Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Gba Ọjọ́ Ọ̀la Mú Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2020


Gba Ọjọ́ Ọ̀la Mú Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́

Ọjọ́ ọ̀la yíò jẹ́ ológo fún àwọn ẹni tí ó múrasílẹ̀ tí ó sì tẹ̀síwájú láti múrasílẹ̀ láti jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Olúwa.

Èyí ti jẹ́ ìrọ̀lẹ́ àìlègbàgbé. Ẹ̀yin arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ó jẹ́ iyì láti wà pẹ̀lú yín. Ẹ ti wà lọ́kàn mi gidi léraléra ni àwọn oṣù díẹ̀ tó kẹ́hìn wọ̀nyí. Ẹ lagbára ju mílíọ́nù mẹ́jọ lọ. Ẹ kìí ṣe àwọn nọ́mbà nìkan ṣùgbọ́n agbára ti ẹ̀mí láti yí ayé padà. Mo ti wò yín ẹ̀ nṣe bẹ́ẹ̀ gan lákoko àjàkálé-àrùn yí.

Àwọn kan lára yín rí ara yín tí ẹ̀ nwá ìpèsè wíwọ́n tàbí iṣẹ́ titun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkọ́ àwọn ọmọ wọ́n sì mbẹ àwọn aladugbo wo. Àwọn kan kí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere káàbọ̀ sí ilé wọn ju bí a ti retí, nígbàtí àwọn míràn yí ilé wọn po sí Gbàgede Idanilẹkọ Ìránṣẹ́ Ìhìnrere. Ẹ ti lo ẹ̀rọ láti sopọ̀ pẹ̀lú ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́, ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn tí ó ní ìmọ́lára ìpatì, àti láti ṣe àṣàrò Wa, Tẹ̀lé Mi pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ẹ ti rí àwọn ọ̀nà titun láti mú Ọjọ́-ìsinmi jẹ́ alárinrin. Ẹ sì ti ṣe àwọn ìbòjú ààbò—fún àwọn mílíọ̀nù lára wọn!

Pẹ̀lù àánú ọkàn àti ìfẹ́ àtinúwá, ọkàn mi lọ sọ́dọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin káàkiri ayé tí àwọn olólùfẹ́ wọn ti kú. A sọkún pẹ̀lú yín. À ngbàdúrà fún yín. A yìn a sì gbàdúrà fún gbogbo ẹni tó ṣiṣẹ́ láìṣàárẹ̀ láti dá ààbò bò ìlera àwọn ẹlòmíràn.

Ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin bákannáà tí jẹ́ alápẹrẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròhìn àwùjọ ti kún fún ìjà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín ti rí àwọn ọ̀nà láti gba àwọn míràn ní ìyànjú àti láti pín ìmọ́lẹ̀ Olùgbàlà.

Ẹ̀yin arábìnrin, gbogbo yín ti jẹ̀ akọni pátápátá! Okun àti ìgbàgbọ́ yín yà mí lẹ́nu. Ẹ ti fihàn pé nínú àwọn ipò ìṣòrò, ẹ lè fì ìgboyà tẹ̀ síwájú. Mo nifẹ́ yín, mo sì fì dá yín lójú pé Olúwa nifẹ yín Ó sì rí àwọn iṣẹ́ nlá ti ẹ̀ nṣe. Ẹ ṣeun! Lẹ́ẹ̀kan si, ẹ ti fihàn pé ẹ̀yin ni ìrètí Isráẹ́lì gangan!

Ẹ jẹ́ àwọn ara ìrètí tí Ààrẹ B. Hinckley ní fún yín nígbàtí ó gbé “Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí Àgbàyé” ọdún mẹẹdọ́gbọ̀n sẹ́hìn ní Oṣù Kẹsan 1995 ní ìpàdé Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ Gbogbogbò. 1 Ó ṣe kókó péó yàn láti fi ìkède pàtàkì yí hàn sí ẹ̀yin obìnrin Ìjọ. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Ààrẹ Hinckley dín agbára àìlèrọ́pò ti àwọn obìnrin kù nínú ètò Olúwa.

