Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ṣùgbọ́n Àwa Kò Kíyèsí Sí Wọn.
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Ṣùgbọ́n Àwa Kò Kíyèsí Sí Wọn.

(1 Néfì 8:33)

Àwọn májẹ̀mú àti ìlànà ntọ́ka wa sí ó sì nrànwálọ́wọ́ nígbàgbogbo láti rántí ìsopọ̀ wa pẹ̀lú Olúwa Jésù Krístì bí a ṣe nlọsíwájú lẹgbẹ ipá-ọ̀nà májẹ̀mú.

Ìyàwó mi, Susan, àwọn ọmọkùnrin wa mẹ́ta àti àwọn ìyàwó wọn, gbogbo àwọn ọmọ-ọmọ wa, àti Quentin L. Cook, ojúgbà-olùjókó mi nínú Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá fún bí ọdún mẹ́ẹ̀dógún, gbogbo wọn yíò ṣetán láti jẹri sí òdodo pé èmi kò lè kọrin dáadáa. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú àìní tálẹ́ntì kíkọrin, mo fẹ́ràn láti kọ àwọn orin ìmúpadàbọ̀sípò. Àpapọ̀ àwọn orin ìmísí ọlọ́lá àti alárinrin nrànmílọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì tí ó sì nrú ọkàn mi sókè.

Orin kan tí ó ti bùkún ayé mi ní àwọn ọ̀nà alámì ni “Ẹ Jẹ́ Kí A Tẹ̀síwájú.” Láìpẹ́ mo ti njíròrò mò sì nkẹkọ nípa àkópọ̀-ọ̀rọ̀ kan nínú ègbè orin náà. “A kò ní gbọ́ ohun tí ẹni búburú kan lè sọ, ṣùgbọ́n Olúwa nìkan ni aó gbọ́ran sí.”1

A kì yíò gbọ́.

Bí mo ti nkọrin “Ẹ Jẹ́ Kí A Tẹ̀síwájú,” mo maa nronú nípa àwọn ènìyàn inú ìran Léhì léraléra tí wọ́n tẹ̀síwájú lórí ipá-ọ̀nà tí ó darí lọ sí ibi igi ìyè tí wọ́n kò “lẹ̀ mọ” lásán2 ṣùgbọ́n tí wọ́n “ntẹ̀síwájú ní dídi ọ̀pá irin mú, títí tí wọn fi wá síwájú tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n sì jẹ èso ti igi náà.”3 Léhì júwe ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn nínú ilé nla àti gbígbòòrò tí wọ́n nna “ọwọ́ ẹ̀gàn sí [i] àti àwọn tí wọ́n … njẹ nínú èso náà.”4 Ìdáhùn Rẹ̀ sí àwọn aruwo àti àrífín tóbi ó sì ní ìrántí: “Ṣùgbọ́n a kò gbọ́ tiwọn.”5

Mo gbàdúrà pé Ẹ̀mí Mímọ́ yíò bùkún àti fòye-hàn sí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bí a ṣe nronú papọ̀ bí a ṣe lè ní okun láti “máṣe gbọ́” àwọn ipa ibi àti àwọn ohùn ẹlẹ́yà ti ayé ìsisìyí nínú èyí tí à ngbé.

Máṣe Gbọ́

Ọ̀rọ̀ náà gbọ́ dá àbá ṣíṣe àkíyèsí sí tàbí fífojúsí ẹnìkan tàbí ohunkan. Báyìí, àwọn ẹsẹ orin “Ẹ Jẹ́ Kí a tẹ̀síwájú” kìlọ̀ fún wa láti ṣe àtẹnumọ́ ìpinnú láti máṣe fojúsí “ohun tí àwọn ìkà lè sọ.” Léhì àti àwọn ènìyàn tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n njẹ́ èso igi náà pèsè àpẹrẹ lìle ti àìfojúsí ṣíṣe-ẹ̀sín àti ẹ̀gàn tí ó nwá léraléra láti ilé nlá àti gbígbòòrò.

