2010–2019
Okun ti Ẹ̀mí
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Okun ti Ẹ̀mí

Bí ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì olotitọ, ẹ lè gba ìmísí araẹni àti ìfihàn, léraléra pẹ̀lú àwọn òfin Rẹ̀, tí a ṣètò síi yín.

Bí mo ṣe nfi àgọ́ àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin sílẹ̀ ní ìgbà ẹ̀rùn yín, ọ̀dọ́mọbìnrin kan dídára kan fún mi ní àkọsílẹ̀ ránpẹ́. Nínú rẹ̀, ó bèèrè, “Báwo ni mo ṣe lè sọ ìgbàtí Ọlọ́run bá ngbìyànjú àti sọ ohunkan fún mi? Mo nifẹ ìbèèrè rẹ̀. Àwọn ẹ̀mí wa nwá ìsopọ̀ kan pẹ̀lú ilé tọ̀run wa. A fẹ́ láti ní ìmọ̀ara ìnílò àti ìwúlo. Ṣùgbọ́n nígbàmíràn a nlàkàkà láti mọ ìyàtọ̀ nínú àwọn èrò tiwa àti àwọn itẹ̀mọ́ra jẹ́jẹ́ ti Ẹ̀mí. Àwọn wòlíì, àtijọ́ àti òde-òní, ti kọ́ni pé “tí ohunkan bá pèni tí ó sì nfanimọ́ra láti ṣe rere, ónwá látọ̀dọ̀ Krístì.”1

Ààrẹ Russell M. Nelson ti nawọ́ ìfipè alágbára, jẹ́jẹ́: “Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti mú okun ti ẹ̀mí yín lékún láti gba ìfihàn. … Yàn láti ṣe iṣẹ́ ti ẹ̀mí tí ó yẹ láti gbádùn ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ àti láti gbọ́ ohùn ti Ẹ̀mí lemọ́lemọ́ si àti kedere síi.”2

Ìfẹ́ mi ní ààrọ́ yí ni láti sọ̀rọ̀ fún yín látinú ọkàn mi nípa ọ̀nà mẹrin láti ní àlékún okun ti ẹ̀mí láti gba ìfihàn.

1. Mọ̀ọ́mọ̀ máa dá Àkokò Sílẹ̀ àti Ààye láti Gbọ́ Ohùn Ọlọ́run

Bí ẹ ṣe nyàn láti yọ jáde àti láti mú àkokò lójoojúmọ́ láti súnmọ́ ohùn Ọlọ́run, nípàtàkì nínú Ìwé Mọ́mọ́nì, nígbà díẹ̀, ohùn Rẹ̀ yíò di kedere àti mímọ̀ síi yín.

Ní ìlòdìsí, àwọn ìdààmú àti aruwo tí ó kún ayé àti àwọn ilé wa àti ìgbé ayé wa lè mú u ṣòrò si láti gbọ́ ohùn Rẹ̀.and our lives can make it more difficult to hear His voice. Àwọn ìdàmú wọ̀nyí lè gba inú àti ọkàn wa tí a kò ní fàyè gba àwọn ìṣìlètí jẹ́jẹ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́ náà mọ́.

Wòlíì Joseph Smith kọ́ni pé Ọlọ́run nfi Ararẹ̀ hàn nígbàkugba “sí ẹnìkọ̀ọ̀kan níkọ̀kọ̀, níbi iṣẹ́ wọn; ní akinjù tàbí pápá, àti pé láìsí aruwo tàbí ìrúkèrúdò gbogbogbò.”3

Sátánì nfẹ́ láti yà wá kúrò nínú ohùn Ọlọ́run nípa pípa wá mọ́ kúrò ní àwọn ibi jẹ́jẹ́. Tí Ọlọ́run bá nsọ̀rọ̀ ní ohùn jẹ́jẹ́, kékeré, ẹ̀yin àti èmí nílò láti súnmọ́ láti gbọ́ Ọ. Kàn ro ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ tí a bá wa digbí ní dídúró ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ọ̀run bí a ṣe ndúró lórí wífì! Mú àkokò kan àti ibi, láti fetísílẹ̀ láti gbọ́ ohùn Ọlọ́run lojoojúmọ́. Pa ìpàdé mímọ́ yí mọ́ pẹ̀lú ìṣedéédé, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ dá léè lórí!

