2010–2019
Òfin Ìkejì Nlá
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Òfin Ìkejì Nlá

Ayọ̀ wa títóbijùlọ nwá bí a ṣe nran àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa lọ́wọ́.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, mo dúpẹ́ lọ́wọ yín fún gbogbo ohun tí ẹ̀ nṣe láti kó Ísráẹ́lì jọ ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú, láti fún ẹbí yín lókun, àti láti bùkún ìgbé ayé àwn wọnnì nínú àìní. Ẹ ṣé fún gbígbé bí àwọn àtẹ̀lé Jésù Krístì tòótọ́.1 Ẹ mọ̀ ẹ sì fẹ́ràn láti gbọ́ran sí àwọn òfin Rẹ̀ nlá méjì, láti fẹ́ràn Ọlọ́run àti láti fẹ́ràn ọmọlàkejì yín.2

Ní oṣù mẹ́fà tó kọjá, Arábìnrin Nelson àti èmi pàdé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ènìyàn Mímọ́ bí a ṣe nrìnrìnàjò sí Àárín àti Gúsù Amẹ̀ríkà, àwọn island ti Pacific, àti onírurú ilù-nlá ní United States. Bí a ṣe nrìrìnàjò, ìrètí wa ní láti gbé ìgbàgbọ́ yín ga. Síbẹ̀ à npadà nígbàgbogbo ní fífún ìgbàgbọ́ wa lókun nípasẹ̀ àwọn ọmọ ìjọ àti ọ̀rẹ́ tí a pàdé. Njẹ́ kí nṣe àbápín àwọn àkokò onítumọ̀ mẹ́ta látinú àwọn ìrírí wa láìpẹ́?

Àwòrán
Ààrẹ Nelson ní New Zealand
Àwòrán
Ààrẹ Nelson ní New Zealand

Ní Oṣù Karun, Arábìnrin Nelson àti èmi rìnrìnàjò pẹ̀lú Alàgbà Gerrit W. Àti Arábìnrin Susan Gong sí Gúsù Pacific. Nígbàtí a wà ní Auckland, New Zealand, a ní ọlá ti pípàdé àwọn Ìmáàmù láti ile-kéwú méjì ní ìjọKrístì, New Zealand, nibití wọ́n ti fìbọn pa àwọn olùjọsìn aláìmọ̀ nínú ìṣe ìjà-agbára tó burújáì, ní oṣù méjì péré ṣíwájú.

A nawọ́ ìbánikẹ́dùn wa sí àwọn arákùnrin ti ìgbàgbọ́ míràn wọ̀nyí àti títún ìfarasìn ìbámu wa ṣe sí ẹ̀sìn òmìnira.

Bákannáà a fi iṣẹ́ ọ̀fẹ́ fúnnì àti ìbámu átìlẹhìn ow´ láti tún àwọn ilé-kéwú náà kọ́. Ìpàdé wa pẹ̀lú àwọn olórí Mùsùlùmí wọ̀nyí kún pẹ̀lú ìfihàn ipò jẹ́jẹ́ arákùnrin.

Àwòrán
Àga-abirùn ní Argetina
Àwòrán
Àga-abirùn ní Argetina

Ní Oṣù Kẹjọ, lẹgbẹ pẹ̀lú Alàgbà Quentin L. àti Arábìnrin Mary Cook, Arábìnrin Nelson àti èmi pàdé àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan ní Buenos Aires, Argentina—púpọ̀ jù nínú wọn kìí ṣe ọmọ ìgbàgbọ́ wa—tí ayé wọn ti yípadà nípa àwọn àga-yíyí tí àwọn Olùrannilọ́wọ́ Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ti pèsè fún wọn. A ní ìmísí bí wọ́n ṣe nfi ayọ̀ tó kún fún ìmoore hàn fún ohun àrìnkà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà.

Àkokò iyebíye kẹta ṣẹlẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ péré sẹ́hìn nihin ní Ìlú-nlá Salt Lake. Ó wá látinú lẹ́tà tó tayọ kan ní ọjọ́ ìbí mi látọ̀dọ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin kan tí èmi ó pè ní Mary—ọmọ ọdún mẹ́rìnlá.