Ẹ̀kọ́ Krístì tí a kọ “pẹ̀lú Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè … nínú tábìlì ẹran-ara [ọkàn wa]”6 nmú okun wa láti “máṣe gbọ́” àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdàmú, ìfibú, àti ìyàsápákan nínú ayé ìṣubú wa. Fún àpẹrẹ, ìgbàgbọ́ tí ó dojúkọ inú àti lórí Olúwa Jésù Krístì ndá ààbò bò wá pẹ̀lú agbára ti-ẹ̀mí. Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì jẹ́ ìpìlẹ-ẹ̀kọ́ ti ìṣe àti agbára. Bí a ti nṣe ìṣe ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òtítọ́ ìhiǹrere Rẹ̀, a ó di alábùkúnfún pẹ̀lú agbára ti-ẹ̀mí láti tẹ̀síwájú nínú àwọn ìpènija ti ayé-ikú nígbàtí à ndojúkọ àwọn ayọ̀ tí Olùgbàlà fi fún wa. Nítòótọ́, “bí a bá ṣe ohun tó tọ̀ a kò nílò láti bẹ̀rù, nítorí Olúwa, olùrànlọ́wọ́ wa, yíò wà nítosí títíláé.”7

Ìsopọ̀ Araẹni nípasẹ̀ àwọn Májẹ̀mú

Wíwọnú àwọn májẹ̀mú mímọ́ àti gbígba àwọn ìlànà oyèàlùfáà ní yíyẹ nmú wa ru ẹrù pẹ̀lú ó sì nso wá mọ́ Olúwa Jésù Krístì àti Baba Ọ̀run.8 Èyí kan túmọ̀ sí pé a ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olùgbàlà bí alágbàwí wa9 àti onílàjà10 kí a sì gbaralé èrè, àánú, àti oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀11 nínú ìrìnàjò ìgbé-ayé. Bí a bá dúróṣinṣin ní wíwá sí ọ̀dọ̀ Krístì àti rírẹ̀rù pẹ̀lú Rẹ̀, a gba ìwẹ̀nùmọ́, ìwòsàn, àti fífún àwọn ìbùkún lókun nipa Ètùtù àìlópin àti ayérayé Rẹ̀.12

Gbígbé àti fífẹ́ àwọn ìfarasìn májẹ̀mú ndá ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa tí ó jinlẹ̀ sílẹ̀ níti-ara àti ti-ẹ̀mí alágbára. Bí a ṣe nbu ọlá fún àwọn ipò májẹ̀mú mímọ́ àti ìlànà, à nfà súnmọ́ Ọ díẹ̀díẹ̀ àti ní púpọ̀si13 a sì nrí ìrírí tí ìkọlù àtọ̀runwá rẹ̀ àti gbigbé òdodo nínú ayé wa. Jésù nígbànáà di púpọ̀-púpọ̀ si ju oókan ìwà nínú àwọn ìtàn ìwé-mímọ́; àpẹrẹ àti àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ nfún gbogbo ìfẹ́, èrò, àti ìṣe wa ní ipá.

Lótítọ́ èmi kò ní okun láti júwé ìwà-ẹ̀dá déédé àti agbára májẹ̀mú wa ní ìsopọ̀ pẹ̀lú alààyè Ọmọ Ọlọ́run tó jíìnde. Ṣùgbọ́n mo jẹri pé àwọn ìsopọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ àti Baba Ọ̀run jẹ́ òdodo ó sì jẹ́ ìdánilójú àwọn orìsun ìgbẹ̀hìn, àláfíà, ayọ̀ àti agbára ti-ẹ̀mí tí ó fi ààyè gbà wá láti “máṣe bẹ̀rù, bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ọ̀tá ngbógun.”14 Bí àwọn ọmọẹ̀hìn olùdá-májẹ̀mú àti olùpamọ́-májẹ̀mú Jésù Krìstì, a lè di alábùkúnfún láti gba “ìgboyà, nítorì Olúwa wà ní ọ̀dọ̀ wa”15 kí a má sì dojúkọ àwọn agbára ibi àti ẹ̀kọ́ ẹlẹ́yà.

Bí mo ti ṣèbẹ̀wò pẹ̀lú àwọn ọmọ Ìjọ yíká ayé, mò nbi wọ́n ní ìbèèrè yí léraléra: kíni ohun tí ó nràn yín lọ́wọ́ láti “máṣe gbọ́” àwọn ipá, ìṣẹ̀sín, àti ẹ̀gàn? Àwọn ìdáhùn wọn nkọ̀ni jùlọ.

