2010–2019
Dídúró nípa àwọn Ilérí Wa àti àwọn Májẹ̀mú
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Dídúró nípa àwọn Ilérí Wa àti àwọn Májẹ̀mú

Mo pè yín láti gbèrò àwọn ìlérí àti májẹ̀mú tí ẹ ṣe pẹ̀lú Olúwa, àti àwọn ẹlòmírán, pẹ̀lú ìṣòṣòtítọ́ nlá, ní mímọ̀ pé ọ̀rọ̀ yín jẹ́ àdéhùn yín.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, bí a ṣe nparì abala yí, njẹ́ kí a lè di ẹ̀rí tí a jẹ́ loni nípa àwọn òtítọ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì mú nínú ọkàn wa. A di alábùkún láti ní àkokò mímọ́ papọ̀ láti tún ìlérí wa ṣe sí Olúwa Jẹ́sù Krístì pé a jẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ àti pé Olùgbàlà wa ni Òun.

Pàtàkì ṣíṣe àti pípa àwọn ìlérí mọ àti májẹ̀mú wúwo gidi nínú mi. Báwo ni ó ti ṣe pàtàkì síi yín tó láti pa ọ̀rọ̀ yín mọ́? lati ṣeé gbẹ́kẹ̀lé? lati ṣe ohun tí ẹ sọ pé ẹ ó ṣe? láti tiraka láti bọlá fún àwọn májẹ̀mú yín mímọ́? láti ní ìwàtítọ́? Nípa gbígbé ìgbé ayé òtítọ́ sí àwọn ìlérí wa sí Olúwa àti àwọn ẹlòmíràn, a nrìn ní ipa-ọ̀nà májẹ̀mú padà sọ́dọ̀ Bàbá ní Ọ̀run a sì nnímọ̀lára ifẹ́ Rẹ̀ nínú ayé wa.

Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, ni alápẹrẹ wa nlá nígbàtí ó bá di ṣíṣe àti pípa àwọn ìléré mọ́ àti àwọn májẹ̀mú. Ó wá sí ilẹ̀ ayé ní ṣíṣe ìlérí láti ṣe ìfẹ́ Bàbá. Ó kọ́ni ní àwọn ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ ìhìnrere ní ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe. Ó ṣètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kí a lè gbé lẹ́ẹ̀kansi. Ó ti bọlá fún gbogbo àwọn ìlérí Rẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

Ṣe a lè sọ bákannáà nípa ẹnìkọ̀ọ̀kan wa? Kíni àwọn ewu tí a bá rẹ́nijẹ díẹ̀, yọ̀ díẹ̀, tàbí tí a kò fi taratara tẹ̀lé àwọn ìfarasìn wa? Tí a bá tilẹ̀ rìn kúrò nínú àwọn májẹ̀mú wa nkọ́? Ṣe àwọn míràn yíò nwá sọ́dọ̀ Krístì nínú ìmọ́lẹ̀ àpẹrẹ wa? Ṣé ọ̀rọ̀ yí njẹ́ àdéhùn yín? Pípa àwọn ìlérí mọ́ kìí ṣe ìwà-àìlèfisílẹ̀; ó jẹ́ ìhùwàsí ti jíjẹ́ ọmọẹhìn Jésù Krístì.

Níní ìfura àwọn àìlera ayé ikú wa, Olúwa ṣèlérí, “Ẹ tújúka, ẹ máṣe bẹ̀rù, nítorí èmi Olúwa wà pẹ̀lú yín, èmi yíò sì dúró tì yín.”1 Mo ti nímọ̀lára wíwà Rẹ̀ nígbàtí mo nílò ìdánilójú, ìtùnú, tàbí òye ti ẹ̀mí nlá, mo sì ti nírẹ̀lẹ̀ jinlẹ̀jinlẹ̀ àti pé mo ní ìmoore fún ojúgbà ti ọ̀run Rẹ̀.