2. Ṣé ìṣe láì Dádúró

Nígbàtí ẹ bá gba àwọn ìṣílétí àti lẹ́hìnnáà ṣe ìṣe pẹ̀lú ìrò, Olúwa lè lò yín. Bí ẹ ṣe nṣe ìṣe si, ni ohùn Ẹ̀mí yíò di ìdámọ̀ fún yín. Ẹ ó dá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run mọ̀ lọ́pọ́lọpọ̀ áti pé Òun “nfẹ́ ... láti fi inú Rẹ àti ìfẹ́ hàn wá.”5 Tí ẹ bá dáwọ́dúró, ẹ lè gbàgbé ìṣílétí tàbí ṣi ààyè láti ran ẹnìkan lọ́wọ́ fún Ọlọ́run.

3. Ẹ Gba Ìránṣẹ́ Yín látọ̀dọ̀ Olúwa

Àdúrà Bàbá Ọ̀run dàbí yíyára láti dáhùn ẹ̀bẹ̀ wa láti gba ìdarí lọ bá ẹnìkan tó nílò ìrànlọ́wọ́ wa. Ààrẹ̀ Eyring ti kọ́ wa láti wá ìfihàn nípasẹ̀ bíbèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ẹnití ó lè rànwálọ́wọ́ fún Un. “Tí ẹ bá bèèrè àwọn ìbèèrè bíi pé, Ẹ̀mí Mímọ́ yíò wá àti pé ẹ ó ní ìmọ̀lára jẹ́jẹ́ nípa àwọn ohun tí ẹ lè ṣe fún àwọn ènìyàn míràn. Nígbàtí ẹ bá lọ tí ẹ sì ṣe àwọn ohun wọnnì, ẹ̀ wà ní ìránṣẹ́ Olúwa, àti pé nígbàtí ẹ bá wà ní ìránṣẹ́ Olúwa, ẹ yege fún ẹ̀bùn Ẹ̀ní Mímọ́.”6

Ẹ lè gbàdúrà kí ẹ sì bi Olúwa fún ìránṣẹ́ kan. Bí ẹ ti nṣeé, Òun lè lo iṣẹ́ yín lásán láti mú iṣẹ́ títayọ Rẹ̀ ṣẹ.

Àwòrán
Bàbá-ìyá Arábìnrin Fritz Lundgren

Bàbá [ìyá mi], Fritz Hjalmar Lungren, kúrò ní Sweden nígbàtí ó wà ní ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún. Ó dé Amẹ́ríkà lóun-nìkan, pẹ̀lú àpótí-aṣọ kan àti pé ní ọdún mẹ́fà ilé-ìwé. Láìlè sọ Èdè Gẹ̀ẹ́sì kankan, ó wá ọ̀nà rẹ̀ lọ sí Oregon ó sì ṣiṣẹ́ níbẹ̀ bí agégi, àti pẹ̀lú ìyá-ìyá mi àti ìyá mi, darapọ̀ mọ́ Ìjọ. Kò ṣàkóso lórí wọ́ọ̀dù kankan rárá, ṣùgbọ́n bí olùkọ́ni ilé olotitọ, ó nmú ju ẹbí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ọta wá sí ìṣeré ìjọ. Báwo ni ó ti ṣe ìyẹn?

Lẹ́hìn ikú ti bàbá ìyá mi, mo nwo inú àpótí ìwé rẹ̀ kan mo sì rí lẹ́tà kan tí a kọ nípasẹ̀ ọkùnrin kan ẹni tí ó padà wá sí ìjọ nítorí ìfẹ́ Bàbá ìyá mi. Lẹ́tà náà ka pé, “Ohun ìkọ̀kọ̀ arákùnrin Fritz, mo gbàgbọ́, ni pé òun nfi ìgbàgbogbo wà ní ìránṣẹ́ fún Bàbá Ọ̀run.”

Lẹ́tà náà wá látọ̀dọ̀ Arákùnrin Wayne Simonis. Bàbá ìyá mi bẹ̀ ẹ́ wò ó sì ọ ẹnìkọ̀ọ̀kan ọmọ ẹbí wọn. Ní àkokò, Bàbá ìyá mi sọ fún wọn pé wọ́n nílò wọn àti pé ó pè wọ́n láti wá sí ìjọ. Ṣùgbọ́n ní Ọjọ́-ìsinmi náà, Arákùnrin Simonis jí pẹ̀lú ewu—kò tíi parì titún òrùlé ilé rẹ̀ ṣe òjò sì nbọ̀ ní ọ̀sẹ̀ náà. Ó gbèrò pé òun ó lọ́ sílé-ìsìn, bọwọ́ pẹ̀lú Bàbá ìyá mi, ṣùgbọ́n kó kúrò kí ó sì lọ sílé láti parí òrùlé. Ẹbí rẹ̀ kò lè wá sí ìpàdé oúnjẹ́ Olúwa láìsi níbẹ̀.

