Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìgbàgbọ́ láti Bèèrè àti Nígbànáà kí a Ṣe Ìṣe Ìgbàgbọ́ láti Bèèrè àti Lẹ́hìnnáà láti Ṣe
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Ìgbàgbọ́ láti Bèèrè àti Lẹ́hìnnáà kí a Ṣe Ìṣe

Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì ni kọ́kọ́rọ́ sí gbígba ìfihàn òtítọ́.

Ẹ̀yin olùfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, mo dúpẹ́ fún ànfàní láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú yín ní abala ìrọ̀lẹ́ Sátidé ti ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Nínú ọ̀rọ̀-ìṣaájú sí ìpàdé àpapọ̀ ní òwúrọ̀ yí, Ààrẹ Russell M. Nelson wí pé “ìfihàn mímọ́ fún àwọn ìbèèrè nínú ọkàn yín yíò mú ìpàdé àpapọ̀ yí jẹ́ elérè àti àìlègbàgbè.” Bí ẹ kò bá tíì lépa fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti Ẹmí Mímọ́ láti ràn yín lọ́wọ́ láti gbọ́ ohun tí Olúwa fẹ́ kí ẹ gbọ́ láàrin àwọn ọjọ́ méjì wọ̀nyí, mo pè yín láti ṣe bẹ́ẹ̀ nísisìyí.”1 Mo ti wá ìbùkún náà bí mo ti nmúrasílẹ̀ láti gba ìfihàn fún ìbẹ̀wò pẹ̀lú yín. Àdúrà tọkàntọkàn mi ni pé kí ẹ lè gba ìfihàn náà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Ọ̀nà láti gba ìfihàn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run kò yípadà láti àwọn ọjọ́ Ádámù àti Éfà. Ó ti jẹ́ ọ̀kannáà fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Olúwa láti ìbẹ̀rẹ̀ di ọjọ́ òní. Ó jẹ́ ọ̀kannáà fún ẹ̀yin àti èmi. Ìgbàgbogbo ni a nṣe é nípa lílo ìgbàgbọ́.2

Ọmọdékùnrin Joseph Smith ní ìgbàgbọ́ tí ó tó láti bèèrè ìbèèrè kan lọ́wọ́ Ọlọ́run, ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run yíò dáhùn àìní àtọkànwá rẹ̀. Ìdáhùn náà tí ó wá yí ayé padà. Ó nfẹ́ láti mọ irú ìjọ tí òun ó darapọ̀mọ́ láti ní ìwẹ̀nùmọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ìdáhùn tí ó gbà fún ní ìyànjú láti tẹramọ́ bíbèèrè àwọn ìbẹ̀ẹ̀rè dídára-si àti láti ṣe iṣe lórí ìṣàn títẹ̀síwájú ìfihàn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀.

Ó lè ṣeéṣe kí ìrírí yín rí bákannáà nínú ìpàdé àpapọ̀ yí. Ẹ lè ní àwọn ìbèèrè fún èyí tí ẹ̀ nwá ìdáhùn. Ẹ ní ìgbàgbọ́ tító ó kéréjù láti ní ìrètí pé ẹ ó gba àwọn ìdáhùn látọ̀dọ̀ Olúwa nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀.4 Ẹ kò ní ní ànfàní láti bèèrè síta fún àwọn ìdáhùn látẹnu àwọn olùsọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ẹ lè bèèrè lọ́wọ́ olùfẹ́ni Baba nínú àdúrà.

Mo mọ̀ látinú ìrírí pé àwọn ìdáhùn yíò wá láti bá àwọn àìní yín àti ìmúrasílẹ̀ ẹ̀mí yín mu. Bí ẹ bá nílò ìdáhùn pé ó ṣe pàtàkì sí àláfíà ayérayé yín tàbí ti àwọn ẹlòmíràn, ó dàbí ìdáhùn náà lè wá. Síbẹ̀síbẹ̀ àní nígbànáà, ẹ lè gbà—bí Joseph Smith ti gba—ìdáhùn láti ní sùúrù.5