Àwọn akọni ọmọ ìjọ máa nfàmì sí pàtàkì ti pípé agbára Ẹ̀mí Mímọ́ sínú ayé wọn nípasẹ àṣàrò onìtumọ̀ ìwé-mímọ́, àdúrà taratara, àti im̀urasìlẹ̀ tòtọ́ láti kópa nìnù ìlànà oùnjẹ-Olúwa. Àwọn ohun tí à ndárúkọ léraléra ni àtìlẹhìn ti-ẹ̀mí àwọn ọmọ ẹbí olódodo àti olùgbẹ́kẹ̀lé àwọn ọ̀rẹ́ bákannáà, àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí a kọ́ nípasẹ̀ ṣíṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ àti sísìn nínú Ìjọ àmúpadàbọ̀sípò Olúwa, àti okun láti ní òye òfo pátápátá ti ohunkóhun nínú tàbí wíwá látinú ilé nlá àti gbígbòòrò.

Mo ti ṣe àkíyèsí kókó àwòṣe àwọn ìdáhùn ọmọ ìjọ wọ̀nyí tí ó ṣe pàtàkì. Lakọkọ àti jíjùlọ, àwọn ọmọẹ̀hìn ní àwọn ẹ̀rí tó dúróṣinṣin nípa ètò ìdùnnú Baba Ọ̀run àti ojúṣe ti Jésù Krístì bí Olùràpadà àti Olùgbàlà wa. Àti èkejì, ìmọ̀ àti ìdánilójú ti-ẹ̀mí wọn jẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan, araẹni, àti kókó; wọn kò wọ́pọ̀ wọn kò sì dá wà. Mo fi etísílẹ̀ sí àwọn olùfọkànsìn ẹ̀mí sọ̀rọ̀ nípa pípèsè okun láti borí àtakò àti ìsopọ̀ wọn pẹ̀lú Olúwa alààyè tí ó ntìwọ́n lẹ́hìn nínú àwọn àkokò méjèèjì rere àti búburú. Sí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan wọ̀nyí, Jésù Krístì nítòótọ́ ni Olùgbàlà araẹni kan.

Àwòrán
Atọ́nà kan

Àwọn májẹ̀mú ìhìnrere àti ìlànà nṣiṣẹ́ nínú ayé wa púpọ̀ bí atọ̀nà kan. Atọ́nà kan ni ẹ̀rọ̀ tí a nlò láti fi àwọn kókó ìdarí ti àríwá, gúsù, ìlà-oòrùn, àti ìwọ̀ oòrùn fún àwọn èrèdí ìṣàlàyé àgbáyé àti lílọ-kiri. Ní irú ọ̀nà kànnáà, àwọn májẹ̀mú àti ìlànà tọ́ka wa sí ó sì nrànwálọ́wọ́ nígbàgbogbo láti rántí ìsopọ̀ wa pẹ̀lú Olúwa Jésù Krístì bí a ṣe nlọsíwájú lẹgbẹ ipá-ọ̀nà májẹ̀mú.

Àwòrán
Krístọ́sì náà

Kókó ìdarí fún gbogbo wa nínú ayé-ikú ni láti wá sọ́dọ̀ àti láti di pípé nínú Krístì.16 Àwọn májẹ̀mú àti ìlànà mímọ́ nrànwálọ́wọ́ láti pa ìdojúkọ wa mọ́ lórí Olùgbàlà àti títiraka, pẹ̀lú oore-ọ̀fẹ́,17 láti dà bíi Tirẹ̀. Dájúdájú gidi, “agbára [àìrí] yíò ràn èmí àti ẹ̀yin lọ́wọ́ nínú ìdí ológo ti òtítọ́.”18

Dídi Ọ̀pà Irin Mú Típẹ́-típẹ́

Ìsopọ̀ májẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run àti Jésù Krístì ni ọ̀nà nínú èyí tí a lè gba okun àti agbára láti “máṣe gbọ́.” Ìsopọ̀ yí nfúnni lókun bí a ti ntẹ̀síwájú láti di ọ̀pá irin mú. Ṣùgbọ́n bí àwọn arákùnrin Néfì ti bèèrè, “Kíni ọ̀pá irin tí baba wa rí túmọ̀ sí… ?

