Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Wíwàásù Ìhìnrere Àlàáfíà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


Wíwàásù Ìhìnrere Àlàáfíà

A ní ojúṣe mímọ́ náà láti pín agbára àti àlàáfíà Jésù Krístì pẹ̀lú gbogbo ẹnití ó bá fetísílẹ̀ tí wọ́n sì jẹ́kí Ọlọ́run Borí nínú ìgbé ayé wọn.

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ káàbọ̀ sí ìpàdé gbogbogbò! Mo ti wo iwájú sí ọjọ́ yí pẹ̀lú ìfojúsọ́nà nlá. Mo ngbàdúrà nípa yín àti fún yín lójojúmọ́. Mo ti gbàdúrà bákannáà pé kí ìpàdé àpapọ̀ yi jẹ́ àkókò ìsọdọ̀tun ti ẹ̀mí fún ẹni kọ̀ọ̀kan yín.

Láti ìgbà ìpàdé àpapọ̀ tó kọjá, àwọn ìṣoro inú ayé tẹ̀síwájú. Àjàkálẹ̀ àrùn káríayé ṣì nyọ ìgbé ayé wa lẹ́nu síbẹ̀. Àti nísisìyí ayé ti di mímì tìtì nípa ìjà kan tí ó nrọ̀jò ẹ̀rù sí orí mílíọ́nù àwọn aláìṣẹ̀ ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé.

Àwọn wòlíì ti rí ọjọ́ wa ṣaájú, nígbàtí àwọn ogun àti àwọn ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun yío wà tí gbogbo ilẹ̀ ayé yío sì wà nínú ìdàrúdàpọ̀.1 Àwa bí atẹ̀lé Jésù Krístì, bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú àwọn olórí ní àwọn orílẹ̀ èdè láti wá ìyanjú pẹ̀lú-àláfíà sí àwọn aáwọ̀ wọn. A pè àwọn ènìyàn níbi gbogbo láti gbàdúrà fún àwọn tí wọ́n wà nínú àìní, láti ṣe ohun tí wọ́n bá le ṣe láti ran àwọn tí wọ́n ní ìbànújẹ́ lọ́wọ́, àti láti wá ìrànlọ́wọ́ Olúwa ní fífi òpin sí àwọn ìjà nlá.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ìhìnrere Jésù Krístì kò tíì jẹ́ nínílò rí láé ju bí ó ti jẹ́ ní òní. Èdè àìyédè ntako ohun gbogbo tí Olùgbàlà dúró fún àti tí ó kọ́ni. Mo fẹ́ràn Olúwa Jésù Krístì mo sì jẹ́ri pé ìhìnrere Rẹ̀ ni ojútùú pípẹ́títí kanṣoṣo fún àlàáfíà. Ìhinrere Rẹ̀ jẹ́ ìhìnrere àlàáfíà.2

Ìhìnrere Rẹ̀ jẹ́ ìdáhùn kanṣoṣo nígbàtí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ayé bá ní ìyàlẹ́nu pẹ̀lú ìbẹ̀rù.3 Èyí ṣe àmì sí nínílò kíakía fún wa láti tẹ̀lé ìkọ́ni Olúwa sí àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ láti “lọ …sí gbogbo ayé, kí wọ́n sì wàásù ìhìnrere sí gbogbo ẹ̀dá.”4 A ní ojúṣe mímọ́ láti pín agbára àti àlàáfíà Jésù Krístì pẹ̀lú gbogbo ẹnití ó bá fetísílẹ̀ tí wọ́n sì jẹ́kí Ọlọ́run Borí nínú ìgbé ayé wọn.

Olukúlùkù ènìyàn tí ó ti dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run ti ṣe ìlérí láti tọ́jú àwọn ẹlòmíràn kí wọn ó sì sin àwọn tí wọ́n wà nínú àìní. A le ṣe àfihàn ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kí a sì ṣetán nígbà gbogbo láti fèsì sí àwọn ẹnití ó bá bèèrè nípa “ìrètí tí ó wà nínú [wa].”5 Olukúlùkù wa ní ipa láti ṣe nínú kíkójọ Ísráẹ́lì.

Lóni mo tún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ tó lágbára ṣe pé Olúwa ti pe gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin tó yẹ, tó ní okun láti múra fún sísìn ní míṣọ̀n kan. Fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, iṣẹ́ ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere jẹ́ ojúṣe òyè àlùfáà. Ẹyin ọ̀dọ́mọkùnrin ni a ti pa mọ́ fún àkokò yí nígbàtí kíkójọ Ísráẹ́lì tí a ti ṣèlérí nwáyé. Bí ẹ ti nsìn ní àwọn míṣọ̀n, ẹ nkó ipa tí ó ṣe kókó nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò sí irú rẹ̀ rí yìí!

Fún ẹ̀yin ọ̀dọ́ àti àwọn arábìnrin tí ó ní okun, iṣẹ́ ìránṣẹ́ bákannáà ni ànfààní tó lágbára kan, ṣùgbọ́n bí ó bá, wuni. A fẹ́ràn àwọn arábìnrin ìránṣẹ́ ìhìnrere a sì kí wọn káàbọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn. Ohun tí ẹ fi lọ́wọ́ sí iṣẹ́ yi tobi púpọ̀! Ẹ gbàdúrà láti mọ̀ bí Olúwa bá fẹ́ kí ẹ sìn ní míṣọ̀n kan, Ẹ̀mí Mímọ́ yío sì fèsì sí ọkàn àti iyè yín.

Ẹyin ọ̀dọ́ ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, olukúlùkù yín ṣe pàtàkì sí Olúwa. Ó ti fi yín sínú ìpamọ́ títí di ìsisìyí láti ṣèrànwọ́ kó Ísráẹ́lì jọ. Ìpinnu yín láti sìn ní míṣọ̀n kan, bóyá ti ìkéde ìhìnrere tàbí ti iṣẹ́ ìsìn, yío bùkún yín àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Bákannáà a gba àwọn àgbà tọkọ-taya láàyè láti sìn nígbàtí àwọn ipò bá fi ààyè gbà. Ní ìrọ̀rùn àwọn aápọn wọn jẹ́ àìlerọ́pò.

Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere nkọ́ni wọ́n sì njẹ́ri nípa Olùgbàlà. Òkùnkùn ti ẹ̀mí nínú ayé nmú ìmọ́lẹ̀ Jésù Krístì di nínílò àní ní ọ̀pọ̀ síi. Gbogbo ènìyàn ní ẹ̀tọ́ sí ànfààní láti mọ̀ nípa ìhìnrere Jésù Krístì tí a múpadà bọ̀sípò. Olukúlùkù ènìyàn ní ẹ̀tọ́ láti mọ ibití wọ́n ti le rí ìrètí àti àlàáfíà tí ó “[tayọ] gbogbo òye.”6

Njẹ́ kí ìpàdé àpapọ̀ yí le jẹ́ àkókò àlàáfíà àti àpèjẹ ti ẹ̀mí fún yín. Njẹ́ kí ẹ wákiri kí ẹ sì rí ìfihàn araẹni ní àkókò àwọn abala wọ̀nyí, ni mo gbàdúrà ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.