Bí ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Krístì ti darí sí ọkàn rírọ̀ nípasẹ̀ àwọn abájáde Ètùtù Rẹ̀, ẹ ó lè ní ìmọ̀lára ìṣílétí Ẹ̀mí ní ìdáhùn sí àwọn àdúrà yín. Ìrìrí araẹni mi ni pé ohùn tínrín, kékeré—èyítí ó dájú—hàn kedere ó sì jẹ́ lílóye nínú mi nígbàtí mo ní ìmọ̀lára ayérayé jẹ́jẹ́ àti fífi arasílẹ̀ sí ìfẹ́ Olúwa. Ìmọ̀lára ìrẹ̀lẹ̀ náà ni a lè júwe bí “Kìí ṣe ìfẹ́ mi, ṣùgbọ́n tìrẹ, ni káṣe.”6

Ètò ìfihàn yí ni ìdí tí ẹ fi lè gbọ́ tí àwọn olùsọ̀rọ̀ nkọ́ni ní ohun tí a pè ní ẹ̀kọ́ Krístì nínú ìpàdé àpapọ̀ yí.7 Ìfihàn nwá sọ́dọ̀ wa ní iye ipò èyí tí a bá fi wá láti gba ẹ̀kọ́ Krístì sínú ọkàn wa àti ṣíṣe é nínú ìgbé-ayé wa.

Ẹ rántí pé Néfì kọ́ wa látinú Ìwé ti Mọ́mọ́nì pé ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì ni kọ́kọ́rọ́ sí gbígba àwọn ìfihàn òtítọ́ àti kọ́kọ́rọ́ sí níní ìgbẹ́kẹ̀lé pé à ntẹ̀lé ìdarí Olùgbàlà. Néfi ti kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní àwọn sẹ̀ntúrì ṣíwájú ìbí Jésù Krístì sínú ayé-ikú.

“Àwọn angẹ́lì nsọ̀rọ̀ nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́; nítorí-èyi, wọ́n nsọ àwọn ọ̀rọ̀ Krístì. Nítorí-èyi, mo wí fún yín, ẹ ṣe àpéjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì; nítorí kíyèsĩ i, àwọn ọ̀rọ̀ Krístì yíò sọ fún yín gbogbo àwọn ohun èyí tí ó yẹ kí ẹ ṣe.

“Nítorí-èyi, nísisìyí lẹ́hìn tí mo ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, bí òye wọn kò bá yé e yín yíò jẹ́ nítorí pé ẹ̀yin kò bèrè, bẹ̃ni ẹ̀yin kò kànkùn; nítorí-èyi, a kò mú yín wá sínú ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò lè ṣe aiparun nínú òkùnkùn.

“Nítorí kíyèsĩ i, mo tun wí fún yín pé bí ẹ̀yin yíò bá wọlé nípasẹ̀ ọ̀nà nã, kí ẹ sì gba Ẹ̀mí Mímọ́, òun yíò fi gbogbo àwọn ohun hàn sí yin èyí tí ó yẹ kí ẹ sẹ.

“Kíyèsĩ i, èyí ni ẹ̀kọ́ Krístì, kì yíò sì sí ẹ̀kọ́ sí i tí a ó fi fún ni títí di lẹ́hìn tí òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí yín nínú ara. Nígbàtí òun yíò sì fi ara rẹ̀ hàn sí yín nínú ara, àwọn ohun èyí tí òun yíò sọ fún yín ni ẹ̀yin yíò ṣọ́ láti ṣe.”8

Olúwa yíò sọ àwọn nkan nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ sí wa ní òní àti ní àwọn ọjọ́ iwájú. Òun yíò sọ àwọn ohun tí a níláti ṣe.9 Olùgbàlà kò ní kígbe àwọn àṣẹ sí ẹ̀yin àti èmi. Bí Ó ti kọ́ Èlíjàh:

“Ó sì wípé, Jáde lọ, kí o sì dúró lórí òkè níwájú Olúwa. Sì kíyèsi, Olúwa kọjá, ìjì nlá àti lílè si fa àwọn òkè ya, ó sì lọ àwọn òkúta tútú níwájú Olúwa, ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú ìjì náà: àti lẹ́hìn ìjì náà ìṣẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínu ìṣẹ́lẹ̀ náà:

“Àti lẹ́hìn ìsẹ́lẹ̀ náà, iná; ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú iná náà: àti lẹ́hìn iná náà, ohùn kẹ́lẹ́ kékeré.”10

Gbígbọ́ ohùn náà yíò wá látinú ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tító, a ó bèèrè fún ìdarí pẹ̀lú èrò-inú láti lọ àti láti ṣe ohunkóhun tí Òun bèèrè. A ó gbèrú ìgbágbọ́ láti mọ̀ pé ohunkóhun tí Ó bá bèèrè yíò bùkún àwọn ẹlòmíràn a sì lè yàwá sí mímọ́ nínú ètò náà nítorí ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa.