Nísisìyí, èmi yíò fẹ́ láti mọ ohun tí ẹ ti kọ́ ní ọdún yí. Ṣe ẹ ti dàgbà súnmọ́ Olúwa si, tàbí ṣe ẹ ní ìmọ̀lára kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀ si? Àti pé báwo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ṣe mú yín ní ìmọ̀lára nípa ọjọ́-ọ̀là?

Ní gbígbà mọ́ra, Olúwa ti sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ wa nínú àwọn ọ̀ràn ìwà-pẹ̀sẹ̀. Ó kìlọ̀ pé ní ọjọ́ wa “àyà àwọn ènìyàn [yíò má já]” 2 àti pé àní àwọn tí àyànfẹ́ gan yíò wà nìnù ewu ìtànjẹ. 3 Ó wí fún Wòlíì Joseph Smith pé “a [o] mú àláfíà kúrò ní ilẹ̀-ayé” 4 àti pé àwọn àjálù yíò wó lù àwọn ènìyàn. 5

Síbẹ̀ Olúwa bákannáà ti pèsè ìran kan nípa bí àkokò ìrírí yí ti lápẹrẹ tó. Ó wí fún Wòlíì Joseph Smith pé “iṣẹ́ … àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí, ni ọ̀kan lára àwọn ìgbòòrò títóbi. … Àwọn ògo rẹ̀ jẹ́ ìjúwe tẹ́lẹ̀rí, àti pé ó jẹ́ ọlánlá tí kò láfiwé.” 6

Nísisìyí, ọlánlá lè má tilẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ẹ ó yàn láti júwe àwọn oṣù díẹ̀ tó kẹ́hìn wọ̀nyí! Báwo ni a ó ṣe ṣe pẹ̀lú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìwà-pẹ̀lẹ́ àti kíkéde ológo náà nípa ọjọ́ wa? Olúwa sọ fún wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn, ṣùgbọ́n ìdánilójú, yíyanilẹ́nu: “Bí ẹ bá múrasílẹ̀ ẹ kò ní bẹ̀rù.” 7

Irú ìlérí kan Ó jẹ́ ọ̀kan tí ó lè yí ọ̀nà bí a tí rí ọjọ́-ọ̀la wa padà. Láìpẹ́ mo gbọ́ tí obìnrin kan tí ó ní ẹ̀rí ìjìnlẹ̀ gba pé àjàkálẹ̀àrùn, pẹ̀lú ìsẹ́lẹ̀ kan ní Àfonífojì Salt Lake, ti ràn án lọ́wọ́ láti damọ̀ pé òun kò múrasílẹ̀ bí ó ti rò pé òun jẹ́. Nígbàtí mo bèère bóyá ó ntọ́ka sí ìkópamọ́ oúnjẹ rẹ̀ tàbí ẹ̀rí rẹ̀, ó rẹrin ó sì wípé, “Bẹ́ẹ̀ni!”

Bí ìmúrasílẹ̀ bá jẹ́ kókó sí gbígba àkokò iṣẹ́ ìríjú mọ́ra àti ọjọ́-ọ̀la wa pẹ̀lú ìgbàgbọ́, báwo ni a ṣe lè múrasílẹ̀ dáadáa jùlọ?

Fún àwọn díkédì, Àwọn wòlíì Olúwa ti rọ̀ wá láti kó oúnjẹ, omi, àti owó ìfipamọ́ fún ìgbà àìní kan. Àjàkálẹ̀ àrùn lọ́wọ́lọ́wọ́ ti tún agbára ọgbọ́n àmọ̀ràn náà ṣe. Mo rọ̀ yín láti gbé ìgbésẹ̀ láti múrasílẹ̀ ránpẹ́. Ṣùgbọ́n àní mo ní àníyàn si nípa ìmúrasílẹ̀ ti ẹ̀mí àti ẹ̀dùn ọkàn yín.

Nínú ìkàsí náà, a lè kẹkọ púpọ̀ látọ̀dọ̀ Ọ̀gágun Mórónì. Bí adarí ogun àwọn ará Néfì, ó dojúkọ àwọn agbára àtakò tí ó lè jù, tí ó pọ ní nọ́mbà, àti ní bíburú. Nítorínáà, Mórónì múra àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ ní àwọn ọ̀nà mẹ́tà pàtàkì.