“[Néfì] wí fún wọn pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dì í mú, kì yíò ṣègbé láé; bẹ̃ni ìdánwò àti àwọn ọfà iná èṣù kò lè borí wọn sí ìfọ́jù, láti darí wọn kúrò sí ìparun.”19

Jọ̀wọ́ kíyèsíi pé agbára láti kọ àwọn àdánwò àti ina ajónirun ti ọ̀tá ni a ṣe ìlérí sí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tó “dìí mú” sànju kí o kàn “rọ̀ mọ́” ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Pẹ̀lú ìfẹ́, Àpóstélì Jòhannù júwe Jésú Krístì bí Ọ̀rọ̀ náà.20

“Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ náà, àti pé Ọ̀rọ̀ náà sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọ̀rọ̀ náà sì ni Ọlọ́run. …

“Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́hìn rẹ̀ a kò sí dá ohunkan nínú óhun tí a dá. …

Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, ó sì mbá wa gbé, (àwà sì nwo ògo rẹ̀, ògò bí ti ọmọ bíbí kanṣoṣo láti ọ̀dọ̀ Baba wá,) ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.”21

Nítorínáà, ọ̀kan lára àwọn orúkọ Jésù Krístì ni “Ọ̀rọ̀ náà.”22

Ní àfikún, Nkan Ìgbàgbọ́ kẹjọ wípé, “A gbàgbọ́ wípé Bíbélì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run níwọ̀n ìgbà tí a bá ṣe ìtúmọ̀ rẹ̀ ní pípé; a gbàgbọ́ bákannã pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”23

Báyì, àwọn ìkọ́ni Olùgbàlà, bí a ti kọ́sílẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́, bákannáà jẹ́ “ọ̀rọ̀ náà.”

Ẹ jẹ́ kí ndá àbá pé dídi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú wà pẹ̀lú (1) rírántí, bíbuọlá-fún, àti fífún ìsopọ̀ araẹni lókun tí a ní pẹ̀lú Olùgbàlà àti Baba Rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú àti ìlànà ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere, àti (2) pẹ̀lú àdúrà, pẹ̀lú ìtara, àti lémọ́lemọ́ ní lílo àwọn ìwé-mímọ́ àti ìkọ̀ni àwọn wòlíì alààyè àti àwọn àpóstélì bí àwọn orísun dídárajú nípa ìfihàn òtítọ́. Bí a bá so mọ́ tí a sì “dì Olúwa mú típẹ́típẹ́” tí a sì ní-ìyípadà nípa gbígbé ìgbé-ayé ẹ̀kọ́ Rẹ̀,24 mo ṣe ìlérí pé ẹnìkọ̀ọ̀kan àti gbogbo wa yíò di alábùkúnfún láti “dúró ní àwọn ibi mímọ́, a kò sì ní yẹsẹ̀.”25 Bí a bá gbé nínú Krístì, nígbànáà Òun yíò gbé nínú wa yíò sì rìn pẹ̀lú wa .26 Dájúdájú, “ni àwọn ọjọ́ àdánwò àwọn Ènìyàn Mímọ́ rẹ̀ ni yíò dùn nínú, yíò sì mú ìdí òtítọ́ lọsíwájú.”27

Ẹrí

Tẹ̀síwájú Dìí Mú Típẹ́-típẹ́. Máṣe kíyèsí

Mo jẹri pé ìwà-mímọ́ sí àwọn májẹ̀mú àti ìlànà nípa ìmúpadàbọ̀sípò Olùgbàlà nfún wa ni ààyè láti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ Olúwa, láti di Í mú ṣinṣin si bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti láti máṣe gbọ́ àwọn ìfanimọ́ra ti ọ̀tá. Nínú ìjà fún ẹ̀tọ́, njẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yọ idà kan, àní “idà nlá òtítọ́,”28 ní orúkọ mímọ́ Olúwa Jésù Krístì, àmín.