Bí ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì ìbá ti darí wa láti bèèrè lọ́wọ́ Baba fún ìdáhùn, bákannáà ìgbàgbọ́ náà ìbá ti mú ìfọwọ́tọ́ rírọ̀ Olùgbàlà tító fún wa láti gbọ́ ìdarí Rẹ̀ àti láti gba ìpinnu àti inúdídùn láti gbọ́ran. Àwa lẹ́hìnnáà yíò kọ àwọn ọ̀rọ̀ orin pẹ̀lú ayọ̀, àní nígbàtí iṣẹ́ náà bá le: “Dídùn ni iṣẹ́ náà, Ọlọ́run mi, Ọba mi.”12

Bí a ti nní ẹ̀kọ́ Krístì si nínú ayé àti ọkàn wa, ni a ó ní ìmọ̀lára ìfẹ́ títóbijù àti ìkááánú si fún àwọn tí wọn kò ní ìbùkún ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì rí tàbí nlàkàkà láti mu un dúró. Ó le láti pa àwọn òfin Olúwa mọ́ láìsí ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀. Bí àwọn kan ti sọ ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà nù, àní wọ́n lè tako àmọ̀ràn Rẹ̀, ní pípe rere ní ibi àti ibi ní rere.13 Láti yẹra fún àṣìṣe yí, ó ṣe kókó pé ìfihàn araẹni nípa èrò àti ìṣe wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìkọ́ni Olúwa àti àwọn wòlíì Rẹ̀.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ó gba ìgbàgbọ́ láti gbọ́ran sí àwọn òfin Olúwa. Ó gba ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì láti sin àwọn míràn fún Un. Ó gba ìgbàgbọ́ láti jáde lọ kọ́ ìhìnrere Rẹ̀ àti láti fi fún àwọn ènìyàn tí wọ́n kò ní ìmọ̀làra ohùn Ẹ̀mí àní tí wọn sì lè sẹ́ òdodo ọ̀rọ̀ náà. Ṣùgbọ́n bí a ti nlo ìgbàgbọ́ wa nínú Krístì—tí a sì ntẹ̀lé wòlíì alààyè Rẹ̀—ìgbàgbọ́ npọ̀si káàkiri àgbáyé. Nítorí ẹ̀rọ̀-ìgbàlódé, bóyá púpọ̀si àwọn ọmọ Ọlọ́run yíò gbọ́ kí wọ́n sì dá ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ̀ ní òpin-ọ̀sẹ̀ yí ju àwọn ọjọ́ méjì ìgbà míràn kankan lọ nínú àkọsílẹ̀-ìtàn.

Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí npọ̀ si pé èyí ni Ìjọ Olúwa àti ìjọba lórí ilẹ̀-ayé, àwọn ọmọ ìjọ npọ̀ si ní sísan idamẹwa àti dídáwó láti ti àwọn tí wọ́n wà nínú àìní lẹ́hìn, àní bí àwọn ọmọ-ìjọ ṣe ndojúkọ ìdánwò ara wọn. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé a pè wọ́n nípasẹ̀ Jésù Krístì, àwọn òjíṣẹ́-ìránṣẹ́ káàkiri àgbáyé ti rí àwọn ọ̀nà láti dìde kọjá àwọn ìpènijà tí a dá sílẹ̀ nípasẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn—ṣíṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìgboyà àti títúká. Àti nínú ìtiraka lílési, ìgbàgbọ́ wọn ti dàgbà púpọ̀si.