Ètò rẹ̀ nṣiṣẹ́ dáradára, títí, dé orí òrùlé, tí òun gbọ́ẹnìkan tó ngun àtègùn náà. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Nígbàtí mo wòkè ...ẹni to dúró ní òkè àtẹ̀gùn náà ni Arákùnrin Fritz. Ó kàn fún mi ní ẹ̀rín nlá. Ní àkọ́kọ́, ojú tì mí mo sì nímọ̀ bíìpé ọmọdé kan tí a mú fún sísá ilé-ìwé. Lẹ́hìnnáà ... Mo ní ìmọ̀ irunú. [Ṣùgbọ́n Arákùnrin Fritz kàn] gbé ẹ̀wù kóòtù kúrò ó sì fi há àtẹ̀gùn. Bí ó ti yí apá ẹ̀wù funfun rẹ̀ sókè, ó yípadà sí mi ó sì wípé, ‘Arákùnrin Simonis, ṣe o ní hámà míràn? Iṣẹ́ yí gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì gidi tàbí ẹ kò ti ní fi ẹbí yín sílẹ̀, àti pé tó bá ṣe pàtàkì, mo fẹ́ láti ràn yín lọ́wọ́. Bí mo ṣe nwo ojú rẹ̀, mo rí inúrere nìkan àti ìfẹ́ bíiti Krístì. Ìrunú mi kúrò. ... Mo gbé ohun èlò mi sílẹ̀ ní Ọjọ́-ìsinmi náà mo sì tẹ̀lé ọ̀rẹ́ mi lọ sílẹ̀ àtẹ̀gùn àti padà sí ilé-ìjọsìn.”

Bàbá ìyá mi ti gba ìránṣẹ́ rẹ̀ látọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì mọ̀ pé òun níláti wá àwọn àgùtàn tó sọnù. Gẹ́gẹ́bí arákùnrin mẹ́rin tí wọ́n gbé ọ̀rẹ́ wọn pẹ̀lú ààrun sórí òrùlé tí wọ́n sì gbe kalẹ̀ lẹ́hìnnáà láti gba ìwòsàn nípasẹ̀ Jésù Krístì,7 bẹ́ẹ̀náà ni ìránṣẹ́ Bàbá ìyá mi ṣe gbe lọ sórí òrùlé. Olúwa nfi ìfìhàn ránṣẹ́ sí àwọn wọnnì tí wọ́n nwá láti ran àwọn míràn lọ́wọ́.

4. Ẹ Gbàgbọ́ Kí Ẹ Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé

Láìpẹ́, mo kà nípa ìránṣẹ́ ìhìnrere nlá míràn ẹnití ó gba ìránṣẹ́ rẹ̀ látọ̀dọ̀ Olúwa. Árọ́nì nkọ́ ọba àwọn Lámánáítì, ẹnití ó yà lẹ́nú ìdí tí arákùnrin Árọ́nì Ámọ́nù kò wá bákannáà láti kọ ọ́. Áárọ́nì sì wí fún ọba nã pé: Kíyèsĩ, Ẹ̀mí Olúwa ti darí rẹ̀ sí ọ̀nà míràn.8

Ẹ̀mí sọ̀rọ̀ sí ọkàn mi: ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní iṣẹ́ ìránṣẹ́ tó yàtọ̀ láti ṣe, àti ní ìgbàmíràn Ẹ̀mí lè pè wá sí “ọ̀nà míràn.” Àwọn ọ̀nà púpọ̀ wa láti gbé ìjọba Ọlọ́run ga bí olùṣe-májẹ̀mú, olùpamọ́-májẹ̀mú ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì. Bí ọmọẹ̀hìn olotitọ Rẹ̀, ẹ lè gba ìmísí araẹni àti ìfihàn, léraléra pẹ̀lú àwọn òfin Rẹ̀ tí a ṣètò síi yín. Ẹ ní àwọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ tó tayọ àti àwọn ojúṣe láti ṣe nínú ayé àti tí a ó fún ní ìtọ́nisọ́nà tó tayọ láti mú wọn ṣẹ.

