2010–2019
Wá, Tẹ̀lé Mi—Ètò Ìlòdì Sí Ète àti Ìronú Ṣíwájú ti Olúwa
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Wá, Tẹ̀lé Mi—Ètò Ìlòdì Sí Ète àti Ìronú Ṣíwájú ti Olúwa

Olúwa nmúra àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀ ní ìlòdì sí àwọn ìkọù ọ̀tá. Wá, Tẹ̀lé Mi ni ètò fún ìlòdì sí ète àti ìronú ṣíwájú ti Olúwa.

A láyọ̀ ní pípàdé papọ̀ nínú ìpàdé nlá gbogbogbò yí ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn Ó jẹ́ ìbùkún láti gba èrò inú àti ìfẹ́ ti Olúwa nípasẹ̀ àwọn ìkọ́ni ti àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì Rẹ̀. Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì alààyè ti Olúwa. Ìmoore wa ti tó fún ìmọ̀ràn àti ìtọ́ni onímìísí tí a ti gbà lóni.

Mo fi ẹ̀rí mi kún àwọn tí wọ́n ti bápín ṣaájú. Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa Ọlọ́run, Baba Ayérayé. Ó wà láàyè ó sì fẹ́ràn wa, ó sì nṣe ìṣọ́ ní orí wa. Ètò ìdùnnú Rẹ̀ pèsè fún ìbùkún ti ayé kíkú yì àti pípadà wa ní ìgbẹ̀hìn sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Bákannáà mo jẹ́ri nípa Jésù Krístì. Òun ni Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Ọlọ́run Ó gbà wá là kúrò lọ́wọ́ ikú, Ó sì nrà wá padà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí a ti nlo ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ tí a sì nronúpìwàdà. Ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ tí kò lópin nítorí wa mú ìbùkún ti àìkú àti ìyè ayérayé wá. “Ọpẹ́ fún Ọlọ́run fún ẹ̀bùn Rẹ̀ àìlẹ́gbẹ́ ti ọmọ Rẹ̀ àtọ̀runwá” (“Krístì Alààyè: Ẹ̀rí àwọn Àpọ́stélì,” Liahona, May 2017, nínú ojú-ewé ìṣaájú).

Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn káàkiri àgbáyé jẹ́ alábùkúnfún láti jọ́sìn sí Jésù Krístì nínú àwọn tẹ́mpìlì mímọ́ Rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn tẹ́mpìlì wọnnì ni wọ́n nkọ́ lọ́wọ́ ní Winnipeg, Canada. Ìyàwó mi, Anne Marie, àti èmi ní ànfààní láti ṣe àbẹ̀wò sí ibi ìkọ́lé náà ní Oṣù Kẹjọ ọdún yi. A ya àwòrán tẹ́mpìlì náà ní rírẹwà, yóo sì yanilẹ́nu dájúdájú nígbàtí ó bá parí. Ṣùgbọ́n, ẹ kò le ní tẹ́mpìlì yíyanilẹ́nu kan ní Winnipeg, tàbí ní ibikíbi míràn, láìní ìpìlẹ̀ líle àti dídúróṣinṣin.

Bí yíyọ́ omi dídì ṣe nwáyé àti àwọn ipò ilẹ̀ ní Winnipeg mú un jẹ́ ìṣòro láti ṣe ìpalẹmọ́ ìpìlẹ̀ tẹ́mpìlì náà. Nítorínáà, ìpinnu di síṣe pé ìpìlẹ̀ fún tẹ́mpìlì yi yío ní àádọ́rin àkójọ àwọn irin tí wọn ó fi sínú kanunkéré. Àwọn àkójọ wọ̀nyí jẹ́ ọgọ́ta ẹsẹ̀ bàtà ní gígùn àti inṣì méjìlá sí ogún ní ipọn. Wọn a jẹ́ títì wọ inú ilẹ̀ títí tí wọn ó fi kan àpáta, ní nkan bíi àádọ́ta ẹsẹ̀ bàtà sí inú ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Ní ọ̀nà yí, àádọ́rin àwọn àkójọ náà pèsè ìpìlẹ̀ líle, dídúróṣinṣin kan fún tẹ́mpìlì rírẹwà ti Winnipeg náà.

Bí Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, a nlépa irú ìpìlẹ̀ dídúróṣinṣin àti dídájú bẹ́ẹ̀ ní ìgbé ayé wa—ìpìlẹ̀ ti ẹ̀mí tí a nílò fún ìrìn-àjò wa la ayé kíkú já àti padà sí ilé wa ọ̀run. Ìpìlẹ̀ náà ni a gbékalẹ̀ ní orí àpáta ti yíyípadà wa sọ́dọ̀ Olúwa Jésù Krístì.

“Àti nísisìyí, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ rántí, ẹ rántí pé ní orí àpáta Olùràpadà wa, ẹnití íṣe Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, ni ẹ̀yin níláti kọ́ ìpìlẹ̀ yín lé, pé nígbàtí èṣù bá sì fẹ́ àwọn ẹ̀fúùfù líle rẹ̀ wá, bẹ́ẹ̀ni, àwọn ọfà rẹ̀ nínú ìjì, bẹ́ẹ̀ni, nígbàtí gbogbo àwọn òkúta yìnyín rẹ̀ àti ìjì líle rẹ̀ bá rọ̀ lé yín, kì yíò ní agbára ní orí yín láti fà yín sọ̀kalẹ̀ sí inú ọ̀gbun òṣì àti ègbé aláìlópin, nítorí àpáta ní orí èyítí a kọ́ yín lé, èyítí íṣe ìpìlẹ̀ dídájú, ìpìlẹ̀ èyítí bí àwọn ènìyàn bá kọ́ lé orí rẹ̀, wọn kì yío ṣubú. ” (Hẹ́lámánì 5:12).

Pẹ̀lú imoore, a ngbé ní àkókò ìgbàtí àwọn wòlíì àti àwọn àpostélì nkọ́ wa nípa Olùgbàlà Jésù Krístì. Títẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn nràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àgbékalẹ̀ ìpìlẹ̀ dídúróṣinṣin nínú Krístì.

Bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti ṣe àlàyé nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa tí ó kọjá, “Àfojúsùn ti Ìjọ láti ìgbà pípẹ́ ni láti ti gbogbo ọmọ ìjọ lẹ́hìn láti mú ìgbàgbọ́ wọn pọ̀ si nínú Olúwa wa Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, láti tì wọ́n lẹ́hìn láti ṣe àti láti pa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, àti láti fúnni lókun àti láti ṣe èdidì àwọn ẹbí wọn.” Nínú ayé dídíjú ti òní yi, eléyí kò rọrùn. Ọ̀tá náà nmú kí atàkò rẹ̀ lórí ìgbàgbọ́ àti lórí àwa àti àwọn ẹbí wa máa pọ̀ síi ní pẹ̀lú ìyára kánkán. Láti yè nípa ti ẹ̀mí, a nílò àwọn ọgbọ́n-àtakò ati ètò ìṣaájú” (“Ọ̀rọ̀ Ìṣíwájú,” Liahona, Nov. 2018, 7; ìtẹnumọ́ àfikún).

Tẹ̀lé ọ̀rọ̀ ti Ààrẹ Nelson, Alàgbà Quentin L. Cook ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá ṣe àfihàn Wá, Tẹ̀lé Mi ohun èlò fún àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan àti àwọn ẹbí. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àwọn ọ̀rọ̀ sísọ wọ̀nyí nínú:

  • “Ohun àṣàrò titun nínú ile Wá, Tẹ̀lé Mi ... ni a gbékalẹ̀ láti ran àwọn ọmọ ìjọ lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere ní inú ilé.”

  • “Ohun èlò yí wà fún gbogbo ẹnìkọ̀ọ̀kan àti ẹbí nínú Ìjọ’ [Wá, Tẹ̀lé Mi—Fún àwọn Ẹnìkọ̀ọ̀kan àti Ẹbí (2019), vi].”

  • “Èrò wa ni láti mú àwọn ìrírí ilé àti Ìjọ báramu ní ọ̀nà tí yíò fi mú ìgbàgbọ́ pọ̀ si àti níti ẹ̀mí àti mímú ìyípadà sí Bàbá Ọ̀run àti Olúwa Jésù Krístì jinlẹ̀.” (“Ìyípadà Pípẹ́ àti Ìjìnlẹ̀ sí Bàbá Ọ̀run àti Olúwa Jésù Krístì,” Liahona, Nov. 2018, 9–10.)

Bẹ̀rẹ̀ nínú Oṣù Kínní ọdún yi, Àwọn Ènìyàn Mímọ́ kárí ayé bẹ̀rẹ̀ síṣe àṣàrò Májẹ̀mú Titun, pẹ̀lú ohun èlò Wá, Tẹ̀lé Mi náà bíi atọ́nà wa. Pẹ̀lú ìlànà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, Wá, Tẹ̀lé Mi nràn wá lọ́wọ́ ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́, ẹ̀kó ti ìhìnrere, àti àwọn ìkọ́ni ti àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì. Ó jẹ́ ohun èlò ìyanu fún gbogbo wa.

Lẹ́hìn oṣù mẹ́sãn ti aápọn àṣàrò ìwé mímọ́ kárí ayé yi, kínni ohun tí a rí? A rí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn níbi gbogbo tí wọn ndàgbà nínú ìgbàgbọ́ àti ìfọkànsìn sí Olúwa Jésù Krístì. A rí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan àti àwọn ẹbí tí wọn nya àkókò sọ́tọ̀ la gbogbo ọ̀sẹ̀ já láti ṣe àṣàrò àwọn ọ̀rọ̀ Olùgbàlà wa. A rí ìkọ́ni ìhìnrere tó ngbèrú síi nínú àwọn àwọn ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi wa bí a ti nṣe àṣàrò ní ilé ti a sì nṣe àbápín àwọn èrò wa ní ilé ìjọsìn. A rí ayọ̀ àti ìrẹ́pọ̀ ẹbí púpọ̀ síi bí a ti sún kúrò ní kíka àwọn ìwé mímọ́ lásán sí ṣíṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ ní ọ̀nà tí ó jinlẹ̀.

Ó ti jẹ́ ànfàní fún mi láti ṣe àbẹ̀wò sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn àti láti gbọ́ nípa àwọn ìrírí wọn pẹ̀lú Wá, Tẹ̀lé Mi. Ìsọ̀rọ̀ wọn nípa ìgbàgbọ́ kún ọkàn mi pẹ̀lú ayọ̀. Ìwọ̀nyí ni díẹ̀ péré nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ onírurú àwọn ọmọ Ìjọ ní oríṣiríṣi apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti ayé:

  • Bàbá kan ṣe àbápín, “Mo gbádùn Wá, Tẹ̀lé Mi bí ó ti npèsè ànfàní láti jẹ́ri nípa Olùgbàlà sí àwọn ọmọ mi.”

  • Ní ilé miràn, ọmọ kan sọ pé, “ààyè kan ni èyí láti gbọ́ àwọn òbí mi ní jíjẹ́ àwọn ẹ̀rí wọn.”s

  • Ìyá kan ṣe àbápín: “A ti ní ìmísí nípa bí a ti le fi Ọlọ́run síwájú. Àkókò tí a [rò pé a] ‘kò ní’ ni ó ti [kún] pẹ̀lú ìrètí, ayọ̀, àlàáfíà, àti àṣeyọrí ní àwọn ọ̀nà tí a kò mọ pé ó ṣeéṣe.”

  • Àwọn tọkọ-taya kan ṣe àkíyèsí: “A nka àwọn ìwé mímọ́ ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀ pátápátá sí bí a ṣe nkà wọ́n tẹ́lẹ̀rí. A nkọ́ ẹ̀kọ́ púpọ̀ síi tóbẹ́ẹ̀ ju bi a ti kọ́ tẹ́lẹ̀rí lọ. Olúwa nfẹ́ kí a rí àwọn nkan ní ọ̀na tí ó yàtọ̀. Olúwa npèsè wa sílẹ̀.”

  • Ìyá kan sọ pé: “Mo fẹ́ràn pé a nkọ́ àwọn ohun kannáà papọ̀. Tẹ́lẹ̀, a máa nkà á ni. Ní òní, a nkọ́ ọ ni.”

  • Arábìnrin kan ṣe àbápín èrò inú ìjìnlẹ̀ yi: “Ṣíwájú, ẹ ti ní ẹ̀kọ́ náà àti àwọn ìwé mímọ́ láti gbè é lẹ́sẹ̀. Nísisìyí, ẹ ní àwọn ìwé mímọ́ àti ẹ̀kọ́ náà láti gbè é lẹ́sẹ̀.”

  • Arábìnrin miràn sọ pé: “Mo nní ìmọ̀lára ìyàtọ̀ nígbàtí mo bá ṣe é [ní àfiwé sí] ìgbàtí èmi kò bá ṣe é. Mo ri pé ó rọrùn síi láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Jésù Krístì àti àwọn ìgbàgbọ́ wa.”

  • Ìyá àgbà kan wípé, “Mo máa npe àwọn ọmọ àti àwọn ọmọ-ọmọ mi ní àwọn Ọjọ́ Ìsinmi, a sì máa nṣe àbápín àwọn ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ láti inú Wá, Tẹ̀lé Mi papọ̀.”

  • Arábìnrin kan ṣe àkíyèsí: “Wá, Tẹ̀lé Mi ní ìmọ̀lára bíi ẹnipe Olùgbàlà nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí mi fúnra ara rẹ̀. Ó jẹ́ ìmísí láti ọ̀run.”

  • Bàbá kan sọ pé, “Bí a ti nlo Wá, Tẹ̀lé Mi, a dàbí àwọn ọmọ Israẹlì, ní síṣe àmì sí àwọn ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà wa, ní dídáàbò bo àwọn ẹbí wa kúrò lọ́wọ́ agbára apanirun náà.”