Olúwa ti wípé, Olúkúlùkù àwọn ọkàn tí ó bá kọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, àti tí ó ké pe orúkọ mi, tí ó sì gbọràn sí ohùn mi, àti tí ó pa àwọn òfin mi mọ́, yíò rí ojú mi yíò sì mọ̀ pé Èmi ni.”2 Bóya ìyẹn ni ìlérí ìgbẹ̀hìn Rẹ̀.

Mo kẹkọ pàtàkì nípa pípa ọ̀rọ̀ mi mọ́ ní èwe mi. Irú àpẹrẹ bẹ́ẹ̀ kan ni ìgbàtí mo dúró gbọingbọin láti ka ìbúra Scáótù. Ìbaraṣe wa pẹ̀lú Scáòtù ọmọdékùnrin ti Amẹ́ríkà, bí ó ti parí báyìí, yíò jẹ́ ogún pàtàkì kan sí mi àti sí Ìjọ nígbàgbogbo. Sí ìṣètò ti Scáótù, sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ti fi akínkanjú sìn bí àwọn olórí Scáótù, sí àwọn màmá—oríyìn gidi lọ síbẹ̀—àti sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n ti kópa ní ṣíṣe Scáótù, mo wípé, Ẹ ṣe.”

Ní abala yí gan an, wòlíì wa ọ̀wọ́n, Ààrẹ Russell M. Nelson, àti Alàgbà Quentin L. Cook ti kéde àwọn àtúntò tí yíò tún-fojúsí ìdojúkọ wa lórí ọ̀dọ́ àti fífi àwọn ìṣètò wa sí ìbámu pẹ̀lú òtítọ́ tí a fihàn. Ní àfikún, ní Ọjọ́-ìsinmi tó kọjá, Ààrẹ Nelson àti Ààrẹ̀ M. Russell Ballard ṣe àlàyé ètò àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn fún gbogbo Ìjọ. Ó jẹ́ ìdojúkọ ìmúbẹ̀rẹ̀ gbogbo àgbáyé lórí Olúwa àti Olùgbàlà, Jésù Krístì. Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì nirẹpọ̀ nínú ìdarí titun yí, àti pé mo jẹ́ ẹ̀rí mi pé Olúwa ntọ́wasọ́nà ní gbogbo ìṣísẹ̀ lọna. Mo ní ìyárí fún àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ Ìjọ láti ní ìrírí ìfisí ìdojúkọ lórí àwọn méjèèjì ní ilé àti ní ijọ̀ bákannáà—nípa ikẹkọ ìhìnrere, iṣẹ́ ìsìn àti àwọn ìṣeré, àti ìdàgbàsókè araẹni.

Àkórí fún àwọn ọ̀dọ́ ní ọdún tó nbọ̀ yí, 2020, sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tótayọ ti Néfì láti “lọ àti láti ṣe.” Ó kọ pé, “Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, sọ fún bàbá mi: Èmi yíò lọ láti ṣe àwọn ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ, nítorí tí èmi mọ̀ wí pé Olúwa kì yíò pa àṣẹ fún àwọn ọmọ ènìyàn, bíkòṣe pé òun yíò pèsè ọ̀nà fún wọn pé kí wọ́n lè parí ohun nã èyí tí òun pa láṣẹ fún wọn.”4 Bíótilẹ̀jẹ́pé a ti sọ́ lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́hìn, àwa ní Ìjọ dúró lórí ìlérí náà loni.

Láti “lọ àti láti ṣe” túmọ̀ sí dídìde kọjá àwọn ọ̀nà ti ayé, ní gbígba àti ṣíṣe ìṣe lórí ìfihàn araẹni, gbígbé tòdodo-tòdodo pẹ̀lú ìrètí àti ìgbàgbọ́ ní ọjọ́-ọ̀la, ṣíṣe àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ láti tẹ̀lé Jésù Krístì, àti nípa èyí ó nmú ìfẹ́ wa fun Un pọ̀ sí, Olùgbàlà aráyé.

