2010–2019
Ẹ Jẹ́ Olóòtítọ́, Kìí ṣe Aláìgbàgbọ́
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Ẹ Jẹ́ Olóòtítọ́, Kìí ṣe Aláìgbàgbọ́

A gbọ́dọ̀ mọ̀ọ́mọ́ gba àkokò ní ojoojúmọ́ lá já ìsopọ̀ nínú ayé àti láti sopọ̀ pẹ̀lú ọ̀run.

Láìpẹ́ mo jí dìdé mo sì múrasílẹ̀ láti ṣàṣarò ìwé-mímọ́. Mo mú fóònù-àgbéká mi mo sì joko lórí àga lẹgbẹ ibùsùn mi, pẹ̀lú èrò láti ṣí ibi ìkópamọ́ ìhìnrere. Mo ṣí fóònù mi mo sì fẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti ṣàṣàrò nígbàtí mo rí ìlàjì dọ́sìnì ọ̀rọ̀ ìfihàni àti àwọn ímeèlì tó ti wá ní òru. Mo ronú pe, “Mo máa wo àwọn ọ̀rọ̀ náà kíákíá, nígbànáà kí nlọ sínú ìwé mímọ́ kíá.” Ó dára, wákàtí méjì lẹ́hìnnáà mo ṣì wà lórí àwọn ìfiṣọwọ́ ọ̀rọ̀, ímeèlì, ìròhìn ṣókí, àti ìbákẹgbẹ́ ìròhìn lílẹ̀. Nígbàtí mo dá ohun tí àkokò jẹ́ mọ̀, mo fi tipátipá sáré láti lọ múra fún ọjọ́ náà. Ní àárọ́ tí mo fo ṣíṣe àṣàrò ìwé mímọ́ mi, tí èmi kò sì ní ìkẹ́ ti ẹ̀mí tí mo nretí ní àbájade fún.

Ṣíṣìkẹ́ ti ẹ̀mí

Ó dá mi lójú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ lé mọ̀. Àwọn ohun ìgbàlódé nbùkún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà. Wọ́n lè sọ wá mọ́ àwọn ọ̀rẹ̀ àti ẹbí, pẹ̀lú ìwífúnni, àti pẹ̀lú àwọn ìròhìn nípa ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní àyíká ayé. Bákannáà, wọ́n le tún dàwálámú kúrò nínú àwọn ìsopọ̀ pàtàkì jùlọ: ìsopọ̀ pẹ̀lú ọ̀run.

Mo tún ohun tí wòlíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, ti wí sọ: “À ngbé nínú ayé tí ó nípọn àti ìjà tó npọ̀si. Wíwà léraléra ti ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn àti àyíká ìròhìn nbòwá pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ àìsimi. Tí a bá níláti ní ìrètí ti yíyọ nínú óríṣiríṣi àwọn ohùn àti ẹ̀kọ́ ayé àwọn ènìyàn tí wọ́n tako òtítọ́, a gbọ́dọ̀ kọ́ láti gba ìfihàn.”

Ààrẹ Nelson tẹ̀síwájú láti kìlọ̀ pé “ní àwọn ọjọ́ tó nbọ̀, kò ní ṣeéṣe láti yè níti ẹ̀mí láìsí ìtọ́nisọ́nà, dídarí, titunú, àti agbára Ẹ̀mí Mímọ́ léraléra.”1

Àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, Ààrẹ Boyd K. Packer sọ fún agbo ìkokò kan pé, nítorí rírọ̀ yìyín líle, bọ́ sí pákúté ìtà ibùgbé àbínibí rẹ̀ àti ìdojúkọ ebi tó ṣeéṣe. Àwọn ènìyàn onítumọ̀, nínú ìtiraka kan láti gba ìkokò là, jù ẹ̀kúnẹrù àgbàdo yíka agbègbè náà—kìí ṣe ohun tí ìkokò yíò jẹ tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n nírètí pé ó kéréjù yíò mú ìkokò la òtútù kọjá. Tìbànújẹ́tibànújẹ́, ọ̀pọ̀ àwọn ìkokò náà ní wọ́n bá ní kíkú. Wọ́n ti jẹ́ àgbàdo, ṣùgbọ́n kò ṣikẹ́ wọn, ó sì pa wọ́n lébi kú pẹ̀lú ikùn wọn níkíkún.2

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bò wá mọ́lẹ̀ nínú ọjọ́ ìwífúnni ni ìbámu ti ẹ̀mí ti bíbọ́ àgbàdo sí ìkokò—a lè jẹ ẹ́ ní gbogbo ọjọ́, ṣùgbọ́n kò ní ṣìkẹ́ wọn.