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ó jẹ́ ayọ̀ láti ṣe àbẹ̀wò síi yín kí a sì gbọ́ bí àwọn aápọn yín pẹ̀lú Wá, Tẹ̀lé Mi ti nbùkún ìgbé ayé yín. Ẹ ṣeun ìfọkànsìn yín.

Síṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ pẹ̀lú Wá, Tẹ̀lé Mi bíi ìtọ́ni nfi okun fún ìyípadà wa sí jésù Krístì àti ìhinrere Rẹ̀. Kìí ṣe pé a kàn dín wákàtí kan kù ní ilé ìjọsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi nítoríi wákàtí kan síi fún àṣàrò ìwé mímọ́ ní ilé. Kíkọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere jẹ́ aápọ̀n títẹramọ́ jálẹ̀ ọ̀sẹ̀. Bí arábìnrin kan ṣe pín pẹ̀lú mi, “Àfojúsùn náà kìí ṣe láti mú ilé ìjọsìn kúrú síi ní ìwọn wákàtí kan; ó jẹ́ láti mú ilé ìjọsìn gùn síi ní ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́fà!”

Nísisìyí, lẹ́ẹ̀kansíi ẹ gbèrò ìkìlọ̀ tí wòlíì wa, Ààrẹ Nelson, fún wa bí ó ṣe nṣí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2018:

‘Ọtá náà nmú kí atàkò rẹ̀ lórí ìgbàgbọ́ àti lórí àwa àti àwọn ẹbí wa máa pọ̀ síi ní pẹ̀lú ìyára kánkán. Láti yè nípa ti ẹ̀mí, a nílò àwọn ètò ìlòdì sí ète àti ìronú ṣíwájú” (Ọ̀rọ̀ Iṣíwájú,” 7).

Nígbànáà (ní nkan bíi wákàtí mọ́kàndínlọ́gbọ̀n lẹ́hìnnáà) ní ọ̀sán Sátidé, ó mú ìpàdé àpapọ̀ náà wá sí òpin pẹ̀lú ìlérí yi: “Bí ẹ ṣe nṣiṣẹ́ pẹ̀lú aápọn láti tún ilé yín ṣe sí ibi ìkẹ́kọ̀ọ́ ìhìnrere, ... agbára ọ̀tá ní ayé yín àti ní ilé yín yío dínkù” (“Dídi Alápẹrẹ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn,” Liahona, Nov. 2018, 113).

Báwo ni àwọn ìkọlù ọ̀tá ṣe le máa pọ̀ síi pẹ̀lú ìyára kánkán ní àkókò kannáà nígbàtí agbára ọ̀tá ndínkù síi nítòótọ́? Ó le ṣẹlẹ̀, ó sì nṣẹlẹ̀ jákèjádò inú Ìjọ, nítorípé Olúwa máa npèsè àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀ dojúkọ àwọn àtakò ọ̀tá náà.. Wá, Tẹ̀lé Mi ni ètò fún ìlòdì sí ète àti ìronú ṣíwájú ti Olúwa. Bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni, “Àwọn ohun èlò tuntun náà tí ó dá lórí ilé, tí Ìjọ sì nṣe àtilẹhìn fún le mú kí ó ṣeéṣe láti sọ agbára àwọn ẹbí di omìnira.” Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, ó nílò yío sì nílò aápọn wa tí ó dára jùlọ; a níláti “[tẹ̀lé] jálẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn àti ìṣọ́ra láti yí àwọn ilé [wa] padà sí ibi mímọ́ ti ìgbàgbọ́”(“Dídi Alápẹrẹ Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ìkẹhìn,” 113).

Ní àkótán, bí Ààrẹ Nelson ti sọ bákannáà, “Olukúlùkù wa ní ojúṣe fún ìdàgbàsókè ti ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní ti ẹ̀mi” (“Ọ̀rọ̀ Ìṣíwájú,” 8).

Pẹ̀lú ohun èlò Wá, Tẹ̀lé Mi, Olúwa npèsè wa sílẹ̀ “fún àwọn àkókò ewu tí a nkojú nísisìyí” (Quentin L. Cook, “Ìyípadà Jíjinlẹ̀ àti Pípẹ́,” 10). Òun nràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àgbékalẹ̀ “ìpìlẹ̀ dídájú náà, ìpìlẹ̀ kan tí ó jẹ́ pé bí àwọn ènìyàn bá kọ́lé sí i, wọn kò le ṣubú” (Helaman 5:12)—Ìpìlẹ̀ ti ẹ̀rí kan tí a mú dúróṣinṣin ninú àpáta ìyípadà wa sí Olúwa Jésù Krístì.

Njẹ́ kí àwọn aápọn wa ojôjúmọ́ ní síṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ ó dáàbò bò wá, kí ó sì mú wa yẹ fún àwọn ìbùkún wọ̀nyí tí a ṣèlérí. Mo gbàdúrà bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.