Àkọ́kọ́, ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dá àwọn agbègbe níbití wọ́n yíò wà láìléwu sílẹ̀—“àwọn ibi ààbò” ni óun pè wọ́n. 8 Èkejì, ó múra “ọkàn àwọn ènìyàn sílẹ̀ láti jẹ́ olotitọ sí Olúwa.” 9 Àti ẹ̀kẹ́ta, kò dúró rára ní mímúra àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀—niti ara àti niti ẹ̀mí. 10 Ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ mẹ́ta wọ̀nyí yẹ̀wò.

Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Nọ́mba Ìkínní: Dá àwọn Ibi Ààbò Sílẹ̀.

Moroni ṣe ìgbáradì gbogbo ìlú-nlá àwọn ará Néfì pẹ̀lú etí bèbè, odi, àti ògiri. 11 Nígbàtí àwọn ará Lámánì wá takò wọ́n, ó “yà wọ́n lẹ́nu gidigidi, nítorí ọgbọ́n àwọn ará Néfì ní mímúra àwọn ibi ààbo wọn sílẹ̀. 12

Bẹ́ẹ̀náà, bí wàhálà ṣe nja yíká wa, a nílò láti dá ibi ààbò sílẹ̀ níbití a ó ti wà láìléwu, níti ara àti níti ẹ̀mí papọ̀. Nígbàtí ilé yín bá di ibi-mímọ́ araẹni ti ìgbàgbọ́—níbití Ẹ̀mí ngbé—ilé yín ndi ìlà àkọ́kọ́ ti ààbò.

Bákannáà,àwọn èèkàn Síónì jẹ́ “ààbò kúró nínú ìjì” 13 nítorí à ndarí wọn nípasẹ̀ àwọn tí ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà mú tí wọ́n sì nlo àṣẹ oyè-àlùfáà. Bí ẹ ṣe ntẹ̀síwájú láti tẹ̀lé àmọ̀ràn àwọn tí Olúwa páṣẹ fún láti tọ́ yín sọ́nà, ẹ ó ní ìmọ̀lára ààbò títóbi jùlọ.

Tẹ̀mpìlì—ilé Olúwa—ni ibi ààbò yàtọ̀ sí òmíràn. Níbẹ̀, ẹ̀yin arábìnrin gba ẹ̀bùn pẹ̀lú agbára oyè-àlùfáà nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú mímọ́ oyè-àlùfáà tí ẹ ṣe. Níbẹ̀ àwọn ẹbí yín ṣe èdidì fún ayé àìlópin. Àní ní ọdún yí, nígbàtí ààyè sí àwọn tẹ́mpìlì wa tí dínkù líle si, agbára ẹ̀bùn yín ti fún yín ní ààyè sí agbára Ọlọ́run bí ẹ ti bu-ọlá fún àwọn májẹ̀mú yín pẹ̀lú Rẹ̀.

Kí a sọ jẹ́jẹ́ pe, ibi ààbò ni ibikíbi tí ẹ ti lè ní ìmọ̀lára lọ́dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ àti ní ìtọ́nisọ́nà nípasẹ̀ Rẹ̀. Nígbàtí Ẹ̀mí Mímọ́ bá wà pẹ̀lú yín, ẹ lè kọ́ òtítọ́, àní nígbàtí ó ba tako àwọn èrò tó nlọ lọ́wọ́. Ẹ ó sì lè jíròrò àwọn ìbèèrè àtinúwá nípa ìhìnrere nínú ayíká ti ìfihàn kan.

Mo pè yín, ẹ̀yin arábìnrin mi ọ̀wọ́n, láti dá ilé tí ó jẹ́ ibi ààbò kan sílẹ̀. Mo si tún ìpè mi sọ fún yín láti mú ìmọ̀ yín nípa agbára oye-àlùfáà pọ̀ si àti nípa àwọn májẹ̀mù tẹ́mpìlì àti ibùkún Níní àwọn ibi ààbò sí èyí tí ẹ lè padàsí yíò ràn yín lọ́wọ́ láti gba ọjọ́-ọ̀la mọ́ra pẹ̀lú ìgbàgbọ́.

Ẹ̀kọ́ Ìpìnlẹ̀ Nọmba Ìkejì: Ẹ Múra Ọkàn Yín Sílẹ̀ láti Jẹ́ Olotitọ sí Ọlọ́run.

A ti ṣe iṣẹ́ kókó kan láti mú ayé àti agbára Tẹ́mpìlì Salt Lake gbòòrò si.

Àwòrán
Kíkọ́ Tẹ́mpìlì Salt Lake

Àwọn kan bèèrè ìnílò fún ṣíṣe irú àwọn ìwọ̀n ju bí ó ti yẹ lọ. Síbẹ̀síbẹ̀, nígbàtí Àfonífojì Salt Lake jìyà ìwárìrì ilẹ̀ 5.7 ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yí, tẹ́mpìlì tó nípalara yí mì tìtì tóbẹ́ẹ̀ tí fèrè orí ère ángẹ́lì Mórónì ṣubú! 16

Àwòrán
Ángẹ́lì Mórónì pẹ̀lú fèrè ṣíṣubú

Gẹ́gẹ́ bí ìpìnlẹ̀ ti Tẹ́mpìlì Salt Lake tí a rí ó gbọ́dọ̀ lé tó láti tako àwọn àjálù àdánidá, àwọn ìpìnlẹ̀ ti ẹ̀mí wa gbọ́dọ̀ le. Lẹ́hìnnáà, nígbàtí àfiwé ìsẹ́lẹ̀ bá nti ìgbé ayé wa, a lè dúró “ṣinṣin àti làìyẹsẹ̀” nítorí ìgbàgbọ́ wa. 17

Olúwa kọ́ wa bí a ó ṣe mú ìgbàgbọ́ wa pọ̀ si nípa ìwákiri “ikẹkọ, àní nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ pẹ̀lú.” 18 À nfún ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì lókun bí a ti npa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ tí a sì “nrántí rẹ̀ nígbàgbogbo.” 19 Síwájúsi, ìgbàgbọ́ wa npọ̀si nígbogbo ìgbà tí a bá lo ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀. Ìyẹn ni ohun tí ikẹkọ nípa ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí.

Fún àpẹrẹ, ìgbàkugbà tí a bá ní ìgbàgbọ́ láti gbọ́ràn sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run—àní nígbàtí àwọn èrò olókìkí bá rẹ̀ wá sílẹ̀—tàbí ìgbàkugbà tí a bá kọ ìmúnilárayá tàbí àwọn àgbàrò tí ó nṣe ayẹyẹ jíjá-májẹ̀mú, à n lo ìgbàgbọ́ wa, èyí tí yíò mú ìgbàgbọ́ wa pọ̀ si.

Síwájú si, àwọn ohun díẹ̀ ní ó ngbé ìgbàgbọ́ ga ju bí ríri ara wa sínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì déédé ti ṣe. Kò sí ìwé míràn tí ó jẹri nípa Jésù Krístì pẹ̀lú irú agbára àti híhàn kedere náà. Àwọn wòlíì ni, bí ìmísí látọwọ́ Olúwa, rí ọjọ́ wa wọ́n sì yan ẹ̀kọ́ àti àwọn òtìtọ̀ tí yíò ràn lọ́wọ́ jùlọ. Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni ìtọ́nisọ́nà ìgbàlà ọjọ́-ìkẹhìn wa.

Bẹ́ẹ̀ni, ààbò ìgbẹ̀hìn wa nwá bí a ti nfún Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì ní àjàgà wa. Ìgbé ayé láìsí Ọlọ́run ni ìgbé ayé tí ó kún fún ẹ̀rù. Ìgbé ayé pẹ̀lú Ọlọ́run ni ìgbé ayé tí ó kún fún àláfíà. Èyí jẹ́ nítorí àwọn ìbùkún ti ẹ̀mí tí ó nwá sọ́dọ̀ olotitọ. Gbígba ìfihàn araẹni ni ọ̀kan lára àwọn ìbùkún tó ga jùlọ.

Olúwa ti ṣèlérí pé bí a bá bèèrè, a lè gba “ìfihàn lórí ìfihàn.” 20 Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ti npọ̀si ní okun láti gba ìfihàn, Olúwa yíò bùkún yín pẹ̀lú ìdarí púpọ̀si fún ìgbé ayé àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn àìlónkà ti ẹ̀mí.

Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Nọmba Ìkẹ́ta: Maṣe Dáwọ́dúró Ní Mímúrasílẹ̀.

Aní nígbàtí àwọn ohunkan bá nlọ dáradára, Ọ̀gágun Mórónì tẹ̀síwájú láti múra àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀. Kò dúró rárá. Kò si di aláròyẹ́ rárá.

Ọ̀tá kò dáwọ́dúró nínú àtakò rárá. Nítorínáà, a kò lè dáwọ́dúró ní mímúràsílẹ̀ rárá! Bí a ti ndi ìgbẹ́kẹ̀lé-araẹni si níti ara, àti ẹ̀dùn-ọkàn, àti ti ẹ̀mí—ni à nmúrasílẹ̀ láti—ti àbùkù àìsimi Sátánì dànù.

Ẹ̀yin arábìnrin ọ̀wọ́n, ẹ̀yin ni ìjìnlẹ̀ ti dídasílẹ̀`wọn ibi ààbò fún ara yín àti àwọn tí ẹ nifẹ. Síwájú si, ẹ ní agbára ẹ̀bùn àtọ̀runwá tí ó fàyè gbà yín láti gbé ìgbàgbọ́ yín ga nínú àwọn ẹlòmíràn ní àwọn ọ̀nà iyàn. 21 Àti pé ẹ kò ní dáwọ́dúró rárá. Ẹ ti júwe iyẹn lẹ́ẹ̀kansi ní ọdún yí.

Ẹ jọ̀wọ́, ẹ tẹramọ́ lílọ síwájú! Ìfojúsílẹ̀ yín ní dídáààbò bo ilé yín àti fífi ìgbàgbọ́ sínú ọkàn àwọn tí a fẹ́ràn yíò kórè èrè fún ìràndíran tó mbọ̀.

Ẹ̀yin arábìnrin mi ọ̀wọ́n, a ni púpọ̀ gidi láti dojúkọ ìwájú sí! Olúwa gbé yín sihin nísisìyí nítorí Ó mọ̀ pé ẹ ní okun láti dúna àwọn ìdíjú líle ìkẹhìn ti ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí. Ó mọ́ pé ẹ ó di iṣẹ́ ọlánlá Rẹ̀ mú kí a sì yára láti ṣèrànwọ́ láti mú u wá sí ìmúṣẹ.

Èmi kò sọ wípé àwọn ọjọ́ ìwájú yíò rọrùn, ṣùgbọ́n mo ṣe ìlérí fún yín pé ọjọ́-ọ̀la yíò jẹ́ ológo fún àwọn tí wọ́n bá mùrasílẹ̀ tí wọ́n sì tẹ̀síwájú láti múrasílẹ̀ láti jẹ́ ohun èlò lọ́wọ́ Olúwa.

Ẹ̀yin arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ máṣe jẹ́ kí a ní ìfaradà ní àkokò yí lásán. Ẹ jẹ́ kí a gba ọjọ́-ọ̀la mọ́ra pẹ̀lú ìgbàgbọ́! Àwọn ìgbà ewu jẹ́ ànfàní fún wa láti tiraka níti ẹ̀mí. Wọ́n jẹ́ àwọn ìgbà tí agbára lè wọnú wa púpọ̀ si ju àwọn ìgbà tó rọlẹ̀ jùlọ.

Mo ṣe ìlérí pé bí a ti ndá àwọn ibi ààbò sílẹ̀, tí a nmúra ọkàn wa sílẹ̀ láti jẹ́ olotitọ sí Ọlọ́run, àti kí a máṣe dáwọ́dúró ní mímúrasílẹ̀ rárá, Ọlọ́run yíò bùkún wa. Òun ó “gbà wá là; bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí [yíò] fi àlãfíà fún ọkàn wa, tí [yíò] sì fún wa ní ìgbàgbọ́ nlá, àti … mú kí a [lè] ní ìrètí nínú rẹ̀ fún ìràpadà wa nínú rẹ̀.” 22

Bí ẹ ṣe nmúrasílẹ̀ láti gba ọjọ́-ọ̀la mọ́ra pẹ̀lú Ìgbàgbọ́, àwọn ìlérí wọ̀nyí yíò jẹ́ tiyín! Ní mo jẹri bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú ìfihàn ìfẹ́ mi fún yín àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú yín, ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.