2010–2019
Wíwà Nínú Májẹ̀mú
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Wíwà Nínú Májẹ̀mú

Láti wà pẹ̀lú Ọlọ́run àti láti rìn pẹ̀lú ara wa ní ipá-ọ̀nà àwọn májẹ̀mú Rẹ̀ ni láti di alábùkúnfún nípasẹ̀ wíwà nínú májẹ̀mú.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, ìtàn náà ni a sọ nípa ọmọdé alakọbẹrẹ tó nkọ́ láti gbàdúrà. “Ẹ ṣé fún lẹ́ta A, lẹta B, ... Lẹta G.” Àdúrà ọmọ ntẹ̀síwájú, “Ẹ ṣe fún àwọn lẹta X, Y, Z. Bàbá Ọ̀run Ọwọn, Ẹ ṣẹ fún nọmba 1, nọmba 2.” Olùkọ́ni Alakọbẹrẹ ndàmú ṣùgbọ́n ó ndúró. Ọmọ náà nwípé, “Ẹ ṣe fún nọmba 5, nọmba 6—àti pé ẹ ṣe fún olùkọ́ni Alakọbẹrẹ mi. Oùn nìkan ni ẹni tí ó ti gbà mí láàyè láti parí àdúrà mi.”

Bàbá Ọ̀run ngbọ́ àdúrà gbogbo ọmọdé. Pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin, Ó npè wá láti wá gbàgbọ́ kí a sì wà sínú májẹ̀mú.

Ayé kún fún ìṣújú, ìrújú, àrékérekè ọwọ́. Ọ̀pọ̀ rẹ̀ dàbíi yíyípada àti órèfé. Nígbàtí a bá gbé àwọn ìbòjú sẹgbẹ, ẹ̀tàn, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìfẹ́ni àti àìfẹ́nì, à nyára ju ọ̀pọ̀ ọ̀ṣọ́-òde, ìsopọ̀ àìpẹ́, tàbí ìgbẹ̀hìn ìlépa asán ifẹ́-araẹni ti ayé. Tìmoore-tìmoore, ọ̀nà kan wà tó lọ sípa àwọn ìdáhùn ọ̀ràn náà.

Nígbà tí a bá débi àwọn òfin Ọlọ́run nlá láti fẹ́ràn Rẹ̀ àti àwọn wọnnì nítòsí wa nípasẹ̀ májẹ̀mú, à nṣe bẹ́ẹ̀ kìí ṣe bíiti àlejò tàbí àjèjì, ṣùgbọ́n bí ọmọ Rẹ̀ nílé.1 Àwọn ọ̀rọ̀ àtijọ́ ṣì jẹ́ òtítọ́ síbẹ̀. Ní jíjọ̀wọ́ arawa sílẹ̀ nínú ayé sí wíwà nínú májẹ̀mú, à nrí a sì ndára jùlọ fún àìnípẹ̀kun arawa2—ní ómínira, ààyè, òtítọ́—kí a sì fìtumọ̀ sí àwọn ìbáṣepọ̀ wa tó ṣe pàtàkì julọ̀. Wíwà nínú májẹ̀mú ni láti ṣe àti láti pa àwọn ìlérí ọ̀wọ̀ mọ́ sí Ọlọ́run àti sí ara wa, nípasẹ̀ àwọn ìlànà, tí ó npe agbára ìwàbí-Ọlọ́run wá láti farahàn nínú ìgbé ayé wa.3 Nígbàtí a bá dá májẹ̀mú gbogbo ohun tí a jẹ́, a lè dà ju bí a ṣe wa. Wíwà nínú májẹ̀mú nfún wa ní ààyè, jíjúwe, okun láti dà bẹ́ẹ̀. Ó nmú àbájáde ìgbàgbọ́ sí ìyè àti ìgbàlà wá.2

Àwọn májẹ̀mú àtọ̀runwá di orísun ìfẹ́ kan fún àti látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Àti pé nípa èyí fún àti pẹ̀lú ara wa. Ọlọ́run, Bàbá wa Ọ̀run, nifẹ wa julọ Ó sì mọ̀ wá ju bí a ṣe nifẹ tàbí mọ arawa. Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti ìyípadà araẹni (ìrònúpìwàdà) nmú àánú, oore ọ̀fẹ́, ìdáríjì wá. Ìwọ̀nyí nmú ìtùnú fún ìpalára, àdánìkanwà, ìrírí àìní-ìdálàre ní ayé-ikú. Jíjẹ́ Ọlọ́run, Bàbá wa Ọ̀run nfẹ́ kí a gba ẹ̀bùn Ọlọ́run to tóbi jùlọ—ayọ̀ Rẹ̀, ìyè ayérayé Rẹ̀.3

Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run májẹ̀mú. Nípasẹ̀ ìwà-àbínibí Rẹ̀, Ó “pa májẹ̀mú mọ́ ó sì fi àánú hàn.”4 Àwọn májẹ̀mú Rẹ̀ dúró pẹ́ “títí bí àkokò yíò ti pẹ́, tàbí tí ilẹ̀ ayé yíò fi dúró, tàbí tí ó [gbọ́dọ̀] fi kù ẹnìkanṣoṣo lórí rẹ̀ tí a ó gbàlà.”5 A kò níláti ṣáko nínú wíwà ní àìnídánilójú àti iyèméjì, ṣùgbọ́n láti yayọ̀ nínú ìkẹ́ àwọn ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú “tó lágbára ju ìdè ikú lọ.”6

Àwọn ìlànà Ọlọ́run àti àwọn májẹ̀mú wà nígbogbo ayé nínú ìbèèrè wọn àti ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú ànfàní wọn. Nínú dídára Ọlọ́run ẹnìkọ̀ọ̀kan ní gbogbo ibi àti ọjọ́ orí lè gba àwọn ìlànà ìgbàlà. Àwọn ìlò Agbára láti yàn wa—ẹnìkọ̀ọ̀kan yàn bóyá láti gba ìfúnni àwọn ìlànà. Àwọn ìlànà Ọlọ́run pèsè òpó-atọ́nà ní ipá-ọ̀nà àwọn májẹ̀mú Rẹ̀. A pe ètò Ọlọ́run láti mú àwọn ọmọ Rẹ̀ wálé ní ètò ìràpadà, ètò ìgbàlà, ètò ìdùnnú. Ìràpadà, ìgbàlà, ìdùnnú sẹ̀lẹ́stíà ṣeéṣe nítorí Jésù Krístì “mu ètùtù pípé yí jáde.”7

Láti wà pẹ̀lú Ọlọ́run àti láti rìn pẹ̀lú ara wa ní ipá-ọ̀nà àwọn májẹ̀mú Rẹ̀ ni láti di alábùkúnfún nípasẹ̀ wíwà nínú májẹ̀mú.

Àkọ́kọ́, wíwà nínú májẹ̀mú dálórí Jésù Krístì bí “olùlàjà májẹ̀mú titun.”8 Gbogbo ohun lè ṣiṣẹ́ papọ̀ fún ire wa nígbàtí a ba di “yíyàsímímọ́ nínú Krístì … nínú májẹ̀mú Bàbá.”9 Gbogbo ire àti ìlérí ìbùkún nwá sọ́dọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n dúró nínú òtítọ́ dé òpin. “Ipò ìdùnnú àwọn wọnnì tí wọ́n pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́” ni láti jẹ́ “alábùkún nínú ohun gbogbo, ní ti ara àti níti ẹ̀mí,” àti láti “gbé pẹ̀lú Ọlọ́run nínú … ìdùnnú àìlòpin.”10

Bí a ti nbọ̀wọ̀ fún àwọn májẹ̀mú wa, a lè fìgbàmíràn ní ìmọ̀làra pé a wà ní ọ̀gbà àwọn ángẹ́lì. A ó jẹ́—àwọn wọnnì tí a nifẹ àti tí wọ́n nbùkún wa ní ẹ̀gbẹ́ ìbòjú yí àti àwọn wọnnì tí wọ́n nifẹ tí wọ́n sì nbùkún wa láti ẹ̀gbẹ́ ìbòjú míràn.

Láìpẹ́ Arábìnrin Gong àti èmi rí wíwà nínú májẹ̀mú ní dídárajùlọ àti ìrọ̀rùn ní yàrá ilé ìwòsàn kan. Bàbá kékeré kan fi ìtara nílò àtúngbìn kíndìnrín kan. Ẹbí rẹ̀ ti sọkún , gbàwẹ̀, àti gbàdúrà fún un láti gba kíndìnrín kan. Nígbàtí ìròhìn wá pé kíndìnrín ìgbàlà-ẹ̀mí kan délẹ̀, ìyàwó rẹ̀ sọ jẹ́jẹ́ pé, “Mo nírètí pé ẹ̀bí míràn wà DÁADÁA.” Láti wà nínú májẹ̀mú ni, nínú àwọn ọ̀rọ̀ Àpọ́stélì Páùlù, “kí nlè nítùnú papọ̀ pẹ̀lú yín nípasẹ̀ ìbárẹ́ ìgbàgbọ́ fún un yín àti èmi.”11