Níbo lá ti lè rí ìṣìkẹ́ ti ẹ̀mí? Nígbàkugbà jùlọ, kìí ṣe kíkiri lórí ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn. A lè ríi nígbàtí a bá “tẹ̀síwájú ní ọ̀nà [wa]” ní ipa-ọ̀nà májẹ̀mú, “títẹramọ́ dídi irin náà mú daindain,” àti ṣíṣe àbápín àwọn èso igi ìyè.3 Èyí túmọ̀ pé a gbọ́dọ̀ mọ̀ọ́mọ́ gba àkokò ní ojoojúmọ́ lá já ìsopọ̀ nínú ayé àti láti sopọ̀ pẹ̀lú ọ̀run.

Nínú àlá rẹ, Léhì rí àwọ ènìyàn tí wọ́n nṣe àbápín èso ṣùgbọ́n lẹ́hìnnáà wọ́n paáti nítorí agbára ti ilé nlá àti aláyè, ìgberaga ayé.4 Ó ṣeéṣe fún àwọn ọ̀dọ́ láti gba ìdìde títọ́ ní ilé Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhin kan, tó nlọ sí g gbo ìpàdé Ìjọ àti kíláàsì tótọ́, àní to nkópa nínú àwọn ìlànà inú tẹ́mpìlì, lẹ́hìnnáà tí wọ́n rìn lọ “sínú ipa-ọ̀nà èèwọ̀ àti pé tí wọn [di] sísọnù.”5 Kínìdí tí èyí fi ṣẹlẹ̀? Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀ràn ó jẹ́ nítorí, ìgbàtí wọ́n lè ti máa lọ nínú ìrìn ti ẹ̀mí, wọn ko yípadà nítoótọ́. A bọ́ wọn ṣùgbọ́n wọn kò gba ìṣìkẹ́.

Àwòrán
Ìṣeré Ọ̀dọ́

Ní ìlòdì, mo ti pàdé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí wọ́n lagbára, jáfáfá, àti olóòtítọ́. Ẹ mọ̀ pé ẹ jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run àti pé Òun ní iṣẹ́ kan fún yín láti ṣe. Ẹ nifẹ ẹ sì nsin Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo “ọkàn, okun, inú àti agbára.”6 Ẹ npa àwọn májẹ̀mú yín mọ́ ẹ sì nsin àwọn ẹlòmíràn, bẹ̀rẹ̀ láti ilé. Ẹ̀ nlo ìgbàgbọ́ yín, ronúpìwàdà, àti gbèrú lojoojúmọ́, áti pe èyí nmú ayọ̀ pípẹ́ wá fún yín. Ẹ̀ nmúrasílẹ̀ fún àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì àti àwọn ànfàní míràn tí ẹ ó ní bí àtẹ̀lé Olùgbàlà. Ẹ sì nṣèrànwọ́ láti múra ayé sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì, pípe àwọn ẹlòmíràn láti wá sọ́dọ̀ Krístì àti ìrírí agbára ètùtù Rẹ̀. Ẹ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ọ̀run.

Àwòrán
Ìrìnàjò tẹ́mpìlì Ọ̀dọ́

Bẹ́ẹ̀ni, ẹ dojúkọ àwọn ìpènijà. Ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ni ní gbogbo ìran. Ìwọ̀nyí ni a`wọn ọjọ́ wa, a`ti pé a nílò láti jẹ́ olóòtítọ́, kìí ṣe aílàgbàgbọ́. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Olúwa mọ̀ nípa àwọn ìpènijà wa, àti pé nínú ipò-olórí ti Ààrẹ Nelson Òun nmúra wa sílẹ̀ láti pàdé wọn. Mo gbàgbọ́ pé ìpò wòlíì àìpẹ́ fún ìjọ gbùngbun-ilé, tí ohun tí a nṣe nínú ilé wa ntìlẹ́hìn,8 ni àpẹrẹ láti rànwálọ́wọ́ láti nígbàlà—àní làkàkà—nínú àìjẹunkánú ti ẹ̀mí.