Májẹ̀mú ni ìlérí ọ̀nà-méjì ní àárín wa àti Olúwa. Bí àwọn ọmọ Ìjọ, a dá májẹ̀mú níbi ìrìbọmi láti gbé orùkọ Jésù Krístì lé orí wa, láti gbé bí Ó ti gbé. Bí àwọn wọnnì tó ṣèrìbọmi ní omi Mọ́mọ́nì, a dá májẹ̀mú láti di ènìyàn Rẹ̀, “láti gbé àjàgà ara wa, kí wọ́n lè fúyẹ́; ... “Láti ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn tó nṣọ̀fọ̀ tu àwọn tó nílò ìtùnú nínú, àti láti dúró bí àwọn ẹlẹri Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà àti nínú ohun gbogbo, àti ní ibi gbogbo.”5 Ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa síra nínú Ìjọ nfi ìfarasìn wa hàn láti bọlá fún àwọn ìlérí wọnnì gan an.

Nígbàtí a bá ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa, a ntún májẹ̀mú wa ṣe láti gbé orúkọ Rẹ̀ lórí ara wa àti láti ṣe àwọn àfikún ìlérí láti dàgbà. Àwọn èrò àti ìṣe wa ojoojúmọ́, títóbi àti kékeré méjèèjì, nfi ìfarasìn wa sí I han. Ìlérí mímọ́ Rẹ̀ ní àbábọ̀ ni, “Tí ẹ bá rántí mi nígbàgbogbo ẹ ó ní Ẹ̀mí mi láti wà pẹ̀lú yín.”6

Ibèèrè mi loni ni pé, ṣé a dúró nípa àwọn ilérí wa àti àwọn májẹ̀mú, tàbí wọ́n kò jáfáfá nínú ifarasìn nígbàmíràn, ní ṣíṣe jẹ́jẹ́ àti fífìrọ̀rùn jakúrò nígbànáà? Nígbàtí a bá sọ fún ẹnìkan pé, “Mo gbàdúrà fún yín,” ṣé à nṣeé? Nígbàtí a bà gbà pé, “Mo máa wà níbẹ̀ láti ṣèrànwọ́,” ṣe a ó ṣe? Nígbàtí a bá ní ojúṣe arawa láti san gbèsè, ṣe à nṣeé? Nígbàtí a bá nawọ́ wa sókè láti ṣèmúdúró ọmọlàkejì ọmọ ìjọ nínú ipè titun kan, èyí túmọ̀ sí fífúnni ní àtìlẹhìn, ṣe à nṣeé?

Ìrọ̀lẹ́ kan ní ìgbà èwe mi, ìyá mi joko pẹ̀lú mi ní ẹsẹ̀ bùsùn rẹ̀ àti pé ó sọ̀rọ̀ taratara nípa pàtàkì gbígbé Ọ̀rọ̀ ti Ọgbọ́n. “Mo mọ̀ látinú ìrírí àwọn ẹlòmíràn, ní ọdún púpọ̀ sẹ́hìn,” ó wipé, “àdánù ti ẹ̀mí àti ìdáhùnsí tí ó nwá ní àìtẹ̀lé Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n.” Ó wò mí lójú tààrà. mo sì nímọ̀lára àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wọnú ọkàn mi: “Ṣèlérí fún mi, Ronnie, loni [ó npè mí ní Ronnie], pé ìwọ ó máa gbé ìgbé Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n.” Mo ṣe ìlérí náà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sí i, mo sì ti dì mọ́ọ ní gbogbo ọdún wọ̀nyí.

Ìfarasìn náà sàn fún mi dáadáa nígbàtí mo wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nígbà ọ̀dọ́ mi àti àwọn ọdún lẹ́hìn náà nígbà tí mo wà ní agbo káràkátà níbití àwọn nkan tí nlọ létòletò. Mo ṣe ìpinnu pàtàkì kan ṣíwájú láti tẹ̀lé àwọn àṣẹ Ọlọ́run, àti pé kí nmáṣe níláti ṣèbẹ̀wò rẹ̀ láéláé. Olúwa ti wípé, “Èmi, Olúwa, ní ojúṣe dandan nígbàtí ẹ bá ṣe ohun tí èmi wí; ṣùgbọ́n nígbàtí ẹ̀yin kò bá ṣe ohun tí èmi wí, ẹ kò ní ìlérí,”7 Kíni Ó nsọ fún àwọn wọnnì tí wọ́n bá gbé nípa Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n? Pé a ó ní ìlérí ìlera, okun, ọgbọ́n, ìmọ̀, àti àwọn ángẹ́lì láti dáàbò bò wá.8

Ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, Arábìrin Rasband àti èmi wà ní Tẹ́mpìlì Salt Lake fún èdidì ti ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin wa. Bí a ṣe dúró níta tẹ́mpìlì pẹ̀lú obìnrin kékeré kan tí kò dàgbà tó láti wá bi ayẹyẹ náà, a sọ̀rọ̀ nípa pàtàkì tí ṣiṣe èdidì nínú tẹ́mpìlì Ọlọ́run. Bí ìyá mi ṣe kọ́mi ní awọn ọdún ṣíwájú, a sọ fún ọmọbìnrin wa, “A fẹ́ kí o ṣe èdidì láìléwu nínú tẹ́mpìlì, a sì fẹ́ kí o ṣèlérí fún wa pé nígbàtí ìwọ bá rí ojúgbà ayérayé rẹ, ìwọ yíò mú ọjọ́ pẹ̀lú rẹ̀ láti ṣe èdidì nínú tẹ́mpìlì.” Ó fún wa ní ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Àwòrán
Ọmọbìnrin Alàgbà Rasband àti ọkọ rẹ̀

Ó ti sọ látìgbànáà pé ọ̀rọ̀ wa àti ìlérí rẹ̀ dáàbò bo òun ó sì rán òun létí “ohun ti ó ṣe pàtàkì jùlọ.” Lẹ́hìnnáà ó dá àwọn májẹ̀mú mímọ́ bí ó ṣe ṣe èdidì pẹ̀lú ọkọ̀ rẹ̀ nínú tẹ́mpìlì.

Ààrẹ Nelson ti kọ̀ni pé: À nlési agbára Olùgbàlà nínú ayé wa nígbàtí a bá dá àwọn májẹ̀mú mímọ́ tí a sì pa àwọn májẹ̀mú náà mọ́ rẹ́gírẹ́gí. Àwọn májẹ̀mú wa dè wá mọ́ Ọ ó sì nfún wa ní agbára ọ̀run.”9

Nígbàtí a bá pa àwọn ìlérí mọ́ sí ara wa. a ó lè pa àwọn ìlérí sí Olúwa mọ́ síi. Rántí àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa: “Níwọ̀n tí ẹ bá ti ṣé sí ọ̀kan tó kéréjù lára àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí ẹ ti ṣé sí mi.”10

Ronú pẹ̀lú mi lórí àwọn àpẹrẹ ìlérí nínú ìwé mímọ́. Ámọ́nì àti àwọn ọmọkùnrin Mòsíàh nínú Ìwé Mọ́mọ́nì farasìn “láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”11 Nígbàtí tí ọmọ-ogun àwọn Lámánáítì mú Ámọ́nì, wọ́n mu lọ síwájú Lámónì Ọba Lámánáítì. Ó fararsìn sí ọba, “Èmi ó jẹ́ ìránṣẹ́.”12 Nígbàtí olùkónilọ wá láti jí àgùtàn ọbọ, Ámọ́nì gé ọwọ́ wọn kúrò. Ó ya ọba lẹ́nu gidi, ó fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ìhìnrere Ámọ́nì ó sì yípadà.