Lẹgbẹ ipá-ọ̀nà ti ìgbé ayé, a lè pàdánù ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n Òun kò pàdánù ìgbàgbọ́ nínú wa. Bí ó ti wà, Iná ìta Rẹ̀ máa nwà ní títàn. Ó pè wá láti wá tàbí padà sí àwọn májẹ̀mú tí ó sàmì sí ipá-ọ̀nà Rẹ̀. Ó ṣetán láti rọ̀mọ́wa, àní nígbàtí a “ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn.”12 Nígbàtí a bá wò pẹ̀lú ojú ìgbàgbọ́ fún àwọn àwòṣe, àtìpó, tàbí ìsopọ̀ àwọn àmì ìrírí wa, a lè rí ìrọ́nú àánú Rẹ̀ àti ìgbani-níyànjú, nípàtàkì nínú àwọn àdánwò wa, ìbànújẹ́, àti àwọn ìpèníjà, bákannáà bí ayọ̀ wa. Bákannáà a máa nkọsẹ̀ tàbí ṣubú nígbàkugbà, tí a bá tẹramọ́ títẹ̀síwájú sí I, Òun yíò rànwálọ́wọ́, ìṣísẹ̀ kan nígbà kan.

Ìkejì, Ìwé ti Mọ́rmọ́nì ni ẹ̀rí gidi tí a lè dìmú nínú ọwọ́ wa ti wíwà nínú májẹ̀mú wa. Ìwé ti Mọ́rmọ́nì ni ohun-èlò ìlérí fún ìkójọ àwọn ọmọ Ọlọ̀run, tí a sọtẹ́lẹ̀ bí májẹ̀mú titun.13 Bí a ti nka Ìwé Mọ́mọ́nì, nípasẹ̀ arawa àti pẹ̀lú àwọn míràn, bóyá kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ tàbí aruwo, a lè bèèrè lọ́wọ Ọlọ́run “pẹ̀lú ọkàn òdodo, pẹ̀lú inú ìrẹ̀lẹ̀, níní ìgbàgbọ́ nínú Krístì,” àti gbígbàá nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́ ìdánilójú Ọlọ́run pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ òtítọ́.14 Èyí pẹ̀lú ìdánilójú pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà wa, Joseph Smith ni wòlíì Ìmúpadàbọ̀sípò, àti pé Ìjọ Olúwa ni à npè ní orúkọ Rẹ̀—Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.15

Ìwé ti Mọ́mọ́nì sọ̀rọ̀ nípa májẹ̀mú àtijọ́ àti òde-òní sí ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ àwọn ọmọ Léhì, “àwọn ọmọ wòlíì.”16 Àwọn bàbánlá yín gba ìlérí májẹ̀mú pé ẹ̀yin, àwọn àtẹ̀lé wọn, yíò dá ohùn kan mọ̀ bíi pé ó wá látinú ẹrùpẹ̀ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì.17 Ohùn náà tí ẹ̀ nni ìmọ̀lára rẹ̀ bi ẹ ṣe nka jẹ́ ẹ̀rí pé “àwọn ọmọ májẹ̀mú” ni yín19 àti pé Jésù ni Olùṣọ́-àgùtàn Rere.

Ìwé Mọ́mọ́nì pe ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, nínú ọ̀rọ̀ Álmà, láti wọnú “májẹ̀mú pẹ̀lú [Olúwa], pé [a] ó sìn kí a sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, kí ó lè da Ẹ̀mí rẹ̀ lé [wa] lórí lọ́pọ̀lọpọ̀.”20 Nígbàtí a fẹ́ láti yípadà fún dídára—bí ẹnìkan ṣe sọọ́, “láti dáwọ́ jíjẹ́ oníròbìnújẹ́ dúró àti láti jẹ́ olùdùnnú jíjẹ́ olùdùnnú”—a lè jí sí dídarí, ìrànlọ́wọ́, àti okun. Nígbàtí a bá wá nípasẹ̀ májẹ̀mú láti wà pẹ̀lú Ọlọ́run àti ìletò àwọn olóòtọ́ onígbàgbọ́ kan, a lè gba ìlérí ìbùkún inú ẹ̀kọ́ ti Krístì21—báyìí.