Mary kọ àwọn ohun tí èmi àti òun ní tó wọ́pọ̀: “Ìwọ ní ọmọ mẹwa. Àwa ní ọmọ mẹwa. Ìwọn nsọ Mandarin. Méje lára àwọn ọmọ nínú ẹbí mi, pẹ̀lú èmi, ni a gbà tọ́ láti China, nítorínáà Mandarin ni èdè àkọ́kọ́ wa. Ìwọ jẹ́ oníṣẹ́ abẹ ọkàn. Arábìnrin mi ti ṣe [àwọn iṣẹ́-abẹ] ṣíṣí-ọkàn méjì. Ìwọ fẹ́ràn ìjọ oníwákàtí-mejì. Àwa fẹ́ràn ìjọ oníwákàtí-mejì. Ìwọ ní ìtẹ́sí pípé. Arákùnrin mi bákannáà ní ìtẹ́sí pípé. Ó fọ́ lójú bíi tèmi.”

Àwọn ọ̀rọ̀ Mary kàn mí lọ́kan jinlẹ̀jinlẹ̀, tí kò fi ẹ̀mí nlá rẹ̀ nìkan hàn ṣùgbọ́n bákannáà ìfọkànjìn ti ìyá àti Bàbá rẹ̀.

Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, bíiti àwọn àtẹ̀lé ti Jésù Krístì míràn, nfi ìgbàgbogbo wá àwọn ọ̀nà láti ṣèrànwọ́, láti gbé ga, àti láti fẹ́ràn àwọn ẹlòmíràn. Àwọn tí wọ́n nfẹ́ láti gba orúkọ ènìyàn Olúwa “nfẹ́ láti gba àjàgà arawa, ... Láti ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tó nṣọ̀fọ̀; ... àti [láti] tu àwọn wọnnì tí wọ́n dúró nínú àìní ìtùnú.”3

Wọ́n nwá nítòótọ́ láti gbé àkọ́kọ́ àti ìkejì nlá àwọn òfin. Nígbàtí a bá fẹ́ràn Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, Ó nyí ọkàn wa padà sí wíwà-láláfíà àwọn ẹlòmíràn nínú agbo ìwàrere, ẹlẹ́wà kan.

Yíò ṣeéṣe láti ka oye iṣẹ́ ìsìn tí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn nfúnni yíká àgbáyé ní gbogbo ọdún, ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe láti ka ire tí Ìjọ bí ìṣètò kan ti ṣe láti bùkún àwọn ọkùnrin àti obìnrin—ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin—tí wọ́n wà nínú àìní ìrànlọ́wọ́.

Ìnawọ́-jáde olùrànnilọ́wọ́ Ìjọ ni a gbé kalẹ̀ ní 1984. Nígbànáà Ìjọ kọ́ọ̀kiri gbàwẹ̀ láti kó owó jọ láti ti àwọn olùpọ́njú nípasẹ̀ ọ̀gbẹlẹ̀ ìparun ní ìlà-òòrùn Áfríkà. Àwọn ọmọ Ìjọ dá míllíọ̀nù Dólà mẹ́fà àti mẹ́rin ní ọjọ́ kanṣoṣo àwẹ̀ náà.

Àwòrán
Lẹ́hìnnáà-Alàgbà ní Ethiopia

Nígbànáà Alàgbà M. Russell Ballard àti Ar´kùnrin Glenn L. Pace la rán lọ sí Ethiopia láti yẹ bí a ṣe lè fi àwọn owo yíyàsọ́tọ̀ náà sí ìwúlò dídárajùlọ. Ìtiraka yí fi ìbẹ̀rẹ̀ ohun tí a ó mọ̀ gẹ́gẹ́bí Arannilọ́wọ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn han.

Látìgbà náà, àwọn Arannilọ́wọ́ Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ti pèsè ju bílíọ̀nù méjì dọ́là ní ìrànlọ́wọ́ láti ti àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú àìní káàkiri ayé. Àtìlẹhìn yí ni a fún àwọn olùgbà láìka ìbáṣe pẹ̀lú Ìjọ sí, orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, ìkọ́ni lórí ìbálopọ̀, akọ tàbí abo, tàbí ìtanni òṣèlú.

Ìyẹn kò tán síbẹ̀. Láti ṣe àtìlẹ̀hìn àwọn ọmọ Ìjọ Olúwa tí wọ́n wà nínú ìpọ́njú, a ní ìfẹ́ a sì ngbé ìgbé àṣẹ àtijọ́ nípa ààwẹ̀ .4 À npebi láti ran àwọn ẹlòmírán tí ebi npa lọ́wọ́. Níjọ́ kan lóṣooṣù, a nlọ láìsí oúnjẹ a sì ndá oye owó oúnjẹ náà (àti díẹ̀ si) láti ran àwọn wọnnì nínú àìní.