Ruth, nínú Májẹ̀mú Láéláé, ṣèlérí fùn ìyá-ọkọ rẹ̀, “Ibikíbi tí ìwọ bá lọ, ni èmi ó lọ.”13 Ó gbé ní òtítọ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Samaritan rere, nínú òwe kan nínú Májẹ̀mú Titun, ṣèlérí fún olùpamọ́ ilé-èrò tí yíò bá tọ́jú arìnrìnàjò olùfarapa, “Ohunkóhun tí ìwọ bá lò si, nígbàtí mo bá wá lẹ́ẹ̀kansi, èmi ó sàn an fún ọ.”14 Sórámù, nínú Ìwé Mọ́mọ́nì, ṣèlérí láti lọ sínú aginjù pẹ̀lú Néfì àti àwọn arákùnrin rẹ̀. Néfì rántí pé “Ìgbà tí Sórámù ti ṣe ìbúra fún wa, ìbẹ̀rùbojo wa dẹ́kun nípa rẹ̀.”15

Báwo ni ti ìlérí àtijọ́ “tí a ṣe sí àwọn bàbá” bí a ti júwe nínú àwọn ìwé mímọ́ pé “ọkàn àwọn ọmọ yíò yípadà sí bàbá wọn”?16 Ní ìṣíwájú-ilẹ̀ ayé nígbàtí a yan ètò Ọlọ́run, a ṣe ìlérí láti ṣèrànwọ́ láti kó Ísráẹ́lì jọ lẹgbẹ́ méjèèjì ìbòjú. “A lọ sínú iṣẹ́ ṣíṣe pẹ̀lú Olúwa.” Alàgbà John A. Widtsoe ṣàlàyé lọ́pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn. “Mímújáde ètò náà nígbànáà kìí ṣe iṣẹ́ Bàbá, àti iṣẹ́ Olùgbàlà lásán, ṣùgbọ́n bákannáà iṣẹ́ wa.”17

“Ìkójọ [náà] ni ohun pàtàkì jùlọ ní ilẹ̀ ayé loni,” Ààrẹ Nelson ti sọ bí òun ṣe nrìnrìnàjò kiri ayé pé. “Nígbàtí a sọ̀rọ̀ nípa ìkójọ, à nsọ jẹ́jẹ́ nípa ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ òtítọ́: gbogbo àwọn ọmọ Bàbá wa Ọ̀run, ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú, lẹtọ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì.”19

Bí Àpọ́stélì Olúwa Jésù Krístì kan, mo parí pẹ̀lú ìfipè kan àti ìlérí. Lakọkọ, ìfipè náà: Mo pè yín láti gbèrò àwọn ìlérí àti májẹ̀mú tí ẹ ṣe pẹ̀lú Olúwa, àti àwọn ẹlòmírán, pẹ̀lú ìṣòṣòtítọ́ nlá, ní mímọ̀ pé ọ̀rọ̀ yín jẹ́ àdéhùn yín. Ìkejì, mo ṣèlérí fún yín, bí ẹ ti nṣe èyí, Olúwa yíò gbé àwọn ọ̀rọ̀ yín kalẹ̀ yíò sì fọwọ́sí àwọn ìṣe yín bí ẹ ti nlàkàkà pẹ̀lú ìtara àìṣàárẹ̀ láti gbé ilé ayé yín ga, ẹbí yín, àti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Òun yíò wà pẹ̀lú yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ lè ṣé, pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé, ẹ wo iwájú sí jíjẹ́ “ìtẹ́wọ́gba sí ọ̀run, pé níbẹ̀ kí [ẹ] lè gbé pẹ̀lú Ọlọ́run ní ipò ìdùnnú àìlópin ... Nitorí Olúwa Ọlọ́run ti sọ́.”20

Nípa Èyí ni mo jẹ́ẹ̀rí ni orúkọ Jésù Krístì, Àmín.