Ìmúpadàbọ̀sípò àṣẹ oyèàlùfáà láti bùkún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ ni ìkẹ́ta ọ̀nà ti wíwà nínú májẹ̀mú. Ní Àkokò yí, Jòhánù onìrìbọmi àti àwọn Àpọ́stélì Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù ti wá bí àwọn olùránṣẹ́ ológo látọ̀dọ̀ Ọlọ́run sí ìmúpadàbọ̀ àṣẹ oyèàlùfáà Rẹ̀.22 Oyèàlùfáà Ọlọ́run àti àwọn ìlànà Rẹ̀ nmú adùn bá àwọn ìbáṣepọ̀ lórí ilẹ̀ ayé àti ìpàṣẹ májẹ̀mú àwọn ìbáṣepọ̀ láti ní agbára ní ọ̀run.23

Oyèàlùfáà lè bùkúnni láti ọmọ-jòjòló sí orórì—láti ìsọlórúkọ ọmọ-ọwọ́ àti ìbùkún lọ sí ìyàsímímọ́ orórì. Ìbùkún oyèàlùfáà nwòsàn, ntuninínú, ngbani-nímọ̀ràn. Bàbá kan nbínú sí ọmọkùnrin rẹ̀ títí tí ìfẹ́ ìdáríjì fi wá bí bàbá ṣe fún ọmọ rẹ̀ ní ìbùkún oyèàlùfáà ìrọnú. Ọmọ Ìjọ kanṣoṣo nínú ẹbí rẹ̀, ọ̀dọ́mọbìnrin ọ̀wọ́n kan kò ní ìdánilójú nìpa ìfẹ́ Ọlọ́run fún un títí tí ó fi gba ìbùkún oyèàlùfáà onímísí kan. Káàkiri àgbáyé, àwọn akọni bàbánlá múrasílẹ̀ níti ẹ̀mí láti fúnni ní àwọn ìbùkún ti bàbánlá. Bí bàbá nlá bá ti gbé ọwọ́ rẹ̀ lée yín lórí, ó ní ìmọ̀lára ó sì fi ìfẹ́ Ọlọ́run síi yín hàn. Ó nsọ ẹ̀yà yín nínú ilé Ísráẹ́lì. O nfi àwọn ìbùkún látọ̀dọ̀ Olúwa hàn. Ní tèròtèrò, aya bàbánlá kan sọ fún mi bí òun àti ẹbí rẹ̀ ṣe pe Ẹ̀mí ní àwọn ọjọ́ tí Pàpá wọn nfúnni ní àwọn ìbùkún bàbánlá.

Nígbẹ̀hìn, àwọn ìbùkún ti wíwà nínú májẹ̀mú nwá nígbàtí a bà tẹ̀lé wòlíì Olúwa àti yíyayọ̀ nínú gbígbé ìgbé májẹ̀mú, pẹ̀lú ìgbeyàwó. Májẹ̀mú ìgbéyàwó di alágbára jùlọ àti àìlópin bí a ti nyàn ìdùnnú àwọn ọkọ tàbí aya wa àti ẹbí ṣíwájú ti arawa lójoojúmọ́. Bí “èmi” ṣe ndi “àwa,” a ó dàgbà papọ̀. A ó dàgbà di-ògbó papọ̀, a ó dàgbà di-ọ̀dọ̀ papọ̀. Bí a ṣe nbùkún arawa ní gbogbo ìgbà -ayé gbígbàgbé arawa, a ó rí àwọn ìdùnmọ́ni àlá tí a yàn nínú ìrètí jẹ́jẹ́ àti ayọ̀, ní àkokò àti ayérayé.

Nígbàtí àwọn ipò yàtọ̀, ìgbà tí a ti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe, dídárajù tí a lè ṣe, àti fífi tòdodo-tòdodo bèèrè àtí wíwá ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ lẹgbẹ ọ̀nà náà, Olúwa yíò tọ́wásọ́nà, ní ìgbà Tirẹ̀ àti ipò, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.24 Àwọn májẹ̀mú ìgbeyàwó jẹ́ ìdè nípasẹ̀ àṣàyàn ìfaramọ́ ti àwọn wọnnì tí nwọ́n nṣe wọ́n—ìrántí kan nípa Ọlọ́run àti ọ̀wọ̀ wa fún agbára láti yàn àti ìbùkún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ nígbàtí a bá nwa pẹ̀lú ìrẹ́pọ̀.

Àwọn èso wíwà nínú májẹ̀mú káákiri ìran àwọn ẹbí ni à ní ìmọ̀lára rẹ̀ nínú àwọn ilé wa àti ọkàn. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ fàyè gbà mí láti júwe pẹ̀lú àwọn àpẹrẹ araẹni.