Èmi kò ní gbàgbé ìbẹ̀wò mi àkọ́kọ́ sí Áfríkà ní 1986 láéláé. Àwọn ènìyàn Mímọ́ wá sí àwọn ìpàdé wa lọ́pọ̀lọpọ̀. Bíótilẹ̀jẹ́pé ọ̀pọ̀ ní ohun àlùmọ́nì díẹ̀, púpọ̀ wá nínú ẹ̀wù funfun àìlábàwọ́n.

Mo bèèrè lọ́wọ́ ààrẹ èèkan bí ó ṣe ntọ́jú àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n ní ohun díẹ̀ lásán. Ó fèsì pé àwọn bíṣọ́ọ̀pù mọ ènìyàn wọn dáadáa. Tí àwọn ọmọ ìjọ bá lè ní oúnjẹ ẹ̀ẹ̀méjì lójúmọ́, kọ̀ sí ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò. Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá lè ní oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kanṣoṣo tàbí dínkù ju bẹ́ẹ̀—àní pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹbí—àwọn bíṣọ́ọ̀pù npèsè oúnjẹ, látinú ọrẹ-ẹbọ. Lẹ́hìnnáà ó fi òtítọ́ olókìkì yí kun pé: ìdáwó ẹbọ-ọrẹ máa npọ̀ ju ìnáwó wọn lọ. Ẹbọ-ọrẹ púpọ̀ nlọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn níbòmíràn nígbànáà tí wọ́n nínú àìní tó ju tiwọn lọ. Àwọn alágbára Ènìyàn Mímọ́ Áfríkà wọnnì kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ nlá nípa agbára ti àṣẹ àti ti ẹ̀mí nípa ààwẹ̀.

Bí àwọn ọmọ Ìjọ, á nímọ̀lára ìbátan sí àwọn wọnnì tí wọ́n njìyà ní ọ̀nàkọnà.5 Gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run, gbogbo wa jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin. A gbọ́ ìkìlọ̀ Májẹ̀mú láéláé kan: “Ìwọn yíò la ọwọ́ rẹ̀ tán sí arákùnrin rẹ̀, sí òtòṣì rẹ, àti sí aláìní rẹ̀.”6

Bákannáà a nlàkàkà láti gbé ìgbé ayé àwọn ìkọ́ni Olúwa Jésù Krístì bí a ṣe kọ́sílẹ̀ ní Máttéù 25:

“Nítorí ebi pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjc, óungbẹ ngbẹ mí, ẹ̀yin fún mi ní ohun mímu: mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì gbà mí sí ilé.

Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin daṣọ bò mí: mo ṣe àìsàn, ẹ̀yin sì bojútó mi. ...

“… Níwọn bí ẹ̀yin ti ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí tí ó kére jùlọ ẹ̀yin ti ṣeé fún mi.”7

Ẹ jẹ́ kí nfún yín ní àwọn àpẹrẹ díẹ̀ bí Ìjọ ṣe ntẹ̀lé àwọn ìkọ́ni nípa Olùgbàlà wọ̀nyí.

Àwòrán
Ilé ìṣura ti Bíṣọ́ọ̀pù

Láti ran elébi lọ́wọ́, Ìjọ nṣe ilé-ìṣura bíṣọ́ọ̀pù mẹ́rìnlélọ́gọ́fà káàkiri ayé. Nípa wọn, bíi irínwó ẹgbẹ̀rún kíkó oúnjẹ fúnni ní à nṣe lọ́dọọdún fún àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àìní. Ní àwọn ibi tí kò sí ilé-ìṣura, àwọn bíṣọ́ọ̀pù àti ààrẹ ẹ̀ka nmú látinú owó ẹbọ-ọrẹ Ìjọ láti pèsè oúnjẹ àti ohun èlò fún àwọn ọmọ ìjọ aláìní wọn.

Bákannáà, ìpènijà ebi kọjá àlà Ìjọ. Ó sì npọ̀si káàkiri ayé. Ìròhìn àìpẹ́ United Nations fihàn pé oye àwọn ènìyàn elébi ní ayé nísisìyí ju míllíọ̀nù irínwó méjì lélógún—tàbí ọ̀kan nínú mẹsan ti àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé.8

Irú ìbàlẹ̀ ìṣirò tí èyí jẹ́! Bí ìmoore wa ṣe tó fún àwọn ìdáwó yín. A dúpẹ́ fún àwọn inúrere àtinúwa yín, àwọn míllíọ̀nù káàkiri ayé yíò gba ọpọ̀ oúnjẹ tí wọ́n nílò, ẹ̀wù, ibùgbé ránpẹ́, àga-yíyí, òògùn, omi mímọ́, àti púpọ̀ síi.

Ọ̀pọ̀ àìsàn káàkiri ayé ni omi àìmọ́ nfàsílẹ̀. Di òní, etò rírannilọ́wọ́ Ìjọ ti ṣèrànwọ́ láti pèsè omi mímọ́ ní ọgọọgọ́ọ̀rún àwọn ìletò ní orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínlọ́gọ́rìn.

Iṣẹ́ kan ní Luputa, ní Democratic Republic ti Congo, ni àpẹrẹ nlá. Pẹ̀lú ìkànìyàn tó kọjá ọgọ́ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún, ìlú náà kò ní omi tó nṣàn kankan. Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè náà ní láti rìn lọ ibi jínjìn fún orísun omi dáadáa. Bíótilẹ̀jẹ́pé wọ́n ṣàwárí ìṣàn òkè kan ní máìlì méjìdínlógún síwájú, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìlú kò lè pọn omi níbẹ̀ déédé.

Àwòrán
Gbígbẹ́ ìsún kan fún omi

Nígbàtí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere olùrannilọ́wọ́ wa kọ́ nípa ìpènijà yí, wọ́n ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn olórí Luputa nípa fífún wọn ní àwọn ohun èlò àti ìdánilẹ́ẹ̀kọ́ láti ri páìpù omi sí ìlú nlá náà. Àwọn ènìyàn Luputa lo ọdún mẹ́ta ní gbígbẹ́ Jíjìn-mítà-kan lọ nínú òkúta àti igbó. Nípa ṣíṣe iṣẹ́ papọ̀, ọjọ́ aláyọ̀ náà dé níparí nígbàtí omi tútù, mímọ́ wà ní gbogbo ìletò náà.

Àwòrán
Gbígbé omi

Bákannáà Ìjọ ran àwọn olùsálọ̀, bóyá láti ìjà abẹ́lé, ìbàjẹ́ àdánidá, tàbí ìninilára ẹ̀sìn. Ju míllíọ̀nù àádọ́rin ènìyàn ló sọ ibùgbè wọn nù nísisìyí.9

Àwòrán
Ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn olùkọ́lọ

Ní ọdún 2018 nìkan Ìjọ pèsè àwọn ohun pajáwìrì fún àwọn rẹfují ní orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínlọ́gọ́ta. Ní àfikún, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Ìjọ yọ̀ọ̀dà àkokò wọn láti ran àwọn rẹfují lọ́wọ́ láti darapọ̀mọ́ àwọn ìletò titun. A dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan yín tí wọ́n nawọ́ jáde láti ran àwọn wọnnì tí wọ́n ngbìyànjú láti gbèra wọn kalẹ̀ sínú ilé titun.

Àwòrán
Pípín Ẹ̀wù

Nípa àwọn ìdáwó inúrere sí àwọn ẹ̀ká ilé-iṣé Deseret ní United States, àwọn míllíọ̀nù ìwọ̀n ẹ̀wù ni a gbà tí a sì nṣà lọ́dọọdún. Nígbàtí àwọn bíṣọ́ọ̀pù ìbílẹ̀ nlo ìyára kà yí láti ran àwọn ọmọ ìjọ nínú àìní lọ́wọ́, apákan títóbijùlọ ni à nfún àwọn ìṣètò olùrannilọ́wọ́ míràn tí wọ́n pín àwọn nkan wọ̀nyí káàkiri ayé.

Ní ọdún tó kọjá lásán, Ìjọ pèsè ìtọ́jú ojú fún àwọn ènìyàn tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwo dínlọ́gọrun ní orílẹ̀ èdè marundinlogojì, itọ́jú ọmọ-bíbí fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìyá àti ọmọ-ọwọ́ ní orílẹ̀-èdè mọ́kàndílógójì, àti àwọn àga-yíyí fún àwọn èníyàn tó ju àádọ́ta tí wọ́n ngbé ní dọ́sìnì orílẹ̀-èdè.

A mọ̀ Ìjọ dáadáa fún wíwà ní àárín àwọn olùfèsì àkọ́kọ́ nígbàtí àjálù bá ṣẹlẹ̀. Àní ṣíwájú kí ìjì líle tó wá, àwọn olórí Ìjọ àti òṣìṣẹ́ ní àwọn ibi ìṣẹ̀lẹ̀ n ṣètò bí wọn ó ṣe ko àwọn ohun ìrànlọ́wọ́ lọ àti àtìlẹhin sí, àwọn wọnnì tí yíò gbàá.

Àwòrán
Sísìn pẹ́lú àwọn Ọwọ̀ Ìrannilọ́wọ́

Lọ́dún tó kọjá nìkan, Ìjọ ṣe àwọn iṣẹ́ ìrànlọ́wọ́-ìjàmbá yíká ayé, ní ríran àwọn olùpalára ìjì-líle, iná, àgbàrá, ìsẹ́lẹ̀, àti àwọn àjálù míràn. Nígbàkugbà tó bá ṣeéṣe, àwọn ọmọ Ìjọ nínú ẹ̀wù yẹ́lò Ọ́wọ́ Rírannilọ́wọ́ nkó àwọn púpọ̀ jọ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn wọnnì tí a pọ́nlójú nípa ìjàmbá. Irú iṣẹ́ ìsìn yí, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe nípasẹ̀ ara yín, ní àkójá ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ gan an.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, àwọn ìṣe tí mo ṣàpèjúwe kàn jẹ́ apákan kékeré ti mímú aláfià àti ìnawọ́síta ìrannilọ́wọ́ ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn dàgbà ni.10 Àti pé ẹ̀yin ni àwọn tí yíò mú gbogbo èyí ṣeéṣe. Nítorí ìgbé ayé alápẹrẹ yín, ọkàn inúrere yín, àti ọwọ́ ìrannilọ́wọ́ yín, ìdí náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìletò àti àwọn olórí ìjọba ṣe nyin àwọn ìtiraka wa.11

Látìgbà tí mo ti di Ààrẹ Ìjọ, ó ti yàmílẹ́nu oye ààrẹ, àwọn olórí òṣìṣẹ́, àti àwọn oníṣẹ́ ọba ti fi tòdodotòdodo dúpẹ́ lọ́wọ́ mi fún iṣẹ́ ìrannilọ́wọ́ wa sí àwọn ènìyàn wọn. Wọ́n ti fi ìmoore hàn fún okun tí àwọn ọmọ ìjọ́ olóòtítọ́ nmú wá sí orílẹ̀-èdè wọn bí olódodo, olùdáwó ọmọ orílẹ̀-èdè.

Bàkannáà ó yàmílẹ́nu bí àwọn olórí ayé ti bẹ Àjọ Ààrẹ Ìkínní wò tí wọ́n sì fi ìrètí wọn hàn fún ìgbékalẹ̀ Ìjọ ní àwọn ilẹ̀ wọn. Kínìdí? Nítorí wọ́n mọ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn yíò ṣèrànwọ́ láti gbé àwọn ẹbí àti ìletò alágbára dìde, ní mímú ìgbé ayé àwọn ẹlòmíràn dára si ní ibikíbi tí wọ́n ngbé.

Láìka ibi tí a pè ní ilé sí, àwọn ọmọ Ìjọ nní ìmọ̀lára taratara nípa Ipò-bàbá ti Ọlọ́run àti ipò-arákùnrin ti ènìyàn. Báyìí, ayọ̀ wa tó tóbijùlọ nwá bí a ṣe nran àwọn arábìnrin áti arákùnrin wa lọ́wọ́, níbikíbi yówù kí a máa gbé nínú ayé ìyanu yí.

Fífún àwọn ẹlòmíràn ní ìrànlọ́wọ́—ṣíṣe ìtiraka taratara láti tọ́jú àwọn ẹlòmíràn gan an tàbí ju bí a ṣe ntọ́jú arawa—ni ayọ̀ wa. Nípàtàkì, mo lè fikun pé, nígbàtí kò bá rọrùn àti nígbàtí ó bá nmú wá kúrò ní ibi ìtura wa. Gbígbé òfin nlá ìkejì náà ni kókó dídàbíi ọmọlẹ́hìn tòótọ́ Jésù Krístì.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, ẹ̀ ngbé ìgbé alápẹrẹ ti èso tó nwá látinú títẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín! Mo nifẹ yín.

Mo mọ̀ pé Ọlọ́run wà láàyè. Jésù ni Krístì. Ìjọ Rẹ̀ ni a ti múpadàbọ̀sípò ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí láti mú àwọn èrò tọ̀run wa ṣẹ. Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ ti Jésù Krístì, àmín.