Àtakò àti àwọn ìdánwò ti jẹ́ ìtẹ́lẹ̀ fún ìdàgbà ìgbàgbọ́ tipẹ́tipẹ́. Ìyẹn ti jẹ́ òtítọ́ nígbàgbogbo, nípàtàkì látìgbà ìbẹ̀rẹ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò àti dídásílẹ̀ Ìjọ Olúwa.14

Ohun tí Ààrẹ George Q. Cannon sọ nígbà pípẹ́ sẹ́hìn jẹ́ òtítọ́ loni yíò sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ títí Olùgbàlà ó dé fúnrarẹ̀ láti darí Ìjọ Rẹ̀ àti àwọn ènìyàn Rẹ̀: “Ìgbọràn sí ìhìnrere nmú [àwọn ènìyàn] wá sí ìbáṣepọ̀ gidi àti sísúnmọ́ pẹ̀lú Olúwa. Ó gbé ìsopọ̀ sísúnmọ́ ní àárín àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀-ayé àti Aṣẹ̀dá Nlá wa ní Àwọn ọ̀run. Ó nmú ìmọ̀lára ìgbẹ́kẹ̀lé pípé nínú Olódùmarè sínú ẹlẹ́ran-ara àti nínú fífẹ́ Rẹ̀ láti fetísílẹ̀ sí àti láti dáhùn ìbẹ̀bẹ̀ àwọn tí wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀. Ní àwọn ìgbà ìdánwò àti ìṣòro ìgbẹ́kẹ̀lé yí kọjá iye. Ìdààmú lè wá sórí ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí àwọn ènìyàn, àjálù lè dẹ́rùba kí ìrètí gbogbo ẹlẹ́ran-ara sì dàbí ó dànù, síbẹ̀, níbití [àwọn ènìyàn] ti nmú arawọn ní ànfàní èyí tí ìgbọràn sí Ìhìnrere nmú wá, wọ́n lè ní ibi dídúró dídájú; ẹsẹ̀ wọn wà lórí àpáta tí a kò lè ṣí nidi.”15

Ó jẹ́ ẹ̀rí mi pé àpáta tí a dúró lé lórí ni ẹ̀ri wa pé Jésù ni Krístì; pé èyí ni Ìjọ Rẹ̀, èyítí ó ndarí Fúnrà rẹ̀, àti pé Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì alààyè Rẹ̀ loni.

Ààrẹ Nelson nwá ó sì ngba ìdarí látọ̀dọ̀ Olúwa. Ó jẹ́ àpẹrẹ ti wíwá ìdarí náà pẹ̀lú ìpinnu láti tẹ̀le e. Irú ìpinnu kannáà láti gbọ́ran sí ìdarí Olúwa wà ní ọkàn gbogbo àwọn tí wọ́n ti sọ̀rọ̀ tàbí tí yíò sọrọ̀, gbàdúrà, tàbí kọrin nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ti Ìjọ Rẹ̀.

Mo gbàdúrà pé káàkiri ilẹ̀-ayé tí wọ́n nwo tàbí nfi etísílẹ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ yí yíò ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Olúwa fún wọn. Baba Ọ̀run ti dáhùn àdúrà mi pé èmi lè ní ìmọ̀ ó kéréjù ara tíntín ìfẹ́ Olùgbàlà fún yín àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún Baba Rẹ̀ Ọ̀run, ẹnití ó jẹ́ Baba wa Ọ̀run.

Mo jẹ̀rí pé Jésù Krístì wà láàyè. Òun ni Olùgbàlà wa àti Olùràpadà wa. Èyí ni Ìjọ Rẹ̀. Òun wà ní orí rẹ̀. Òun, pẹ̀lú Baba Rẹ̀ Ọ̀run, farahàn níti-ara sí Joseph Smith nínú igbó-ṣúúrú ti àwọn igi ní New York. Ìhìnrere Jésù Krístì àti oyèàlùfáà Rẹ̀ ni a múpadàbọ̀sípò nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ tọ̀run.16 Nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́, mo mọ̀ pé èyí jẹ́ òtítọ́.

Mo gbàdúrà pé kí ẹ lè ní irú ẹ̀rí kannáà. Mo gbàdúrà pé ẹ̀yin yíò bèèrè lọ́wọ́ Baba Ọ̀run fún ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì tí ẹ nílò láti ṣe àti láti pa àwọn májẹ̀mú tí yíò fi ààyè gba Ẹ̀mí Mímọ́ láti jẹ́ ojúgbà yín léraléra. Mo fi ìfẹ́ mi àti ẹ̀rí mi dídájú sílẹ̀ pẹ̀lú yín ni orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.