Néfì, arákùnrin Jared, àní gbogbo wọn àti Mósè ní omi títóbi láti là kọjá—ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ṣeé yàtọ̀. Néfì ṣiṣẹ́ “ọnà igi lóríṣiríṣi.”8 Arákùnrin Járẹ́dì kọ́ ọkọ̀ omi to “fún pọ̀ bi igbá kan.”9 Àti pé Mósè “lórí ìyànjẹ ilẹ̀ ní àárín òkun.”10

Ọ̀kọ̀ọ̀kan gba ìdárí ti-araẹni, tí a ṣètò sí wọn, àti pé ẹnìkọ̀ọ̀kan nigbẹkẹlé wọ́n sì ṣe ìṣe. Olúwa nwo àwọn wọnnì tí wọ́n gbọ́ran àti, nínú àwọn ọ̀rọ̀ Néfì, yíò “múra ọ̀nà kan sílẹ̀ fùn [wa láti] yege nínú ohun èyí tí òun ti pàṣẹ.”12 Ṣàkíyèsí pé Néfì wípé, “ọ̀nà kan”— kìí ṣeọ̀nà náà.

Ṣe a ó sọ́nu tàbí mú ìránṣẹ́ araẹni kúrò látọ́dọ́ Olúwa nítorí Òun ti múra “ọ̀nà kan” sílẹ̀ tó yàtọ̀ ju ọ̀kan tí a rò?

Bàbá ìyá mi ni a darí sí ibi àìmọ̀—nínú kóòtù kan, lórí òrùlé, níjọ́ ìsinmi kan. Ẹ gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run láti darí yín, àní tí ọ̀nà náà bá yàtọ̀ ju bí ẹ ṣe rò tàbí ó yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn.

Àwọn Ènìyàn Mímọ́ nwá ní onírurú ẹ̀yà àti ìwọn, ṣùgbọ́n “gbogbo wa rí bákannáà sí Ọlọ́run”—“dúdú àti funfun, ẹrú àti òmìnira, ọkùnrin àti obìnrin,” àdáwà àti lọ́kọláya, olówó àti òṣì, ọmọdé àti àgbà, ọmọ ìjọ tipẹ́tipẹ́ àti olùyípada lọ́wọ́lọ́wọ́.13 Ẹni yówù tí ẹ jẹ́ tàbí òhun tí ẹ̀ nbáyí, a pè yín sí tábìlì Olúwa.14

Bí ìwákiri àti ṣíṣe ìfẹ́ ti Bàbá bá di ìrẹ̀lẹ̀ ìgbé ayé yín, bẹ́ẹ̀ni, ẹ ó, gba ìdarí láti yípadà àti láti ronúpìwàdà.

Etò titun Ìjọ fún àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ ngbé ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ ti ìkọ́ni láti wá ìfihàn, ṣíṣe-àwárí ohun tí Olúwa yíò fẹ́ kí a ṣe, àti lẹ́hìnnáà ṣíṣe ìṣe ní ìdarí náà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa, láìka ọjọ́ orí tàbí ipò sí lè tiraka láti wákiri, gbà, àti láti ṣe ìṣe. Bí ẹ ṣe ntẹ̀lé àwòṣe ayérayé yí fún yín ní ọjọ́ wa, ẹ ó súnmọ́ Jésù Krístì—ìfẹ́ Rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀, ìdarí Rẹ̀, àláfíà Rẹ̀, àti ìwòsàn Rẹ̀ àti níní agbára. Ẹ o ní àlékún okun ti ẹ̀mí láti di ohun èlò ojoojúmọ́ ní ọwọ́ Rẹ̀ ní ṣíṣe àṣeyege iṣẹ́ nlá Rẹ̀. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. David A. Bednar, in Face to Face with Elder and Sister Bednar (worldwide youth broadcast, May 12, 2015), facetoface.ChurchofJesusChrist.org; see also Moroni 7:16.

  2. Russell M. Nelson, “Revelation for the Church, Revelation for Our Lives,” Liahona, May 2018, 96; emphasis added.

  3. Teachings of Presidents of the Church: Joseph Smith (2007), 121.

  4. Russell M. Nelson, “Revelation for the Church, Revelation for Our Lives,” 94.

  5. Henry B. Eyring, in “President Eyring 1990s,” Deseret News, Apr. 2, 2009, deseretnews.com.

  6. Wo Mark 2:1-12.

  7. Alma 22:4; ìtẹnumọ́ àfikún.

  8. 1 Néfì 18:1.

  9. Wo Ether 6:5–8.

  10. Exodus 14:29.

  11. Néfì 3:7.

  12. 2 Nephi 26:33.

  13. Wo Quentin L. Cook, “The Eternal Everyday,” Liahona, Nov. 2017, 51.