Nígbàtí arábìnrin Gong àti èmi nwọnú ìfẹ́ síwájú ìgbeyàwó, mo kọ́ nípa agbára láti yàn àti ìgbèrò. Fún àsìkò ìgbà kan, à ngbé ní orílẹ̀-èdè méjì yíyàtọ̀ ní agbègbè méjì. Òhun ni ìdí tí mo lè fi òótọ́ wípé mo gba oyè gígajùlọ kan ní àwọn ìbáṣe àwọn orílẹ̀-èdè.

Nígbàtí mo bèèrè, “Bàbá Ọ̀run, ṣé kí nfẹ́ Susan? Mo ní ìmọ̀lára àláfíà. Ṣùgbọ́n ìgbà tí mo kọ́ láti gbàdúra pẹ́lú éró òdodo, “Bàbá Ọ̀run, mo nifẹ Susan mo sì fẹ́ fi ṣaya. Mo ṣèlérí pé èmi yíò jẹ́ ọkọ tó dárajùlọ tí mo lè jẹ́”—nígbàtí mo ṣiṣẹ́ tí mo sì ṣe àwọn ìpinnu mi tó dárajùlọ, nígbànáà ni ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ti ẹ̀mí tó lókun jùlọ wá.

Nísisìyí Ìwákiri àwọn igi ẹbí Gong wa àti Lindsay, àwọn ìtàn, àti àwọn fọ́tò nrànwálọ́wọ́ láti ṣàwárí àti láti sopọ̀ nípa ìrírí ìgbé ayé ti wíwà nínú májẹ̀mú ìradíran.26 Fún wa, bíbọ̀wọ̀ fún àwọn àṣíwájú wa pẹ̀lú:

Àwòrán
Alice Blauer Bangerter

Màmá-màmá-màmá Maria Elizabetha Blauer, ẹnití ó ní ìbèèrè fún ìgbeyàwó mẹ́ta ní ọjọ́ kan, lẹ́hìnnáà ó bèèrè lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀ láti ri àtẹ́lẹsẹ̀ ìtisẹ̀ sí bọ́tà ìgún-wàrà rẹ̀ kí ó lè gún bọ́tà, kí ó sì kàá lẹ́ẹ̀kannáà.

Àwòrán
Loy Kuei Char

Bàbá-bàbá-bàbá Loy Kuei Char gbé àwọn ọmọ rẹ̀ sẹ́hìn rẹ̀ àti àwọn ohun ìní ẹbí rẹ̀ díẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bí wọ́n ṣe sọdá pápá lava ní Hawaii Big Island. Ìfọkànsìn àwọn ìran ẹbí Char àti ìrúbọ nbùkún ẹbí wa loni.

Àwòrán
Mary Alice Powell Lindsay

Màmá-màmá Mary Alice Powell Lindsay ní ó kù pẹ̀lú àwọn ọmọ kékeré marun nígbàtí ọkọ rẹ̀ àti ọmọkùnrin àgbà méjèèjì kú lójijì lọ́jọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ síra. Opó fún ọdún mẹ́tàdínláàdọ̀ta, Gram tọ́ ẹbí rẹ̀ pẹ̀lú ìmúdúró ìfẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn olórí àti àwọn ọmọ ìjọ. Ní àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún wọnnì, Gram ṣèlérí fún Olúwa tí Ó bá lè rán òun lọ́wọ́, òun kò ní ráhùn láéláé. Olúwa rán án lọ́wọ́. Kò ráhùn láéláé.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ní ìjẹ́ẹ̀rí sí nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, gbogbo ohun rere àti àìlópin wà ní gbùngbun gbígbé ìgbé ayé òdodo ti Ọlọ́run, Bàbá wa ayérayé, àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, àti Ẹ̀tùtù Rẹ̀. Olúwa wa, Jésù Krístì, ni Alágbàwí májẹ̀mú titun. Jijẹri Jésù Krístì ni èrò májẹ̀mú kan ti Ìwé Mọ́mọ́nì.27 Nípa ìmùlẹ̀ àti májẹ̀mú, èrò Ọlọ́run ní mímú àṣẹ oyèàlùfáà padàbọ̀sípò ni láti bùkún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run, pẹ̀lú ipasẹ̀ májẹ̀mú ìgbéyàwó, ẹbí ìrandíran, àti àwọn ìbùkún ẹnìkọ̀ọ̀kan.

Olùgbàlà wa kéde, “Èmi ni Álfà àti Ómégà, Krístì Olúwa; bẹ́ẹ̀ni, àní èmi ni, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin, Olùràpadà aráyé.”27

Pẹ̀lú wa ní ìbẹ̀rẹ̀, Ó wà pẹ̀lú wa, nínú gbogbo wíwà nínú májẹ̀mú wa, dé òpin. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín