbà Andersen kọ́ni ní ìtọ́nisọ́nà ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ yí: “Ẹ̀kọ́ náà ni a kọ́ nípasẹ̀ gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ mẹ́ẹ̀dógún ti Àjọ Àarẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá. Kò pamọ́ sínú òkùnkùn gbolóhùn ọ̀rọ̀ ti ọ̀rọ̀ kan.”6 Ìkéde sí ẹbí, ni a bọwọ́lù nípasẹ̀ gbogbo àwọn wòlíì mẹẹdogun, aríran, àti olùfihàn, ni ìjúwe alárà ti ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ náà.

Kọjá ohunkan bíi ti ìkéde ẹbí, ìkọ́ni àwọn wòlíì ti àwọn Ààrẹ Ìjọ, tí a tẹnumọ nípasẹ̀ àwọn wòlíì míràn àti àpọ́stélì, bákannáà ni àpẹrẹ èyí. Gẹ́gẹ́bí àwọn ipò ní ayé ẹ̀mí, Wòlíì Joseph Smith fúnni ní àwọn ìkọ́ni méjì súnmọ́ ìparí iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ tí a tí nkọ́ni lemọ́lemọ́ nípasẹ̀ àwọn àtèlé rẹ̀. Ọkàn lára àwọn ìkọ́ni rẹ̀ wọ̀nyí nínú ìwàásù Ọba Follett pé àwọn ọmọ ẹbí tí wọ́n jẹ́ olódodo yíò wà papọ̀ nínú ayé ẹ̀mí.7 Òmíràn ni gbólóhùn-ọ̀rọ̀ ní ìsìnkú ọdún tó gbẹ̀hìn láyé rẹ̀: “Àwọn ẹ̀mí òtítọ́ ní ìgbéga sí iṣẹ́ títóbi jùlọ àti ológo ... [ní] ayé ti àwọn ẹ̀mí. ... Wọn kò jìnnà sí wa, wọ́n mọ̀ wọ́n sì ní òye àwọn èrò wa, ìmọ̀lára, àti ẹ̀dùn-ọkàn, wọ́n sì nní ìrora nígbàkugbà síbẹ̀.”8

Nítorínáà, Kíni ó ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìbèèrè kan tí mo sọ ṣíwájú nípa ibi tí àwọn ẹ̀mí ngbé? Tí ìbèèrè náà bá dàbì àjèjì tàbí tí kò ṣe pàtàkì sìi yín, ẹ gbèrò ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbèèrè ti ara yín, tàbí àní àwọn wọnnì tí ẹ ti gbìdánwò láti dáhùn lórí kókó ohunkan tí ẹ́ gbọ́ látẹnu ẹnìkan sẹ́hìn? Fún gbogbo àwọn ìbèèrè nípa ayé ẹ̀mí, mo daba ìdáhùn méjì. Àkọ́kọ́, ẹ rántí pé Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn ọmọ Rẹ̀ àti pé dájúdájú yíò ṣe ohun tí ó dárajùlọ fún ẹnìkọ̀ọkan wa. Ìkejì, rántí ìkọ́ni dídámọ̀ Bíbélì yí, èyí tí ó ti ṣèrànlọ́wọ́ jùlọ fún mi lórí ọ̀pọ̀ àwọn ìbèèrè àìlèdáhùn:

Fi gbogbo àyà rẹ gbẹ́kẹ̀lé Olúwa; másì ṣe tẹ̀ sí ìmọ̀ ara rẹ.

“Mọ̀ọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun ó sì máa tọ ipa-ọ̀nà rẹ” (Àwọn Ìwé Òwe 3:5–6).

Bákannáà, Néfì parí orin dáfídì nlá pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Óò Olúwa, mo nígbẹ́kẹ̀lé nínú yín, èmi ó sì gbẹ́kẹ̀lé yín títíláé. Èmi kì yíò fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sọ́wọ́ ẹlẹ́ran ara” (2 Nephi 4:34).

Gbogbo wa lè ro àwọn ipò inú ayé ẹ̀mí níkọ̀kọ̀, tàbí àní kí a sọ àwọn wọnyí tàbí àwọn ìbèèrè àìlèdáhùn míràn nínú ẹbí tàbí àwọn àgbékalẹ̀ tó súnmọ́ni míràn. Ṣùgbọ́n ẹ máṣe jẹ́ kí a kọ́ni tàbí lòó bí ẹ̀kọ́ gbogbogbò ohun tí kò bá òdiwọ̀n ẹ̀kọ́ gbogbogbò mu. Láti ṣe bẹ́ẹ̀ kò ní mú iṣẹ́ Olúwa tẹ̀síwájú ó sì lè mú kí ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n nwá ìtùnú ara wọn tàbí ìgbéga ìfihàn araẹni tí ètò Olúwa npèsè fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ni ìjákulẹ̀. Gbígbáralé ìkọ́ni araẹni jù tàbí àwísọ lè fà wá kúrò ní dídojúkọ ikẹkọ àti ìtiraka tí yíò mú ìmọ̀ wa tẹ̀síwájú àti rànwá lọ́wọ́ síwájú ní ipa-ọ̀nà májẹ̀mú.

Igbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa jẹ́ ìkọ́ni ìdámọ̀ àti òtítọ́ ní Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ìyẹn ni ìkọ́ni Joseph Smith nígbàtí àwọn Ènìyàn Mímọ́ ìṣíwájú nní ìrírí inúnibíni tó le àti àwọn ìdíwọ́ tó dàbí àìlèṣẹ́gun.9 Ìyẹn ṣì ni ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ dídára jù tí a lè lo nígbàtí àwọn ìtiraka wa láti kẹkọ tàbí àwọn ìgbìyànjú wa láti rí ìtùnú láti kojú àwọn ìdíwọ́ ní àwọn ọ̀ràn tí a kò tíi fi hàn tàbí gbàmọ́ra bí ẹ̀kọ́ gbogbogbò Ìjọ.

Irú ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ náà wúlò sí àwọn ìbèèrè àìdáhùn nípa èdidì ní ayé tó nbọ̀ tàbí ìfẹ́ àtúnṣe nítorí ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ìrékojá nínú ayé ikú. Ọ̀pọ̀ wà tí a kò mọ̀ pé igbọ́kànlé wa tó dájú ni láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa àti ifẹ́ Rẹ̀ fún àwọn ọmọ Rẹ̀.

Ní ìparí, ohun tí a kò mọ̀ nípa ayé ẹ̀mí ni pé iṣẹ́ ìgbàlà Bàbá àti Ọmọ ntẹ̀síwájú níbẹ̀. Olùgbàlà wa gbé iṣẹ́ kíkede òmìnira sí awọn tó wà lóko-ẹrú (see 1 Pétérù 3:18–19; 4:6; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 138:6–11, 18–21, 28–37), iṣẹ́ náà ntẹ̀síwájú bí àwọn olóòtọ́ àti olùyege olùránṣẹ́ ṣe tẹ̀síwájú láti wàásù ìhìnrere, pẹ̀lú ìrònúpìwàdà, sí àwọn wọnnì tó nílo agbára ìwẹ̀nùmọ́ (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 138:57). Erèdí gbogbo ìyẹn ni a júwe nínú iṣẹ̀ ẹ̀kọ́ Ìjọ, tí a fúnni nínú ìfìhàn òde-òní.

Àwọn okú tí wọn bá ronúpìwàdà ni a ó ràpadà, nípasẹ̀ ìgbọràn sí àwọn ìlànà ti ilé Ọlọ́run,

“Àti lẹ́hìn tí wọ́n bá ti jìyà fún àwọn ìrékọjá wọn, àti tí a wẹ̀ wọ́n mọ́, wọn yíò gba èrè kan ní ìbamu sí àwọn iṣẹ́ wọn, nítorí wọn jẹ́ ajogún ìgbàlà” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 138:58–59).

Ojúṣe ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ni láti kọ́ni ní ẹ̀kọ́ ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere, pa àwọn òfin mọ́, fẹ́ràn àti láti ran ara wa lọ́wọ́, àti láti ṣe iṣẹ́ ìgbàlà nínú àwọn tẹ́mpìlì mímọ́.

Mo jẹri nípa òtítọ́ ohun tí mo sọ nihin nípa àwọn otítọ́ tí a ti kọ́ni àti èyí tí a ó kọ́ni nínú ìpàdé àpapọ̀ yí. Gbogbo èyí ṣeéṣe nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì. Bí a ṣe mọ̀ látinú ìfihàn òde-oní, Òun “yin Bàbá lógo, tí ó sì gba gbogbo àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ là” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 76:43; àtẹnumọ́ àfikún). Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. “Kíló wà ní Ẹ̀gbẹ́ Míràn? Ìbanisọ̀rọ̀ kan pẹ̀lú Brent L. Top lórí Ayé Ẹ̀mí,” Religious Educator, vol. 14, no. 2 (2013), 43, 48.

  2. Wo Teachings of the Prophet Joseph Smith, sel. Joseph Fielding Smith (1976), 309–10; Joseph Smith, “Journal, December 1842–June 1844; Book 2,” p. 246, The Joseph Smith Papers, josephsmithpapers.org.

  3. Ìfihàn kan sí Joseph Smith tí a túnsọ léraléra nípa ayé ẹ̀mí sọpé, “Irú ìbákẹ́gbẹ́ èyí tí ó wà laarin wa nihin yíò wà ní àárín wa níbẹ̀” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú130:2). This may describe a kingdom of glory rather than the spirit world, since it continues, “Only it will be coupled with eternal glory, which glory we do not now enjoy” (verse 2).

  4. Fún àpẹrẹ, George G. Ritchie, Return from Tomorrow (1978) àti Raymond Moody, Life after Life (1975).

  5. D. Todd Christofferson, “Ẹ̀kọ́ ti Krístì,” Liahona, May 2012, 88; bákannáà wo Joseph F. Smith, Gospel Doctrine, 5th ed. (1939), 42. Fún àpẹrẹ, wo, the description in Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 74:5 of a personal teaching by the Apostle Paul.

  6. Neil L. Andersen, “Àdánwò Ìgbàgbọ́ Yín,” Liahona, Nov. 2012, 41.

  7. Wo Àwọn Ìkọ́ni ti Ìjọ: Joseph Smith (2007), 175.

  8. Ìwé ìtàn Ìjọ, 6:52; wà nínú Àwọn Ìkọ́ni Wòlíì Joseph Smith, 326; àtúnsọ lemọ́lemọ́, bí inú Henry B. Eyring, Láti Súnmọ́ Ọlọ́run (1997), 122; Bákannáà also Àwọn Ìkọ́ni ti Ààrẹ Ìjọ: Brigham Young (1997), chapter 38, “Ayé Ẹmí.”

  9. Wo Teachings: Joseph Smith, 231–33.