Gbùngbun Ilé

Kíni ó túmọ́sí láti jẹ́ ijọ gbùngbún ilé kan? Àwọn ilé lè yàtọ̀ síra káàkiri àgbáyé. Ẹ lè wà nínú ẹbí kan tí ó ti wà nínú Ìjọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran. Tàbí jẹ́ ọmọ Ìjọ kanṣoṣo nínú ẹbí yín. Ẹ lè ti ṣègbeyàwó tàbí àdáwà, pẹ̀lú tàbí àìsí àwọn ọmọ nílé.

Láìka àwọn ipò yín sí, ẹ lè mú ilé yín jẹ́ gbùgbun ikẹkọ ìhìnrere àti ìgbé ayé. Ó kan túmọ̀sí gbígba ojúṣe araẹni fún ìyípadà yín àti ìdàgbà ti ẹ̀mí. Ó túmọ̀ sí títẹ̀lé ìmọ̀ràn Ààrẹ Nelson “láti [tún ilé yín] ṣe sí ilé-ìṣọ́ ti ìgbàgbọ́.”8

Ọ̀tá yíò gbìyànjú láti rọ̀ yín pé ìṣìkẹ́ ti ẹ̀mí kò ṣeéṣe tàbí, ẹ̀tàn síi, tí kò ní lè dúró. Òun ni ọ̀gá ìdàmú àti olùdásílẹ̀ ìfidọ̀la. Òun yíò mú àwọn ohun míràn tí ó dàbí ó ṣe kánkán wá siranti yín ṣùgbọ́n ní òdodo tí kò ṣe pàtàkì. Òun yíò jẹ́ kí ẹ “dààmú tóbẹ́ẹ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohunkan” tí ẹ fi “ohun kan [tí] ó wúlò.”9

Bí mo ṣe nímoore tó fún “àwọn òbí mi,”10 ti wọ́n tọ́ ẹbí wọn ní ilé kan nípa ìṣìkẹ́ ti ẹ̀mí lemọ́lémọ́, ìbáṣẹpọ̀ ìfẹ́ni, àti àwọn ìṣeré ìdárayá oníyì. Àwọn ìkọ́ni tí wọ́n pèsè ní ìgbà ọ̀dọ́ mi ti dì mímú nínú ìdúró déédé. Ẹ̀yin òbí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ gbé àwọn ìbáṣepọ̀ alágbára dìde pẹ̀lú àwọn ọmọ yín. Wọ́n nílò àkokò yí síi, kìí ṣe dídínkù.

Àtìlẹ́hìn Ìjọ

Bí ẹ ti nṣé, Ìjọ wà nbẹ̀ láti ṣàtìlẹhìn. Àwọn ìrírí ní ìjọ lè tún ìṣìkẹ́ ti ẹ̀mí tó nṣẹlẹ̀ nílé. Ní ọdún yí, a ti rí irú àtìlẹhìn Ìjọ ní Ilé-ẹ̀kọ́ Ọjọ́-ìsinmi. A ó rí ọ̀pọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ìpàdé Oyè-àlùfáà Árọ́nì àti ọ̀dọ́mọbìnrin bákannáà. Bẹ̀rẹ̀ ní Oṣù Ìkínní, ohun èlò fún àwọn ìpàdé wọ̀nyí yíò ní àtúnṣe díẹ̀. Yíò ṣì dojúkọ àwọn kókó àkọlé pàtàkì, ṣùgbọ́n àwọn àkọlé wọnnì yíò wà ní ìbámu pẹ̀lú Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún Ẹnìkọ̀ọ̀kan àti Ẹbí. Ìyípadà kekeré ni èyí, ṣùgbọ́n ó lè mú ipá nlá wá sórí ìṣìkẹ́ ti ẹ̀mí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin.

Irú áwọn àtìlẹhìn míràn wo ni Ìjọ pèsè? Ní Ìjọ àbápín oúnjẹ Olúwa, èyí tí ó nrànwálọ́wọ́ láti tún ìfàrasìn wá sí Olùgbàlà ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àti pé ní Ìjọ a nkórajọ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ míràn tí wọ́n ti ṣe irú ìfarasìn bẹ́ẹ̀. Àwọn ibáṣepọ̀ ifẹ́ni tí a mú dàgbà pẹ̀lú ọmọlàkejì àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì lè jẹ́ àtìlẹhìn alágbára sí àwọn gbùngbunilé jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn arawa.

Nígbàtí mo jẹ́ ọdún mẹ́rìnlá, ẹbí mi kó lọ sí agbègbè titun. Nísisìyí, èyí lè dàbí ẹnipé ìjàmbá burúkú ni síi yín, ṣùgbọ́n nínú mi, ní àkokò náà, ó jẹ́ ìparun. Ó túmọ̀ sí wíwà ní àyíká nípasẹ̀ àwọn ènìyàn tí èmi kò mọ̀. Ó túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin nínú wọ́ọ̀dù yíò lọ sí ilé-ìwé kan ju tèmi. Ní ọdún mẹ́rìnlá iyenu mi, mo ro pé, “Báwo ni àwọn òbí mi ṣe lè ṣe èyí sí mi?” Mo ní ìmọ̀lára bíì pé ayé mi ti bàjẹ́.

Bákannáà, nínú àwọn ìṣeré Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo gbé àwọn ìbáṣepọ̀ dide pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìyèjú, àti pé wọ́n sì di àwọn ọ̀rẹ́ mi. Ní àfikún, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ bìṣọ́príkì àti olùgbani-nímọ̀ràn Oyè-àlùfáà Árọ́nì bẹ̀rẹ sí nní ìfẹ́ pàtàkì nínú ayé mi. Wọ́n wá síbi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣeré-ìdárayá mi. Wọ́n kọ àwọn àkọsílẹ̀ ránpẹ́ ìgbani-níyànjú pé mo ti wà di ọjọ́ yí. Wọ́n tẹramọ́ fífi ìwéṣọwọ́ sími lẹ́hìn tí mo ti lọ sí kọllẹ́jì àti nígbàtí mo lọ fún míṣọ̀n. Ọ̀kan lára wọn tilẹ̀ wà ní atúkọ̀-òfúrufú nígbàtí mo délé. Èmi ó fi ìmoore hàn títíláé fún àwọn arákùnrin rere wọ̀nyí àti àpapọ̀ ìfẹ́ wọn àti ìgbìró gíga. Wọ́n darí mi lọ sí ọ̀nàìgbàlà, àti pé ìgbé ayé di títàn, dídùn, àti aláyọ̀.

Báwo ni àwà, bíàwọn olórí àti òbí, fi lè ṣèránwọ́ fún àwọn ọpdọ́ láti mọ̀ pé wọn kò dá wà bí wọ́n ṣe nrìn ní ipa-ọ̀nà májẹ̀mú? Ní àfikún láti gbé àwọn ìbáṣepọ̀ araẹni ga, a pè wọ́n láti kórajọ ní kékeré àti nlá—nínú àwọn ìpàdé àpappọ̀ Fún Okun ti Ọ̀dọ́ àti àwọn ìpàgọ́ ọ̀dọ́ sí àwọn ìṣeré kíláàsì àwọn iyejú ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Ẹ máṣe fojú rẹ agbára tí ó nwá látinú dídúró papọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ngbìyànjú bákannáà láti lókun rẹlẹ̀. Àwọn Bìṣọ́ọ̀pù àti àwọn olórí míràn. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ dojúkọ ṣíṣìkẹ́ àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ ní wọ́ọ̀dù yín. Wọ́n nílò àkokò yín síi, kìí ṣe dídínkù.

Bóyá ẹ jẹ́ olórí kan, aladugbo, ọmọ ẹgbẹ́ iyejú, tàbí kàn jẹ́ Ènìyàn Mímọ́ kan, tí ẹ bá ní ànfàní láti fọwọ́tọ́ ayé ọ̀dọ́ kan, ràn ọkùnrin tàbí obìnrin lọ́wọ́ láti nísopọ̀ pẹ̀lú ọ̀run, Agbára yín lè jẹ́ “àtìlẹhìn Ijọ” rẹ́gí tí ọ̀dọ́mọdé kan nílò.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù Krístì wà ní orí Ìjọ yí. Ó nmísí àwọn olórí wa Ó sì ntọ́wasọ́nà láti ṣìkẹ́ ti ẹ̀mí tí a nílò láti yè àti láti yege ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Ṣíṣìkẹ́ ti ẹ̀mí náà yíò rànwálọ́wọ́ láti jẹ́ olóótọ́ áti kí a maṣe aláìgbàgbọ́. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.